< Hebrews 8 >
1 Nísinsin yìí, kókó ohun tí à ń sọ nìyí. Àwa ní irú olórí àlùfáà bẹ́ẹ̀, tí ó jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún ìtẹ́ Ọláńlá nínú àwọn ọ̀run,
Now the sum of the things that have been said is this, that we have such an high-priest, who is sat down at the right hand of the throne of the majesty in the heavens;
2 Ìránṣẹ́ ibi mímọ́, àti ti àgọ́ tòótọ́, tí Olúwa pa, kì í ṣe ènìyàn.
a minister of holy things, and of the true tabernacle, which the Lord hath raised, and not man.
3 Nítorí a fi olórí àlùfáà kọ̀ọ̀kan jẹ láti máa mú ẹ̀bùn wá láti máa rú ẹbọ, nítorí náà ó ṣe pàtàkì fún eléyìí náà láti ní nǹkan tí ó máa fi sílẹ̀.
For every high-priest is appointed to offer gifts and sacrifices; wherefore it was necessary that He also should have something to offer.
4 Tí ó bá jẹ́ pé ó wà ní ayé ni, òun kì bá ti jẹ́ àlùfáà, nítorí pé àwọn ọkùnrin tí ó ń fi ẹ̀bùn sílẹ̀ ti wà bí òfin ṣe là á sílẹ̀.
For if He were on earth, He could not be a priest, seeing there are priests already that offer gifts according to the law:
5 Àwọn ẹni tí ń jọ́sìn nínú pẹpẹ kan tí ó jẹ́ àpẹẹrẹ àti òjìji ohun tí ń bẹ ní ọ̀run. Ìdí abájọ nìyí tí a fi kìlọ̀ fún Mose nígbà tí ó fẹ́ kọ́ àgọ́, nítorí ó wí pé, “Kíyèsí i, kí ìwọ kí ó ṣe wọ́n gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ wọn, ti a fi hàn ọ́ ni orí òkè.”
who worship under the representation and shadow of heavenly things; as Moses was ordered by God, when he was about to finish the tabernacle. For see, saith He, that thou make all according to the model shewn thee in the mount.
6 Ṣùgbọ́n nísinsin yìí o ti gba iṣẹ́ ìránṣẹ́ tí ó ni ọlá jù, níwọ̀n bí o ti jẹ pé alárinà májẹ̀mú tí o dára jù ní i ṣe, èyí tí a fi ṣe òfin lórí ìlérí tí o sàn jù bẹ́ẹ̀ lọ.
But now He hath obtained a more excellent ministry, inasmuch as He is also the mediator of a better covenant, which is established upon better promises.
7 Nítorí ìbá ṣe pé májẹ̀mú ìṣáájú nì kò ní àbùkù, ǹjẹ́ a kì bá ti wá ààyè fún èkejì.
For if the first covenant had been unexceptionable, there had been no room for a second:
8 Nítorí tí ó rí àbùkù lára wọn, ó wí pé, “Ìgbà kan ń bọ̀, ni Olúwa wí, tí Èmi yóò bá ilé Israẹli àti ilé Juda dá májẹ̀mú tuntun.
as we see there was, for after complaining of them, He adds, "Behold the days come, saith the Lord, that I will make a new covenant with the house of Israel, and with the house of Judah:
9 Kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí májẹ̀mú tí mo ti bá àwọn baba baba wọn dá, nígbà tí mo fà wọ́n lọ́wọ́ láti mú wọn jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti, nítorí wọn kò jẹ́ olóòtítọ́ sí májẹ̀mú mi èmi kò sì ta wọ́n nu, ni Olúwa wí.
not according to the covenant which I made with their fathers, in the day when I took them by the hand to lead them out of the land of Egypt; for they continued not in my covenant, and I regarded them not, saith the Lord.
10 Nítorí èyí ni májẹ̀mú tí èmi yóò bá ilé Israẹli dá lẹ́yìn àwọn ọjọ́ wọ̀nyí, ni Olúwa wí. Èmi ó fi òfin mi sí inú wọn, èmi ó sì kọ wọ́n sí ọkàn wọn, èmi ó sì máa jẹ́ Ọlọ́run fún wọn, wọn ó sì máa jẹ́ ènìyàn fún mi.
But this is the covenant that I will make with the house of Israel after those days, saith the Lord, I will put my laws into their mind, and I will inscribe them on their hearts; and I will be to them a God, and they shall be to me a people.
11 Olúkúlùkù kò ní tún máa kọ́ ara ìlú rẹ̀, tàbí olúkúlùkù arákùnrin rẹ̀, pé, ‘Mọ Olúwa,’ nítorí pé gbogbo wọn ni yóò mọ̀ mí, láti kékeré dé àgbà.
And they shall not teach every one his neighbour, and every one his brother, saying, Know the Lord: for they shall all know me, from the lest even to the greatest of them.
12 Nítorí pé èmi ó ṣàánú fún àìṣòdodo wọn, àti ẹ̀ṣẹ̀ wọn àti àìṣedéédéé wọn lèmi ki yóò sì rántí mọ́.”
For I will forgive their crimes, and their sins and their iniquities I will remember no more."
13 Ní èyí tí ó wí pé, májẹ̀mú títún ó ti sọ ti ìṣáájú di ti láéláé. Ṣùgbọ́n èyí tí ó ń di i ti láéláé tí ó sì ń gbó, o múra àti di asán.
Now by saying, a new covenant, He hath antiquated the first: and what is antiquated, and groweth old, is near it's exit.