< Genesis 46 >

1 Báyìí ni Israẹli mú ìrìnàjò rẹ̀ pọ̀n pẹ̀lú ohun gbogbo tí ó ní, nígbà tí ó sì dé Beerṣeba, ó rú ẹbọ sí Ọlọ́run Isaaki baba rẹ̀.
Izrael je šel na svojo pot z vsem, kar je imel in prišel v Beeršébo in žrtvoval klavne daritve Bogu svojega očeta Izaka.
2 Ọlọ́run sì bá Israẹli sọ̀rọ̀ ní ojú ìran ní òru pé, “Jakọbu! Jakọbu!” Ó sì dáhùn pé, “Èmi nìyí.”
Bog je Izraelu spregovoril v videnjih noči in rekel: »Jakob, Jakob.« Ta je rekel: »Tukaj sem.«
3 Ọlọ́run sì wí pé, “Èmi ni Ọlọ́run, Ọlọ́run baba rẹ, má ṣe bẹ̀rù láti sọ̀kalẹ̀ lọ sí ilẹ̀ Ejibiti nítorí, èmi yóò sọ ọ́ di orílẹ̀-èdè ńlá níbẹ̀.
Rekel je: »Jaz sem Bog, Bog tvojega očeta. Ne boj se iti dol v Egipt, kajti iz tebe bom tam naredil velik narod.
4 Èmi yóò sì sọ̀kalẹ̀ pẹ̀lú rẹ lọ sí Ejibiti, èmi yóò sì tún mú ọ padà wá. Ọwọ́ Josẹfu fúnra rẹ̀ ni ìwọ yóò sì kú sí.”
S teboj bom šel dol v Egipt in zagotovo te bom ponovno privedel gor in Jožef bo svojo roko položil na tvoje oči.«
5 Nígbà náà ni Jakọbu kúrò ní Beerṣeba, àwọn ọmọ Israẹli sì mú Jakọbu baba wọn àti àwọn aya wọn àti àwọn ọmọ wọn, wọ́n sì kó wọn sí inú kẹ̀kẹ́ ẹrù tí Farao fi ránṣẹ́ fún ìrìnàjò rẹ̀.
Jakob je vstal izpred Beeršébe in Izraelovi sinovi so odvedli svojega očeta Jakoba, svoje malčke in svoje žene v vozove, ki jih je faraon poslal, da ga odpeljejo.
6 Wọ́n tún kó àwọn ohun ọ̀sìn wọn àti gbogbo ohun ìní tí wọ́n ti ní láti ilẹ̀ Kenaani, Jakọbu àti gbogbo irú-ọmọ rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ lọ sí Ejibiti.
Vzeli so svojo živino in svoje dobrine, ki so jih pridobili v kánaanski deželi in prišli v Egipt, Jakob in vse njegovo potomstvo z njim,
7 Ó kó àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin pẹ̀lú àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀ ọkùnrin, àwọn ọmọ rẹ̀ obìnrin pẹ̀lú àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀ obìnrin, gbogbo irú-ọmọ rẹ̀ lọ sí Ejibiti.
njegovi sinovi in sinovi njegovih sinov z njim, njegove hčere in hčere njegovih sinov in vse svoje potomstvo je s seboj privedel v Egipt.
8 Èyí ni orúkọ àwọn ọmọ Israẹli (Jakọbu àti ìran rẹ̀) tí ó sọ̀kalẹ̀ lọ Ejibiti: Reubeni àkọ́bí Jakọbu.
To so imena Izraelovih otrok, ki so prišli v Egipt. Jakob in njegovi sinovi: Ruben, Jakobov prvorojenec.
9 Àwọn ọmọkùnrin Reubeni: Hanoku, Pallu, Hesroni àti Karmi.
Vsi Rubenovi sinovi: Henoh, Palú, Hecrón in Karmí.
10 Àwọn ọmọkùnrin Simeoni: Jemueli, Jamini, Ohadi, Jakini, Sohari àti Saulu, tí ìyá rẹ̀ jẹ́ ọmọbìnrin ará Kenaani.
Simeonovi sinovi: Jemuél, Jamín, Ohad, Jahín, Cohar in Šaúl, sin kánaanske ženske.
11 Àwọn ọmọkùnrin Lefi: Gerṣoni, Kohati àti Merari.
Lévijevi sinovi: Geršón, Kehát in Merarí.
12 Àwọn ọmọkùnrin Juda: Eri, Onani, Ṣela, Peresi àti Sera (ṣùgbọ́n Ẹri àti Onani ti kú ní ilẹ̀ Kenaani). Àwọn ọmọ Peresi: Hesroni àti Hamulu.
Judovi sinovi: Er, Onán, Šelá, Parec in Zerah, toda Er in Onán sta umrla v kánaanski deželi. Parecova sinova pa sta bila Hecrón in Hamúl.
13 Àwọn ọmọkùnrin: Isakari! Tola, Pua, Jaṣibu àti Ṣimroni.
Isahárjevi sinovi: Tolá, Puvá, Job in Šimrón.
14 Àwọn ọmọkùnrin Sebuluni: Seredi, Eloni àti Jahaleli.
Zábulonovi sinovi: Sered, Elón in Jahleél.
15 Wọ̀nyí ni àwọn ọmọkùnrin Lea tí ó bí fún Jakọbu ní Padani-Aramu yàtọ̀ fún Dina ọmọbìnrin rẹ̀. Àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ àti ọmọbìnrin rẹ̀ wọ̀nyí jẹ́ mẹ́tàlélọ́gbọ̀n lápapọ̀.
To so Leini sinovi, ki jih je rodila Jakobu v Padan–aramu z njegovo hčerjo Dino. Vseh duš njegovih sinov in njegovih hčera je bilo triintrideset.
16 Àwọn ọmọkùnrin Gadi: Sefoni, Haggi, Ṣuni, Esboni, Eri, Arodi, àti Areli.
Gadovi sinovi: Cifjón, Hagí, Šuní, Ecbón, Erí, Aród in Arelí.
17 Àwọn ọmọkùnrin Aṣeri: Imina, Iṣifa, Iṣfi àti Beriah. Arábìnrin wọn ni Sera. Àwọn ọmọkùnrin Beriah: Heberi àti Malkieli.
Aserjevi sinovi: Jimná, Jišvá, Jišví, Berijá in njihova sestra Sêraha. In Berijájeva sinova: Heber in Malkiél.
18 Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ tí Jakọbu bí nípasẹ̀ Silipa, ẹni tí Labani fi fún Lea ọmọbìnrin rẹ̀. Gbogbo wọn jẹ́ mẹ́rìndínlógún lápapọ̀.
To so sinovi Zilpe, ki jo je Labán dal svoji hčeri Lei in te je rodila Jakobu: šestnajst duš.
19 Àwọn ọmọkùnrin Rakeli aya Jakọbu: Josẹfu àti Benjamini.
Sinova Jakobove žene Rahele: Jožef in Benjamin.
20 Ní Ejibiti, Asenati ọmọbìnrin Potifẹra, alábojútó àti àlùfáà Oni, bí Manase àti Efraimu fún Josẹfu.
Jožefu sta bila v egiptovski deželi rojena Manáse in Efrájim, katera mu je rodila Asenáta, hči Potifêra, duhovnika iz Ona.
21 Àwọn ọmọ Benjamini: Bela, Bekeri, Aṣbeli, Gera, Naamani, Ehi, Roṣi, Mupimu, Huppimu àti Ardi.
Benjaminovi sinovi so bili Bela, Beher, Ašbél, Gerá, Naamán, Ehí, Roš, Mupím, Hupím in Ard.
22 Wọ̀nyí ni àwọn ọmọkùnrin tí Rakeli bí fún Jakọbu. Wọ́n jẹ́ mẹ́rìnlá lápapọ̀.
To so Rahelini sinovi, ki so bili rojeni Jakobu. Vseh duš je bilo štirinajst.
23 Àwọn ọmọ Dani: Huṣimu.
Danovi sinovi: Huším.
24 Àwọn ọmọ Naftali: Jasieli, Guni, Jeseri, àti Ṣillemu.
Neftálijevi sinovi: Jahceél, Guní, Jecer in Šilém.
25 Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ tí Biliha ẹni tí Labani fi fún Rakeli ọmọ rẹ̀ bí fún Jakọbu. Wọ́n jẹ́ méje lápapọ̀.
To so sinovi Bilhe, ki jo je Labán dal svoji hčeri Raheli in te je rodila Jakobu. Vseh duš je bilo sedem.
26 Gbogbo àwọn tí ó lọ pẹ̀lú Jakọbu sí Ejibiti, àwọn tí ó jẹ́ ìran rẹ̀ tààrà láìka àwọn aya ọmọ rẹ̀, jẹ́ ènìyàn mẹ́rìndínláàádọ́rin.
Vseh duš, ki so z Jakobom prišle v Egipt, ki so prišle iz njegovih ledij, poleg žen Jakobovih sinov, vseh duš je bilo šestinšestdeset.
27 Pẹ̀lú àwọn ọmọkùnrin méjì tí a bí fún Josẹfu ní Ejibiti àwọn ará ilé Jakọbu tí ó lọ sí Ejibiti jẹ́ àádọ́rin lápapọ̀.
Jožefova sinova, ki sta bila rojena v Egiptu, sta bili dve duši. Vseh duš Jakobove hiše, ki so prišle v Egipt, je bilo sedemdeset.
28 Jakọbu sì rán Juda ṣáájú rẹ̀ lọ sọ́dọ̀ Josẹfu, kí wọn bá à le mọ ọ̀nà Goṣeni. Nígbà tí wọ́n dé agbègbè Goṣeni,
Pred njim je poslal k Jožefu Juda, da njegov obraz usmeri v Gošen, in prišli so v gošensko deželo.
29 Josẹfu tọ́jú kẹ̀kẹ́-ẹṣin rẹ̀ ó sì lọ sí Goṣeni láti pàdé Israẹli baba rẹ̀. Bí Josẹfu ti dé iwájú baba rẹ̀, ó dì mọ́ baba rẹ̀ ó sì sọkún fún ìgbà pípẹ́.
Jožef je pripravil svoj bojni voz in odšel v Gošen, da sreča svojega očeta Izraela in se mu predstavi in planil je na njegov vrat in na njegovem vratu dolgo časa jokal.
30 Israẹli wí fún Josẹfu pé, “Wàyí o, mo le kú, níwọ̀n bí mo ti rí i fún ara mi pé, o wà láààyè síbẹ̀.”
Izrael je Jožefu rekel: »Sedaj naj umrem, ker sem videl tvoj obraz, ker si še vedno živ.«
31 Nígbà náà ni Josẹfu wí fún àwọn arákùnrin rẹ̀ àti fún àwọn ará ilé baba rẹ̀ pé, “Èmi yóò gòkè lọ, èmi yóò sì bá Farao sọ̀rọ̀, èmi yóò sì wí fún un pé, ‘Àwọn arákùnrin mi àti ìdílé baba mi tí ń gbé ní Kenaani ti tọ̀ mí wá.
Jožef je rekel svojim bratom in vsej očetovi hiši: »Odšel bom gor in faraonu pokazal ter mu rekel: ›Moji bratje in hiša mojega očeta, ki so bili v kánaanski deželi, so prišli k meni.
32 Darandaran ni àwọn ènìyàn náà, wọ́n ń tọ́jú ẹran ọ̀sìn, wọ́n sì kó agbo ẹran wọn àti agbo màlúù wọn àti gbogbo ohun tí wọ́n ní pẹ̀lú wá.’
Ljudje so pastirji, kajti njihovo ukvarjanje je, da pasejo živino in pripeljali so svoje trope in svoje črede in vse, kar imajo.‹
33 Nígbà tí Farao bá pè yín wọlé tí ó sí béèrè irú iṣẹ́ tí ẹ ń ṣe,
In zgodilo se bo, ko vas bo faraon poklical in vam rekel: ›Kaj je vaš poklic?‹
34 ẹ fún un lésì pé, ‘Àwọn ìránṣẹ́ rẹ ń tọ́jú ẹran ọ̀sìn ni láti ìgbà èwe wa wá gẹ́gẹ́ bí a ṣe ba a lọ́wọ́ àwọn baba wa.’ Nígbà náà ni wọn yóò fún un yín láààyè láti tẹ̀dó sí ilẹ̀ Goṣeni, nítorí pé àwọn ará Ejibiti kórìíra ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́ darandaran.”
da boste rekli: ›Ukvarjanje tvojih služabnikov je okoli živine od naše mladosti celo do sedaj, tako mi in tudi naši očetje.‹ Da boste lahko prebivali v gošenski deželi, kajti vsak pastir je Egipčanom ogabnost.«

< Genesis 46 >