< Hosea 2 >
1 “Sọ fún àwọn arákùnrin rẹ, ‘Ènìyàn mi,’ kí o sì wí fún àwọn arábìnrin rẹ ‘Àyànfẹ́ mi.’
“Say of your brothers, ‘My people,’ and of your sisters, ‘My loved one.’
2 “Ẹ bá ìyá yín wí, ẹ bá a wí, nítorí pé kì í ṣe ìyàwó mi, Èmi náà kì í sì í ṣe ọkọ rẹ̀. Jẹ́ kí ó yọ àgbèrè rẹ̀ kúrò lójú rẹ̀ àti àìṣòótọ́ kúrò ní àyà rẹ̀.
Rebuke your mother, rebuke her, for she is not My wife, and I am not her husband. Let her remove the adultery from her face and the unfaithfulness from between her breasts.
3 Àìṣe bẹ́ẹ̀ èmi yóò tú u sí ìhòhò, Èmi yóò sì gbé e kalẹ̀ bí ọjọ́ tí a bí i. Èmi yóò ṣe ọ́ bí i aṣálẹ̀ ilẹ̀, Èmi yóò sì sọ ọ́ di ìyàngbẹ ilẹ̀ Èmi yóò sì fi òǹgbẹ gbẹ ẹ́.
Otherwise, I will strip her naked and expose her like the day of her birth. I will make her like a desert and turn her into a parched land, and I will let her die of thirst.
4 Èmi kò ní fi àánú mi hàn sí àwọn ọmọ rẹ̀ nítorí ọmọ àgbèrè ni wọ́n jẹ́.
I will have no compassion on her children, because they are the children of adultery.
5 Nítorí ìyá wọn ti hùwà àgbèrè, ó sì lóyún wọn nínú ìtìjú. Ó wí pé, ‘Èmi ó tún tọ́ àwọn àyànfẹ́ mi lẹ́yìn, tó ń fún mi ní oúnjẹ àti omi, ní irun àgùntàn mi àti ọ̀gbọ̀ mi, òróró mi àti ohun mímu mi.’
For their mother has played the harlot and has conceived them in disgrace. For she thought, ‘I will go after my lovers, who give me bread and water, wool and linen, oil and drink.’
6 Nítorí náà, èmi ó fi ẹ̀gún dì í lọ́nà, Èmi ó mọ odi yí i ká kí ó má ba à rọ́nà lọ.
Therefore, behold, I will hedge up her path with thorns; I will enclose her with a wall, so she cannot find her way.
7 Yóò sáré lé àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ ṣùgbọ́n kò ní bá wọn; yóò wá wọn ṣùgbọ́n kò ní rí wọn. Nígbà náà ni yóò sọ pé, ‘Èmi ó padà sí ọ̀dọ̀ ọkọ mi àkọ́kọ́ nítorí pé ó dára fún mi nígbà náà ju ìsinsin yìí lọ.’
She will pursue her lovers but not catch them; she will seek them but not find them. Then she will say, ‘I will return to my first husband, for then I was better off than now.’
8 Nítorí pé kò tí ì mọ̀ pé èmi ni àti ẹni tó fún un ní ọkà, ọtí wáìnì tuntun àti òróró ẹni tí ó fún un ní fàdákà àti wúrà lọ́pọ̀lọ́pọ̀, èyí tí wọ́n lò fún Baali.
For she does not acknowledge that it was I who gave her grain, new wine, and oil, who lavished on her silver and gold— which they crafted for Baal.
9 “Nítorí náà, èmi yóò mú ọkà mi kúrò nígbà tó bá pọ́n, èmi yóò sì mú wáìnì mi kúrò ní àsìkò rẹ̀. Èmi yóò sì gba irun àgùntàn àti ọ̀gbọ̀ mi padà ti mo ti fi fún un láti bo ìhòhò rẹ̀.
Therefore I will take back My grain in its time and My new wine in its season; I will take away My wool and linen, which were given to cover her nakedness.
10 Èmi yóò sì fi ìwà ìtìjú rẹ̀ hàn lójú àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ kò sí ẹni tí yóò gbà á sílẹ̀ lọ́wọ́ mi,
And then I will expose her lewdness in the sight of her lovers, and no one will deliver her out of My hands.
11 Èmi yóò mú gbogbo ayọ̀ rẹ̀ wá sí òpin: àjọ̀dún ọdọọdún rẹ̀, oṣù tuntun rẹ̀, ọjọ́ ìsinmi, àti gbogbo àwọn àjọ̀dún tí a yàn.
I will put an end to all her exultation: her feasts, New Moons, and Sabbaths— all her appointed feasts.
12 Èmi yóò pa àjàrà àti igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀ run, èyí tí ó pè ní èrè rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn olólùfẹ́ rẹ̀, Èmi yóò sọ wọ́n di igbó, àwọn ẹranko búburú yóò sì jẹ́ wọn run.
I will destroy her vines and fig trees, which she thinks are the wages paid by her lovers. So I will make them into a thicket, and the beasts of the field will devour them.
13 Èmi yóò bẹ̀ ọjọ́ Baalimu wò ní ara rẹ̀ nínú èyí tó ń fi tùràrí jóná fún Baali; tí ó fi òrùka etí àti ohun ọ̀ṣọ́ rẹ̀, ṣe ara rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́, tó sì tẹ̀lé àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ lọ. Ṣùgbọ́n èmi ni òun gbàgbé,” ni Olúwa wí.
I will punish her for the days of the Baals when she burned incense to them, when she decked herself with rings and jewelry, and went after her lovers. But Me she forgot,”
14 “Nítorí náà, èmi yóò tàn án, Èmi ó sì mú u lọ sí ilẹ̀ aṣálẹ̀, Èmi ó fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ bá a sọ̀rọ̀
“Therefore, behold, I will allure her and lead her to the wilderness, and speak to her tenderly.
15 Níbẹ̀ ni èmi yóò ti dá ọgbà àjàrà rẹ̀ padà fún un, Èmi yóò fi àfonífojì Akori ṣe ìlẹ̀kùn ìrètí fún un. Yóò sì kọrin níbẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìgbà èwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìgbà tó kúrò ní Ejibiti.
There I will give back her vineyards and make the Valley of Achor into a gateway of hope. There she will respond as she did in the days of her youth, as in the day she came up out of Egypt.
16 “Yóò sì ṣe ní ọjọ́ náà, ìwọ yóò pè mí ní ‘ọkọ mi’; ìwọ kò sì ní pè mí ní ‘olúwa à mi mọ́,’ ni Olúwa wí.
In that day,” declares the LORD, “you will call Me ‘my Husband,’ and no longer call Me ‘my Master.’
17 Èmi yóò mú orúkọ, àwọn òrìṣà Baali kúrò lẹ́nu rẹ̀; ìwọ kò sì ní rí orúkọ òrìṣà Baali pè mọ́.
For I will remove from her lips the names of the Baals; no longer will their names be invoked.
18 Ní ọjọ́ náà, èmi yóò ṣe májẹ̀mú fún wọn àti àwọn ẹranko igbó àti ẹyẹ ojú ọ̀run àti àwọn ẹ̀dá tí ń rìn lórí ilẹ̀. Kí wọn má bà á bẹ̀rù ara wọn mọ́. Ọfà, idà àti ogun jíjà ni èmi ó parun ní ilẹ̀ náà kí gbogbo ènìyàn bá a lè wà ní àìléwu.
On that day I will make a covenant for them with the beasts of the field and the birds of the air and the creatures that crawl on the ground. And I will abolish bow and sword and weapons of war in the land, and will make them lie down in safety.
19 Èmi yóò fẹ́ ọ fún ara mi títí láé; Èmi ó fẹ́ ọ ní ìwà òdodo àti òtítọ́, ní ìfẹ́ àti àánú.
So I will betroth you to Me forever; I will betroth you in righteousness and justice, in loving devotion and compassion.
20 Èmi yóò fẹ́ ọ fún ara mi ní òtítọ́ ìwọ yóò sì mọ Olúwa.
And I will betroth you in faithfulness, and you will know the LORD.”
21 “Èmi yóò sì dáhùn ní ọjọ́ náà,” ni Olúwa wí; “Èmi yóò dá àwọn ọ̀run lóhùn àwọn ọ̀run yóò sì dá ilẹ̀ lóhùn;
“On that day I will respond—” declares the LORD— “I will respond to the heavens, and they will respond to the earth.
22 ilẹ̀ náà yóò sì dá ọkà, wáìnì tuntun àti òróró lóhùn Gbogbo wọn ó sì dá Jesreeli lóhùn.
And the earth will respond to the grain, to the new wine and oil, and they will respond to Jezreel.
23 Èmi ó sì gbìn ín fún ara mi lórí ilẹ̀ náà, Èmi yóò ṣàánú fún ẹni tí kò tì í ri ‘Àánú gbà.’ Èmi yóò sọ fún àwọn tí ‘Kì í ṣe ènìyàn mi pé,’ ‘Ẹ̀yin ni ènìyàn mi’; àwọn náà yóò sì wí pé, ‘Ìwọ ni Ọlọ́run mi.’”
And I will sow her as My own in the land, and I will have compassion on ‘No Compassion.’ I will say to those called ‘Not My People,’ ‘You are My people,’ and they will say, ‘You are my God.’”