< Hosea 1 >

1 Ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó tọ Hosea ọmọ Beeri wá ní àkókò ìjọba Ussiah, Jotamu, Ahasi àti Hesekiah; àwọn ọba Juda àti ní àkókò ọba Jeroboamu ọmọ Jehoaṣi ní Israẹli.
דבר יהוה אשר היה אל הושע בן בארי בימי עזיה יותם אחז יחזקיה מלכי יהודה--ובימי ירבעם בן יואש מלך ישראל
2 Nígbà tí Olúwa bẹ̀rẹ̀ sí ní sọ̀rọ̀ láti ẹnu Hosea, Olúwa wí fún un pé, “Lọ, fẹ́ àgbèrè obìnrin kan fún ara rẹ, kí ó sì bí ọmọ àgbèrè fún ọ nípasẹ̀ àwọn ọkùnrin mìíràn, nítorí ilẹ̀ ti ṣẹ ẹ̀ṣẹ̀ àgbèrè púpọ̀ nípa yíyapa kúrò lọ́dọ̀ Olúwa.”
תחלת דבר יהוה בהושע ויאמר יהוה אל הושע לך קח לך אשת זנונים וילדי זנונים--כי זנה תזנה הארץ מאחרי יהוה
3 Nígbà náà ni ó sì lọ, ó sì fẹ́ Gomeri ọmọbìnrin Diblaimu, ọmọbìnrin náà sì lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan fún un.
וילך ויקח את גמר בת דבלים ותהר ותלד לו בן
4 Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Hosea pé, “Pe orúkọ ọmọ náà ní Jesreeli, nítorí pé láìpẹ́ ni èmi yóò jẹ ìdílé Jehu ní ìyà fún ẹ̀jẹ̀ àwọn ènìyàn tó pa ní ìpakúpa ní Jesreeli, Èmi yóò sì mú ìjọba Israẹli wá sí òpin.
ויאמר יהוה אליו קרא שמו יזרעאל כי עוד מעט ופקדתי את דמי יזרעאל על בית יהוא והשבתי ממלכות בית ישראל
5 Ní ọjọ́ náà ni Èmi yóò ṣẹ́ ọrun Israẹli ní àfonífojì Jesreeli.”
והיה ביום ההוא ושברתי את קשת ישראל בעמק יזרעאל
6 Gomeri sì tún lóyún, ó sì bí ọmọbìnrin kan. Olúwa sọ fún un pé, “Pe orúkọ rẹ̀ ní Lo-ruhama, nítorí pé, Èmi kò ní ṣàánú fún ilé Israẹli mọ́, Èmi kò sì ní dáríjì wọ́n.
ותהר עוד ותלד בת ויאמר לו קרא שמה לא רחמה כי לא אוסיף עוד ארחם את בית ישראל--כי נשא אשא להם
7 Síbẹ̀, èmi yóò ṣàánú fún ilé Juda, èmi ó gbà wọ́n—kì í ṣe nípa ọfà, idà tàbí ogun, ẹṣin tàbí kẹ̀kẹ́ ẹlẹ́ṣin bí kò ṣe nípa Olúwa Ọlọ́run wọn.”
ואת בית יהודה ארחם והושעתים ביהוה אלהיהם ולא אושיעם בקשת ובחרב ובמלחמה בסוסים ובפרשים
8 Lẹ́yìn ìgbà tí ó gba ọmú lẹ́nu Lo-ruhama, ó sì lóyún ó sì bí ọmọkùnrin mìíràn. Nígbà náà ni
ותגמל את לא רחמה ותהר ותלד בן
9 Olúwa sì sọ fún un pé, “Pe orúkọ rẹ̀ ní Lo-Ammi, nítorí pé ẹ kì í ṣe ènìyàn mi, èmi náà kì í sì í ṣe Ọlọ́run yín.
ויאמר קרא שמו לא עמי כי אתם לא עמי ואנכי לא אהיה לכם
10 “Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Israẹli yóò pọ̀ bí i iyanrìn etí Òkun tí a kò le wọ́n, tí a kò sì le è kà, yóò sì ṣe. Ní ibi tí wọ́n ti sọ fún wọn pé. ‘Ẹ̀yin kì í ṣe ènìyàn mi,’ níbẹ̀ ni a ó ti máa pè wọ́n ní ‘Ọmọ Ọlọ́run alààyè.’
והיה מספר בני ישראל כחול הים אשר לא ימד ולא יספר והיה במקום אשר יאמר להם לא עמי אתם יאמר להם בני אל חי
11 Àwọn ènìyàn Juda àti àwọn ènìyàn Israẹli yóò parapọ̀, wọn yóò sì yan olórí kan tí yóò jáde láti ilẹ̀ náà, nítorí pé ọjọ́ ńlá ni ọjọ́ Jesreeli yóò jẹ́.
ונקבצו בני יהודה ובני ישראל יחדו ושמו להם ראש אחד ועלו מן הארץ כי גדול יום יזרעאל

< Hosea 1 >