< Genesis 23 >

1 Sara sì pé ọmọ ọdún mẹ́tàdínláàádóje.
و ایام زندگانی ساره، صد و بیست وهفت سال بود، این است سالهای عمرساره.۱
2 Ó sì kú ní Kiriati-Arba (ìyẹn ní Hebroni) ní ilẹ̀ Kenaani, Abrahamu lọ láti ṣọ̀fọ̀ àti láti sọkún nítorí Sara.
و ساره در قریه اربع، که حبرون باشد، درزمین کنعان مرد. و ابراهیم آمد تا برای ساره ماتم و گریه کند.۲
3 Abrahamu sì dìde lẹ́gbẹ̀ẹ́ òkú aya rẹ̀, ó sì sọ fún àwọn ará Hiti wí pé,
و ابراهیم از نزد میت خودبرخاست، و بنی حت را خطاب کرده، گفت:۳
4 “Èmi jẹ́ àtìpó àti àlejò láàrín yín, ẹ ta ilẹ̀ ìsìnkú fún mi kí èmi le sin òkú tí ó kú fún mi sí.”
«من نزد شما غریب و نزیل هستم. قبری از نزد خود به ملکیت من دهید، تا میت خود را از پیش روی خود دفن کنم.»۴
5 Àwọn ọmọ Hiti dá Abrahamu lóhùn pé,
پس بنی حت در جواب ابراهیم گفتند:۵
6 “Olúwa mi, gbọ́ tiwa, ó jẹ́ alágbára ọmọ-aládé láàrín wa, sin òkú rẹ sí ibojì tí ó dára jù nínú àwọn ibojì wa, kò sí ẹni tí yóò fi ibojì rẹ dù ọ́ láti sin òkú rẹ sí.”
«ای مولای من، سخن ما را بشنو. تو درمیان ما رئیس خدا هستی. در بهترین مقبره های ما، میت خود را دفن کن. هیچ کدام از ما، قبرخویش را از تو دریغ نخواهد داشت که میت خودرا دفن کنی.»۶
7 Nígbà náà ni Abrahamu dìde, ó sì tẹríba níwájú àwọn ará ilẹ̀ náà, àwọn ará Hiti.
پس ابراهیم برخاست، و نزد اهل آن زمین، یعنی بنی حت، تعظیم نمود.۷
8 Ó sì wí fún wọn pé, “Bí ó bá ṣe pé, lóòótọ́ ni ẹ fẹ́ kí n sin òkú mi kúrò nílẹ̀, ẹ gbọ́ tèmi, ẹ bá mi bẹ Efroni ọmọ Sohari,
و ایشان را خطاب کرده، گفت: «اگر مرضی شما باشد که میت خود را از نزد خود دفن کنم، سخن مرابشنوید و به عفرون بن صوحار، برای من سفارش کنید،۸
9 kí ó ta ihò àpáta Makpela tí ó jẹ́ tirẹ̀ fún mi, èyí tí ó wà ni orí oko rẹ̀, kí ó tà á fún mi ni iye owó tí à ń ta irú rẹ̀ fún ilẹ̀ ìsìnkú láàrín yín.”
تا مغاره مکفیله را که از املاک او در کنارزمینش واقع است، به من دهد، به قیمت تمام، درمیان شما برای قبر، به ملکیت من بسپارد.»۹
10 Efroni ará Hiti sì wà níbẹ̀ pẹ̀lú, ó sì dá Abrahamu lóhùn lójú gbogbo àwọn ará ìlú tí ó wà níbẹ̀, lẹ́nu ibodè ìlú,
و عفرون در میان بنی حت نشسته بود. پس عفرون حتی، در مسامع بنی حت، یعنی همه که به دروازه شهر او داخل می‌شدند، در جواب ابراهیم گفت:۱۰
11 pé, “Rárá, olúwa mi. Gbọ́ tèmi; mo fún ọ ní ilẹ̀ náà àti ihò àpáta tí ó wà níbẹ̀. Mo fún ọ níwájú gbogbo àwọn ènìyàn mi. Sin òkú rẹ síbẹ̀.”
«ای مولای من، نی، سخن مرا بشنو، آن زمین را به تو می‌بخشم، و مغاره‌ای را که در آن است به تو می‌دهم، بحضور ابنای قوم خود، آن رابه تو می‌بخشم. میت خود را دفن کن.»۱۱
12 Abrahamu sì tún tẹríba níwájú àwọn ènìyàn ìlú náà,
پس ابراهیم نزد اهل آن زمین تعظیم نمود،۱۲
13 ó sì wí fún Efroni lójú gbogbo wọn pé, “Bí ìwọ bá fẹ́, gbọ́ tèmi, èmi yóò san owó ilẹ̀ náà, gbà á lọ́wọ́ mi kí n lè sin òkú mi síbẹ̀.”
و عفرون را به مسامع اهل زمین خطاب کرده، گفت: «اگر تو راضی هستی، التماس دارم عرض مرا اجابت کنی. قیمت زمین را به تو می‌دهم، از من قبول فرمای، تا در آنجا میت خود را دفن کنم.»۱۳
14 Efroni sì dá Abrahamu lóhùn pé,
عفرون در جواب ابراهیم گفت:۱۴
15 “Gbọ́ tèmi Olúwa mi, irinwó òsùwọ̀n owó fàdákà ni ilẹ̀ náà, ṣùgbọ́n kín ni ìyẹn já mọ láàrín àwa méjèèjì? Sá à sin òkú rẹ.”
«ای مولای من، از من بشنو، قیمت زمین چهارصد مثقال نقره است، این در میان من و تو چیست؟ میت خود رادفن کن.»۱۵
16 Abrahamu sì gbọ́ tí Efroni wí, Abrahamu sì wọn iye fàdákà náà fún Efroni, tí ó sọ ní etí àwọn ọmọ Hiti, irinwó òsùwọ̀n ṣékélì fàdákà, tí ó kọjá lọ́dọ̀ àwọn oníṣòwò.
پس ابراهیم، سخن عفرون را اجابت نمود، و آن مبلغی را که در مسامع بنی حت گفته بود، یعنی چهارصد مثقال نقره رایج المعامله، به نزدعفرون وزن کرد.۱۶
17 Báyìí ni ilẹ̀ Efroni tí ó wà ni Makpela nítòsí Mamre, ilẹ̀ náà àti ihò àpáta tí ó wà nínú rẹ̀ àti gbogbo igi tí ó wà nínú ilẹ̀ náà ni a ṣe ètò rẹ̀ dájú,
پس زمین عفرون، که درمکفیله، برابر ممری واقع است، یعنی زمین ومغاره‌ای که در آن است، با همه درختانی که در آن زمین، و در تمامی حدود و حوالی آن بود، مقررشد۱۷
18 bí ohun ìní fún Abrahamu níwájú gbogbo ará Hiti tí ó wá sí ẹnu ibodè ìlú náà.
به ملکیت ابراهیم، بحضور بنی حت، یعنی همه که به دروازه شهرش داخل می‌شدند.۱۸
19 Lẹ́yìn náà ni Abrahamu sin aya rẹ̀ Sara sínú ihò àpáta ní ilẹ̀ Makpela nítòsí Mamre (tí í ṣe Hebroni) ní ilẹ̀ Kenaani.
ازآن پس، ابراهیم، زوجه خود، ساره را در مغاره صحرای مکفیله، در مقابل ممری، که حبرون باشد، در زمین کنعان دفن کرد.۱۹
20 Ilẹ̀ náà àti ihò àpáta tí ó wà nínú rẹ̀ ni àwọn ará Hiti fi fún Abrahamu gẹ́gẹ́ bí ohun ìní títí láé, bí ilẹ̀ ìsìnkú fún àwọn òkú tí ó bá kú fun un.
و آن صحرا، بامغاره‌ای که در آن است، از جانب بنی حت، به ملکیت ابراهیم، به جهت قبر مقرر شد.۲۰

< Genesis 23 >