< Hebrews 9 >

1 Bẹ́ẹ̀ ni májẹ̀mú àkọ́kọ́ ní ìlànà fún ìsìn àti ibi mímọ́ ti ayé yìí.
Εἶχε μὲν οὖν καὶ ἡ πρώτη δικαιώματα λατρείας τό τε ἅγιον κοσμικόν.
2 A gbé àgọ́ kan dìde. Nínú yàrá rẹ̀ àkọ́kọ́ ni a ti rí ọ̀pá fìtílà, tábìlì, àti àkàrà ìfihàn. Èyí tí a ń pè ní ibi mímọ́.
σκηνὴ γὰρ κατεσκευάσθη ἡ πρώτη, ἐν ᾗ ἥ τε λυχνία καὶ ἡ τράπεζα καὶ ἡ πρόθεσις τῶν ἄρτων, ἥτις λέγεται Ἅγια·
3 Àti lẹ́yìn aṣọ ìkélé kejì, òun ni àgọ́ tí à ń pè ní Ibi Mímọ́ Jùlọ;
μετὰ δὲ τὸ δεύτερον καταπέτασμα σκηνὴ ἡ λεγομένη Ἅγια ἁγίων,
4 tí ó ní àwo tùràrí wúrà, àti àpótí ẹ̀rí tí a fi wúrà bò yíká, nínú èyí tí ìkòkò wúrà tí ó ní manna gbé wà, àti ọ̀pá Aaroni tí o rúdí, àti àwọn wàláà májẹ̀mú;
χρυσοῦν ἔχουσα θυμιατήριον καὶ τὴν κιβωτὸν τῆς διαθήκης περικεκαλυμμένην πάντοθεν χρυσίῳ, ἐν ᾗ στάμνος χρυσῆ ἔχουσα τὸ μάννα καὶ ἡ ῥάβδος Ἀαρὼν ἡ βλαστήσασα καὶ αἱ πλάκες τῆς διαθήκης,
5 àti lórí àpótí ni àwọn kérúbù ògo ti i síji bo ìtẹ́ àánú; èyí tí a kò lè sọ̀rọ̀ rẹ̀ nísinsin yìí lọ́kọ̀ọ̀kan.
ὑπεράνω δὲ αὐτῆς Χερουβεὶν δόξης κατασκιάζοντα τὸ ἱλαστήριον· περὶ ὧν οὐκ ἔστιν νῦν λέγειν κατὰ μέρος.
6 Ǹjẹ́ nígbà tí a ti ṣe ètò nǹkan wọ̀nyí báyìí, àwọn àlùfáà a máa lọ nígbàkígbà sínú àgọ́ èkínní, wọn a máa ṣe iṣẹ́ ìsìn.
Τούτων δὲ οὕτως κατεσκευασμένων εἰς μὲν τὴν πρώτην σκηνὴν διὰ παντὸς εἰσίασιν οἱ ἱερεῖς τὰς λατρείας ἐπιτελοῦντες,
7 Ṣùgbọ́n sínú èkejì ni olórí àlùfáà nìkan máa ń lọ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo lọ́dún, fún ara rẹ̀, àti fún ìṣìnà àwọn ènìyàn.
εἰς δὲ τὴν δευτέραν ἅπαξ τοῦ ἐνιαυτοῦ μόνος ὁ ἀρχιερεύς, οὐ χωρὶς αἵματος, ὃ προσφέρει ὑπὲρ ἑαυτοῦ καὶ τῶν τοῦ λαοῦ ἀγνοημάτων,
8 Ẹ̀mí Mímọ́ ń tọ́ka èyí pé a kò ì tí ì ṣí ọ̀nà Ibi Mímọ́ Jùlọ sílẹ̀ níwọ̀n ìgbà tí àgọ́ èkínní bá sì dúró,
τοῦτο δηλοῦντος τοῦ Πνεύματος τοῦ Ἁγίου, μήπω πεφανερῶσθαι τὴν τῶν ἁγίων ὁδὸν ἔτι τῆς πρώτης σκηνῆς ἐχούσης στάσιν,
9 èyí tí i ṣe àpẹẹrẹ fún ìgbà ìsinsin yìí. Gẹ́gẹ́ bí ètò yìí, a ń mú ẹ̀bùn àti ẹbọ wá, tí kò lè mú ẹ̀rí ọkàn olùsìn di pípé.
ἥτις παραβολὴ εἰς τὸν καιρὸν τὸν ἐνεστηκότα, καθ’ ἣν δῶρά τε καὶ θυσίαι προσφέρονται μὴ δυνάμεναι κατὰ συνείδησιν τελειῶσαι τὸν λατρεύοντα,
10 Èyí sì wà nínú ohun jíjẹ àti ohun mímu àti onírúurú ìwẹ̀, tí í ṣe ìlànà ti ara nìkan tí a fi lélẹ̀ títí fi di ìgbà àtúnṣe.
μόνον ἐπὶ βρώμασιν καὶ πόμασιν καὶ διαφόροις βαπτισμοῖς, δικαιώματα σαρκὸς μέχρι καιροῦ διορθώσεως ἐπικείμενα.
11 Ṣùgbọ́n nígbà tí Kristi dé bí olórí àlùfáà àwọn ohun rere tí ń bọ̀, nípasẹ̀ àgọ́ tí o tóbi ti ó sì pé ju ti ìṣáájú, èyí tí a kò fi ọwọ́ dá, èyí yìí ni, tí kì í ṣe ti ẹ̀dá yìí.
Χριστὸς δὲ παραγενόμενος ἀρχιερεὺς τῶν γενομένων ἀγαθῶν, διὰ τῆς μείζονος καὶ τελειοτέρας σκηνῆς οὐ χειροποιήτου, τοῦτ’ ἔστιν οὐ ταύτης τῆς κτίσεως,
12 Bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ ewúrẹ́ àti ọmọ màlúù, ṣùgbọ́n nípa ẹ̀jẹ̀ òun tìkára rẹ̀, o wọ Ibi Mímọ́ Jùlọ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, lẹ́yìn tí ó ti rí ìdáǹdè àìnípẹ̀kun gbà fún wa. (aiōnios g166)
οὐδὲ δι’ αἵματος τράγων καὶ μόσχων, διὰ δὲ τοῦ ἰδίου αἵματος, εἰσῆλθεν ἐφάπαξ εἰς τὰ ἅγια, αἰωνίαν λύτρωσιν εὑράμενος. (aiōnios g166)
13 Nítorí bí ẹ̀jẹ̀ ewúrẹ́ àti ti akọ màlúù àti eérú ẹgbọrọ abo màlúù tí a fi wọ́n àwọn tí a ti sọ di aláìmọ́ ba ń sọ ni di mímọ́ fún ìwẹ̀nùmọ́ ara:
εἰ γὰρ τὸ αἷμα τράγων καὶ ταύρων καὶ σποδὸς δαμάλεως ῥαντίζουσα τοὺς κεκοινωμένους ἁγιάζει πρὸς τὴν τῆς σαρκὸς καθαρότητα,
14 mélòó mélòó ni ẹ̀jẹ̀ Kristi, ẹni, nípa Ẹ̀mí ayérayé, tí ó fi ara rẹ̀ rú ẹbọ sí Ọlọ́run láìní àbàwọ́n, yóò wẹ èérí ọkàn yín nù kúrò nínú òkú iṣẹ́ láti sin Ọlọ́run alààyè? (aiōnios g166)
πόσῳ μᾶλλον τὸ αἷμα τοῦ Χριστοῦ, ὃς διὰ Πνεύματος αἰωνίου ἑαυτὸν προσήνεγκεν ἄμωμον τῷ Θεῷ, καθαριεῖ τὴν συνείδησιν ἡμῶν ἀπὸ νεκρῶν ἔργων εἰς τὸ λατρεύειν Θεῷ ζῶντι. (aiōnios g166)
15 Àti nítorí èyí ni ó ṣe jẹ́ alárinà májẹ̀mú tuntun pé bí ikú ti ń bẹ fún ìdáǹdè àwọn ìrékọjá ti o tí wà lábẹ́ májẹ̀mú ìṣáájú, kí àwọn tí a ti pè lè rí ìlérí ogún àìnípẹ̀kun gbà. (aiōnios g166)
Καὶ διὰ τοῦτο διαθήκης καινῆς μεσίτης ἐστίν, ὅπως θανάτου γενομένου εἰς ἀπολύτρωσιν τῶν ἐπὶ τῇ πρώτῃ διαθήκῃ παραβάσεων τὴν ἐπαγγελίαν λάβωσιν οἱ κεκλημένοι τῆς αἰωνίου κληρονομίας. (aiōnios g166)
16 Nítorí níbi tí ìwé ogún bá gbé wà, ikú ẹni tí o ṣe é kò lè ṣe àìsí pẹ̀lú;
ὅπου γὰρ διαθήκη, θάνατον ἀνάγκη φέρεσθαι τοῦ διαθεμένου·
17 nítorí ìwé ogún ní agbára lẹ́yìn ìgbà tí ènìyàn bá kú, nítorí kò ní agbára rárá nígbà tí ẹni tí o ṣè e bá ń bẹ láààyè.
διαθήκη γὰρ ἐπὶ νεκροῖς βεβαία, ἐπεὶ μή ποτε ἰσχύει ὅτε ζῇ ὁ διαθέμενος.
18 Nítorí náà ni a kò ṣe ya májẹ̀mú ìṣáájú pàápàá sí mímọ́ láìsí ẹ̀jẹ̀.
Ὅθεν οὐδὲ ἡ πρώτη χωρὶς αἵματος ἐνκεκαίνισται.
19 Nítorí nígbà tí Mose ti sọ gbogbo àṣẹ nípa ti òfin fún gbogbo àwọn ènìyàn, ó mú ẹ̀jẹ̀ ọmọ màlúù àti ti ewúrẹ́, pẹ̀lú omi, àti òwú òdòdó, àti ewé hísópù ó sì fi wọ́n àti ìwé pàápàá àti gbogbo ènìyàn.
λαληθείσης γὰρ πάσης ἐντολῆς κατὰ τὸν νόμον ὑπὸ Μωϋσέως παντὶ τῷ λαῷ, λαβὼν τὸ αἷμα τῶν μόσχων καὶ τῶν τράγων μετὰ ὕδατος καὶ ἐρίου κοκκίνου καὶ ὑσσώπου, αὐτό τε τὸ βιβλίον καὶ πάντα τὸν λαὸν ἐράντισεν,
20 Wí pé, “Èyí ní ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú tí Ọlọ́run pàṣẹ fún yín.”
λέγων Τοῦτο τὸ αἷμα τῆς διαθήκης ἧς ἐνετείλατο πρὸς ὑμᾶς ὁ Θεός.
21 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ó sì fi ẹ̀jẹ̀ wọ́n àgọ́, àti gbogbo ohun èlò ìsìn.
καὶ τὴν σκηνὴν δὲ καὶ πάντα τὰ σκεύη τῆς λειτουργίας τῷ αἵματι ὁμοίως ἐράντισεν.
22 Ó sì fẹ́rẹ̀ jẹ́ ohun gbogbo ni a fi ẹ̀jẹ̀ wẹ̀nù gẹ́gẹ́ bí òfin; àti pé láìsí ìtàjẹ̀ sílẹ̀ kò sí ìdáríjì.
καὶ σχεδὸν ἐν αἵματι πάντα καθαρίζεται κατὰ τὸν νόμον, καὶ χωρὶς αἱματεκχυσίας οὐ γίνεται ἄφεσις.
23 Nítorí náà a kò lè ṣàì fi ìwọ̀nyí wé àwọn àpẹẹrẹ ohun tí ń bẹ lọ́run mọ́; ṣùgbọ́n ó yẹ kí a fi ẹbọ tí ó sàn ju ìwọ̀nyí lọ wẹ àwọn ohun ọ̀run pàápàá mọ́; ṣùgbọ́n ó yẹ kí a fi ẹbọ tí ó sàn ju ìwọ̀nyí lọ wẹ àwọn ohun ọ̀run pàápàá mọ́.
Ἀνάγκη οὖν τὰ μὲν ὑποδείγματα τῶν ἐν τοῖς οὐρανοῖς τούτοις καθαρίζεσθαι, αὐτὰ δὲ τὰ ἐπουράνια κρείττοσιν θυσίαις παρὰ ταύτας.
24 Nítorí Kristi kò wọ ibi mímọ́ tí a fi ọwọ́ ṣe lọ tí i ṣe àpẹẹrẹ ti òtítọ́; ṣùgbọ́n ó lọ sí ọ̀run pàápàá, nísinsin yìí láti farahàn ní iwájú Ọlọ́run fún wa.
οὐ γὰρ εἰς χειροποίητα εἰσῆλθεν ἅγια Χριστός, ἀντίτυπα τῶν ἀληθινῶν, ἀλλ’ εἰς αὐτὸν τὸν οὐρανόν, νῦν ἐμφανισθῆναι τῷ προσώπῳ τοῦ Θεοῦ ὑπὲρ ἡμῶν·
25 Kì í sí i ṣe pé kí ó lè máa fi ara rẹ̀ rú ẹbọ nígbàkígbà, bí olórí àlùfáà tí máa ń wọ inú Ibi Mímọ́ Jùlọ lọ lọ́dọọdún ti òun pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ ti kì í ṣe tirẹ̀,
οὐδ’ ἵνα πολλάκις προσφέρῃ ἑαυτόν, ὥσπερ ὁ ἀρχιερεὺς εἰσέρχεται εἰς τὰ ἅγια κατ’ ἐνιαυτὸν ἐν αἵματι ἀλλοτρίῳ,
26 bí bẹ́ẹ̀ bá ni, òun ìbá tí máa jìyà nígbàkígbà láti ìpìlẹ̀ ayé. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí ni ó fi ara hàn lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo lópin ayé láti mu ẹ̀ṣẹ̀ kúrò nípa ẹbọ ara rẹ̀. (aiōn g165)
ἐπεὶ ἔδει αὐτὸν πολλάκις παθεῖν ἀπὸ καταβολῆς κόσμου· νυνὶ δὲ ἅπαξ ἐπὶ συντελείᾳ τῶν αἰώνων εἰς ἀθέτησιν τῆς ἁμαρτίας διὰ τῆς θυσίας αὐτοῦ πεφανέρωται. (aiōn g165)
27 Níwọ́n bí a sì ti fi lélẹ̀ fún gbogbo ènìyàn láti kú lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, ṣùgbọ́n lẹ́yìn èyí ìdájọ́,
καὶ καθ’ ὅσον ἀπόκειται τοῖς ἀνθρώποις ἅπαξ ἀποθανεῖν, μετὰ δὲ τοῦτο κρίσις,
28 bẹ́ẹ̀ ni Kristi pẹ̀lú lẹ́yìn tí a ti fi rú ẹbọ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo láti ru ẹ̀ṣẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀, yóò farahàn ní ìgbà kejì láìsí ẹ̀ṣẹ̀ fún àwọn tí n wo ọ̀nà rẹ̀ fún ìgbàlà.
οὕτως καὶ ὁ Χριστός, ἅπαξ προσενεχθεὶς εἰς τὸ πολλῶν ἀνενεγκεῖν ἁμαρτίας, ἐκ δευτέρου χωρὶς ἁμαρτίας ὀφθήσεται τοῖς αὐτὸν ἀπεκδεχομένοις εἰς σωτηρίαν.

< Hebrews 9 >