< Hosea 4 >

1 Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa ẹ̀yin ọmọ Israẹli, nítorí pé Olúwa fi ẹ̀sùn kan ẹ̀yin tí ń gbé ní ilẹ̀ náà. “Kò sí ìwà òtítọ́, kò sí ìfẹ́, Kò sí ìmọ̀ Ọlọ́run ní ilẹ̀ náà,
Ascoltate la parola del Signore, o Israeliti, poichè il Signore ha un processo con gli abitanti del paese. Non c'è infatti sincerità né amore del prossimo, nè conoscenza di Dio nel paese.
2 àfi èpè, irọ́ pípa àti ìpànìyàn olè jíjà àti panṣágà. Wọ́n rú gbogbo òfin, ìtàjẹ̀ sílẹ̀ sì ń gorí ìtàjẹ̀ sílẹ̀.
Si giura, si mentisce, si uccide, si ruba, si commette adulterio, si fa strage e si versa sangue su sangue.
3 Nítorí èyí, ilẹ̀ náà ń ṣọ̀fọ̀, gbogbo olùgbé ibẹ̀ sì ń ṣòfò dànù. Ẹranko igbó àti ẹyẹ ojú ọ̀run àti ẹja inú omi ló ń kú.
Per questo è in lutto il paese e chiunque vi abita langue insieme con gli animali della terra e con gli uccelli del cielo; perfino i pesci del mare periranno.
4 “Ṣùgbọ́n kí ẹnikẹ́ni má ṣe mú ẹ̀sùn wá, kí ẹnìkan má sì ṣe fi ẹ̀sùn kan ẹnìkejì nítorí àwọn ènìyàn rẹ̀ dàbí àwọn ti ń fi ẹ̀sùn kan àlùfáà.
Ma nessuno accusi, nessuno contesti; contro di te, sacerdote, muovo l'accusa.
5 Ẹ ń ṣubú lọ́sàn án àti lóru àwọn wòlíì yín sì ń ṣubú pẹ̀lú yín. Èmi ó pa ìyá rẹ run,
Tu inciampi di giorno e il profeta con te inciampa di notte e fai perire tua madre.
6 àwọn ènìyàn mi ń ṣègbé nítorí pé wọn kò ní ìmọ̀. “Nítorí pé ẹ ti kọ ìmọ̀ sílẹ̀. Èmi náà kọ̀ yín ní àlùfáà mi; nítorí pé ẹ ti kọ òfin Ọlọ́run yín sílẹ̀, Èmi náà yóò gbàgbé àwọn ọmọ yín.
Perisce il mio popolo per mancanza di conoscenza. Poichè tu rifiuti la conoscenza, rifiuterò te come mio sacerdote; hai dimenticato la legge del tuo Dio e io dimenticherò i tuoi figli.
7 Bí àwọn àlùfáà ṣe ń pọ̀ sí i bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe ń dẹ́ṣẹ̀ sí mi. Wọ́n yí ògo mi padà sí ohun ìtìjú
Tutti hanno peccato contro di me; cambierò la loro gloria in vituperio.
8 wọ́n ń jẹun nípa ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn mi, wọ́n sì ń gbádùn nínú ìwà búburú wọn.
Essi si nutrono del peccato del mio popolo e sono avidi della sua iniquità.
9 Yóò sì ṣe gẹ́gẹ́ bí ènìyàn ṣe rí náà ni àwọn àlùfáà rí. Èmi ó jẹ gbogbo wọn ní yà nítorí ọ̀nà wọn. Èmi ó sì san án fún wọn gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ wọn.
Il popolo e il sacerdote avranno la stessa sorte; li punirò per la loro condotta, e li retribuirò dei loro misfatti.
10 “Wọn ó máa jẹun ṣùgbọ́n wọn kò ní yó; wọn ó ṣe àgbèrè ṣùgbọ́n, wọn kò ni pọ̀ sí i, nítorí pé wọ́n ti kọ Olúwa sílẹ̀, wọ́n sì ti fi ara wọn
Mangeranno, ma non si sazieranno, si prostituiranno, ma non avranno prole, perchè hanno abbandonato il Signore per darsi alla prostituzione.
11 fún àgbèrè; wọ́n fi ara wọn fún wáìnì àtijọ́, àti tuntun èyí tó gba òye àwọn ènìyàn mi sọnù.
Il vino e il mosto tolgono il senno.
12 Wọ́n ń gba ìmọ̀ràn lọ́wọ́ ère igi ọ̀pá igi sì ń dá wọn lóhùn. Ẹ̀mí àgbèrè ti mú wọn ṣìnà wọ́n sì jẹ́ aláìṣòótọ́ sí Ọlọ́run wọn.
Il mio popolo consulta il suo pezzo di legno e il suo bastone gli dà il responso, poichè uno spirito di prostituzione li svia e si prostituiscono, allontanandosi dal loro Dio.
13 Wọ́n ń rú ẹbọ lórí àwọn òkè ńlá, wọ́n sì ń sun ọrẹ tùràrí lórí àwọn òkè kékeré, lábẹ́ igi óákù, àti igi Poplari àti igi ẹlimuati onírúurú igi tí ìbòjú rẹ̀ dára. Nítorí náà àwọn ọmọbìnrin yín yóò ṣe àgbèrè àti àwọn àfẹ́sọ́nà yín yóò ṣe àgbèrè.
Sulla cima dei monti fanno sacrifici e sui colli bruciano incensi sotto la quercia, i pioppi e i terebinti, perchè buona è la loro ombra. Perciò si prostituiscono le vostre figlie e le vostre nuore commettono adulterio.
14 “Èmi kò ní jẹ àwọn ọmọbìnrin yín ní yà nígbà tí wọ́n bá ṣe àgbèrè tàbí àwọn àfẹ́sọ́nà ọmọ yín, nígbà tí wọ́n bá ṣe àgbèrè nítorí pé àwọn ọkùnrin pàápàá ń bá alágbèrè kẹ́gbẹ́. Wọ́n sì ń rú ẹbọ pẹ̀lú àwọn alágbèrè ojúbọ òrìṣà. Nítorí náà, ènìyàn tí kò bá ní òye yóò parun!
Non punirò le vostre figlie se si prostituiscono, nè le vostre nuore se commettono adulterio; poichè essi stessi si appartano con le prostitute e con le prostitute sacre offrono sacrifici; un popolo, che non comprende, va a precipizio.
15 “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé o ṣe àgbèrè ìwọ Israẹli, ìdájọ́ yìí wà fún un yín. Ẹ má ṣe jẹ́ kí Juda di ẹlẹ́bi. “Ẹ má ṣe lọ sí Gilgali. Ẹ má sì ṣe gòkè lọ sí Beti-Afeni ẹ má sì búra pé, ‘Bí Olúwa ti wà láààyè nítòótọ́!’
Se ti prostituisci tu, Israele, non si renda colpevole Giuda. Non andate a Gàlgala, non salite a Bet-Avèn, non giurate per il Signore vivente.
16 Àwọn ọmọ Israẹli ṣe agídí bí alágídí ọmọ màlúù. Báwo wá ni Olúwa ṣe fẹ́ bọ́ wọn bí àgùntàn ní pápá oko tútù?
E poiché come giovenca ribelle si ribella Israele, forse potrà pascolarlo il Signore come agnello in luoghi aperti?
17 Efraimu ti darapọ̀ mọ́ òrìṣà, ẹ fi sílẹ̀!
Si è alleato agli idoli Efraim,
18 Bí ohun mímu wọn bá tilẹ̀ tán, wọ́n tún tẹ̀síwájú nínú àgbèrè. Àwọn olórí wọn fẹ́ràn ohun ìtìjú ju ohun ìyìn lọ.
si accompagna ai beoni; si son dati alla prostituzione, han preferito il disonore alla loro gloria.
19 Ìjì ni yóò gbá wọn lọ. Gbogbo ìrúbọ wọn yóò sì kó ìtìjú bá wọn.
Un vento li travolgerà con le sue ali e si vergogneranno dei loro sacrifici.

< Hosea 4 >