< Hosea 11 >
1 “Nígbà tí Israẹli wà ní ọmọdé mo fẹ́ràn rẹ̀, mo sì pe ọmọ mi jáde láti Ejibiti wá.
2 Bí a ti ń pe wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe ń sá kúrò lọ́dọ̀ mi, wọn rú ẹbọ sí Baali, wọn sì fi tùràrí jóná sí ère fínfín.
3 Lóòtítọ́ mo kọ́ Efraimu pẹ̀lú ní ìrìn mo di wọ́n mú ní apá, ṣùgbọ́n wọn kò mọ̀ pé mo ti mú wọn láradá.
4 Mo fi okùn ènìyàn fà wọ́n àti ìdè ìfẹ́. Mo mú àjàgà kúrò ni ọrùn wọn, Mo sì fi ara balẹ̀ fún wọn ni oúnjẹ.
5 “Ṣé wọn ò wá ní padà sí Ejibiti bí. Ṣé Asiria kò sì ní jẹ ọba lé wọn lórí bí nítorí pé wọ́n kọ̀ jálẹ̀ láti ronúpìwàdà?
6 Idà yóò kọ mọ̀nà ní gbogbo ìlú wọn yóò si bá gbogbo irin ẹnu odi ìlú wọn jẹ́ yóò sì fi òpin sí gbogbo èrò wọn.
7 Àwọn ènìyàn mi ti pinnu láti pẹ̀yìndà kúrò lọ́dọ̀ mi bí wọ́n tilẹ̀ pè wọ́n sọ́dọ̀ Ọ̀gá-ògo jùlọ, kò ní gbé wọn ga rárá.
8 “Báwo ni èmi ó ṣe fi ọ́ sílẹ̀, Efraimu? Báwo ni èmi ó ṣe yọ̀ǹda rẹ̀, Israẹli? Báwo ni mo ṣe lè ṣe ọ bi i Adma? Báwo ni mo ṣe lè ṣe ọ bi i Seboimu? Ọkàn mi yípadà nínú mi àánú mi sì ru sókè.
9 Èmi kò ni mú ìbínú gbígbóná mi ṣẹ, tàbí kí èmi wá sọ Efraimu di ahoro. Nítorí pé èmi ni Ọlọ́run, àní, èmi kì í ṣe ènìyàn. Ẹni mímọ́ láàrín yín, Èmi kò ní í wá nínú ìbínú.
10 Wọn yóò máa tẹ̀lé Olúwa; òun yóò bú ramúramù bí i kìnnìún. Nígbà tó bá bú, àwọn ọmọ rẹ yóò wá ní ìwárìrì láti ìwọ̀-oòrùn.
11 Wọn ó wá pẹ̀lú ẹ̀rù bí i ẹyẹ láti Ejibiti, bí i àdàbà láti Asiria, Èmi ó mú wọn padà sí ilé wọn,” ni Olúwa wí.
12 Efraimu tí fi irọ́ yí mi ká ilé Israẹli pẹ̀lú ẹ̀tàn. Ṣùgbọ́n Juda sì dúró ṣinṣin pẹ̀lú Ọlọ́run. Ó sì ṣe olóòtítọ́ sí Ẹni mímọ́ Israẹli.