< Genesis 4 >

1 Adamu sì bá aya rẹ̀ Efa lòpọ̀, ó sì lóyún, ó sì bí Kaini. Ó wí pé, “Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Olúwa ni mo bí ọmọ ọkùnrin.”
Adam vero cognovit Havam uxorem suam quae concepit et peperit Cain dicens possedi hominem per Dominum
2 Lẹ́yìn náà, ó sì bí ọmọkùnrin mìíràn tí a pè ní Abeli. Abeli jẹ́ darandaran, Kaini sì jẹ́ àgbẹ̀.
rursusque peperit fratrem eius Abel fuit autem Abel pastor ovium et Cain agricola
3 Ó sì ṣe lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, Kaini mú ọrẹ wá fún Olúwa nínú èso ilẹ̀ rẹ̀.
factum est autem post multos dies ut offerret Cain de fructibus terrae munera Domino
4 Ṣùgbọ́n Abeli mú ẹran tí ó sanra wá fún Olúwa nínú àkọ́bí ẹran ọ̀sìn rẹ̀. Olúwa sì fi ojúrere wo Abeli àti ọrẹ rẹ̀,
Abel quoque obtulit de primogenitis gregis sui et de adipibus eorum et respexit Dominus ad Abel et ad munera eius
5 ṣùgbọ́n Olúwa kò fi ojúrere wo Kaini àti ẹbọ rẹ̀. Nítorí náà inú bí Kaini gidigidi, ojú rẹ̀ sì fàro.
ad Cain vero et ad munera illius non respexit iratusque est Cain vehementer et concidit vultus eius
6 Nígbà náà ni Olúwa bi Kaini pé, “Èéṣe tí ìwọ ń bínú? Èéṣe tí ojú rẹ sì fàro?
dixitque Dominus ad eum quare maestus es et cur concidit facies tua
7 Bí ìwọ bá ṣe ohun tí ó tọ́, ṣé ìwọ kò ní jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà? Ṣùgbọ́n bí ìwọ kò bá ṣe ohun tí ó tọ́, ẹ̀ṣẹ̀ ń bẹ ní ẹnu-ọ̀nà rẹ, ó fẹ́ ní ọ ní ìní, ṣùgbọ́n ìwọ gbọdọ̀ ṣe àkóso rẹ̀.”
nonne si bene egeris recipies sin autem male statim in foribus peccatum aderit sed sub te erit appetitus eius et tu dominaberis illius
8 Kaini wí fún Abeli arákùnrin rẹ̀ pé, “Jẹ́ kí a lọ sí oko.” Ó sì ṣe, bí wọ́n ti wà ní oko; Kaini da ojú ìjà kọ Abeli arákùnrin rẹ̀, ó sì pa á.
dixitque Cain ad Abel fratrem suum egrediamur foras cumque essent in agro consurrexit Cain adversus Abel fratrem suum et interfecit eum
9 Nígbà náà ni Olúwa béèrè lọ́wọ́ Kaini pé, “Níbo ni Abeli arákùnrin rẹ wà?” Ó sì dáhùn pé, “Èmi kò mọ ibi tí ó wà, èmí ha ń ṣe olùṣọ́ arákùnrin mi bí?”
et ait Dominus ad Cain ubi est Abel frater tuus qui respondit nescio num custos fratris mei sum
10 Olúwa wí pé, “Kín ni ohun tí ìwọ ṣe yìí? Gbọ́! Ẹ̀jẹ̀ arákùnrin rẹ ń kígbe pè mí láti ilẹ̀ wá.
dixitque ad eum quid fecisti vox sanguinis fratris tui clamat ad me de terra
11 Láti ìsinsin yìí lọ, ìwọ ti wà lábẹ́ ègún, a sì ti lé ọ lórí ilẹ̀ tí ó ya ẹnu gba ẹ̀jẹ̀ arákùnrin rẹ lọ́wọ́ rẹ.
nunc igitur maledictus eris super terram quae aperuit os suum et suscepit sanguinem fratris tui de manu tua
12 Bí ìwọ bá ro ilẹ̀, ilẹ̀ kì yóò fi agbára rẹ̀ so èso rẹ̀ fún ọ mọ́. Ìwọ yóò sì jẹ́ ìsáǹsá àti alárìnkiri ni orí ilẹ̀ ayé.”
cum operatus fueris eam non dabit tibi fructus suos vagus et profugus eris super terram
13 Kaini wí fún Olúwa pé, “Ẹrù ìyà ẹ̀ṣẹ̀ mi pọ̀ ju èyí tí mo le rù lọ.
dixitque Cain ad Dominum maior est iniquitas mea quam ut veniam merear
14 Lónìí, ìwọ lé mi kúrò lórí ilẹ̀, mó sì di ẹni tí ó fi ara pamọ́ kúrò ní ojú rẹ, èmi yóò sì di ìsáǹsá àti alárìnkiri ní ayé, ẹnikẹ́ni tí ó bá rí mi, yóò sì pa mí.”
ecce eicis me hodie a facie terrae et a facie tua abscondar et ero vagus et profugus in terra omnis igitur qui invenerit me occidet me
15 Ṣùgbọ́n, Olúwa wí fún pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́, bí ẹnikẹ́ni bá pa Kaini, èmi yóò gbẹ̀san ní ara onítọ̀hún ní ìgbà méje.” Nígbà náà ni Ọlọ́run fi àmì sí ara Kaini, kí ẹnikẹ́ni tí ó bá ri má ba à pa á.
dixitque ei Dominus nequaquam ita fiet sed omnis qui occiderit Cain septuplum punietur posuitque Dominus Cain signum ut non eum interficeret omnis qui invenisset eum
16 Kaini sì kúrò níwájú Olúwa, ó sì ń gbé ilẹ̀ Nodi ní ìhà ìlà-oòrùn Edeni.
egressusque Cain a facie Domini habitavit in terra profugus ad orientalem plagam Eden
17 Kaini sì bá aya rẹ̀ lòpọ̀, ó sì lóyún, ó sì bí Enoku. Kaini sì tẹ ìlú kan dó, ó sì fi orúkọ ọmọ rẹ̀ ọkùnrin Enoku sọ ìlú náà.
cognovit autem Cain uxorem suam quae concepit et peperit Enoch et aedificavit civitatem vocavitque nomen eius ex nomine filii sui Enoch
18 Enoku sì bí Iradi, Iradi sì ni baba Mehujaeli, Mehujaeli sì bí Metuṣaeli, Metuṣaeli sì ni baba Lameki.
porro Enoch genuit Irad et Irad genuit Maviahel et Maviahel genuit Matusahel et Matusahel genuit Lamech
19 Lameki sì fẹ́ aya méjì, orúkọ èkínní ni Adah, àti orúkọ èkejì ni Silla.
qui accepit uxores duas nomen uni Ada et nomen alteri Sella
20 Adah sì bí Jabali, òun ni baba irú àwọn tí ń gbé inú àgọ́, tí wọ́n sì ń sin ẹran ọ̀sìn.
genuitque Ada Iabel qui fuit pater habitantium in tentoriis atque pastorum
21 Orúkọ arákùnrin rẹ̀ ni Jubali, òun ni baba irú àwọn tí ń tẹ dùùrù tí wọ́n sì ń fọn fèrè.
et nomen fratris eius Iubal ipse fuit pater canentium cithara et organo
22 Silla náà sì bí ọmọkùnrin tí ń jẹ́ Tubali-Kaini, tí ó ń rọ oríṣìíríṣìí ohun èlò láti ara idẹ àti irin. Arábìnrin Tubali-Kaini ni Naama.
Sella quoque genuit Thubalcain qui fuit malleator et faber in cuncta opera aeris et ferri soror vero Thubalcain Noemma
23 Lameki wí fún àwọn aya rẹ̀, “Adah àti Silla, ẹ tẹ́tí sí mi; ẹ̀yin aya Lameki, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ mi. Mo ti pa ọkùnrin kan tí ó kọlù mí, ọ̀dọ́mọkùnrin tí ó pa mí lára.
dixitque Lamech uxoribus suis Adae et Sellae audite vocem meam uxores Lamech auscultate sermonem meum quoniam occidi virum in vulnus meum et adulescentulum in livorem meum
24 Bí a ó bá gbẹ̀san Kaini ní ìgbà méje, ǹjẹ́ kí a gba ti Lameki nígbà mẹ́tàdínlọ́gọ́rin.”
septuplum ultio dabitur de Cain de Lamech vero septuagies septies
25 Adamu sì tún bá aya rẹ̀ lòpọ̀, ó sì bí ọmọkùnrin kan tí ó pe orúkọ rẹ̀ ní Seti, tí ó túmọ̀ sí pé, “Ọlọ́run fún mi ní ọmọkùnrin mìíràn ní ipò Abeli tí Kaini pa.”
cognovit quoque adhuc Adam uxorem suam et peperit filium vocavitque nomen eius Seth dicens posuit mihi Deus semen aliud pro Abel quem occidit Cain
26 Seti náà sì bí ọmọkùnrin kan, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Enoṣi. Láti àkókò náà lọ ni àwọn ènìyàn ti bẹ̀rẹ̀ sí ní ké pe orúkọ Olúwa.
sed et Seth natus est filius quem vocavit Enos iste coepit invocare nomen Domini

< Genesis 4 >