< Hebrews 7 >

1 Nítorí Melkisedeki yìí, ọba Salẹmu, àlùfáà Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo, ẹni tí ó pàdé Abrahamu bí ó ti ń padà bọ̀ láti ibi pípa àwọn ọba, tí ó sì súre fún un,
For this Melchizedek, king of Salem, priest of God Most High, who met Abraham returning from the slaughter of the kings and blessed him,
2 ẹni tí Abrahamu sì pín ìdámẹ́wàá ohun gbogbo fún. Ní ọ̀nà èkínní orúkọ rẹ̀ túmọ̀ sí “ọba òdodo”; àti lẹ́yìn náà pẹ̀lú, “ọba Salẹmu,” tí í ṣe “ọba àlàáfíà.”
to whom also Abraham divided a tenth part of all (being first, by interpretation, “king of righteousness”, and then also “king of Salem”, which means “king of peace”,
3 Láìní baba, láìní ìyá, láìní ìtàn ìran, bẹ́ẹ̀ ni kò ní ìbẹ̀rẹ̀ ọjọ́ tàbí òpin ọjọ́ ayé; ṣùgbọ́n a ṣe é bí Ọmọ Ọlọ́run; ó wà ní àlùfáà títí.
without father, without mother, without genealogy, having neither beginning of days nor end of life, but made like the Son of God), remains a priest continually.
4 Ǹjẹ́ ẹ gbà á rò bí ọkùnrin yìí ti pọ̀ tó, ẹni tí Abrahamu baba ńlá fi ìdámẹ́wàá nínú àwọn àṣàyàn ìkógun fún.
Now consider how great this man was, to whom even Abraham the patriarch gave a tenth out of the best plunder.
5 Àti nítòótọ́ àwọn tí ó jẹ́ ọmọ Lefi, tí o gba oyè àlùfáà, wọ́n ní àṣẹ láti máa gba ìdámẹ́wàá lọ́wọ́ àwọn ènìyàn gẹ́gẹ́ bí òfin, èyí yìí, lọ́wọ́ àwọn arákùnrin wọn, bí ó tilẹ̀ ti jẹ́ pé, wọn ti inú Abrahamu jáde.
They indeed of the sons of Levi who receive the priest’s office have a commandment to take tithes from the people according to the law, that is, of their brothers, though these have come out of the body of Abraham,
6 Ṣùgbọ́n òun ẹni tí a kò tilẹ̀ pìtàn ìran rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ wọn wá, gba ìdámẹ́wàá lọ́wọ́ Abrahamu, ó sì súre fún ẹni tí ó gba ìlérí,
but he whose genealogy is not counted from them has accepted tithes from Abraham, and has blessed him who has the promises.
7 láìsí ìjiyàn rárá ẹni kò tó ẹni tí à ń súre fún láti ọ̀dọ̀ ẹni tí ó ju ni.
But without any dispute the lesser is blessed by the greater.
8 Ni apá kan, àwọn ẹni kíkú gba ìdámẹ́wàá; ṣùgbọ́n níbẹ̀, ẹni tí a jẹ́rìí rẹ̀ pé o ń bẹ láààyè nì.
Here people who die receive tithes, but there one receives tithes of whom it is testified that he lives.
9 Àti bí a ti lè wí, Lefi pàápàá tí ń gba ìdámẹ́wàá, ti san ìdámẹ́wàá nípasẹ̀ Abrahamu.
We can say that through Abraham even Levi, who receives tithes, has paid tithes,
10 Nítorí o sá à sì ń bẹ ní inú baba rẹ̀, nígbà ti Melkisedeki pàdé rẹ̀.
for he was yet in the body of his father when Melchizedek met him.
11 Ǹjẹ́ ìbá ṣe pé pípé ń bẹ nípa oyè àlùfáà Lefi (nítorí pé lábẹ́ rẹ̀ ni àwọn ènìyàn gba òfin), kín ni ó sì tún kù mọ́ tí àlùfáà mìíràn ìbá fi dìde ní títẹ̀lé àpẹẹrẹ tí Melkisedeki, tí a kò si wí pé ní títẹ̀lé àpẹẹrẹ tí Aaroni?
Now if perfection was through the Levitical priesthood (for under it the people have received the law), what further need was there for another priest to arise after the order of Melchizedek, and not be called after the order of Aaron?
12 Nítorí pé bí a ti ń pààrọ̀ iṣẹ́ àlùfáà, a kò sì lè ṣàì máa pààrọ̀ òfin.
For the priesthood being changed, there is of necessity a change made also in the law.
13 Nítorí ẹni tí à ń sọ̀rọ̀ nǹkan wọ̀nyí nípa rẹ̀ jẹ́ ẹ̀yà mìíràn, láti inú èyí tí ẹnikẹ́ni kò tì jọ́sìn rí níbi pẹpẹ.
For he of whom these things are said belongs to another tribe, from which no one has officiated at the altar.
14 Nítorí ó hàn gbangba pé láti inú ẹ̀yà Juda ni Olúwa wa ti dìde; nípa ẹ̀yà yìí Mose kò sọ ohunkóhun ní ti àwọn àlùfáà.
For it is evident that our Lord has sprung out of Judah, about which tribe Moses spoke nothing concerning priesthood.
15 Ó sì tún hàn gbangba ju bẹ́ẹ̀ lọ bí ó ti jẹ pé àlùfáà mìíràn dìde ní àpẹẹrẹ ti Melkisedeki.
This is yet more abundantly evident, if after the likeness of Melchizedek there arises another priest,
16 Èyí tí a fi jẹ́, kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí ìlànà òfin nípa ti ara, bí kò ṣe nípa agbára ti ìyè àìlópin.
who has been made, not after the law of a fleshly commandment, but after the power of an endless life;
17 Nítorí a jẹ́rìí pé: “Ìwọ ni àlùfáà títí láé ní ipasẹ̀ ti Melkisedeki.” (aiōn g165)
for it is testified, “You are a priest forever, according to the order of Melchizedek.” (aiōn g165)
18 Nítorí a mú òfin ìṣáájú kúrò nítorí àìlera àti àìlérè rẹ̀.
For there is an annulling of a foregoing commandment because of its weakness and uselessness
19 (Nítorí òfin kò mú ohunkóhun pé), a sì mú ìrètí tí ó dára jù wá nípa èyí tí àwa ń súnmọ́ Ọlọ́run.
(for the law made nothing perfect), and a bringing in of a better hope, through which we draw near to God.
20 Níwọ́n bí ó sì ti ṣe pé kì í ṣe ní àìbúra ni. Nítorí àwọn àlùfáà tẹ́lẹ̀ jẹ oyè láìsí ìbúra,
Inasmuch as he was not made priest without the taking of an oath
21 ṣùgbọ́n ti òun jẹ́ pẹ̀lú ìbúra nígbà tí Ọlọ́run wí fún un pé, “Olúwa búra, kí yóò sì yí padà: ‘Ìwọ ni àlùfáà kan títí láé.’” (aiōn g165)
(for they indeed have been made priests without an oath), but he with an oath by him that says of him, “The Lord swore and will not change his mind, ‘You are a priest forever, according to the order of Melchizedek.’” (aiōn g165)
22 Níwọ́n bẹ́ẹ̀ ni Jesu ti di onígbọ̀wọ́ májẹ̀mú tí ó dára jù.
By so much, Jesus has become the guarantee of a better covenant.
23 Àti nítòótọ́ àwọn púpọ̀ ní a ti fi jẹ àlùfáà, nítorí wọn kò lè wà títí nítorí ikú.
Many, indeed, have been made priests, because they are hindered from continuing by death.
24 Ṣùgbọ́n òun, nítorí tí o wà títí láé, ó ní oyè àlùfáà tí a kò lè rọ̀ ní ipò. (aiōn g165)
But he, because he lives forever, has his priesthood unchangeable. (aiōn g165)
25 Nítorí náà ó sì le gbà wọ́n là pẹ̀lú títí dé òpin, ẹni tí ó bá tọ Ọlọ́run wá nípasẹ̀ rẹ̀, nítorí tí o ń bẹ láààyè títí láé láti máa bẹ̀bẹ̀ fún wọn.
Therefore he is also able to save to the uttermost those who draw near to God through him, seeing that he lives forever to make intercession for them.
26 Nítorí pé irú olórí àlùfáà bẹ́ẹ̀ ni o yẹ wá, mímọ́, àìlẹ́gàn, àìléèérí, tí a yà sọ́tọ̀ kúrò láàrín àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, tí a sì gbéga ju àwọn ọ̀run lọ.
For such a high priest was fitting for us: holy, guiltless, undefiled, separated from sinners, and made higher than the heavens;
27 Ẹni tí kò ní láti máa rú ẹbọ lójoojúmọ́, bí àwọn olórí àlùfáà, fún ẹ̀ṣẹ̀ ti ara rẹ̀ náà, àti lẹ́yìn náà fún tí àwọn ènìyàn; nítorí èyí ni tí ó ṣe lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, nígbà tí ó fi ara rẹ̀ rú ẹbọ.
who doesn’t need, like those high priests, to offer up sacrifices daily, first for his own sins, and then for the sins of the people. For he did this once for all, when he offered up himself.
28 Nítorí pé òfin a máa fi àwọn ènìyàn tí ó ní àìlera jẹ olórí àlùfáà; ṣùgbọ́n nípa ọ̀rọ̀ ti ìbúra, tí ó ṣe lẹ́yìn òfin, ó fi ọmọ jẹ; ẹni tí a sọ di pípé títí láé. (aiōn g165)
For the law appoints men as high priests who have weakness, but the word of the oath, which came after the law, appoints a Son forever who has been perfected. (aiōn g165)

< Hebrews 7 >