< Haggai 2 >

1 Ní ọjọ́ kọkànlélógún oṣù keje, ni ọ̀rọ̀ Olúwa wá nípasẹ̀ wòlíì Hagai wí pé,
El 21 del mes séptimo, la Palabra de Yavé vino por medio del profeta Hageo:
2 “Sọ fún Serubbabeli ọmọ Ṣealitieli, baálẹ̀ Juda, àti Joṣua ọmọ Josadaki, olórí àlùfáà àti àwọn ènìyàn yòókù. Béèrè lọ́wọ́ wọn pé,
Habla ahora a Zorobabel, hijo de Salatiel, gobernador de Judá, y a Josué, hijo del sumo sacerdote Josadac, y al resto del pueblo:
3 ‘Ta ni nínú yín tí ó kù tí ó sì ti rí ilé yìí ní ògo rẹ̀ àkọ́kọ́? Báwo ni ó ṣe ri sí yín nísinsin yìí? Ǹjẹ́ kò dàbí asán lójú yín?
¿Quién de ustedes vio esta Casa en su primer esplendor? ¿Y cómo la ve ahora? ¿No les parece como nada en comparación?
4 Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, múra gírí, ìwọ Serubbabeli,’ ni Olúwa wí. ‘Múra gírí, ìwọ Joṣua ọmọ Josadaki, olórí àlùfáà. Ẹ sì múra gírí gbogbo ẹ̀yin ènìyàn ilẹ̀ náà,’ ni Olúwa wí, ‘kí ẹ sì ṣiṣẹ́. Nítorí èmi wà pẹ̀lú yín,’ ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.
Ahora pues, esfuérzate, Zorobabel, dice Yavé. Esfuérzate tú también, Josué, hijo del sumo sacerdote Josadac, y esfuércese todo el pueblo de esta tierra. Actúen, porque Yo estoy con ustedes, dice Yavé de las huestes.
5 ‘Èyí ni ohun tí Èmi fi bá a yín dá májẹ̀mú nígbà tí ẹ jáde kúrò ní Ejibiti, bẹ́ẹ̀ ni Ẹ̀mí ì mi sì wà pẹ̀lú yín. Ẹ má ṣe bẹ̀rù.’
Según el Pacto que hice con ustedes cuando salieron de Egipto, mi Espíritu estará en medio de ustedes. No teman.
6 “Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé, ‘Láìpẹ́ jọjọ, Èmi yóò mi àwọn ọrun àti ayé, Òkun àti ìyàngbẹ ilẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i.
Porque Yavé de las huestes dice: Dentro de poco Yo estremeceré el cielo y la tierra, el mar y la tierra seca.
7 Èmi yóò mi gbogbo orílẹ̀-èdè, ìfẹ́ gbogbo orílẹ̀-èdè yóò fà sí tẹmpili yìí, Èmi yóò sì kún ilé yìí pẹ̀lú ògo,’ ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.
Estremeceré a todas las naciones y vendrán al Deseado de todas las naciones. Y Yo llenaré de gloria este Templo, dice Yavé de las huestes.
8 ‘Tèmi ni fàdákà àti wúrà,’ ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.
Mía es la plata y mío es el oro, dice Yavé de las huestes.
9 ‘Ògo ìkẹyìn ilé yìí yóò pọ̀ ju ti ìṣáájú lọ,’ ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, ‘Àti ní ìhín yìí ni Èmi ó sì fi àlàáfíà fún ni,’ ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.”
La gloria final de este Templo será mayor que la del primero. En este lugar daré paz, dice Yavé de las huestes.
10 Ní ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù kẹsànán ní ọdún kejì Dariusi, ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ wòlíì Hagai wá pé,
El día 24 del noveno mes, en el segundo año de Darío, vino la Palabra de Yavé por medio del profeta Hageo:
11 “Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, ‘Béèrè lọ́wọ́ àwọn àlùfáà ohun tí òfin wí pé:
Yavé de la huestes dice: Pregunta ahora a los sacerdotes con respecto a la Ley:
12 Bí ẹnìkan bá gbé ẹran mímọ́ ní ìṣẹ́tí aṣọ rẹ̀, tí ìṣẹ́tí aṣọ rẹ̀ kan àkàrà tàbí ọbẹ̀, wáìnì, òróró tàbí oúnjẹ mìíràn, ǹjẹ́ yóò ha jẹ́ mímọ́ bí?’” Àwọn àlùfáà sì dáhùn wí pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́.”
Si alguno lleva carne consagrada en la falda de su ropa, y con ella toca algún pan, vianda, vino, aceite o cualquier alimento, ¿son santificados? Y los sacerdotes respondieron: No.
13 Nígbà náà ni Hagai wí pé, “Bí ẹnìkan tí ó jẹ́ aláìmọ́ nípa fífi ara kan òkú bá fi ara kan ọ̀kan lára nǹkan wọ̀nyí, ǹjẹ́ yóò ha jẹ́ aláìmọ́?” Àwọn àlùfáà sì dáhùn wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, yóò jẹ́ aláìmọ́.”
Hageo dijo: Si un impuro a causa de un cadáver, toca cualquiera de estas cosas, ¿será impuro? Y contestaron los sacerdotes: Será impuro.
14 Nígbà náà ni Hagai dáhùn ó sì wí pé, “‘Bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn wọ̀nyí rí, bẹ́ẹ̀ sì ni orílẹ̀-èdè yìí rí níwájú mi,’ ni Olúwa wí. ‘Bẹ́ẹ̀ sì ni olúkúlùkù iṣẹ́ ọwọ́ wọn; èyí tí wọ́n sì fi rú ẹbọ níbẹ̀ jẹ́ aláìmọ́.
Y Hageo respondió: Así es este pueblo y esta nación delante de Mí, dice Yavé. Toda obra de sus manos y todo lo que ofrecen allí es impuro.
15 “‘Ǹjẹ́ nísinsin yìí, ẹ ro èyí dáradára láti òní yìí lọ, ẹ kíyèsi bí nǹkan ṣe rí tẹ́lẹ̀, a to òkúta kan lé orí èkejì ní tẹmpili Olúwa.
Ahora pues, desde hoy en adelante, reflexionen antes que coloquen piedra sobre piedra en la Casa de Yavé.
16 Nígbà tí ẹnikẹ́ni bá dé ibi òkìtì òsùwọ̀n ogun, mẹ́wàá péré ni yóò ba níbẹ̀. Nígbà tí ẹnikẹ́ni bá dé ibi ìfúntí wáìnì láti wọn àádọ́ta ìwọ̀n, ogún péré ni yóò ba níbẹ̀.
En aquel tiempo, cuando alguien iba a una pila de 20 medidas, solo hallaba diez, o cuando iba al lagar para sacar 50 cubos, solo había 20.
17 Mo fi ìrẹ̀dànù, ìmúwòdù àti yìnyín bá gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ yín jẹ; síbẹ̀ ẹ̀yin kò yípadà sí ọ̀dọ̀ mi,’ ni Olúwa wí.
Los golpeé con honguillo, parásito y granizo en toda obra de sus manos, pero ninguno de ustedes se volvió a mí, dice Yavé.
18 ‘Láti òní lọ, láti ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù kẹsànán yìí kí ẹ kíyèsi, kí ẹ sì rò ó dáradára, ọjọ́ ti a fi ìpìlẹ̀ tẹmpili Olúwa lélẹ̀, rò ó dáradára.
Reflexionen, pues, desde hoy en adelante, desde el día 24 del mes noveno, a partir del día cuando se echó el cimiento de la Casa de Yavé. Reflexionen:
19 Ǹjẹ́ èso ha wà nínú abà bí? Títí di àkókò yìí, àjàrà àti igi ọ̀pọ̀tọ́ àti pomegiranate, àti igi olifi kò ì tí ì so èso kankan. “‘Láti òní lọ ni èmi yóò bùkún fún un yin.’”
¿Está aún la semilla en el granero? Ni la vid, ni la higuera, ni el granado, ni el olivo produjeron, pero desde hoy en adelante los bendeciré.
20 Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tún tọ Hagai wá nígbà kejì, ní ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù náà pé,
El 24 del mismo mes vino la Palabra de Yavé por segunda vez a Hageo:
21 “Sọ fún Serubbabeli baálẹ̀ Juda pé èmi yóò mi àwọn ọ̀run àti ayé.
Habla a Zorobabel, gobernador de Judá: Yo haré temblar el cielo y la tierra.
22 Èmi yóò bi ìtẹ́ àwọn ìjọba ṣubú, Èmi yóò sì pa agbára àwọn aláìkọlà run, Èmi yóò sì dojú àwọn kẹ̀kẹ́ ogun dé, àti àwọn tí ń gùn wọ́n; ẹṣin àti àwọn ẹlẹ́ṣin yóò ṣubú; olúkúlùkù nípa idà arákùnrin rẹ̀.”
Trastornaré el trono de los reinos y destruiré la fuerza de los reinos de las naciones. Volcaré carruajes y a los que suben a ellos. Y caerán caballos y jinetes, cada uno por la espada de su hermano.
23 Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé, “Ní ọjọ́ náà, ìwọ ìránṣẹ́ mi Serubbabeli ọmọ Ṣealitieli, Èmi yóò mú ọ, Èmi yóò sì sọ ọ di bí òrùka èdìdì mi, nítorí mo ti yan ọ, ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.”
En aquel día, dice Yavé de las huestes, te tomaré, oh Zorobabel, hijo de Salatiel, esclavo mío. Te pondré como un anillo de sellar, porque te escogí, dice Yavé de las huestes.

< Haggai 2 >