< Isaiah 2 >

1 Èyí ni ohun tí Isaiah ọmọ Amosi rí nípa Juda àti Jerusalẹmu.
verbum quod vidit Isaias filius Amos super Iudam et Hierusalem
2 Ní ìgbẹ̀yìn ọjọ́ òkè tẹmpili Olúwa ni a ó fi ìdí rẹ̀ kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olú nínú àwọn òkè, a ó sì gbé e ga ju àwọn òkè kéékèèké lọ, gbogbo orílẹ̀-èdè yóò sì máa sàn sínú un rẹ̀.
et erit in novissimis diebus praeparatus mons domus Domini in vertice montium et elevabitur super colles et fluent ad eum omnes gentes
3 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni yóò wá, wọn yóò sì wí pé, “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á gòkè ńlá Olúwa, àti sí ilé Ọlọ́run Jakọbu. Òun yóò kọ́ wa ní ọ̀nà rẹ̀, kí àwa kí ó lè rìn ní ọ̀nà rẹ̀.” Òfin yóò jáde láti Sioni wá, àti ọ̀rọ̀ Olúwa láti Jerusalẹmu.
et ibunt populi multi et dicent venite et ascendamus ad montem Domini et ad domum Dei Iacob et docebit nos vias suas et ambulabimus in semitis eius quia de Sion exibit lex et verbum Domini de Hierusalem
4 Òun ó ṣe ìdájọ́ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, yóò sì parí aáwọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn. Wọn yóò fi idà wọn rọ ọkọ́ ìtulẹ̀, wọn yóò sì fi ọ̀kọ̀ wọn rọ dòjé. Orílẹ̀-èdè kì yóò sì gbé idà sí orílẹ̀-èdè mọ́, bẹ́ẹ̀ ní wọn kì yóò kọ́ ogun jíjà mọ́.
et iudicabit gentes et arguet populos multos et conflabunt gladios suos in vomeres et lanceas suas in falces non levabit gens contra gentem gladium nec exercebuntur ultra ad proelium
5 Wá, ẹ̀yìn ará ilé e Jakọbu, ẹ jẹ́ kí a rìn nínú ìmọ́lẹ̀ Olúwa.
domus Iacob venite et ambulemus in lumine Domini
6 Ìwọ ti kọ àwọn ènìyàn rẹ sílẹ̀, ìwọ ilé Jakọbu. Wọ́n kún fún ìgbàgbọ́ tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ tí ó ti ìlà-oòrùn wá, wọ́n ń wo iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí àwọn Filistini, wọ́n ń pa ọwọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn abọ̀rìṣà.
proiecisti enim populum tuum domum Iacob quia repleti sunt ut olim et augures habuerunt ut Philisthim et pueris alienis adheserunt
7 Ilẹ̀ wọn kún fún fàdákà àti wúrà, ìṣúra wọn kò sì ní òpin. Ilẹ̀ ẹ wọn kún fún ẹṣin, kẹ̀kẹ́ ogun wọn kò sì lópin.
repleta est terra argento et auro et non est finis thesaurorum eius
8 Ilẹ̀ ẹ wọn kún fún ère, wọ́n sì ń foríbalẹ̀ fún iṣẹ́ ọwọ́ ara wọn, èyí tí ìka ọwọ́ àwọn tìkára wọn ti ṣe.
et repleta est terra eius equis et innumerabiles quadrigae eius et repleta est terra eius idolis opus manuum suarum adoraverunt quod fecerunt digiti eorum
9 Nítorí náà ni a ó ṣe rẹ ènìyàn sílẹ̀ ìran ọmọ ènìyàn ni yóò sì di onírẹ̀lẹ̀, má ṣe dáríjì wọ́n.
et incurvavit se homo et humiliatus est vir ne ergo dimittas eis
10 Wọ inú àpáta lọ, fi ara pamọ́ nínú erùpẹ̀ kúrò nínú ìpayà Olúwa, àti ògo ọláńlá rẹ̀!
ingredere in petram abscondere fossa humo a facie timoris Domini et a gloria maiestatis eius
11 Ojú agbéraga ènìyàn ni a ó rẹ̀ sílẹ̀ a ó sì tẹrí ìgbéraga ènìyàn ba, Olúwa nìkan ṣoṣo ni a ó gbéga ní ọjọ́ náà.
oculi sublimis hominis humiliati sunt et incurvabitur altitudo virorum exaltabitur autem Dominus solus in die illa
12 Olúwa àwọn ọmọ-ogun ní ọjọ́ kan ní ìpamọ́ fún gbogbo agbéraga àti ọlọ́kàn gíga nítorí gbogbo àwọn tí a gbéga (ni a ó rẹ̀ sílẹ̀),
quia dies Domini exercituum super omnem superbum et excelsum et super omnem arrogantem et humiliabitur
13 nítorí gbogbo igi kedari Lebanoni, tó ga tó rìpó àti gbogbo óákù Baṣani,
et super omnes cedros Libani sublimes et erectas et super omnes quercus Basan
14 nítorí gbogbo òkè gíga ńlá ńlá àti àwọn òkè kéékèèké,
et super omnes montes excelsos et super omnes colles elevatos
15 fún ilé ìṣọ́ gíga gíga àti àwọn odi ìdáàbòbò,
et super omnem turrem excelsam et super omnem murum munitum
16 fún gbogbo ọkọ̀ àwọn oníṣòwò àwọn ọkọ̀ tí a ṣe lọ́ṣọ̀ọ́.
et super omnes naves Tharsis et super omne quod visu pulchrum est
17 Ìgbéraga ènìyàn ni a ó tẹ̀ lórí ba a ó sì rẹ ìgbéraga ènìyàn sílẹ̀, Olúwa nìkan ṣoṣo ni a ó gbéga ní ọjọ́ náà,
et incurvabitur sublimitas hominum et humiliabitur altitudo virorum et elevabitur Dominus solus in die illa
18 gbogbo ère òrìṣà yóò pòórá.
et idola penitus conterentur
19 Àwọn ènìyàn yóò sálọ sínú ihò àpáta àti sínú ihò ilẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ìpayà Olúwa àti ògo ọláńlá rẹ̀, nígbà tí ó bá dìde láti mi ayé tìtì.
et introibunt in speluncas petrarum et in voragines terrae a facie formidinis Domini et a gloria maiestatis eius cum surrexerit percutere terram
20 Ní ọjọ́ náà ni àwọn ènìyàn yóò máa sọ àwọn ère fàdákà àti ère wúrà tí wọ́n ti yá fún bíbọ sí èkúté àti àwọn àdán.
in die illa proiciet homo idola argenti sui et simulacra auri sui quae fecerat sibi ut adoraret talpas et vespertiliones
21 Wọn yóò sálọ sínú ihò ìsàlẹ̀ àpáta àti sínú ihò pàlàpálá àpáta kúrò lọ́wọ́ ìpayà Olúwa àti ògo ọláńlá rẹ̀, nígbà tí ó bá dìde láti mi ayé tìtì.
et ingredietur fissuras petrarum et cavernas saxorum a facie formidinis Domini et a gloria maiestatis eius cum surrexerit percutere terram
22 Dẹ́kun à ń gba ènìyàn gbọ́, èémí ẹni tó wà ní ihò imú rẹ̀. Nítorí nínú kín ni a lè kà á sí?
quiescite ergo ab homine cuius spiritus in naribus eius quia excelsus reputatus est ipse

< Isaiah 2 >