< Hosea 8 >

1 “Fi ìpè sí ẹnu rẹ! Ẹyẹ idì wà lórí ilé Olúwa nítorí pé àwọn ènìyàn ti dalẹ̀ májẹ̀mú, wọ́n sì ti ṣọ̀tẹ̀ sí òfin mi.
אל חכך שפר כנשר על בית יהוה יען עברו בריתי ועל תורתי פשעו׃
2 Israẹli kígbe pè mí, ‘Ọlọ́run wa, àwa mọ̀ ọ́n!’
לי יזעקו אלהי ידענוך ישראל׃
3 Ṣùgbọ́n Israẹli ti kọ ohun tí ó dára sílẹ̀ ọ̀tá yóò sì máa lépa rẹ̀.
זנח ישראל טוב אויב ירדפו׃
4 Wọ́n fi àwọn ọba jẹ ṣùgbọ́n, kì í ṣe nípasẹ̀ mi wọ́n yan ọmọ-aládé láì si ìmọ̀ mi níbẹ̀. Wọ́n fi fàdákà àti wúrà ṣe ère fún ara wọn, si ìparun ara wọn.
הם המליכו ולא ממני השירו ולא ידעתי כספם וזהבם עשו להם עצבים למען יכרת׃
5 Ju ère ẹgbọrọ màlúù rẹ, ìwọ Samaria! Ìbínú mi ń ru sí wọn: yóò ti pẹ́ tó kí wọ́n tó dé ipò àìmọ̀kan?
זנח עגלך שמרון חרה אפי בם עד מתי לא יוכלו נקין׃
6 Israẹli ni wọ́n ti wá! Ère yìí agbẹ́gilére ló ṣe é, àní ère ẹgbọrọ màlúù Samaria, ni a ó fọ́ túútúú.
כי מישראל והוא חרש עשהו ולא אלהים הוא כי שבבים יהיה עגל שמרון׃
7 “Wọ́n gbin afẹ́fẹ́ wọ́n sì ká ìjì. Igi ọkà kò lórí, kò sì ní mú oúnjẹ wá. Bí ó bá tilẹ̀ ní ọkà àwọn àjèjì ni yóò jẹ.
כי רוח יזרעו וסופתה יקצרו קמה אין לו צמח בלי יעשה קמח אולי יעשה זרים יבלעהו׃
8 A ti gbé Israẹli mì, báyìí, ó sì ti wà láàrín àwọn orílẹ̀-èdè bí ohun èlò tí kò wúlò.
נבלע ישראל עתה היו בגוים ככלי אין חפץ בו׃
9 Nítorí pé wọ́n ti gòkè lọ sí Asiria gẹ́gẹ́ bí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó tó ń rìn kiri. Efraimu ti ta ara rẹ̀ fún àwọn olólùfẹ́ rẹ̀.
כי המה עלו אשור פרא בודד לו אפרים התנו אהבים׃
10 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti ta ara wọn sí àárín Orílẹ̀-èdè, Èmi ó ṣà wọ́n jọ nísinsin yìí. Wọn ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣòfò dànù lọ́wọ́ ìnilára ọba alágbára.
גם כי יתנו בגוים עתה אקבצם ויחלו מעט ממשא מלך שרים׃
11 “Nítorí Efraimu ti kọ́ pẹpẹ púpọ̀ fún ìrúbọ ẹ̀ṣẹ̀ gbogbo rẹ̀ ti di pẹpẹ ìdẹ́ṣẹ̀ fún un
כי הרבה אפרים מזבחת לחטא היו לו מזבחות לחטא׃
12 Mo kọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun tí ó jẹ́ òfin mi fún wọn, ṣùgbọ́n wọn kà á sí ohun àjèjì.
אכתוב לו רבו תורתי כמו זר נחשבו׃
13 Wọ́n ń rú ẹbọ tí wọ́n yàn fún mi, wọ́n sì ń jẹ ẹran ibẹ̀, ṣùgbọ́n inú Olúwa kò dùn sí wọn. Báyìí yóò rántí ìwà búburú wọn yóò sì jẹ wọ́n ní yà fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Wọn yóò padà sí Ejibiti.
זבחי הבהבי יזבחו בשר ויאכלו יהוה לא רצם עתה יזכר עונם ויפקד חטאותם המה מצרים ישובו׃
14 Nítorí Israẹli ti gbàgbé ẹlẹ́dàá rẹ̀ Ó sì ń kọ́ ààfin púpọ̀ Juda ti kọ́ ìlú olódi púpọ̀ ṣùgbọ́n èmi ó rán iná kan sí orí àwọn ìlú rẹ̀ èyí tí yóò jẹ ibi agbára rẹ̀ run.”
וישכח ישראל את עשהו ויבן היכלות ויהודה הרבה ערים בצרות ושלחתי אש בעריו ואכלה ארמנתיה׃

< Hosea 8 >