< Isaiah 20 >

1 Ní ọdún tí olórí ogun, tí Sagoni ọba Asiria rán an, wá sí Aṣdodu, ó kọlù ú ó sì kó o—
Before the year that the chief commander, sent by Sargon king of Assyria, came to Ashdod and attacked and captured it,
2 ní àkókò náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa ti ẹnu Isaiah ọmọ Amosi jáde. Ó sọ fún un pé, “Mú aṣọ ọ̀fọ̀ kúrò ní ara rẹ kí o sì bọ́ sálúbàtà kúrò ní ẹsẹ̀ rẹ.” Ó sì ṣe bẹ́ẹ̀, ó ń lọ káàkiri ní ìhòhò àti láì wọ bàtà.
the LORD had already spoken through Isaiah son of Amoz, saying, “Go, remove the sackcloth from your waist and the sandals from your feet.” And Isaiah did so, walking around naked and barefoot.
3 Lẹ́yìn náà ni Olúwa wí pé, “Gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ mi Isaiah ti lọ káàkiri ní ìhòhò àti láì wọ bàtà fún ọdún mẹ́ta, gẹ́gẹ́ bí àmì àti àpẹẹrẹ sí Ejibiti àti Kuṣi,
Then the LORD said, “Just as My servant Isaiah has gone naked and barefoot for three years as a sign and omen against Egypt and Cush,
4 bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ọba Asiria yóò kó àwọn ìgbèkùn Ejibiti lọ ní ìhòhò àti láì wọ bàtà pẹ̀lú àwọn àtìpó Kuṣi, ọ̀dọ́ àti àgbà, pẹ̀lú ìbàdí ìhòhò—bí àbùkù Ejibiti.
so the king of Assyria will lead away the captives of Egypt and the exiles of Cush, young and old alike, naked and barefoot, with bared buttocks—to Egypt’s shame.
5 Gbogbo àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé Kuṣi tí wọ́n sì ń fi Ejibiti yangàn ni ẹ̀rù yóò dé bá tí a ó sì dójútì wọ́n.
Those who made Cush their hope and Egypt their boast will be dismayed and ashamed.
6 Ní ọjọ́ náà àwọn ènìyàn tí ó ń gbé ní etí Òkun yóò wí pé, ‘Wo ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ sí àwọn tí a ti gbẹ́kẹ̀lé, àwọn tí a sá tọ̀ lọ fún ìrànlọ́wọ́ àti ìtúsílẹ̀ láti ọwọ́ ọba Asiria! Báwo ni a ó ṣe sálà?’”
And on that day the dwellers of this coastland will say, ‘See what has happened to our source of hope, those to whom we fled for help and deliverance from the king of Assyria! How then can we escape?’”

< Isaiah 20 >