< Hebrews 6 >
1 Nítorí náà, ó yẹ kí á fi àwọn ẹ̀kọ́ ìgbà tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ gba Kristi sílẹ̀, kí á tẹ̀síwájú nínú àwọn ẹ̀kọ́ tí yóò mú wa dàgbàsókè ní pípé. Láìtún ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ máa tẹnumọ́ ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ bí i ìrònúpìwàdà kúrò nínú òkú iṣẹ́ àti ìgbàgbọ́ nípa ti Ọlọ́run,
Διὸ ἀφέντες τὸν τῆς ἀρχῆς τοῦ χριστοῦ λόγον, ἐπὶ τὴν τελειότητα φερώμεθα· μὴ πάλιν θεμέλιον καταβαλλόμενοι μετανοίας ἀπὸ νεκρῶν ἔργων, καὶ πίστεως ἐπὶ θεόν,
2 ti ẹ̀kọ́ àwọn bamitiisi, àti ti ìgbọ́wọ́-léni, ti àjíǹde òkú, àti tí ìdájọ́ àìnípẹ̀kun. (aiōnios )
βαπτισμῶν διδαχῆς, ἐπιθέσεώς τε χειρῶν, ἀναστάσεώς [τε] νεκρῶν, καὶ κρίματος αἰωνίου. (aiōnios )
3 Èyí ní àwa yóò sì ṣe bí Ọlọ́run bá fẹ́.
καὶ τοῦτο ποιήσομεν, ἐάν περ ἐπιτρέπῃ ὁ θεός.
4 Nítorí pé, kò ṣe é ṣe fún àwọn tí a ti là lójú lẹ́ẹ̀kan, tí wọ́n sì ti tọ́ ẹ̀bùn ọ̀run wò, tí wọn sì ti di alábápín Ẹ̀mí Mímọ́,
ἀδύνατον γὰρ τοὺς ἅπαξ φωτισθέντας, γευσαμένους τε τῆς δωρεᾶς τῆς ἐπουρανίου, καὶ μετόχους γενηθέντας πνεύματος ἁγίου,
5 tí wọn sì tọ́ ọ̀rọ̀ rere Ọlọ́run wò, àti agbára ayé tí ń bọ̀, (aiōn )
καὶ καλὸν γευσαμένους θεοῦ ῥῆμα, δυνάμεις τε μέλλοντος αἰῶνος, (aiōn )
6 láti tún sọ wọ́n di ọ̀tun sí ìrònúpìwàdà bí wọn bá ṣubú kúrò; nítorí tí wọ́n tún kan Ọmọ Ọlọ́run mọ́ àgbélébùú sí ara wọn lọ́tun, wọ́n sì dójútì í ní gbangba.
καὶ παραπεσόντας, πάλιν ἀνακαινίζειν εἰς μετάνοιαν, ἀνασταυροῦντας ἑαυτοῖς τὸν υἱὸν τοῦ θεοῦ καὶ παραδειγματίζοντας.
7 Nítorí ilẹ̀ tí ó ń fa omi òjò tí ń rọ̀ sórí rẹ̀ nígbà gbogbo mu, tí ó sì ń hu ewébẹ̀ tí ó dára fún àwọn tí à ń tìtorí wọn ro ó pẹ̀lú, ń gba ìbùkún lọ́wọ́ Ọlọ́run.
γῆ γὰρ ἡ πιοῦσα τὸν ἐπ᾽ αὐτῆς ἐρχόμενον πολλάκις ὑετόν, καὶ τίκτουσα βοτάνην εὔθετον ἐκείνοις δι᾽ οὓς καὶ γεωργεῖται, μεταλαμβάνει εὐλογίας ἀπὸ τοῦ θεοῦ·
8 Ṣùgbọ́n bí ó ba ń hu ẹ̀gún àti òṣùṣú yóò di kíkọ̀sílẹ̀, kò si jìnnà sí fífi gégùn ún, òpin èyí tí yóò wà fún ìjóná.
ἐκφέρουσα δὲ ἀκάνθας καὶ τριβόλους, ἀδόκιμος καὶ κατάρας ἐγγύς, ἧς τὸ τέλος εἰς καῦσιν.
9 Ṣùgbọ́n olùfẹ́, àwa ní ohun tí ó dára jù bẹ́ẹ̀ lọ, ní tiyín, àti ohun tí ó fi ara mọ́ ìgbàlà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé à ń ṣe báyìí sọ̀rọ̀.
Πεπείσμεθα δὲ περὶ ὑμῶν, ἀγαπητοί, τὰ κρείσσονα καὶ ἐχόμενα σωτηρίας, εἰ καὶ οὕτως λαλοῦμεν.
10 Nítorí Ọlọ́run kì í ṣe aláìṣòdodo tí yóò fi gbàgbé iṣẹ́ yin àti ìfẹ́ tí ẹ̀yin fihàn sí orúkọ rẹ̀, nípa iṣẹ́ ìránṣẹ́ tí ẹ ti ṣe fún àwọn ènìyàn mímọ́, tí ẹ sì tún ń ṣe.
οὐ γὰρ ἄδικος ὁ θεὸς ἐπιλαθέσθαι τοῦ ἔργου ὑμῶν, καὶ τῆς ἀγάπης ἧς ἐνεδείξασθε εἰς τὸ ὄνομα αὐτοῦ, διακονήσαντες τοῖς ἁγίοις καὶ διακονοῦντες.
11 Àwa sì fẹ́ kí olúkúlùkù yín máa fi irú àìsimi kan náà hàn, fún ẹ̀kún ìdánilójú ìrètí títí dé òpin.
ἐπιθυμοῦμεν δὲ ἕκαστον ὑμῶν τὴν αὐτὴν ἐνδείκνυσθαι σπουδὴν πρὸς τὴν πληροφορίαν τῆς ἐλπίδος ἄχρι τέλους·
12 Kí ẹ má ṣe di onílọ̀ra, ṣùgbọ́n aláfarawé àwọn tí wọn ti ipa ìgbàgbọ́ àti sùúrù jogún àwọn ìlérí.
ἵνα μὴ νωθροὶ γένησθε, μιμηταὶ δὲ τῶν διὰ πίστεως καὶ μακροθυμίας κληρονομούντων τὰς ἐπαγγελίας.
13 Nítorí nígbà tí Ọlọ́run ṣe ìlérí fún Abrahamu, bí kò ti rí ẹni tí ó pọ̀jù òun láti fi búra, ó fi ara rẹ̀ búra, wí pé,
τῷ γὰρ Ἀβραὰμ ἐπαγ γειλάμενος ὁ θεός, ἐπεὶ κατ᾽ οὐδενὸς εἶχεν μείζονος ὀμόσαι, ὤμοσεν καθ᾽ ἑαυτοῦ,
14 “Nítòótọ́ ní bíbùkún èmi ó bùkún fún ọ, àti ní bíbísí èmi ó sì mú ọ bí sí i.”
λέγων, Εἰ μὴν εὐλογῶν εὐλογήσω σε, καὶ πληθύνων πληθυνῶ σε·
15 Bẹ́ẹ̀ náà sì ni, lẹ́yìn ìgbà tí Abrahamu fi sùúrù dúró, ó ri ìlérí náà gbà.
καὶ οὕτως μακροθυμήσας ἐπέτυχεν τῆς ἐπαγγελίας.
16 Nítorí ènìyàn a máa fi ẹni tí ó pọ̀jù wọ́n lọ búra: ìbúra náà a sì fi òpin sí gbogbo ìjiyàn wọn fún ìfẹ̀sẹ̀ múlẹ̀ ọ̀rọ̀.
ἄνθρωποι γὰρ κατὰ τοῦ μείζονος ὀμνύουσιν, καὶ πάσης αὐτοῖς ἀντιλογίας πέρας εἰς βεβαίωσιν ὁ ὅρκος·
17 Nínú èyí tí Ọlọ́run, ẹni tí ń fẹ́ gidigidi láti fi àìlèyípadà ète rẹ̀ hàn fún àwọn ajogún ìlérí náà, ó fi ìbúra sáàrín wọn.
ἐν ᾧ περισσότερον βουλόμενος ὁ θεὸς ἐπιδεῖξαι τοῖς κληρονόμοις τῆς ἐπαγγελίας τὸ ἀμετάθετον τῆς βουλῆς αὐτοῦ, ἐμεσίτευσεν ὅρκῳ,
18 Pé, nípa ohun àìlèyípadà méjì, nínú èyí tí kò le ṣe é ṣe fún Ọlọ́run láti ṣèké, kí a lè mú àwa tí ó ti sá sábẹ́ ààbò rẹ̀ ní ọkàn lè láti di ìrètí tí a gbé kalẹ̀ níwájú wa mú ṣinṣin.
ἵνα διὰ δύο πραγμάτων ἀμεταθέτων, ἐν οἷς ἀδύνατον ψεύσασθαι θεόν, ἰσχυρὰν παράκλησιν ἔχωμεν οἱ καταφυγόντες κρατῆσαι τῆς προκειμένης ἐλπίδος·
19 Èyí tí àwa níbi ìdákọ̀ró ọkàn fún ọkàn wa, ìrètí tí ó dájú tí ó sì dúró ṣinṣin, tí ó sì wọ inú ilé lọ lẹ́yìn aṣọ ìkélé;
ἣν ὡς ἄγκυραν ἔχομεν τῆς ψυχῆς ἀσφαλήν τε καὶ βεβαίαν, καὶ εἰσερχομένην εἰς τὸ ἐσώτερον τοῦ καταπετάσματος,
20 níbi tí Jesu, aṣáájú wa ti wọ̀ lọ fún wa, òun sì ni a fi jẹ alábojútó àlùfáà títí láé ní ipasẹ̀ Melkisedeki. (aiōn )
ὅπου πρόδρομος ὑπὲρ ἡμῶν εἰσῆλθεν Ἰησοῦς, κατὰ τὴν τάξιν Μελχισεδὲκ ἀρχιερεὺς γενόμενος εἰς τὸν αἰῶνα. (aiōn )