< Genesis 5 >

1 Èyí ni àkọsílẹ̀ ìran Adamu. Nígbà tí Ọlọ́run dá ènìyàn, ní àwòrán Ọlọ́run ni ó dá a.
This [is] the book of the generations of Adam: In the day that God created man, in the likeness of God made he him:
2 Àti akọ àti abo ni Ó dá wọn, ó sì súre fún wọn, ó sì pe orúkọ wọ́n ní Adamu ní ọjọ́ tí ó dá wọn.
Male and female created he them; and blessed them, and called their name Adam, in the day when they were created.
3 Nígbà tí Adamu di ẹni àádóje ọdún, ó bí ọmọkùnrin kan tí ó jọ ọ́, tí ó jẹ́ àwòrán ara rẹ̀, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Seti.
And Adam lived a hundred and thirty years, and begat [a son] in his own likeness, after his image; and called his name Seth:
4 Ọjọ́ Adamu, lẹ́yìn ìgbà tí ó bí Seti, jẹ́ ẹgbẹ̀rin ọdún, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin.
And the days of Adam after he had begotten Seth were eight hundred years: and he begat sons and daughters:
5 Àpapọ̀ ọdún tí Adamu gbé ní orí ilẹ̀ jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún ọdún ó lé ọgbọ̀n, ó sì kú.
And all the days that Adam lived were nine hundred and thirty years: and he died.
6 Nígbà tí Seti pé àrùnlélọ́gọ́rùn-ún ọdún, ó bí Enoṣi.
And Seth lived a hundred and five years, and begat Enos:
7 Lẹ́yìn ìgbà tí ó bí Enoṣi, Seti sì gbé fún ẹgbẹ̀rin ọdún ó lé méje, ó sì bí àwọn; ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin.
And Seth lived after he begat Enos eight hundred and seven years, and begat sons and daughters:
8 Àpapọ̀ ọdún Seti sì jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún ọdún ó lé méjìlá, ó sì kú.
And all the days of Seth were nine hundred and twelve years; and he died.
9 Nígbà tí Enoṣi di ẹni àádọ́rùn-ún ọdún ni ó bí Kenani.
And Enos lived ninety years, and begat Cainan.
10 Lẹ́yìn tí ó bí Kenani, Enoṣi sì wà láààyè fún ẹgbẹ̀rin ọdún ó lé mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, ó sì bí àwọn ọkùnrin àti obìnrin.
And Enos lived after he begat Cainan eight hundred and fifteen years, and begat sons and daughters:
11 Àpapọ̀ ọdún Enoṣi jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún ọdún ó lé márùn-ún, ó sì kú.
And all the days of Enos were nine hundred and five years; and he died.
12 Nígbà tí Kenani di àádọ́rin ọdún ni ó bí Mahalaleli.
And Cainan lived seventy years, and begat Mahalaleel:
13 Lẹ́yìn tí ó bí Mahalaleli, Kenani wà láààyè fún òjìlélẹ́gbẹ̀rin ọdún, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin.
And Cainan lived after he begat Mahalaleel eight hundred and forty years, and begat sons and daughters:
14 Àpapọ̀ ọjọ́ Kenani jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún ọdún ó lé mẹ́wàá, ó sì kú.
And all the days of Cainan were nine hundred and ten years; and he died.
15 Nígbà tí Mahalaleli pé ọmọ àrùnlélọ́gọ́ta ọdún ni ó bí Jaredi.
And Mahalaleel lived sixty and five years, and begat Jared:
16 Mahalaleli sì gbé fún ẹgbẹ̀rin ọdún ó lé ọgbọ̀n lẹ́yìn ìgbà tí ó bí Jaredi, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin.
And Mahalaleel lived after he begat Jared eight hundred and thirty years, and begat sons and daughters:
17 Àpapọ̀ iye ọdún Mahalaleli jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún ọdún ó dín márùn-ún, ó sì kú.
And all the days of Mahalaleel were eight hundred ninety and five years; and he died.
18 Nígbà tí Jaredi pé ọmọ ọgọ́jọ ọdún ó lé méjì ni ó bí Enoku.
And Jared lived a hundred sixty and two years, and he begat Enoch:
19 Lẹ́yìn èyí, Jaredi wà láààyè fún ẹgbẹ̀rin ọdún Enoku sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin.
And Jared lived after he begat Enoch eight hundred years, and begat sons and daughters:
20 Àpapọ̀ ọdún Jaredi sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún dín méjìdínlógójì, ó sì kú.
And all the days of Jared were nine hundred sixty and two years; and he died.
21 Nígbà tí Enoku pé ọmọ ọgọ́ta ọdún ó lé márùn ni ó bí Metusela.
And Enoch lived sixty and five years, and begat Methuselah:
22 Lẹ́yìn tí ó bí Metusela, Enoku sì bá Ọlọ́run rìn ní ọ̀ọ́dúnrún ọdún, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin.
And Enoch walked with God after he begat Methuselah three hundred years, and begat sons and daughters:
23 Àpapọ̀ ọjọ́ Enoku sì jẹ́ irinwó ọdún dín márùndínlógójì.
And all the days of Enoch were three hundred sixty and five years:
24 Enoku bá Ọlọ́run rìn; a kò sì rí i mọ́ nítorí Ọlọ́run mú un lọ.
And Enoch walked with God, and he [was] not: for God took him.
25 Nígbà tí Metusela pé igba ọdún dín mẹ́tàlá ní o bí Lameki.
And Methuselah lived a hundred eighty and seven years, and begat Lamech:
26 Lẹ́yìn èyí Metusela wà láààyè fún ẹgbẹ̀rin ọdún dín méjìdínlógún, lẹ́yìn ìgbà tí ó bí Lameki, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin.
And Methuselah lived after he begat Lamech seven hundred eighty and two years, and begat sons and daughters:
27 Àpapọ̀ ọdún Metusela jẹ́ ẹgbẹ̀rún ọdún dín mọ́kànlélọ́gbọ̀n, ó sì kú.
And all the days of Methuselah were nine hundred sixty and nine years; and he died.
28 Nígbà tí Lameki pé ọdún méjìlélọ́gọ́sàn án ni ó bí ọmọkùnrin kan.
And Lamech lived a hundred eighty and two years; and begat a son:
29 Ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Noa, ó sì wí pé, “Eléyìí ni yóò tù wá nínú ni iṣẹ́ àti làálàá ọwọ́ wa, nítorí ilẹ̀ tí Olúwa ti fi gégùn ún.”
And he called his name Noah, saying, This [same] shall comfort us concerning our work and toil of our hands, because of the ground which the LORD hath cursed.
30 Lẹ́yìn tí ó bí Noa, Lameki gbé fún ẹgbẹ̀ta ọdún dín márùn-ún, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin.
And Lamech lived after he begat Noah five hundred ninety and five years, and begat sons and daughters:
31 Àpapọ̀ ọdún Lameki sì jẹ́ ẹgbẹ̀rin ọdún dín mẹ́tàlélógún, ó sì kú.
And all the days of Lamech were seven hundred seventy and seven years; and he died.
32 Lẹ́yìn tí Noa pé ọmọ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ọdún ni ó bí Ṣemu, Hamu àti Jafeti.
And Noah was five hundred years old: and Noah begat Shem, Ham, and Japheth.

< Genesis 5 >