< Isaiah 28 >

1 Ègbé ni fún adé ìgbéraga, fún àwọn ọ̀mùtí Efraimu, àti fún ìtànná rírọ, ẹwà ògo rẹ̀, tí ó tò sí orí àfonífojì ẹlẹ́tù lójú àti sí ìlú náà ìgbéraga àwọn tí ọtí wáìnì ń pa tí a rẹ̀ sílẹ̀.
Woe to the crown of pride of the drunkards of Ephraim, and to the fading flower of his glorious beauty, which is on the head of the fertile valley of those who are overcome with wine!
2 Kíyèsi i, Olúwa ní ẹnìkan tí ó le, tí ó sì lágbára, gẹ́gẹ́ bí ọ̀wọ́ yìnyín àti bí ìjì apanirun, gẹ́gẹ́ bí àrọ̀dá òjò àti òjò tí ó mú ìkún omi wá, òun yóò fi tipátipá sọ ọ́ sílẹ̀.
Behold, the Lord has one who is mighty and strong. Like a storm of hail, a destroying storm, and like a storm of mighty waters overflowing, he will cast them down to the earth with his hand.
3 Adé ìgbéraga àwọn ọ̀mùtí Efraimu, ni a ó fi ẹsẹ̀ tẹ̀ mọ́lẹ̀.
The crown of pride of the drunkards of Ephraim will be trodden under foot.
4 Òdòdó tí ó ń rọ náà tí í ṣe ẹwà ògo rẹ̀, tí ó tò sí orí àfonífojì ẹlẹ́tù lójú, yóò dàbí èso ọ̀pọ̀tọ́ tí ó pọ́n ṣáájú ìkórè bí ẹnikẹ́ni bá ti rí i tí ó sì mú un ní ọwọ́ rẹ̀, òun a sì mì ín.
The fading flower of his glorious beauty, which is on the head of the fertile valley, shall be like the first-ripe fig before the summer, which someone picks and eats as soon as he sees it.
5 Ní ọjọ́ náà Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò jẹ́ adé tí ó lógo, àti adé tí ó lẹ́wà fún àwọn ènìyàn rẹ̀ tí ó ṣẹ́kù.
In that day, the LORD of Armies will become a crown of glory and a diadem of beauty to the residue of his people,
6 Òun yóò sì jẹ́ ẹ̀mí ìdájọ́ òdodo fún ẹni tí ó jókòó ní ìtẹ́ ìdájọ́ àti orísun agbára fún àwọn ẹni tí ó ń dá ogun padà ní ẹnu ibodè.
and a spirit of justice to him who sits in judgment, and strength to those who turn back the battle at the gate.
7 Àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n fún ọtí wáìnì wọ́n pòòrì fún ọtí líle, àwọn àlùfáà àti wòlíì ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n fún ọtí líle wọ́n ta gíẹ́ gíẹ́ fún ọtí wáìnì wọ́n ń lọ́ bìrì bìrì fún ọtí líle, wọ́n ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n nígbà tí wọ́n ń ríran, wọ́n kọsẹ̀ nígbà tí wọ́n ń mú ìpinnu wá.
They also reel with wine, and stagger with strong drink. The priest and the prophet reel with strong drink. They are swallowed up by wine. They stagger with strong drink. They err in vision. They stumble in judgment.
8 Gbogbo orí tábìlì ni ó kún fún èébì kò sì ṣí ibìkan tí kò sí ẹ̀gbin.
For all tables are completely full of filthy vomit and filthiness.
9 “Ta ni ẹni náà tí ó ń gbìyànjú àti kọ́? Ta ni ó sì ń ṣàlàyé ìròyìn in rẹ̀ fún? Sí àwọn ọmọdé tí a já lẹ́nu ọmú wọn, sí àwọn tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ gbà lẹ́nu ọmú.
Whom will he teach knowledge? To whom will he explain the message? Those who are weaned from the milk, and drawn from the breasts?
10 Nítorí tí í ṣe: báyìí ni orí, ṣe, kí o si túnṣe, ṣe kí o si túnṣe, àṣẹ n gorí àṣẹ, àṣẹ n gorí àṣẹ; díẹ̀ níhìn-ín, díẹ̀ lọ́hùn.”
For it is precept on precept, precept on precept; line on line, line on line; here a little, there a little.
11 Ó dára báyìí, pẹ̀lú ètè àjèjì àti ahọ́n àìmọ̀ Ọlọ́run yóò bá àwọn ènìyàn yìí sọ̀rọ̀
But he will speak to this nation with stammering lips and in another language,
12 àwọn tí ó sọ fún wí pé, “Èyí ni ibi ìsinmi, jẹ́ kí àwọn aláàárẹ̀ sinmi”; àti pé, “Èyí ni ibi ìsinmi”; ṣùgbọ́n wọn kò tẹ́tí sílẹ̀.
to whom he said, “This is the resting place. Give rest to the weary,” and “This is the refreshing;” yet they would not hear.
13 Fún ìdí èyí, ọ̀rọ̀ Olúwa sí wọn yóò di pé, ṣe èyí, ṣe ìyẹn, àṣẹ n gorí àṣẹ, àṣẹ n gorí àṣẹ; díẹ̀ níhìn-ín, díẹ̀ lọ́hùn, bẹ́ẹ̀ ni wọn yóò lọ tí wọn yóò tún ṣubú sẹ́yìn, wọn yóò fi ara pa, wọn yóò bọ́ sínú okùn a ó sì gbá wọn mú.
Therefore the LORD’s word will be to them precept on precept, precept on precept; line on line, line on line; here a little, there a little; that they may go, fall backward, be broken, be snared, and be taken.
14 Nítorí náà, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa, ẹ̀yin ẹlẹ́gàn, tí ń jẹ ọba lórí àwọn ènìyàn wọ̀nyí ní Jerusalẹmu.
Therefore hear the LORD’s word, you scoffers, that rule this people in Jerusalem:
15 Ẹ fọ́n pé, “Àwa ti bá ikú mulẹ̀, pẹ̀lú ibojì ni àwa ti jọ ṣe àdéhùn. Nígbà tí ìbáwí gbígbóná fẹ́ kọjá, kò le kàn wá lára, nítorí a ti fi irọ́ ṣe ààbò o wa àti àìṣòótọ́ ibi ìpamọ́ wa.” (Sheol h7585)
"Because you have said, 'We have made a covenant with death, and we are in agreement with Sheol (Sheol h7585). When the overflowing scourge passes through, it will not come to us; for we have made lies our refuge, and we have hidden ourselves under falsehood.'"
16 Nítorí náà, báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí: “Kíyèsi i, èmi gbé òkúta kan lélẹ̀ ní Sioni, òkúta tí a dánwò, òkúta igun ilé iyebíye fún ìpìlẹ̀ tí ó dájú; ẹnikẹ́ni tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé kì yóò ní ìfòyà.
Therefore the Lord GOD says, “Behold, I lay in Zion for a foundation a stone, a tried stone, a precious cornerstone of a sure foundation. He who believes shall not act hastily.
17 Èmi yóò fi ìdájọ́ ṣe okùn òsùwọ̀n àti òdodo òjé òsùwọ̀n; yìnyín yóò gbá ààbò yín dànù àti irọ́, omi yóò sì kún bo gbogbo ibi tí ẹ ń fi ara pamọ́ sí mọ́lẹ̀.
I will make justice the measuring line, and righteousness the plumb line. The hail will sweep away the refuge of lies, and the waters will overflow the hiding place.
18 Májẹ̀mú yín tí ẹ bá ikú dá ni a ó fa igi lé; àdéhùn yín pẹ̀lú ibojì ni kì yóò dúró. Nígbà tí ìbínú gbígbóná náà bá fẹ́ kọjá, a ó ti ipa rẹ̀ lù yín bolẹ̀. (Sheol h7585)
Your covenant with death shall be annulled, and your agreement with Sheol (Sheol h7585) shall not stand. When the overflowing scourge passes through, then you will be trampled down by it.
19 Nígbàkígbà tí ó bá ti wá ni yóò máa gbé ọ lọ, ni àràárọ̀, ní ọ̀sán àti ní òru, ni yóò máa fẹ́ kọjá lọ.” Ìmòye ọ̀rọ̀-ìmọ̀ yìí yóò máa mú ìpayà ńlá wá.
As often as it passes through, it will seize you; for morning by morning it will pass through, by day and by night; and it will be nothing but terror to understand the message.”
20 Ibùsùn kúrú púpọ̀ fún ìnara lé lórí, ìbora kò fẹ̀ tó láti yí ara yín ká.
For the bed is too short to stretch out on, and the blanket is too narrow to wrap oneself in.
21 Olúwa yóò dìde sókè gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ní òkè Perasimu yóò ru ara rẹ̀ sókè gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ní àfonífojì Gibeoni— láti ṣe iṣẹ́ rẹ̀, abàmì iṣẹ́ ẹ rẹ̀, yóò ṣe iṣẹ́ rẹ̀, àní àjèjì iṣẹ́ rẹ̀.
For the LORD will rise up as on Mount Perazim. He will be angry as in the valley of Gibeon; that he may do his work, his unusual work, and bring to pass his act, his extraordinary act.
22 Ní ìsinsin yìí ẹ dákẹ́ ẹlẹ́yà ṣíṣe, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ ìdè e yín yóò le sí i; Olúwa, àní Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti sọ fún mi nípa àṣẹ ìparun ti ó ti pa lórí gbogbo ilẹ̀ náà.
Now therefore do not be scoffers, lest your bonds be made strong; for I have heard a decree of destruction from the Lord, GOD of Armies, on the whole earth.
23 Tẹ́tí kí o sì gbọ́ ohùn mi, fi ara balẹ̀ kí o sì gbọ́ ohun tí mo sọ.
Give ear, and hear my voice! Listen, and hear my speech!
24 Nígbà tí àgbẹ̀ kan bá tu ilẹ̀ láti gbìn yóò ha máa tulẹ̀ títí bi? Ǹjẹ́ yóò ha máa tu ilẹ̀ kí ó sì máa jọ̀ ọ́ títí lọ bí?
Does he who plows to sow plow continually? Does he keep turning the soil and breaking the clods?
25 Nígbà tí òun bá ti tẹ́ ojú ilẹ̀ rẹ̀ pẹrẹsẹ òun kò ha ń fúnrúgbìn dílì kí ó sì fúnrúgbìn kummini ká? Kí ó sì gbin alikama lẹ́sẹẹsẹ, barle tí a yàn, àti spelti ní ipò rẹ̀?
When he has leveled its surface, does not he plant the dill, and scatter the cumin seed, and put in the wheat in rows, the barley in the appointed place, and the spelt in its place?
26 Ọlọ́run rẹ̀ tọ́ ọ ṣọ́nà ó sì kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ ní ọ̀nà tó tọ́.
For his God instructs him in right judgment and teaches him.
27 Nítorí a kò fi ohun èlò ìpakà dili, bẹ́ẹ̀ ni a kì í yí kẹ̀kẹ́ ẹrù kiri lórí kummini; ṣùgbọ́n ọ̀pá ni a fi ń pa dili jáde, ọ̀gọ ni a sì lu kummini.
For the dill is not threshed with a sharp instrument, neither is a cart wheel turned over the cumin; but the dill is beaten out with a stick, and the cumin with a rod.
28 A gbọdọ̀ lọ ìyẹ̀fun kí a tó ṣe àkàrà; bẹ́ẹ̀ ni ẹnìkan kì í máa pa á lọ títí láé. Bí ó tilẹ̀ yí ẹsẹ̀ kẹ̀kẹ́ ìpakà a rẹ̀ lórí i rẹ̀, àwọn ẹṣin rẹ̀ kò le lọ̀ ọ́.
Bread flour must be ground; so he will not always be threshing it. Although he drives the wheel of his threshing cart over it, his horses do not grind it.
29 Gbogbo èyí pẹ̀lú ti ọ̀dọ̀ Olúwa àwọn ọmọ-ogun wá, oníyanu ní ìmọ̀ràn àti ológo ní ọgbọ́n.
This also comes out from the LORD of Armies, who is wonderful in counsel, and excellent in wisdom.

< Isaiah 28 >