< Genesis 40 >

1 Kò pẹ́ lẹ́yìn èyí, ni agbọ́tí ọba àti alásè rẹ̀ ṣẹ̀ ọba Ejibiti, olúwa wọn.
これらの事の後エジプト王の酒人と膳夫その主エジプト王に罪ををかす
2 Farao sì bínú sí méjì nínú àwọn ìjòyè rẹ̀, olórí agbọ́tí àti olórí alásè,
パロその二人の臣すなはち酒人の長と膳夫の長を怒りて
3 Ó sì fi wọ́n sí ìhámọ́ ní ilé olórí ẹ̀ṣọ́, ní inú ẹ̀wọ̀n ibi tí Josẹfu pẹ̀lú wà.
之を侍衞の長の家の中なる獄に幽囚ふヨセフが繋れをる所なり
4 Olórí ẹ̀ṣọ́ sì yan Josẹfu láti máa ṣe ìránṣẹ́ wọn. Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti wà ní ìhámọ́ fún ìgbà díẹ̀.
侍衞の長ヨセフをして彼等の側に侍しめたればヨセフ之につかふ彼等幽囚れて日を經たり
5 Ni ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọkùnrin méjèèjì náà—olórí agbọ́tí àti olórí alásè ọba Ejibiti, tí a dè sínú túbú, lá àlá ní òru kan náà, àlá kọ̀ọ̀kan sì ní ìtumọ̀ tirẹ̀.
茲に獄に繋れたるエジプト王の酒人と膳夫の二人ともに一夜の中に各夢を見たりその夢はおのおんおのその解明にかなふ
6 Nígbà tí Josẹfu dé ọ̀dọ̀ wọn ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, ó ṣe àkíyèsí pé, inú wọn kò dùn.
ヨセフ朝に及びて彼等の所に入て視るに彼等物憂に見ゆ
7 Ó sì bi àwọn ìjòyè Farao tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ nínú ìhámọ́, nínú ilé olúwa rẹ̀ léèrè pé, “Èéṣe tí ojú yín fi fàro bẹ́ẹ̀ ní òní, tí inú yín kò sì dùn?”
是に於てヨセフその主人の家に己とともに幽囚をるパロの臣に問て汝等なにゆゑに今日は顏色あやしきやといふに
8 Wọ́n wí pé, “Àwa méjèèjì ni a lá àlá, kò sì sí ẹni tí yóò túmọ̀ rẹ̀.” Josẹfu sì wí fún wọn pé, “Ọlọ́run nìkan ni ó ni ìtumọ̀. Ẹ sọ àwọn àlá yín fún mi.”
彼等これにいふ我等夢を見たれど之を解く者なしとヨセフ彼等にいひけるは解く事は神によるにあらずや請ふ我に述よ
9 Olórí agbọ́tí sì ṣọ́ àlá rẹ̀ fún Josẹfu, wí pé, “Ní ojú àlá mi, mo rí àjàrà kan (tí wọn ń fi èso rẹ̀ ṣe wáìnì) níwájú mi,
酒人の長その夢をヨセフに述て之にいふ我夢の中に見しにわが前に一の葡萄樹あり
10 mo sì rí ẹ̀ka mẹ́ta lórí àjàrà náà, ó yọ ẹ̀ka tuntun, ó sì tanná, láìpẹ́, ó bẹ̀rẹ̀ sí ní í ní èso tí ó ti pọ́n.
その樹に三の枝あり芽いで花ひらきて葡萄なり球をなして熟たるがごとくなりき
11 Ife Farao sì wà lọ́wọ́ mi, mo sì mú àwọn èso àjàrà náà, mo sì fún un sínú ife Farao, mo sì gbé ife náà fún Farao.”
時にパロの爵わが手にあり我葡萄を摘てこれをパロの爵に搾りその爵をパロの手に奉たり
12 Josẹfu wí fún un pé, “Èyí ni ìtumọ̀ àlá rẹ. Ẹ̀ka mẹ́ta náà dúró fún ọjọ́ mẹ́ta.
ヨセフ彼にいひけるはその解明は是のごとし三の枝は三日なり
13 Láàrín ọjọ́ mẹ́ta Farao yóò mú ọ jáde nínú ẹ̀wọ̀n padà sí ipò rẹ, ìwọ yóò sì tún máa gbé ọtí fún un, gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ àtẹ̀yìnwá.
今より三日の中にパロなんぢの首を擧げ汝を故の所にかへさん汝は曩に酒人たりし時になせし如くパロの爵をその手に奉ぐるにいたらん
14 Ṣùgbọ́n nígbà tí ohun gbogbo bá dára fún ọ, rántí mi kí o sì fi àánú hàn sí mi. Dárúkọ mi fún Farao, kí o sì mú mi jáde kúrò ní ìhín.
然ば請ふ汝善ならん時に我をおもひて我に恩惠をほどこし吾事をパロにのべてこの家よりわれを出せ
15 Nítorí á jí mi gbé tà kúrò ní ilẹ̀ àwọn Heberu ni, àti pé níhìn-ín èmi kò ṣe ohunkóhun tí ó fi yẹ kí èmi wà ní ìhámọ́ bí mo ti wà yìí.”
我はまことにヘブル人の地より掠れ來しものなればなりまた此にても我は牢にいれらるるがごとき事はなさざりしなり
16 Nígbà tí olórí alásè rí i wí pé ìtumọ̀ tí Josẹfu fún àlá náà dára, ó wí fún Josẹfu pé, “Èmi pẹ̀lú lá àlá, mo ru agbọ̀n oúnjẹ mẹ́ta lórí.
茲に膳夫の長その解明の善りしを見てヨセフにいふ我も夢を得て見たるに白きパン三筐わが首にありて
17 Nínú agbọ̀n tí ó wà lókè, onírúurú oúnjẹ ló wà níbẹ̀ fún Farao, ṣùgbọ́n àwọn ẹyẹ sì ń ṣà wọ́n jẹ láti inú apẹ̀rẹ̀ náà tí ó wà lórí mi.”
その上の筐には膳夫がパロのために作りたる各種の饌ありしが鳥わが首の筐の中より之をくらへり
18 Josẹfu dáhùn, “Èyí ni ìtumọ̀ àlá rẹ. Agbọ̀n mẹ́ta náà túmọ̀ sí ọjọ́ mẹ́ta.
ヨセフこたへていひけるはその解明はかくのごとし三の筐は三日なり
19 Láàrín ọjọ́ mẹ́ta, Farao yóò tú ọ sílẹ̀, yóò sì bẹ́ orí rẹ, yóò sì gbé ara rẹ kọ́ sí orí igi. Àwọn ẹyẹ yóò sì jẹ ara rẹ.”
今より三日の中にパロ汝の首を擧はなして汝を木に懸んしかして鳥汝の肉をくらひとるべしと
20 Ọjọ́ kẹta sì jẹ́ ọjọ́ ìbí Farao, ó sì ṣe àsè fún gbogbo àwọn ìjòyè e rẹ̀. Ó sì mú olórí agbọ́tí àti olórí alásè jáde kúrò nínú ẹ̀wọ̀n.
第三日はパロの誕辰なればパロその諸の臣僕に筵席をなし酒人の長と膳夫の長をして首をその臣僕の中に擧しむ
21 Ó dá olórí agbọ́tí padà sí ipò tí ó wà tẹ́lẹ̀, kí ó ba à le máa fi ago lé Farao ní ọwọ́,
即ちパロ酒人の長をその職にかへしければ彼爵をパロの手に奉たり
22 ṣùgbọ́n, ó so olórí alásè kọ́ sórí igi, gẹ́gẹ́ bí Josẹfu ti sọ fún wọn nínú ìtumọ̀ rẹ̀ sí àlá wọn.
されど膳夫の長は木に懸らるヨセフの彼等に解明せるがごとし
23 Ṣùgbọ́n, olórí agbọ́tí kò rántí Josẹfu mọ́, kò tilẹ̀ ronú nípa rẹ̀.
然るに酒人の長ヨセフをおぼえずして之を忘れたり

< Genesis 40 >