< Isaiah 23 >
1 Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ tí ó kan Tire. Hu, ìwọ ọkọ̀ ojú omi Tarṣiṣi! Nítorí a ti pa Tire run láìsí ilé tàbí èbúté. Láti ilẹ̀ Saipurọsi ni ọ̀rọ̀ ti wá sọ́dọ̀ wọn.
2 Dákẹ́ jẹ́ẹ́, ẹ̀yin ènìyàn erékùṣù àti ẹ̀yin oníṣòwò ti Sidoni, ẹ̀yin tí àwọn a wẹ Òkun ti sọ dọlọ́rọ̀.
3 Láti orí àwọn omi ńlá ni irúgbìn ìyẹ̀fun ti ilẹ̀ Ṣihori ti wá; ìkórè ti odò Naili ni owóòná Tire, òun sì ti di ibùjókòó ọjà fún àwọn orílẹ̀-èdè.
4 Kí ojú kí ó tì ọ́, ìwọ Sidoni àti ìwọ àní ìwọ ilé ààbò ti Òkun, nítorí Òkun ti sọ̀rọ̀. “Èmi kò tí ì wà ní ipò ìrọbí tàbí ìbímọ rí Èmi kò tí ì wo àwọn ọmọkùnrin tàbí kí n tọ́ àwọn ọmọbìnrin dàgbà rí.”
5 Nígbà tí ọ̀rọ̀ bá dé Ejibiti, wọn yóò wà ní ìpayínkeke nípa ìròyìn láti Tire.
6 Kọjá wá sí Tarṣiṣi; pohùnréré, ẹ̀yin ènìyàn erékùṣù.
7 Ǹjẹ́ èyí náà ni ìlú àríyá yín, ògbólógbòó ìlú náà, èyí tí ẹsẹ̀ rẹ̀ ti sìn ín lọ láti lọ tẹ̀dó sí ilẹ̀ tí ó jìnnà réré.
8 Ta ló gbèrò èyí sí Tire, ìlú aládé, àwọn oníṣòwò ẹni tí ó jẹ́ ọmọ-aládé tí àwọn oníṣòwò wọ́n jẹ́ ìlúmọ̀míká ní orílẹ̀ ayé?
9 Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti ṣètò rẹ̀, láti tẹrí ìgbéraga àti ògo rẹ ba àti láti rẹ gbogbo àwọn ọlọ́lá ilé ayé sílẹ̀.
10 Tu ilẹ̀ rẹ gẹ́gẹ́ bí i ti ipadò odò Ejibiti, ìwọ ọmọbìnrin Tarṣiṣi, nítorí ìwọ kò ní èbúté mọ́.
11 Olúwa ti na ọwọ́ rẹ̀ jáde sí orí Òkun ó sì mú kí àwọn ilẹ̀ ọba wárìrì. Ó ti pa àṣẹ kan tí ó kan Kenaani pé kí a pa ilé ààbò rẹ̀ run.
12 Ó wí pé, “Kò sí àríyá fún ọ mọ́, ìwọ wúńdíá ti Sidoni, tí a ti tẹ̀ mọ́lẹ̀ báyìí! “Gbéra, rékọjá lọ sí Saipurọsi, níbẹ̀ pẹ̀lú o kì yóò ní ìsinmi.”
13 Bojú wo ilẹ̀ àwọn ará Babeli, àwọn ènìyàn tí kò jámọ́ nǹkan kan báyìí. Àwọn Asiria ti sọ ọ́ di ibùgbé àwọn ohun ẹranko aginjù; wọn ti gbé ilé ìṣọ́ ìtẹ̀gùn wọn sókè, wọ́n ti tú odi rẹ̀ sí ìhòhò wọ́n sì ti sọ ọ́ di ààtàn.
14 Hu, ìwọ ọkọ̀ ojú omi Tarṣiṣi; wọ́n ti pa odi rẹ̀ run!
15 Ní àkókò náà a ó gbàgbé Tire fún àádọ́rin ọdún, ọjọ́ ayé ọba kan. Ṣùgbọ́n ní òpin àádọ́rin ọdún wọ̀nyí, yóò ṣẹlẹ̀ sí Tire gẹ́gẹ́ bí orin àgbèrè:
16 “Mú dùùrù kan, rìn kọjá láàrín ìlú, ìwọ àgbèrè tí a ti gbàgbé; lu dùùrù dáradára, kọ ọ̀pọ̀ orin, kí a lè ba à rántí rẹ.”
17 Ní òpin àádọ́rin ọdún náà, Olúwa yóò bá Tire jà. Òun yóò sì padà sí àyálò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí panṣágà, yóò sì máa ṣe òwò rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ilẹ̀ ọba tí ó wà ní ilẹ̀ ayé.
18 Síbẹ̀síbẹ̀ èrè rẹ̀ àti owó iṣẹ́ rẹ̀ ni a ó yà sọ́tọ̀ fún Olúwa; a kò ní kó wọn pamọ́ tàbí kí a há wọn mọ́wọ́. Ère rẹ̀ ni a ó fi fún àwọn tí ó ń gbé níwájú Olúwa, fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ oúnjẹ àti aṣọ.