< Hebrews 2 >

1 Nítorí náà, ó yẹ kí àwa máa fi iyè sí àwọn nǹkan wọ̀n-ọn-nì gidigidi tí àwa ti gbọ́, kí a má ba à gbá wa lọ kúrò nínú wọn nígbà kan.
Therefore we must pay greater attention to what we have heard, so that we do not drift away.
2 Nítorí bí ọ̀rọ̀ tí a tí ẹnu àwọn angẹli sọ bá sì dúró ṣinṣin, àti tí olúkúlùkù ẹ̀ṣẹ̀ sí òfin àti àìgbọ́ràn gba ìjìyà tí ó tọ́ sí i,
For if the message spoken through angels was valid and every transgression and disobedience received a just retribution,
3 kín ni ohun náà tí ó mú wa lérò pé a lè bọ́ kúrò nínú ìjìyà bí a kò bá náání ìgbàlà ńlá yìí? Ìgbàlà tí Olúwa fúnra rẹ̀ kọ́kọ́ kéde, èyí tí a sì fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ fún wa láti ọwọ́ àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà lẹ́nu rẹ̀.
how will we escape if we neglect so great a salvation? This salvation was first announced by the Lord, and it was confirmed to us by those who heard him.
4 Ọlọ́run jẹ́rìí sí i nípa àwọn iṣẹ́ àmì àti ìyanu àti oríṣìíríṣìí iṣẹ́ agbára àti nípa ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́ tí a pín gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ̀.
God also bore further witness with signs, wonders, various miracles, and gifts of the Holy Spirit distributed according to his will.
5 Nítorí pé, kì í ṣe abẹ́ ìṣàkóso àwọn angẹli ni ó fi ayé tí ń bọ̀, tí àwa ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ sí.
For it was not to angels that God subjected the world to come, about which we are speaking.
6 Ṣùgbọ́n ibìkan wà tí ẹnìkan tí jẹ́rìí pé “Kí ni ènìyàn tí ìwọ fi ń ṣe ìrántí rẹ̀, tàbí ọmọ ènìyàn, tí ìwọ fi ń bẹ̀ ẹ́ wò?
But in one place someone has testified: “What is man that yoʋ are mindful of him, or the son of man that yoʋ care for him?
7 Ìwọ dá a ní onírẹ̀lẹ̀ díẹ̀ ju àwọn angẹli lọ; ìwọ fi ògo àti ọlá de e ni adé, ìwọ sì fi í jẹ olórí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ,
Yoʋ made him a little lower than the angels and crowned him with glory and honor;
8 Ìwọ fi ohun gbogbo sábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀.” Ní ti fífi ohun gbogbo sábẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n àwa kò ì tí ì rí ohun kan tí ó kù tí kò sí ní abẹ́ àkóso rẹ̀. Síbẹ̀ nísinsin yìí àwa kò ì tí ì rí pé ó fi ohun gbogbo sábẹ́ ìṣàkóso rẹ̀.
yoʋ put everything in subjection under his feet.” In subjecting everything to him, God left nothing that is not subjected to him. But now we do not yet see everything subjected to him.
9 Ṣùgbọ́n àwa rí Jesu ẹni tí a rẹ̀ sílẹ̀ díẹ̀ ju àwọn angẹli lọ fún àkókò díẹ̀, àní Jesu, ẹni tí a fi ògo àti ọlá dé ní adé nítorí ìjìyà wa; kí ó lè tọ́ ikú wò fún olúkúlùkù ènìyàn nípa oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run.
But we do see Jesus, who for a little while was made lower than the angels, now crowned with glory and honor because he suffered death, so that by the grace of God he might taste death for everyone.
10 Nítorí pé ó yẹ fún Ọlọ́run, nítorí nípasẹ̀ ẹni tí ohun gbogbo ṣẹ̀ wà, láti mú àwọn ọmọ púpọ̀ wá sínú ògo, láti ṣe balógun ìgbàlà wọn ni àṣepé nípa ìjìyà.
For in bringing many sons to glory, it was fitting that God, for whom and through whom all things exist, should make the author of their salvation perfect through suffering.
11 Nítorí àti ẹni tí ń sọ ni di mímọ́ àti àwọn tí a ń sọ di mímọ́, láti ọ̀dọ̀ ẹnìkan ṣoṣo ni gbogbo wọn ti wá, nítorí èyí ni kò ṣe tijú láti pè wọ́n ni arákùnrin.
For he who sanctifies and those who are being sanctified all have one Father. That is why Jesus is not ashamed to call them brothers,
12 Àti wí pé, “Èmi ó sọ̀rọ̀ orúkọ rẹ̀ fún àwọn ará mi, ni àárín ìjọ ni èmi yóò kọrin ìyìn rẹ̀.”
saying, “I will declare yoʋr name to my brothers; in the midst of the congregation I will sing yoʋr praise.”
13 Àti pẹ̀lú, “Èmi yóò gbẹ́kẹ̀ mi lé e.” Àti pẹ̀lú, “Kíyèsi í, èmi rèé, èmi àti àwọn ọmọ tí Ọlọ́run fi fún mi.”
And again, “I will put my trust in him.” And again, “Here I am, with the children God has given me.”
14 Ǹjẹ́ ni ìwọ̀n bí àwọn ọmọ tí ṣe alábápín ará àti ẹ̀jẹ̀, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni òun pẹ̀lú sì ṣe alábápín nínú ohun kan náà; kí ó lè ti ipa ikú rẹ̀ pa ẹni tí ó ní agbára ikú run, èyí ni èṣù.
Therefore, since the children all have flesh and blood, Jesus himself took on flesh and blood as well, so that through death he might destroy the one who has the power of death, that is, the devil,
15 Kí o sì lè gba gbogbo àwọn tí ó tìtorí ìbẹ̀rù ikú wà lábẹ́ ìdè lọ́jọ́ ayé wọn gbogbo kúrò lọ́wọ́ ìbẹ̀rù.
and free those who all their lives were held in slavery by the fear of death.
16 Nítorí pé, nítòótọ́, kì í ṣe àwọn angẹli ni ó ṣe ìrànlọ́wọ́ fún, ṣùgbọ́n àwọn irú-ọmọ Abrahamu ni ó ṣe ìrànlọ́wọ́ fún.
For surely it is not angels that he helps, but the descendants of Abraham.
17 Nítorí náà, ó yẹ pé nínú ohun gbogbo kí ó dàbí àwọn ará rẹ̀, kí ó lè jẹ́ aláàánú àti olóòtítọ́ alábojútó Àlùfáà nínú ohun tí i ṣe ti Ọlọ́run, kí o lè ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn.
Therefore he had to become like his brothers in every way, so that he could be a merciful and faithful high priest in service to God, in order to make atonement for the sins of the people.
18 Nítorí níwọ̀n bí òun tìkára rẹ̀ ti jìyà tí a sì ti dán an wò, òun ní agbára láti ran àwọn tí a ń dánwò lọ́wọ́.
Because he himself suffered when he was tempted, he is able to help those who are being tempted.

< Hebrews 2 >