< Isaiah 27 >
1 Ní ọjọ́ náà, Olúwa yóò fi idà rẹ̀ jẹ ni ní yà idà rẹ̀ a mú bí iná tí ó tóbi tí ó sì lágbára Lefitani ejò tí ń yọ̀ tẹ̀ẹ̀rẹ̀ n nì, Lefitani ejò tí ń lọ́ bìrìkìtì; Òun yóò sì pa ẹ̀mí búburú inú Òkun náà.
2 Ní ọjọ́ náà, “Kọrin nípa ọgbà àjàrà eléso kan.
3 Èmi Olúwa ń bojútó o, Èmi ó bomirin ín láti ìgbàdégbà. Èmi ó ṣọ́ ọ tọ̀sán tòru kí ẹnikẹ́ni má ba à pa á lára.
4 Inú kò bí mi. Bí ẹ̀gún àti ẹ̀wọ̀n bá dojú ìjà kọ mí! Èmi yóò dìde sí wọn ní ogun, Èmi yóò sì dáná sun gbogbo wọn.
5 Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, jẹ́ kí wọn wá sọ́dọ̀ mi fún ààbò; jẹ́ kí wọ́n wá àlàáfíà pẹ̀lú mi, bẹ́ẹ̀ ni, jẹ́ kí wọn wá àlàáfíà pẹ̀lú mi.”
6 Ní ọjọ́ iwájú Jakọbu yóò ta gbòǹgbò, Israẹli yóò tanná yóò sì rudi èso rẹ̀ yóò sì kún gbogbo ayé.
7 Ǹjẹ́ Olúwa ti lù ú gẹ́gẹ́ bí ó ti lu àwọn tí ó lù ú bolẹ̀? Ǹjẹ́ a ti pa á gẹ́gẹ́ bí a ti pa àwọn tí ó pa á?
8 Nípa ogun jíjà àti ìjìyà ti o le ni ó fi dojúkọ ọ́ pẹ̀lú ìjì gbígbóná ni ó lé e jáde, gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ tí afẹ́fẹ́ ìlà-oòrùn fẹ́.
9 Nítorí èyí báyìí ni ètùtù yóò ṣe wà fún ẹ̀ṣẹ̀ Jakọbu, èyí ni yóò sì jẹ́ èso kíkún ti ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ rẹ. Nígbà tí ó bá mú kí àwọn òkúta pẹpẹ dàbí òkúta ẹfun tí a fọ́ sí wẹ́wẹ́, kì yóò sí ère Aṣerah tàbí pẹpẹ tùràrí tí yóò wà ní ìdúró.
10 Ìlú olódi náà ti dahoro, ibùdó ìkọ̀sílẹ̀, tí a kọ̀ tì gẹ́gẹ́ bí aginjù; níbẹ̀ ni àwọn ọmọ màlúù ti ń jẹ oko níbẹ̀ ni wọn ń sùn sílẹ̀; wọn sì jẹ gbogbo ẹ̀ka rẹ̀ tán.
11 Nígbà tí àwọn ẹ̀ka rẹ̀ bá rọ, a ó ya wọn dànù àwọn obìnrin dé, wọ́n sì fi wọ́n dáná nítorí aláìlóye ènìyàn ni wọn jẹ́, nítorí náà ni ẹni tí ó dá wọn kì yóò ṣàánú fún wọn; bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ó mọ wọn kì yóò sì fi ojúrere wò wọ́n.
12 Ní ọjọ́ náà Olúwa yóò sì kó oore láti ìṣàn omi odo Eufurate wá títí dé Wadi ti Ejibiti, àti ìwọ, ìwọ ọmọ Israẹli, ni a ó kójọ ní ọ̀kọ̀ọ̀kan.
13 Àti ní ọjọ́ náà, a ó fun fèrè ńlá kan. Gbogbo àwọn tí ń ṣègbé lọ ní Asiria àti àwọn tí ń ṣe àtìpó ní Ejibiti yóò wá sin Olúwa ní òkè mímọ́ ní Jerusalẹmu.