< Isaiah 13 >
1 Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ tí ó kan Babeli èyí tí Isaiah ọmọ Amosi rí.
ὅρασις ἣν εἶδεν Ησαιας υἱὸς Αμως κατὰ Βαβυλῶνος
2 Gbé àsíá sókè ní orí òkè gbẹrẹfu, kígbe sí wọn, pè wọ́n láti wọlé sí ẹnu-ọ̀nà àwọn ọlọ́lá.
ἐπ’ ὄρους πεδινοῦ ἄρατε σημεῖον ὑψώσατε τὴν φωνὴν αὐτοῖς μὴ φοβεῖσθε παρακαλεῖτε τῇ χειρί ἀνοίξατε οἱ ἄρχοντες
3 Mo ti pàṣẹ fún àwọn ẹni mímọ́ mi, mo ti pe àwọn jagunjagun mi láti gbé ìbínú mi jáde àwọn tí ń yọ̀ nínú ìṣẹ́gun mi.
ἐγὼ συντάσσω καὶ ἐγὼ ἄγω αὐτούς ἡγιασμένοι εἰσίν καὶ ἐγὼ ἄγω αὐτούς γίγαντες ἔρχονται πληρῶσαι τὸν θυμόν μου χαίροντες ἅμα καὶ ὑβρίζοντες
4 Gbọ́ ohùn kan ní àwọn orí òkè, gẹ́gẹ́ bí i ti ogunlọ́gọ̀ ènìyàn. Gbọ́ ìdàrúdàpọ̀ láàrín àwọn ìjọba, gẹ́gẹ́ bí i ti ìkórajọ àwọn orílẹ̀-èdè! Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti kó ogun rẹ̀ jọ àwọn jagunjagun fún ogun.
φωνὴ ἐθνῶν πολλῶν ἐπὶ τῶν ὀρέων ὁμοία ἐθνῶν πολλῶν φωνὴ βασιλέων καὶ ἐθνῶν συνηγμένων κύριος σαβαωθ ἐντέταλται ἔθνει ὁπλομάχῳ
5 Wọ́n wá láti ọ̀nà jíjìn réré, láti ìpẹ̀kun ọ̀run wá Olúwa pẹ̀lú àwọn ohun ìjà ìbínú rẹ̀, láti pa gbogbo orílẹ̀-èdè náà run.
ἔρχεσθαι ἐκ γῆς πόρρωθεν ἀπ’ ἄκρου θεμελίου τοῦ οὐρανοῦ κύριος καὶ οἱ ὁπλομάχοι αὐτοῦ τοῦ καταφθεῖραι τὴν οἰκουμένην ὅλην
6 Ẹ hu, nítorí ọjọ́ Olúwa súnmọ́ tòsí, yóò sì wá gẹ́gẹ́ bí ìparun láti ọ̀dọ̀ Alágbára jùlọ.
ὀλολύζετε ἐγγὺς γὰρ ἡ ἡμέρα κυρίου καὶ συντριβὴ παρὰ τοῦ θεοῦ ἥξει
7 Nítorí èyí, gbogbo ọwọ́ ni yóò rọ, ọkàn ẹnìkọ̀ọ̀kan yóò rẹ̀wẹ̀sì.
διὰ τοῦτο πᾶσα χεὶρ ἐκλυθήσεται καὶ πᾶσα ψυχὴ ἀνθρώπου δειλιάσει
8 Ẹ̀rù yóò gbá wọn mú, ìrora àti ìpayínkeke yóò dìwọ́n mú, wọn yóò kérora gẹ́gẹ́ bí obìnrin tí ó ń rọbí. Ẹnìkínní yóò wo ẹnìkejì rẹ̀ pẹ̀lú ìpayà ojú wọn á sì gbinájẹ.
καὶ ταραχθήσονται οἱ πρέσβεις καὶ ὠδῖνες αὐτοὺς ἕξουσιν ὡς γυναικὸς τικτούσης καὶ συμφοράσουσιν ἕτερος πρὸς τὸν ἕτερον καὶ ἐκστήσονται καὶ τὸ πρόσωπον αὐτῶν ὡς φλὸξ μεταβαλοῦσιν
9 Kíyèsi i, ọjọ́ Olúwa ń bọ̀ ọjọ́ búburú, pẹ̀lú ìbínú àti ìrunú gbígbóná— láti sọ ilẹ̀ náà dahoro, àti láti pa àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ inú rẹ̀ run.
ἰδοὺ γὰρ ἡμέρα κυρίου ἀνίατος ἔρχεται θυμοῦ καὶ ὀργῆς θεῖναι τὴν οἰκουμένην ὅλην ἔρημον καὶ τοὺς ἁμαρτωλοὺς ἀπολέσαι ἐξ αὐτῆς
10 Àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run àti ìkójọpọ̀ wọn kò sì ní fi ìmọ́lẹ̀ wọn hàn. Àṣẹ̀ṣẹ̀yọ oòrùn yóò di òkùnkùn àti òṣùpá kò ní fi ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ hàn.
οἱ γὰρ ἀστέρες τοῦ οὐρανοῦ καὶ ὁ Ὠρίων καὶ πᾶς ὁ κόσμος τοῦ οὐρανοῦ τὸ φῶς οὐ δώσουσιν καὶ σκοτισθήσεται τοῦ ἡλίου ἀνατέλλοντος καὶ ἡ σελήνη οὐ δώσει τὸ φῶς αὐτῆς
11 Èmi yóò jẹ ayé ní ìyà nítorí ibi rẹ̀, àwọn ìkà nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Èmi yóò fi òpin sí gààrù àwọn agbéraga èmi ó sì rẹ ìgbéraga àwọn aláìláàánú sílẹ̀.
καὶ ἐντελοῦμαι τῇ οἰκουμένῃ ὅλῃ κακὰ καὶ τοῖς ἀσεβέσιν τὰς ἁμαρτίας αὐτῶν καὶ ἀπολῶ ὕβριν ἀνόμων καὶ ὕβριν ὑπερηφάνων ταπεινώσω
12 Èmi yóò jẹ́ kí ọkùnrin kí ó wọn ju ojúlówó wúrà lọ, yóò sì ṣọ̀wọ́n ju wúrà Ofiri lọ.
καὶ ἔσονται οἱ καταλελειμμένοι ἔντιμοι μᾶλλον ἢ τὸ χρυσίον τὸ ἄπυρον καὶ ὁ ἄνθρωπος μᾶλλον ἔντιμος ἔσται ἢ ὁ λίθος ὁ ἐκ Σουφιρ
13 Nítorí náà èmi yóò jẹ́ kí àwọn ọ̀run kí ó wárìrì; ayé yóò sì mì tìtì ní ibùjókòó rẹ̀ láti ọwọ́ ìbínú Olúwa àwọn ọmọ-ogun, ní ọjọ́ ìbínú gbígbóná rẹ.
ὁ γὰρ οὐρανὸς θυμωθήσεται καὶ ἡ γῆ σεισθήσεται ἐκ τῶν θεμελίων αὐτῆς διὰ θυμὸν ὀργῆς κυρίου σαβαωθ τῇ ἡμέρᾳ ᾗ ἂν ἐπέλθῃ ὁ θυμὸς αὐτοῦ
14 Gẹ́gẹ́ bí egbin tí à ń dọdẹ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí àgùntàn tí kò ní olùṣọ́, ọ̀kọ̀ọ̀kan yóò padà tọ àwọn ènìyàn rẹ̀ lọ, ọ̀kọ̀ọ̀kan yóò sá padà sí ilẹ̀ abínibí i rẹ̀.
καὶ ἔσονται οἱ καταλελειμμένοι ὡς δορκάδιον φεῦγον καὶ ὡς πρόβατον πλανώμενον καὶ οὐκ ἔσται ὁ συνάγων ὥστε ἄνθρωπον εἰς τὸν λαὸν αὐτοῦ ἀποστραφῆναι καὶ ἄνθρωπον εἰς τὴν χώραν αὐτοῦ διῶξαι
15 Ẹnikẹ́ni tí a bá gbámú ni a ó wọ́ nílẹ̀ tuurutu, gbogbo àwọn tí ọwọ́ bá tẹ̀ ni yóò ti ipa idà kú.
ὃς γὰρ ἂν ἁλῷ ἡττηθήσεται καὶ οἵτινες συνηγμένοι εἰσίν μαχαίρᾳ πεσοῦνται
16 Àwọn ọ̀dọ́mọdé wọn ni a ó fọ́ sí wẹ́wẹ́ níṣojú wọn, gbogbo ilẹ̀ wọn ni a ó kó àwọn aya wọn ni a ó sì bá dàpọ̀.
καὶ τὰ τέκνα αὐτῶν ἐνώπιον αὐτῶν ῥάξουσιν καὶ τὰς οἰκίας αὐτῶν προνομεύσουσιν καὶ τὰς γυναῖκας αὐτῶν ἕξουσιν
17 Kíyèsi i, èmi yóò ru àwọn Media sókè sí wọn, àwọn tí kò bìkítà fún fàdákà tí kò sì ní inú dídùn sí wúrà.
ἰδοὺ ἐπεγείρω ὑμῖν τοὺς Μήδους οἳ οὐ λογίζονται ἀργύριον οὐδὲ χρυσίου χρείαν ἔχουσιν
18 Ọrùn wọn yóò ré àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin lulẹ̀; wọn kò ní ṣàánú àwọn ọ̀dọ́mọdé tàbí kí wọn síjú àánú wo àwọn ọmọdé.
τοξεύματα νεανίσκων συντρίψουσιν καὶ τὰ τέκνα ὑμῶν οὐ μὴ ἐλεήσωσιν οὐδὲ ἐπὶ τοῖς τέκνοις οὐ φείσονται οἱ ὀφθαλμοὶ αὐτῶν
19 Babeli, ohun ọ̀ṣọ́ àwọn ìjọba ògo ìgbéraga àwọn ará Babeli ni Ọlọ́run yóò da ojú rẹ̀ bolẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Sodomu àti Gomorra.
καὶ ἔσται Βαβυλών ἣ καλεῖται ἔνδοξος ὑπὸ βασιλέως Χαλδαίων ὃν τρόπον κατέστρεψεν ὁ θεὸς Σοδομα καὶ Γομορρα
20 A kì yóò tẹ̀ ibẹ̀ dó mọ́ tàbí kí á gbé inú rẹ̀ láti ìrandíran; ará Arabia kì yóò pa àgọ́ níbẹ̀ mọ́, olùṣọ́-àgùntàn kan kì yóò kó ẹran rẹ̀ sinmi níbẹ̀.
οὐ κατοικηθήσεται εἰς τὸν αἰῶνα χρόνον οὐδὲ μὴ εἰσέλθωσιν εἰς αὐτὴν διὰ πολλῶν γενεῶν οὐδὲ μὴ διέλθωσιν αὐτὴν Ἄραβες οὐδὲ ποιμένες οὐ μὴ ἀναπαύσωνται ἐν αὐτῇ
21 Ṣùgbọ́n àwọn ẹranko igbó ni yóò dùbúlẹ̀ níbẹ̀, àwọn ajáko yóò kún inú ilé wọn, níbẹ̀ ni àwọn òwìwí yóò máa gbé níbẹ̀ ni àwọn ewúrẹ́ igbó yóò ti máa bẹ́ kiri.
καὶ ἀναπαύσονται ἐκεῖ θηρία καὶ ἐμπλησθήσονται αἱ οἰκίαι ἤχου καὶ ἀναπαύσονται ἐκεῖ σειρῆνες καὶ δαιμόνια ἐκεῖ ὀρχήσονται
22 Ìkookò yóò máa gbó ní ibùba wọn, àwọn ajáko nínú arẹwà ààfin wọn.
καὶ ὀνοκένταυροι ἐκεῖ κατοικήσουσιν καὶ νοσσοποιήσουσιν ἐχῖνοι ἐν τοῖς οἴκοις αὐτῶν ταχὺ ἔρχεται καὶ οὐ χρονιεῖ