< Isaiah 18 >

1 Ègbé ni fún ilẹ̀ tí ó kún fún ariwo ìyẹ́ eṣú, ní àwọn ipadò Kuṣi,
הוי ארץ צלצל כנפים אשר מעבר לנהרי כוש
2 tí ó rán àwọn ikọ̀ lórí Òkun lórí omi nínú ọkọ̀-ọpọ́n tí a fi eèsún papirusi ṣe. Ẹ lọ, ẹ̀yin ikọ̀ tí ó yára, sí àwọn ènìyàn gíga tí àwọ̀ ara wọn jọ̀lọ̀, sí àwọn ènìyàn tí a ń bẹ̀rù káàkiri, orílẹ̀-èdè aláfojúdi alájèjì èdè, tí odò pín ilẹ̀ rẹ̀ yẹ́lẹyẹ̀lẹ.
השלח בים צירים ובכלי גמא על פני מים לכו מלאכים קלים אל גוי ממשך ומורט אל עם נורא מן הוא והלאה--גוי קו קו ומבוסה אשר בזאו נהרים ארצו
3 Gbogbo ẹ̀yin ènìyàn ayé, tí ó ń gbé orílẹ̀ ayé, nígbà tí a bá gbé àsíá kan sókè lórí òkè, ẹ ó rí i, nígbà tí a bá fun fèrè kan ẹ ó gbọ́ ọ.
כל ישבי תבל ושכני ארץ כנשא נס הרים תראו וכתקע שופר תשמעו
4 Èyí ni ohun tí Olúwa sọ fún mi: “Èmi yóò dákẹ́ jẹ́ẹ́, èmi yóò sì máa wo òréré láti ibùgbé e mi wá, gẹ́gẹ́ bí ooru gbígbóná nínú ìtànṣán oòrùn, gẹ́gẹ́ bí òjò-dídì ní àárín gbùngbùn ìkórè.”
כי כה אמר יהוה אלי אשקוטה (אשקטה) ואביטה במכוני כחם צח עלי אור כעב טל בחם קציר
5 Nítorí, kí ìkórè tó bẹ̀rẹ̀, nígbà tí ìrudí bá kún, nígbà tí ìtànná bá di èso àjàrà pípọ́n. Òun yóò sì fi dòjé rẹ́ ẹ̀ka tuntun, yóò sì mu kúrò, yóò sì gé ẹ̀ka lulẹ̀.
כי לפני קציר כתם פרח ובסר גמל יהיה נצה וכרת הזלזלים במזמרות ואת הנטישות הסיר התז
6 A ó fi wọ́n sílẹ̀ fún àwọn ẹyẹ òkè ńlá àti fún àwọn ẹranko búburú; àwọn ẹyẹ yóò fi wọ́n ṣe oúnjẹ nínú ẹ̀ẹ̀rùn àti àwọn ẹranko búburú nígbà òjò.
יעזבו יחדו לעיט הרים ולבהמת הארץ וקץ עליו העיט וכל בהמת הארץ עליו תחרף
7 Ní àkókò náà ni a ó mú ẹ̀bùn wá fún Olúwa àwọn ọmọ-ogun láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn gíga tí ẹran-ara wọn jọ̀lọ̀, láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn tí a bẹ̀rù níbi gbogbo, orílẹ̀-èdè aláfojúdi àti alájèjì èdè, ilẹ̀ ẹni tí omi pín sí yẹ́lẹyẹ̀lẹ— a ó mú àwọn ẹ̀bùn náà wá sí òkè Sioni, ibi tí orúkọ Olúwa àwọn ọmọ-ogun gbé wà.
בעת ההיא יובל שי ליהוה צבאות עם ממשך ומורט ומעם נורא מן הוא והלאה גוי קו קו ומבוסה אשר בזאו נהרים ארצו אל מקום שם יהוה צבאות הר ציון

< Isaiah 18 >