< Genesis 21 >

1 Olúwa sì bẹ Sara wò bí ó ti wí, Olúwa sì ṣe fún Sara gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí.
The Lord came to help Sarah as he'd said he would. The Lord did for Sarah what he'd promised.
2 Sara sì lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan fún Abrahamu ní ọjọ́ ogbó rẹ̀, ní àkókò náà gan an tí Ọlọ́run ti ṣèlérí fún un.
She became pregnant and had a son for Abraham when he was old, at the exact time God said she would.
3 Abrahamu sì sọ orúkọ ọmọ náà tí Sara bí fun un ní Isaaki.
Abraham named their son Isaac.
4 Nígbà tí Isaaki pé ọmọ ọjọ́ mẹ́jọ, Abrahamu sì kọ ọ́ ní ilà gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti pàṣẹ fún un.
Abraham circumcised him when Isaac was eight days old, following God's command.
5 Ẹni ọgọ́rùn-ún ọdún ni Abrahamu nígbà tí ó bí Isaaki.
Abraham was 100 when Isaac was born.
6 Sara sì wí pé, “Ọlọ́run ti pa mí lẹ́rìn-ín. Gbogbo ẹni tí ó bá sì gbọ́ pé mo bímọ yóò rẹ́rìn-ín pẹ̀lú mi.”
Sarah declared, “God has made me laugh, and all those who hear about this will laugh with me.”
7 Ó sì fi kún un pé, “Ta ni ó le sọ fún Abrahamu pé, Sara yóò di ọlọ́mọ? Síbẹ̀síbẹ̀, mo sì tún bí ọmọ fún Abrahamu ní ìgbà ogbó rẹ.”
She also said, “Would anyone have announced to Abraham that Sarah was going to have children to nurse? But now I have had a son for Abraham even when he was old!”
8 Nígbà tí ọmọ náà dàgbà, ó sì gbà á lẹ́nu ọmú, ní ọjọ́ tí a gba Isaaki lẹ́nu ọmú, Abrahamu ṣe àsè ńlá.
The baby grew up, and on the day Isaac was weaned Abraham held a large feast.
9 Ṣùgbọ́n Sara rí ọmọ Hagari ará Ejibiti tí ó bí fún Abrahamu tí ó fi ṣe ẹlẹ́yà,
But Sarah noticed that Ishmael, Hagar the Egyptian's son she'd had for Abraham, was making fun of Isaac.
10 ó sì wí fún Abrahamu pé, “Lé ẹrúbìnrin yìí àti ọmọ rẹ̀ jáde, nítorí ọmọ ẹrú yìí kò ní bá ọmọ mi Isaaki pín ogún.”
So she went to Abraham and told him, “You have to get rid of this slave woman and this son of hers! A slave woman's son is not going to be one of your heirs and inherit together with my son Isaac!”
11 Ọ̀rọ̀ náà sì ba Abrahamu lọ́kàn jẹ́ gidigidi nítorí ọmọ rẹ̀ náà sá à ni Iṣmaeli i ṣe.
Abraham felt very bad about it because Ishmael was his son.
12 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run wí fun Abrahamu pé, “Má ṣe ba ọkàn jẹ́ nítorí ọmọ náà àti ẹrúbìnrin rẹ. Gbọ́ ohun tí Sara wí fún ọ, nítorí nínú Isaaki ni a ó ti pe irú-ọmọ rẹ̀.
But God told Abraham, “Don't feel bad about the boy and the slave woman. Do whatever Sarah tells you, because it's through Isaac that your descendants will be counted.
13 Èmi yóò sọ ọmọ ẹrúbìnrin náà di orílẹ̀-èdè pẹ̀lú, nítorí ọmọ rẹ ni.”
Don't worry—I will also make the son of the slave woman into a nation because he's your son.”
14 Abrahamu sì dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, ó sì mú oúnjẹ àti ìgò omi kan, ó sì kó wọn fún Hagari, ó kó wọn lé e léjìká, ó sì lé e jáde pẹ̀lú ọmọ náà. Ó sì lọ lọ́nà rẹ, ó sì ń ṣe alárìnkiri ní ijù Beerṣeba.
Abraham got up early the next morning. He packed up some food and a skin of water which he gave to Hagar, putting them on her shoulder. Then he sent her and the boy away. She left and wandered through the Desert of Beersheba.
15 Nígbà tí omi inú ìgò náà tan, ó gbé ọmọ náà sí abẹ́ igbó.
When the water ran out, she left the boy under one of the bushes.
16 Ó sì lọ, ó sì jókòó nítòsí ibẹ̀, níwọ̀n bí ìtafà kan, nítorí, ó rò ó nínú ara rẹ̀ pé, “Èmi kò fẹ́ wo bí ọmọ náà yóò ṣe kú.” Bí ó sì ti jókòó sí tòsí ibẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí ní sọkún.
She went and sat down some way off, a few hundred yards away, saying, “I can't bear to watch my son die!” As she sat down she burst into tears.
17 Ọlọ́run gbọ́ ohun ẹkún náà, Angẹli Ọlọ́run sì pe Hagari láti ọ̀run, ó sì wí fun un pé, “Hagari, kín ni ó ṣe ọ́? Má bẹ̀rù nítorí Ọlọ́run ti gbọ́ ẹkún ọmọ náà níbi tí o tẹ́ ẹ sí.
God heard the boy's cries, and the angel of God called to Hagar from heaven and asked her, “What's the matter, Hagar? Don't be afraid! God has heard the boy crying from where he is.
18 Dìde, gbé ọmọ náà sókè, kí o sì dìímú (tù ú nínú) nítorí èmi yóò sọ ọmọ náà di orílẹ̀-èdè ńlá.”
Get up, go over and help the boy up, and encourage him, for I will make him into a great nation.”
19 Ọlọ́run sì ṣí ojú Hagari, ó sì rí kànga kan, ó lọ síbẹ̀, ó rọ omi kún inú ìgò náà, ó sì fún ọmọ náà mu.
God opened her eyes and she saw a well nearby. She went and filled the skin with water and gave the boy a drink.
20 Ọlọ́run sì wà pẹ̀lú ọmọ náà bí ó ti ń dàgbà, ó ń gbé nínú ijù, ó sì di tafàtafà.
God blessed Ishmael and he grew up, living in the desert. He became a skilled archer.
21 Nígbà tí ó ń gbé ni aginjù ní Parani, ìyá rẹ̀ fẹ́ ìyàwó fún un láti ilẹ̀ Ejibiti wá.
He lived in the Desert of Paran. His mother chose a wife for him from the land of Egypt.
22 Ní àkókò yìí ni ọba Abimeleki àti Fikoli, olórí ogun rẹ̀ wí fún Abrahamu pé, “Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ̀ nínú gbogbo ohun tí ó ń ṣe.
Around this time Abimelech came with Phicol, the commander of his army, to see Abraham. “God blesses you in everything you do,” Abimelech said.
23 Ǹjẹ́ nísinsin yìí, fi Ọlọ́run búra fún mi, ìwọ kì yóò tàn mí àti àwọn ọmọ mi àti àwọn ìran mi, ìwọ yóò fi inú rere hàn fún mi àti orílẹ̀-èdè tí ìwọ ti ṣe àtìpó, bí mo ti fihàn fún ọ pẹ̀lú.”
“So swear to me right here and now that you won't betray me, my children, or my descendants. In the same way I've proved I'm trustworthy to you, do the same to me and my country where you're currently living.”
24 Abrahamu sì wí pé, “Èmí búra.”
“I so swear,” Abraham replied.
25 Nígbà náà ni Abrahamu fi ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ hàn fún Abimeleki nípa kànga tí àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ gbà lọ́wọ́ rẹ̀.
Then Abraham raised an issue with Abimelech of a well that Abimelech's servants had taken by force.
26 Ṣùgbọ́n Abimeleki dáhùn pé, “Èmi kò mọ ẹni tí ó ṣe nǹkan yìí. Ìwọ kò sì sọ fún mi, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò gbọ́, bí kò ṣe lónìí.”
“I don't know who did this, and you didn't mention it before. I haven't heard anything about it until today,” Abimelech responded.
27 Abrahamu sì mú àgùntàn àti màlúù wá, ó sì kó wọn fún Abimeleki. Àwọn méjèèjì sì dá májẹ̀mú.
Then Abraham gave Abimelech some of his sheep and cattle, and the two of them made an agreement.
28 Abrahamu sì ya abo ọ̀dọ́-àgùntàn méje nínú agbo àgùntàn rẹ̀ sọ́tọ̀.
Abraham also separated out seven female lambs from the flock.
29 Abimeleki sì béèrè lọ́wọ́ Abrahamu pé, “Kín ni ìtumọ̀ yíyà tí ìwọ ya àwọn ọ̀dọ́-àgùntàn méje wọ̀nyí sọ́tọ̀ sí.”
“What are these seven female lambs for that you've separated from the flock?” Abimelech asked.
30 Ó dalóhùn pé, “Gba àwọn abo ọ̀dọ́-àgùntàn méje wọ̀nyí lọ́wọ́ mi gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí pé èmi ni mo gbẹ́ kànga yìí.”
“I'm giving you these seven female lambs in return for your admission that I dug this well,” Abraham replied.
31 Nítorí náà ni a ṣe ń pe ibẹ̀ náà ni Beerṣeba nítorí níbẹ̀ ni àwọn méjèèjì gbé búra.
That's why he called the place Beersheba, because the two of them swore and oath to each other.
32 Lẹ́yìn májẹ̀mú tí wọ́n dá ní Beerṣeba yìí, ni Abimeleki àti Fikoli olórí ogun rẹ̀ padà sí ilẹ̀ àwọn ará Filistini.
After making the agreement at Beersheba, Abimelech and Phicol the commander of his army left and went home to the country of the Philistines.
33 Abrahamu lọ́ igi tamariski kan sí Beerṣeba, níbẹ̀ ni ó sì pe orúkọ Olúwa Ọlọ́run ayérayé.
Abraham planted a tamarisk tree in Beersheba and there he worshiped the Lord, the Eternal God.
34 Abrahamu sì gbé ilẹ̀ àwọn ará Filistini fún ọjọ́ pípẹ́.
Abraham lived in the country of the Philistines for a long time.

< Genesis 21 >