< Genesis 36 >

1 Wọ̀nyí ni ìran Esau, ẹni tí a ń pè ní Edomu.
以扫就是以东,他的后代记在下面。
2 Nínú àwọn ọmọbìnrin Kenaani ni Esau ti fẹ́ àwọn ìyàwó rẹ̀: Adah ọmọbìnrin Eloni ará Hiti àti Oholibama, ọmọbìnrin Ana, ọmọ ọmọ Sibeoni ará Hifi.
以扫娶迦南的女子为妻,就是赫人以伦的女儿亚大和希未人祭便的孙女、亚拿的女儿阿何利巴玛,
3 Ó sì tún fẹ́ Basemati ọmọ Iṣmaeli arábìnrin Nebaioti.
又娶了以实玛利的女儿、尼拜约的妹子巴实抹。
4 Adah bí Elifasi fún Esau, Basemati sì bí Reueli,
亚大给以扫生了以利法;巴实抹生了流珥;
5 Oholibama pẹ̀lú sì bí Jeuṣi, Jalamu, àti Kora. Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ tí Esau bí ní Kenaani.
阿何利巴玛生了耶乌施、雅兰、可拉。这都是以扫的儿子,是在迦南地生的。
6 Esau sì mú àwọn aya rẹ̀, àwọn ọmọkùnrin rẹ̀, àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ àti gbogbo àwọn ará ilé rẹ̀, àwọn ohun ọ̀sìn rẹ̀ àti àwọn ẹran ọ̀sìn mìíràn àti gbogbo ohun ìní mìíràn tí ó ní, ni Kenaani, ó sì kó lọ sí ilẹ̀ mìíràn, jìnà sí ibi tí Jakọbu arákùnrin rẹ̀ wà.
以扫带着他的妻子、儿女,与家中一切的人口,并他的牛羊、牲畜,和一切货财,就是他在迦南地所得的,往别处去,离了他兄弟雅各。
7 Ohun ìní wọn pọ̀ ju èyí tí àwọn méjèèjì lè máa gbé ní ojú kan lọ. Ilẹ̀ tí wọ́n wà kò le gba àwọn méjèèjì nítorí àwọn ohun ọ̀sìn wọn.
因为二人的财物群畜甚多,寄居的地方容不下他们,所以不能同居。
8 Báyìí ni Esau (tí a tún mọ̀ sí Edomu) tẹ̀dó sí àwọn orílẹ̀-èdè olókè tí Seiri.
于是以扫住在西珥山里;以扫就是以东。
9 Èyí ni ìran Esau baba àwọn ará Edomu ní àwọn orílẹ̀-èdè olókè Seiri.
以扫是西珥山里以东人的始祖,他的后代记在下面。
10 Wọ̀nyí ni orúkọ àwọn ọmọ Esau: Elifasi ọmọ Adah aya Esau àti Reueli, ọmọ Basemati tí í ṣe aya Esau pẹ̀lú.
以扫众子的名字如下。以扫的妻子亚大生以利法;以扫的妻子巴实抹生流珥。
11 Àwọn ọmọ Elifasi ni ìwọ̀nyí: Temani, Omari, Sefi, Gatamu, àti Kenasi.
以利法的儿子是提幔、阿抹、洗玻、迦坦、基纳斯。
12 Elifasi ọmọ Esau sì tún ní àlè tí a ń pè ní Timna pẹ̀lú, òun ló bí Amaleki fún un. Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ ọmọ Adah aya Esau.
亭纳是以扫儿子以利法的妾;她给以利法生了亚玛力。这是以扫的妻子亚大的子孙。
13 Àwọn ọmọ Reueli: Nahati, Sera, Ṣamma àti Missa. Àwọn ni ọmọ ọmọ Basemati aya Esau.
流珥的儿子是拿哈、谢拉、沙玛、米撒。这是以扫妻子巴实抹的子孙。
14 Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Oholibama ọmọbìnrin Ana ọmọ ọmọ Sibeoni: tí ó bí fún Esau: Jeuṣi, Jalamu àti Kora.
以扫的妻子阿何利巴玛是祭便的孙女,亚拿的女儿;她给以扫生了耶乌施、雅兰、可拉。
15 Àwọn wọ̀nyí ni olórí nínú àwọn ọmọ Esau: àwọn ọmọ Elifasi, àkọ́bí Esau, Temani, Omari, Sefi, Kenasi,
以扫子孙中作族长的记在下面。以扫的长子以利法的子孙中,有提幔族长、阿抹族长、洗玻族长、基纳斯族长、
16 Kora, Gatamu àti Amaleki. Àwọn wọ̀nyí ló jẹ́ olórí ìdílé tí ó ti ọ̀dọ̀ Elifasi ní Edomu wá, wọ́n jẹ́ ọmọ ọmọ Adah.
可拉族长、迦坦族长、亚玛力族长。这是在以东地从以利法所出的族长,都是亚大的子孙。
17 Wọ̀nyí sì ni àwọn ọmọ Esau, ọmọ Rueli: Nahati olórí, Sera olórí, Ṣamma olórí, Missa olórí. Àwọn wọ̀nyí ló jẹ́ olórí ìdílé tí ó ti ọ̀dọ̀ Reueli jáde ní Edomu. Ọmọ ọmọ Basemati aya Esau ni wọ́n jẹ́.
以扫的儿子流珥的子孙中,有拿哈族长、谢拉族长、沙玛族长、米撒族长。这是在以东地从流珥所出的族长,都是以扫妻子巴实抹的子孙。
18 Àwọn ọmọ Oholibama aya Esau: Jeuṣi, Jalamu, àti Kora, àwọn wọ̀nyí ló jẹ́ olórí ìdílé tí ó ti ọ̀dọ̀ Oholibama ọmọ Ana, ìyàwó Esau wá.
以扫的妻子阿何利巴玛的子孙中,有耶乌施族长、雅兰族长、可拉族长。这是从以扫妻子,亚拿的女儿,阿何利巴玛子孙中所出的族长。
19 Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ Esau (ti o túmọ̀ sí Edomu). Àwọn wọ̀nyí ni olórí wọn.
以上的族长都是以扫的子孙;以扫就是以东。
20 Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Seiri ará Hori tí ó ń gbé ní ilẹ̀ náà: Lotani, Ṣobali, Sibeoni, Ana,
那地原有的居民—何利人西珥的子孙记在下面:就是罗坍、朔巴、祭便、亚拿、
21 Diṣoni, Eseri, àti Diṣani, àwọn wọ̀nyí olórí ènìyàn Hori, àwọn ọmọ Seiri ni ilẹ̀ Edomu.
底顺、以察、底珊。这是从以东地的何利人西珥子孙中所出的族长。
22 Àwọn ọmọ Lotani: Hori àti Homamu: Timna sì ni arábìnrin Lotani.
罗坍的儿子是何利、希幔;罗坍的妹子是亭纳。
23 Àwọn ọmọ Ṣobali: Alifani, Manahati, Ebali, Ṣefo àti Onamu.
朔巴的儿子是亚勒文、玛拿辖、以巴录、示玻、阿南。
24 Àwọn ọmọ Sibeoni: Aiah àti Ana. Èyí ni Ana tí ó rí ìsun omi gbígbóná ní inú aginjù bí ó ti ń da àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ Ṣebeoni baba rẹ̀.
祭便的儿子是亚雅、亚拿(当时在旷野放他父亲祭便的驴,遇着温泉的,就是这亚拿)。
25 Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Ana: Diṣoni àti Oholibama ọmọbìnrin Ana.
亚拿的儿子是底顺;亚拿的女儿是阿何利巴玛。
26 Àwọn ọmọ Diṣoni ni: Hemdani, Eṣbani, Itrani àti Kerani.
底顺的儿子是欣但、伊是班、益兰、基兰。
27 Àwọn ọmọ Eseri: Bilhani, Saafani àti Akani.
以察的儿子是辟罕、撒番、亚干。
28 Àwọn ọmọ Diṣani ni: Usi àti Arani.
底珊的儿子是乌斯、亚兰。
29 Àwọn wọ̀nyí ni olórí ìdílé Hori: Lotani, Ṣobali, Sibeoni, Ana,
从何利人所出的族长记在下面:就是罗坍族长、朔巴族长、祭便族长、亚拿族长、
30 Diṣoni Eseri, àti Diṣani. Àwọn ni olórí ìdílé àwọn ará Hori gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn ní ilẹ̀ Seiri.
底顺族长、以察族长、底珊族长。这是从何利人所出的族长,都在西珥地,按着宗族作族长。
31 Àwọn wọ̀nyí ni ọba tí ó jẹ ní Edomu kí ó tó di pé ọba kankan jẹ lórí Israẹli:
以色列人未有君王治理以先,在以东地作王的记在下面。
32 Bela ọmọ Beori jẹ ní Edomu. Orúkọ ìlú rẹ̀ ni Dinhaba.
比珥的儿子比拉在以东作王,他的京城名叫亭哈巴。
33 Nígbà tí Bela kú, Jobabu ọmọ Sera ti Bosra sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.
比拉死了,波斯拉人谢拉的儿子约巴接续他作王。
34 Nígbà tí Jobabu kú, Huṣamu láti ilẹ̀ Temani sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.
约巴死了,提幔地的人户珊接续他作王。
35 Nígbà tí Huṣamu kú, Hadadi ọmọ Bedadi tí ó kọlu Midiani ní ìgbẹ́ Moabu, ó sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀. Orúkọ ìlú rẹ̀ ni Afiti.
户珊死了,比达的儿子哈达接续他作王;这哈达就是在摩押地杀败米甸人的,他的京城名叫亚未得。
36 Nígbà tí Hadadi sì kú, Samla láti Masreka, ó sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.
哈达死了,玛士利加人桑拉接续他作王。
37 Samla sì kú, Saulu ti Rehoboti, létí odò sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.
桑拉死了,大河边的利河伯人扫罗接续他作王。
38 Nígbà tí Saulu kú, Baali-Hanani ọmọ Akbori jẹ ọba ní ipò rẹ̀.
扫罗死了,亚革波的儿子巴勒·哈南接续他作王。
39 Nígbà tí Baali-Hanani ọmọ Akbori kú, Hadadi ni ó jẹ ọba ní ipò rẹ̀. Orúkọ ìlú rẹ̀ ni Pau, orúkọ ìyàwó sì ni Mehetabeeli ọmọbìnrin Matiredi, ọmọbìnrin Mesahabu.
亚革波的儿子巴勒·哈南死了,哈达接续他作王,他的京城名叫巴乌;他的妻子名叫米希她别,是米·萨合的孙女,玛特列的女儿。
40 Àwọn wọ̀nyí ni orúkọ àwọn baálẹ̀ tí ó ti ọ̀dọ̀ Esau jáde wá, ní orúkọ ìdílé wọn, bí ìpínlẹ̀ wọn ti rí: baálẹ̀ Timna, baálẹ̀ Alfa, baálẹ̀ Jeteti.
从以扫所出的族长,按着他们的宗族、住处、名字记在下面:就是亭纳族长、亚勒瓦族长、耶帖族长、
41 Baálẹ̀ Oholibama, baálẹ̀ Ela, baálẹ̀ Pinoni,
阿何利巴玛族长、以拉族长、比嫩族长、
42 baálẹ̀ Kenasi, baálẹ̀ Temani, baálẹ̀ Mibsari,
基纳斯族长、提幔族长、米比萨族长、
43 Magdieli, àti Iramu. Àwọn wọ̀nyí ni baálẹ̀ Edomu, gẹ́gẹ́ bí wọn ti tẹ̀dó sí ilẹ̀ tí wọ́n gbà. Èyí ni Esau baba àwọn ará Edomu.
玛基叠族长、以兰族长。这是以东人在所得为业的地上,按着他们的住处。(所有的族长都是以东人的始祖以扫的后代。)

< Genesis 36 >