< Hebrews 5 >

1 Nítorí olórí àlùfáà kọ̀ọ̀kan tí a yàn nínú àwọn ènìyàn, ní a fi jẹ nítorí iṣẹ́ ìsìn àwọn ènìyàn sí Ọlọ́run láti máa mú ẹ̀bùn àti ẹbọ wá nítorí ẹ̀ṣẹ̀.
πας γαρ αρχιερευς εξ ανθρωπων λαμβανομενος υπερ ανθρωπων καθισταται τα προς τον θεον ινα προσφερη δωρα τε και θυσιας υπερ αμαρτιων
2 Ẹni tí ó lè ṣe jẹ́ẹ́jẹ́ pẹ̀lú àwọn aláìmòye, tí ó sì lé bá àwọn tí ó ti yapa kẹ́dùn, nítorí a fi àìlera yí òun náà ká pẹ̀lú.
μετριοπαθειν δυναμενος τοις αγνοουσιν και πλανωμενοις επει και αυτος περικειται ασθενειαν
3 Nítorí ìdí èyí ni ó ṣe yẹ, bí ó ti ń rú ẹbọ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ fún àwọn ènìyàn rẹ̀, bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ní ń ṣe fún ara rẹ̀ náà.
και δια ταυτην οφειλει καθως περι του λαου ουτως και περι εαυτου προσφερειν υπερ αμαρτιων
4 Kọ sí ẹni tí o gba ọlá yìí fún ara rẹ̀, bí kò ṣe ẹni tí a pè láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá gẹ́gẹ́ bí a ti pe Aaroni.
και ουχ εαυτω τις λαμβανει την τιμην αλλα ο καλουμενος υπο του θεου καθαπερ και ο ααρων
5 Bẹ́ẹ̀ ni Kristi pẹ̀lú kò sì ṣe ara rẹ̀ lógo láti jẹ́ olórí àlùfáà; bí kò ṣe ẹni tí o wí fún ún pé, “Ìwọ ni ọmọ mi, lónìí ni mo bí ọ.”
ουτως και ο χριστος ουχ εαυτον εδοξασεν γενηθηναι αρχιερεα αλλ ο λαλησας προς αυτον υιος μου ει συ εγω σημερον γεγεννηκα σε
6 Bí ó ti wí pẹ̀lú ní ibòmíràn pé, “Ìwọ ni àlùfáà títí láé ní ipasẹ̀ Melkisedeki.” (aiōn g165)
καθως και εν ετερω λεγει συ ιερευς εις τον αιωνα κατα την ταξιν μελχισεδεκ (aiōn g165)
7 Ní ìgbà ọjọ́ Jesu nínú ayé, ó fi ìkérora rara àti omijé gbàdúrà, tí ó sì bẹ̀bẹ̀ lọ́dọ̀ ẹni tí ó lè gbà á sílẹ̀ lọ́wọ́ ikú, a sì gbóhùn rẹ̀ nítorí ó ní ẹ̀mí ìbẹ̀rù Ọlọ́run rẹ̀.
ος εν ταις ημεραις της σαρκος αυτου δεησεις τε και ικετηριας προς τον δυναμενον σωζειν αυτον εκ θανατου μετα κραυγης ισχυρας και δακρυων προσενεγκας και εισακουσθεις απο της ευλαβειας
8 Bí òun tilẹ̀ ń ṣe Ọmọ Ọlọ́run, síbẹ̀ ó kọ́ ìgbọ́ran nípa ohun tí ó jìyà rẹ̀.
καιπερ ων υιος εμαθεν αφ ων επαθεν την υπακοην
9 Bí a sì ti sọ ọ di pípé, o wa di orísun ìgbàlà àìnípẹ̀kun fún gbogbo àwọn tí ó ń gbọ́ tirẹ̀, (aiōnios g166)
και τελειωθεις εγενετο τοις υπακουουσιν αυτω πασιν αιτιος σωτηριας αιωνιου (aiōnios g166)
10 tí a yàn ní olórí àlùfáà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá ní ipasẹ̀ Melkisedeki.
προσαγορευθεις υπο του θεου αρχιερευς κατα την ταξιν μελχισεδεκ
11 Nípa èyí àwa ní ohun púpọ̀ láti sọ, tí ó sì ṣòro láti túmọ̀, nítorí pé ẹ yigbì ní gbígbọ́.
περι ου πολυς ημιν ο λογος και δυσερμηνευτος λεγειν επει νωθροι γεγονατε ταις ακοαις
12 Nítorí pé báyìí ó ti yẹ kí ẹ jẹ́ olùkọ́ni, ẹ tún wà ní ẹni tí ẹnìkan yóò máa kọ́ ni ìbẹ̀rẹ̀ ìpìlẹ̀ ẹ̀kọ́ àwọn ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ẹ sì tún di irú àwọn tí ó mu wàrà, tí wọn kò sì fẹ́ oúnjẹ líle.
και γαρ οφειλοντες ειναι διδασκαλοι δια τον χρονον παλιν χρειαν εχετε του διδασκειν υμας τινα τα στοιχεια της αρχης των λογιων του θεου και γεγονατε χρειαν εχοντες γαλακτος και ου στερεας τροφης
13 Nítorí olúkúlùkù ẹni tí ń mu wàrà jẹ́ aláìlóye ọ̀rọ̀ òdodo, nítorí ọmọ ọwọ́ ni.
πας γαρ ο μετεχων γαλακτος απειρος λογου δικαιοσυνης νηπιος γαρ εστιν
14 Ṣùgbọ́n oúnjẹ líle wà fún àwọn tí ó dàgbà, àwọn ẹni nípa ìrírí, tí wọn ń lo ọgbọ́n wọn láti fi ìyàtọ̀ sáàrín rere àti búburú.
τελειων δε εστιν η στερεα τροφη των δια την εξιν τα αισθητηρια γεγυμνασμενα εχοντων προς διακρισιν καλου τε και κακου

< Hebrews 5 >