< Hosea 14 >

1 Yípadà ìwọ Israẹli sí Olúwa Ọlọ́run rẹ. Ẹ̀ṣẹ̀ rẹ ló fa ìparun rẹ!
שובה ישראל עד יהוה אלהיך כי כשלת בעונך
2 Ẹ gba ọ̀rọ̀ Olúwa gbọ́, kí ẹ sì yípadà sí Olúwa. Ẹ sọ fún un pé, “Darí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá kí o sì fi oore-ọ̀fẹ́ gbà wá, kí àwa kí ó lè fi ètè wa sán an fún ọ
קחו עמכם דברים ושובו אל יהוה אמרו אליו כל תשא עון וקח טוב ונשלמה פרים שפתינו
3 Asiria kò le gbà wá là; a kò ní í gorí ẹṣin ogun. A kò sì ní tún sọ ọ́ mọ́ láé, ‘Àwọn ni òrìṣà wa’ sí àwọn ohun tí ó fi ọwọ́ wa ṣe; nítorí pé lọ́dọ̀ rẹ ni àwọn aláìní baba tí ń rí àánú.”
אשור לא יושיענו על סוס לא נרכב ולא נאמר עוד אלהינו למעשה ידינו--אשר בך ירחם יתום
4 “Èmi wo àgàbàgebè wọn sàn, Èmi ó sì fẹ́ràn wọn, lọ́fẹ̀ẹ́, nítorí ìbínú mi ti yípadà kúrò lọ́dọ̀ wọn.
ארפא משובתם--אהבם נדבה כי שב אפי ממנו
5 Èmi o dàbí ìrì sí Israẹli, wọn o sì yọ ìtànná bi ewéko lílì. Bi kedari ti Lebanoni yóò si ta gbòǹgbò.
אהיה כטל לישראל יפרח כשושנה ויך שרשיו כלבנון
6 Àṣẹ̀ṣẹ̀yọ ẹ̀ka rẹ̀ yóò dàgbà, dídán ẹwà yóò rẹ̀ dànù bí igi olifi. Òórùn rẹ yóò sì dàbí igi kedari ti Lebanoni.
ילכו ינקותיו ויהי כזית הודו וריח לו כלבנון
7 Àwọn ènìyàn yóò tún padà gbé lábẹ́ òjijì rẹ̀. Yóò rúwé bi ọkà. Yóò sì yọ ìtànná bi àjàrà, òórùn rẹ yóò dàbí ti wáìnì Lebanoni.
ישבו ישבי בצלו יחיו דגן ויפרחו כגפן זכרו כיין לבנון
8 Ìwọ Efraimu, kín ló tún kù tí mo ní ṣe pẹ̀lú ère òrìṣà? Èmi ó dá a lóhùn, èmi ó sì ṣe ìtọ́jú rẹ. Mo dàbí igi junifa tó ń fi gbogbo ìgbà tutù, èso tí ìwọ ń so si ń wá láti ọ̀dọ̀ mi.”
אפרים מה לי עוד לעצבים אני עניתי ואשורנו אני כברוש רענן--ממני פריך נמצא
9 Ta ni ọlọ́gbọ́n? Òun yóò mòye àwọn nǹkan wọ̀nyí. Ta a ní ó mọ̀? Òun yóò ní ìmọ̀ wọn. Títọ́ ni ọ̀nà Olúwa àwọn olódodo si ń rìn nínú wọn, ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́tẹ̀ ni yóò kọsẹ̀ nínú wọn.
מי חכם ויבן אלה נבון וידעם כי ישרים דרכי יהוה וצדקים ילכו בם ופשעים יכשלו בם

< Hosea 14 >