< Isaiah 19 >

1 Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ tí ó kan Ejibiti. Kíyèsi i, Olúwa gun àwọsánmọ̀ tí ó yára lẹ́ṣin ó sì ń bọ̀ wá sí Ejibiti. Àwọn ère òrìṣà Ejibiti wárìrì níwájú rẹ̀, ọkàn àwọn ará Ejibiti sì ti domi nínú wọn.
מַשָּׂא מִצְרָיִם הִנֵּה יְהֹוָה רֹכֵב עַל־עָב קַל וּבָא מִצְרַיִם וְנָעוּ אֱלִילֵי מִצְרַיִם מִפָּנָיו וּלְבַב מִצְרַיִם יִמַּס בְּקִרְבּֽוֹ׃
2 “Èmi yóò rú àwọn ará Ejibiti sókè sí ara wọn arákùnrin yóò bá arákùnrin rẹ̀ jà, aládùúgbò yóò dìde sí aládùúgbò rẹ̀, ìlú yóò dìde sí ìlú, ilẹ̀ ọba sí ilẹ̀ ọba.
וְסִכְסַכְתִּי מִצְרַיִם בְּמִצְרַיִם וְנִלְחֲמוּ אִישׁ־בְּאָחִיו וְאִישׁ בְּרֵעֵהוּ עִיר בְּעִיר מַמְלָכָה בְּמַמְלָכָֽה׃
3 Àwọn ará Ejibiti yóò sọ ìrètí nù, èmi yóò sì sọ èrò wọn gbogbo di òfo; wọn yóò bá àwọn òrìṣà àti ẹ̀mí àwọn òkú sọ̀rọ̀, àwọn awoṣẹ́ àti àwọn abókùúsọ̀rọ̀.
וְנָבְקָה רוּחַ־מִצְרַיִם בְּקִרְבּוֹ וַעֲצָתוֹ אֲבַלֵּעַ וְדָרְשׁוּ אֶל־הָֽאֱלִילִים וְאֶל־הָאִטִּים וְאֶל־הָאֹבוֹת וְאֶל־הַיִּדְּעֹנִֽים׃
4 Èmi yóò fi Ejibiti lé agbára àwọn ìkà amúnisìn lọ́wọ́, ọba aláìláàánú ni yóò jẹ ọba lé wọn lórí,” ni Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.
וְסִכַּרְתִּי אֶת־מִצְרַיִם בְּיַד אֲדֹנִים קָשֶׁה וּמֶלֶךְ עַז יִמְשׇׁל־בָּם נְאֻם הָאָדוֹן יְהֹוָה צְבָאֽוֹת׃
5 Gbogbo omi inú odò ni yóò gbẹ, gbogbo ilẹ̀ àyíká odò ni yóò gbẹ tí yóò sì sáàpá.
וְנִשְּׁתוּ־מַיִם מֵֽהַיָּם וְנָהָר יֶחֱרַב וְיָבֵֽשׁ׃
6 Adágún omi yóò sì di rírùn; àwọn odò ilẹ̀ Ejibiti yóò máa dínkù wọn yóò sì gbẹ. Àwọn koríko odò àti ìrẹ̀tẹ̀ yóò gbẹ,
וְהֶאֶזְנִיחוּ נְהָרוֹת דָּלְלוּ וְחָרְבוּ יְאֹרֵי מָצוֹר קָנֶה וָסוּף קָמֵֽלוּ׃
7 àwọn igi ipadò Naili pẹ̀lú, tí ó wà ní orísun odò, gbogbo oko tí a dá sí ipadò Naili yóò gbẹ dànù tí yóò sì fẹ́ dànù tí kò sì ní sí mọ́.
עָרוֹת עַל־יְאוֹר עַל־פִּי יְאוֹר וְכֹל מִזְרַע יְאוֹר יִיבַשׁ נִדַּף וְאֵינֶֽנּוּ׃
8 Àwọn apẹja yóò sọkún kíkorò, àti gbogbo àwọn tí ó ń ju ìwọ̀ sínú odò; odò náà yóò sì máa rùn.
וְאָנוּ הַדַּיָּגִים וְאָבְלוּ כׇּל־מַשְׁלִיכֵי בַיְאוֹר חַכָּה וּפֹרְשֵׂי מִכְמֹרֶת עַל־פְּנֵי־מַיִם אֻמְלָֽלוּ׃
9 Àwọn tí ó ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ọ̀gbọ̀ yóò kọminú àwọn ahunṣọ ọ̀gbọ̀ yóò sọ ìrètí nù.
וּבֹשׁוּ עֹבְדֵי פִשְׁתִּים שְׂרִיקוֹת וְאֹרְגִים חוֹרָֽי׃
10 Àwọn tí ń ṣiṣẹ́ aṣọ yóò rẹ̀wẹ̀sì, gbogbo àwọn oníṣẹ́ oṣù ni àìsàn ọkàn yóò ṣe.
וְהָיוּ שָׁתֹתֶיהָ מְדֻכָּאִים כׇּל־עֹשֵׂי שֶׂכֶר אַגְמֵי־נָֽפֶשׁ׃
11 Àwọn oníṣẹ́ Ṣoani ti di aláìgbọ́n, àwọn ọlọ́gbọ́n olùdámọ̀ràn Farao ń mú ìmọ̀ràn àìgbọ́n wá. Báwo ló ṣe lè sọ fún Farao pé, “Mo jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọlọ́gbọ́n ènìyàn, ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn àwọn ọba àtijọ́.”
אַךְ־אֱוִלִים שָׂרֵי צֹעַן חַכְמֵי יֹעֲצֵי פַרְעֹה עֵצָה נִבְעָרָה אֵיךְ תֹּאמְרוּ אֶל־פַּרְעֹה בֶּן־חֲכָמִים אֲנִי בֶּן־מַלְכֵי־קֶֽדֶם׃
12 Níbo ni àwọn ọlọ́gbọ́n ènìyàn rẹ wà báyìí? Jẹ́ kí wọn fihàn ọ́ kí wọn sì sọ ọ́ di mí mọ̀ ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti pinnu lórí Ejibiti.
אַיָּם אֵפוֹא חֲכָמֶיךָ וְיַגִּידוּ נָא לָךְ וְיֵדְעוּ מַה־יָּעַץ יְהֹוָה צְבָאוֹת עַל־מִצְרָֽיִם׃
13 Àwọn ọmọ-aládé Ṣoani ti di aṣiwèrè, a ti tan àwọn ọmọ-aládé Memfisi jẹ; àwọn òkúta igun ilé tí í ṣe ti ẹ̀yà rẹ ti ṣi Ejibiti lọ́nà.
נֽוֹאֲלוּ שָׂרֵי צֹעַן נִשְּׁאוּ שָׂרֵי נֹף הִתְעוּ אֶת־מִצְרַיִם פִּנַּת שְׁבָטֶֽיהָ׃
14 Olúwa ti da ẹ̀mí òòyì sínú wọn; wọ́n mú Ejibiti ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n nínú ohun gbogbo tí ó ń ṣe, gẹ́gẹ́ bí ọ̀mùtí ti í ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n nínú èébì rẹ̀.
יְהֹוָה מָסַךְ בְּקִרְבָּהּ רוּחַ עִוְעִים וְהִתְעוּ אֶת־מִצְרַיִם בְּכׇֽל־מַעֲשֵׂהוּ כְּהִתָּעוֹת שִׁכּוֹר בְּקִיאֽוֹ׃
15 Kò sí ohun tí Ejibiti le ṣe— orí tàbí ìrù, ọ̀wá ọ̀pẹ tàbí koríko odò.
וְלֹא־יִהְיֶה לְמִצְרַיִם מַעֲשֶׂה אֲשֶׁר יַעֲשֶׂה רֹאשׁ וְזָנָב כִּפָּה וְאַגְמֽוֹן׃
16 Ní ọjọ́ náà ni àwọn ará Ejibiti yóò dàbí obìnrin. Wọn yóò gbọ̀n jìnnìjìnnì pẹ̀lú ẹ̀rù nítorí ọwọ́ Olúwa àwọn ọmọ-ogun tí a gbé sókè sí wọn.
בַּיּוֹם הַהוּא יִהְיֶה מִצְרַיִם כַּנָּשִׁים וְחָרַד ׀ וּפָחַד מִפְּנֵי תְּנוּפַת יַד־יְהֹוָה צְבָאוֹת אֲשֶׁר־הוּא מֵנִיף עָלָֽיו׃
17 Ilẹ̀ Juda yóò sì di ẹ̀rù fún Ejibiti; gbogbo àwọn tí a bá ti dárúkọ Juda létí wọn ni yóò wárìrì, nítorí ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun gbèrò láti ṣe sí wọn.
וְהָיְתָה אַדְמַת יְהוּדָה לְמִצְרַיִם לְחׇגָּא כֹּל אֲשֶׁר יַזְכִּיר אֹתָהּ אֵלָיו יִפְחָד מִפְּנֵי עֲצַת יְהֹוָה צְבָאוֹת אֲשֶׁר־הוּא יוֹעֵץ עָלָֽיו׃
18 Ní ọjọ́ náà ìlú márùn-ún ní ilẹ̀ Ejibiti yóò sọ èdè àwọn ará Kenaani, wọn yóò sì búra àtìlẹ́yìn fún Olúwa àwọn ọmọ-ogun. Ọ̀kan nínú wọn ni a ó sì máa pè ní ìlú ìparun.
בַּיּוֹם הַהוּא יִהְיוּ חָמֵשׁ עָרִים בְּאֶרֶץ מִצְרַיִם מְדַבְּרוֹת שְׂפַת כְּנַעַן וְנִשְׁבָּעוֹת לַיהֹוָה צְבָאוֹת עִיר הַהֶרֶס יֵאָמֵר לְאֶחָֽת׃
19 Ní ọjọ́ náà pẹpẹ kan yóò wà fún Olúwa ní àárín gbùngbùn Ejibiti, àti ọ̀wọ́n kan fún Olúwa ní etí bodè rẹ̀.
בַּיּוֹם הַהוּא יִֽהְיֶה מִזְבֵּחַ לַֽיהֹוָה בְּתוֹךְ אֶרֶץ מִצְרָיִם וּמַצֵּבָה אֵצֶל־גְּבוּלָהּ לַֽיהֹוָֽה׃
20 Yóò sì jẹ́ àmì àti ẹ̀rí sí Olúwa àwọn ọmọ-ogun ní ilẹ̀ Ejibiti. Nígbà tí wọ́n bá ké pe Olúwa nítorí àwọn aninilára wọn, yóò rán olùgbàlà àti olùgbèjà kan sí wọn tí yóò sì gbà wọ́n sílẹ̀.
וְהָיָה לְאוֹת וּלְעֵד לַיהֹוָה צְבָאוֹת בְּאֶרֶץ מִצְרָיִם כִּֽי־יִצְעֲקוּ אֶל־יְהֹוָה מִפְּנֵי לֹחֲצִים וְיִשְׁלַח לָהֶם מוֹשִׁיעַ וָרָב וְהִצִּילָֽם׃
21 Báyìí ni Olúwa yóò sọ ara rẹ̀ di mí mọ̀ fún àwọn ará Ejibiti àti ní ọjọ́ náà ni wọn yóò gba Olúwa gbọ́. Wọn yóò sìn ín pẹ̀lú ẹbọ ọrẹ ìyẹ̀fun, wọn yóò jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún Olúwa wọn yóò sì mú un ṣẹ.
וְנוֹדַע יְהֹוָה לְמִצְרַיִם וְיָדְעוּ מִצְרַיִם אֶת־יְהֹוָה בַּיּוֹם הַהוּא וְעָֽבְדוּ זֶבַח וּמִנְחָה וְנָדְרוּ־נֵדֶר לַיהֹוָה וְשִׁלֵּֽמוּ׃
22 Olúwa yóò fi àjàkálẹ̀-ààrùn kan bá Ejibiti jà; yóò bá wọn jà yóò sì tún wò wọ́n sàn. Wọn yóò yípadà sí Olúwa, Òun yóò sì gbọ́ ẹ̀bẹ̀ wọn yóò sì wò wọ́n sàn.
וְנָגַף יְהֹוָה אֶת־מִצְרַיִם נָגֹף וְרָפוֹא וְשָׁבוּ עַד־יְהֹוָה וְנֶעְתַּר לָהֶם וּרְפָאָֽם׃
23 Ní ọjọ́ náà òpópónà kan yóò wá láti Ejibiti lọ sí Asiria. Àwọn ará Asiria yóò lọ sí Ejibiti àti àwọn ará Ejibiti lọ sí Asiria. Àwọn ará Ejibiti àti ará Asiria yóò jọ́sìn papọ̀.
בַּיּוֹם הַהוּא תִּהְיֶה מְסִלָּה מִמִּצְרַיִם אַשּׁוּרָה וּבָא־אַשּׁוּר בְּמִצְרַיִם וּמִצְרַיִם בְּאַשּׁוּר וְעָבְדוּ מִצְרַיִם אֶת־אַשּֽׁוּר׃
24 Ní ọjọ́ náà Israẹli yóò di ẹ̀kẹta pẹ̀lú Ejibiti àti Asiria, àní orísun ìbùkún ní ilẹ̀ ayé.
בַּיּוֹם הַהוּא יִהְיֶה יִשְׂרָאֵל שְׁלִישִׁיָּה לְמִצְרַיִם וּלְאַשּׁוּר בְּרָכָה בְּקֶרֶב הָאָֽרֶץ׃
25 Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò bùkún wọn yóò wí pé, “Ìbùkún ni fún Ejibiti ènìyàn mi, Asiria iṣẹ́ ọwọ́ mi, àti Israẹli ìní mi.”
אֲשֶׁר בֵּרְכוֹ יְהֹוָה צְבָאוֹת לֵאמֹר בָּרוּךְ עַמִּי מִצְרַיִם וּמַעֲשֵׂה יָדַי אַשּׁוּר וְנַחֲלָתִי יִשְׂרָאֵֽל׃

< Isaiah 19 >