< Hosea 10 >
1 Israẹli jẹ́ igi àjàrà tó gbilẹ̀ ó ń so èso fún ara rẹ̀. Bí èso rẹ̀ ṣe ń pọ̀ bẹ́ẹ̀ ni ó ń kọ́ pẹpẹ sí i bí ilẹ̀ rẹ̀ ṣe ń ṣe rere o bu ọlá fún òkúta ìyàsọ́tọ̀ ère rẹ̀.
Israel es una vid exuberante que produce su fruto. Según la abundancia de sus frutos ha multiplicado sus altares. A medida que su tierra ha prosperado, han adornado sus piedras sagradas.
2 Ọkàn wọn kún fún ìtànjẹ báyìí wọ́n gbọdọ̀ ru ẹ̀bi wọn. Olúwa yóò wó pẹpẹ wọn palẹ̀ yóò sì pa gbogbo òkúta ìyàsọ́tọ̀ wọn run.
Su corazón está dividido. Ahora serán declarados culpables. Él demolerá sus altares. Destruirá sus piedras sagradas.
3 Nígbà náà ni wọn yóò wí pé, “A kò ní ọba nítorí tí a kò bọ̀wọ̀ fún Olúwa ṣùgbọ́n bí a tilẹ̀ ní ọba, kí ni yóò ṣe fún wa?”
Seguramente ahora dirán: “No tenemos rey, porque no tememos a Yahvé; y el rey, ¿qué puede hacer por nosotros?”
4 Wọ́n ṣe ìlérí púpọ̀, wọ́n ṣe ìbúra èké, wọ́n da májẹ̀mú; báyìí ni ìdájọ́ hù sókè bí igi ìwọ̀ ni aporo oko, bi i koríko májèlé láàrín oko tí a ro.
Hacen promesas, jurando en falso al hacer pactos. Por eso, el juicio brota como maleza venenosa en los surcos del campo.
5 Àwọn ènìyàn tí ń gbé Samaria bẹ̀rù nítorí ère abo màlúù tó wà ní Beti-Afeni. Àwọn ènìyàn rẹ̀ yóò ṣọ̀fọ̀ le e lórí bẹ́ẹ̀ ni àwọn àlùfáà abọ̀rìṣà rẹ̀. Gbogbo àwọn tó láyọ̀ sì dídán rẹ̀, nítorí tí a ti mú lọ sí ìgbèkùn.
Los habitantes de Samaria estarán aterrorizados por los becerros de Bet Aven, porque su pueblo se lamentará por él, junto con sus sacerdotes que se regocijaron por ello, para su gloria, porque se ha apartado de ella.
6 A ó gbé lọ sí Asiria gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn fún ọba ńlá a ó dójútì Efraimu; ojú yóò ti Israẹli nítorí ìgbìmọ̀ rẹ̀.
También será llevada a Asiria como regalo para un gran rey. Efraín recibirá la vergüenza, e Israel se avergonzará de su propio consejo.
7 Bí igi tó léfòó lórí omi ni Samaria àti àwọn ọba rẹ yóò sàn lọ.
Samaria y su rey se alejan flotando como una ramita en el agua.
8 Àwọn ibi gíga tí ẹ tí ń hùwà búburú ni a o parun, èyí ni ẹ̀ṣẹ̀ Israẹli. Ẹ̀gún ọ̀gàn àti ẹ̀gún òṣùṣú yóò hù jáde, yóò sì bo àwọn pẹpẹ wọn. Wọn yóò sọ fún àwọn òkè gíga pé, “Bò wá mọ́lẹ̀!” àti fún àwọn òkè kéékèèké pé, “Ṣubú lù wá!”
Los lugares altos también de Aven, el pecado de Israel, serán destruidos. El espino y el cardo subirán a sus altares. Dirán a las montañas: “¡Cúbrenos!” y a las colinas: “¡Caigan sobre nosotros!”
9 “Láti ìgbà Gibeah, ni ó ti ṣẹ̀, ìwọ Israẹli, ìwọ sì tún wà níbẹ̀. Ǹjẹ́ ogun kò lé ẹ̀yin aṣebi ni Gibeah bá bí?
“Israel, has pecado desde los días de Gabaa. Allí se quedaron. La batalla contra los hijos de la iniquidad no los alcanza en Gabaa.
10 Nígbà tó bá tẹ́ mi lọ́rùn, èmi yóò fi ìyà jẹ wọ́n; Orílẹ̀-èdè yóò kó ra wọn jọ, wọ́n ó sì dojúkọ wọn, láti fi wọn sínú ìdè nítorí ìlọ́po ẹ̀ṣẹ̀ wọn.
Cuando sea mi deseo, los castigaré; y las naciones se reunirán contra ellos cuando están atados a sus dos transgresiones.
11 Efraimu jẹ́ ọmọ abo màlúù tí a tí kọ́, to si fẹ́ràn láti máa pa ọkà; lórí ọrun rẹ̀ tó lẹ́wà ni èmi ó dí ẹrù wúwo lé. Èmi yóò mú kí a gun Efraimu bí ẹṣin Juda yóò tú ilẹ̀, Jakọbu yóò sì fọ́ ògúlùtu rẹ̀.
Efraín es una novilla amaestrada que le gusta trillar, así que pondré un yugo en su hermoso cuello. Pondré un jinete en Efraín. Judá arará. Jacob romperá sus terrones.
12 Ẹ gbin òdòdó fún ara yín, kí ẹ sì ká èso ìfẹ́ àìlópin. Ẹ tu ilẹ̀ yín tí a kò ro, nítorí pé ó ti tó àsìkò láti wá Olúwa, títí tí yóò fi dé, tí yóò sì rọ òjò òdodo lé yín lórí.
Sembrad para vosotros mismos en la justicia, cosechar según la bondad. Rompe tu barbecho, porque es hora de buscar a Yahvé, hasta que venga y haga llover justicia sobre ti.
13 Ṣùgbọ́n ẹ tí gbin búburú ẹ si ka ibi, ẹ ti jẹ èso èké nítorí ẹ tí gbẹ́kẹ̀lé agbára yín àti àwọn ọ̀pọ̀ jagunjagun yín,
Has arado la maldad. Has cosechado iniquidad. Has comido el fruto de la mentira, porque confiaste en tu camino, en la multitud de tus valientes.
14 ariwo ogun yóò bo àwọn ènìyàn yín kí gbogbo odi agbára yín ba le parun. Gẹ́gẹ́ bí Ṣalmani ṣe pa Beti-Arbeli run lọ́jọ́ ogun, nígbà tí a gbé àwọn ìyá ṣánlẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn.
Por eso se levantará un rugido de batalla entre tu pueblo, y todas sus fortalezas serán destruidas, como Shalman destruyó Beth Arbel en el día de la batalla. La madre fue despedazada con sus hijos.
15 Báyìí ni a o sì ṣe sí ọ, ìwọ Beteli, nítorí pé ìwà búburú yín ti pọ̀jù. Ní àfẹ̀mọ́júmọ́ ọjọ́ náà, a o pa ọba Israẹli run pátápátá.
Así te hará Betel a causa de tu gran maldad. Al amanecer el rey de Israel será destruido.