< Hosea 12 >
1 Efraimu ń jẹ afẹ́fẹ́; o ń lépa afẹ́fẹ́ ìwọ̀-oòrùn ní gbogbo ọjọ́. O sì ń gbèrú nínú irọ́ o dá májẹ̀mú pẹ̀lú Asiria o sì fi òróró olifi ránṣẹ́ sí Ejibiti.
Ephraim pascit ventum, et sequitur aestum: tota die mendacium, et vastitatem multiplicat: et foedus cum Assyriis iniit, et oleum in Aegyptum ferebat.
2 Olúwa ní ẹjọ́ kan tí yóò bá Juda rò, yóò fì ìyà jẹ Jakọbu gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà rẹ̀ yóò sì sán fún un gẹ́gẹ́ bí i ìṣe rẹ̀.
Iudicium ergo Domini cum Iuda, et visitatio super Iacob: iuxta vias eius, et iuxta adinventiones eius reddet ei.
3 Láti inú oyún ni ó ti di arákùnrin rẹ̀ mú ni gìgísẹ̀, àti nípa ipá rẹ̀ ó ni agbára pẹ̀lú Ọlọ́run
In utero supplantavit fratrem suum: et in fortitudine sua directus est cum angelo.
4 Ó bá angẹli ja ìjàkadì, ó sì borí rẹ̀, o sọkún, ó sì bẹ̀bẹ̀ fún ojúrere rẹ̀. Ó bá Olúwa ní Beteli, Ó sì bá a sọ̀rọ̀ níbẹ̀,
Et invaluit ad angelum, et confortatus est: flevit, et rogavit eum: in Bethel invenit eum, et ibi locutus est nobiscum.
5 àní Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun; Olúwa ni orúkọ ìrántí rẹ̀.
Et Dominus Deus exercituum, Dominus memoriale eius.
6 Ṣùgbọ́n ìwọ gbọdọ̀ padà sọ́dọ̀ Ọlọ́run rẹ̀; di ìfẹ́ àti ìdájọ́ òdodo mú kí ẹ sì dúró de Ọlọ́run yín nígbà gbogbo.
Et tu ad Dominum Deum tuum converteris: misericordiam et iudicium custodi, et spera in Deo tuo semper.
7 Oníṣòwò ń lo òsùwọ̀n èké o fẹ́ràn láti rẹ́ ni jẹ.
Chanaan, in manu eius statera dolosa, calumniam dilexit.
8 Efraimu gbéraga, “Èmi ní ìní fún ara mi, mo sì ti di ọlọ́rọ̀, pẹ̀lú gbogbo ọrọ̀ mi yìí, wọn kò le ká àìṣedéédéé tàbí ẹ̀ṣẹ̀ kankan mọ́ mi lọ́wọ́.”
Et dixit Ephraim: Verumtamen dives effectus sum, inveni idolum mihi: omnes labores mei non invenient mihi iniquitatem, quam peccavi.
9 “Èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ; ẹni tí ó mu ọ jáde wá láti ilẹ̀ Ejibiti; èmi yóò tún mú yín gbé nínú àgọ́ bí i ọjọ́ àjọ̀dún tí a yàn wọ̀n-ọn-nì.
Et ego Dominus Deus tuus ex Terra Aegypti, adhuc sedere te faciam in tabernaculis, sicut in diebus festivitatis.
10 Mo sọ fún àwọn wòlíì, mo fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìran hàn wọ́n mo sì pa òwe láti ẹnu wòlíì wọn.”
Et locutus sum super prophetas, et ego visionem multiplicavi, et in manu prophetarum assimilatus sum.
11 Gileadi ha burú bí? Àwọn ènìyàn rẹ̀ jẹ́ asán. Ǹjẹ́ wọ́n ń fi akọ màlúù rú ẹbọ ní Gilgali? Gbogbo pẹpẹ wọ́n sì dàbí ebè nínú aporo oko.
Si Galaad idolum, ergo frustra errant in Galgal bobus immolantes: nam et altaria eorum quasi acervi super sulcos agri:
12 Jakọbu sálọ si orílẹ̀-èdè Aramu; Israẹli sìn kí o tó fẹ́ ìyàwó ó ṣe ìtọ́jú ẹran láti fi san owó ìyàwó.
Fugit Iacob in regionem Syriae, et servivit Israel in uxorem, et in uxore servavit.
13 Olúwa lo wòlíì kan láti mú Israẹli jáde wá láti Ejibiti, nípasẹ̀ wòlíì kan ó ṣe ìtọ́jú rẹ̀.
In propheta autem eduxit Dominus Israel de Aegypto: et in propheta servatus est.
14 Ṣùgbọ́n Efraimu ti mú un bínú gidigidi; Olúwa rẹ̀ yóò sì fi ẹ̀bi ìtàjẹ̀ sílẹ̀ sí orí rẹ̀ òun yóò sì san án padà fún un nítorí ìwà ẹ̀gàn an rẹ̀.
Ad iracundiam me provocavit Ephraim in amaritudinibus suis, et sanguis eius super eum veniet, et opprobrium eius restituet ei Dominus Deus suus.