< Genesis 2 >

1 Báyìí ni Ọlọ́run parí dídá àwọn ọ̀run àti ayé, àti ohun gbogbo tí ó wà nínú rẹ̀.
Tā ir pabeigtas debesis un zeme un viss viņu spēks.
2 Ní ọjọ́ keje Ọlọ́run sì parí iṣẹ́ rẹ̀ tí ó ti ń ṣe; ó sì sinmi ní ọjọ́ keje kúrò nínú iṣẹ́ rẹ̀ gbogbo tí ó ti ń ṣe.
Un Dievs pabeidza septītā dienā Savu darbu, ko bija darījis, un dusēja septītā dienā no visa Sava darba, ko bija darījis.
3 Ọlọ́run sì súre fún ọjọ́ keje, ó sì yà á sí mímọ́, nítorí pé ní ọjọ́ náà ni ó sinmi kúrò nínú iṣẹ́ dídá ayé tí ó ti ń ṣe.
Un Dievs svētīja to septīto dienu un to iesvētīja, tāpēc ka Viņš bija dusējis no visa Sava darba, ko Dievs bija radījis un taisījis.
4 Èyí ni ìtàn bí Ọlọ́run ṣe dá àwọn ọ̀run àti ayé nígbà tí ó dá wọn. Nígbà tí Olúwa Ọlọ́run dá ayé àti àwọn ọ̀run.
Tā debesis un zeme cēlušās, kad tās tapa radītas tai laikā, kad Dievs Tas Kungs zemi un debesis darīja.
5 Kò sí igi igbó kan ní orí ilẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ewéko igbó kan tí ó tí ì hù jáde ní ilẹ̀, nítorí Olúwa Ọlọ́run kò tí ì rọ̀jò sórí ilẹ̀, kò sì sí ènìyàn láti ro ilẹ̀.
Un vēl nekādu krūmu nebija laukā virs zemes, un vēl nekāda zāle nezēla, jo Dievs Tas Kungs vēl nebija licis lietum līt virs zemes, un cilvēka nebija, kas zemi būtu kopis.
6 Ṣùgbọ́n ìsun omi ń jáde láti ilẹ̀, ó sì ń bu omi rin gbogbo ilẹ̀.
Bet migla cēlās no zemes un slapināja visu zemi.
7 Olúwa Ọlọ́run sì fi erùpẹ̀ ilẹ̀ mọ ènìyàn, ó si mí èémí ìyè sí ihò imú rẹ̀, ènìyàn sì di alààyè ọkàn.
Un Dievs Tas Kungs taisīja cilvēku no zemes pīšļiem un iepūta viņa nāsīs dzīvības dvašu; tad cilvēks tapa par dzīvu dvēseli.
8 Olúwa Ọlọ́run sì gbin ọgbà kan sí Edeni ní ìhà ìlà-oòrùn, níbẹ̀ ni ó fi ọkùnrin náà tí ó ti dá sí.
Un Dievs Tas Kungs stādīja dārzu Ēdenē pret rītiem un iecēla tur to cilvēku, ko Viņš bija taisījis.
9 Olúwa Ọlọ́run sì mú kí onírúurú igi hù jáde láti inú ilẹ̀, àwọn igi tí ó dùn ún wò lójú, tí ó sì dára fún oúnjẹ. Ní àárín ọgbà náà ni igi ìyè àti igi tí ń mú ènìyàn mọ rere àti búburú wà.
Un Dievs Tas Kungs izaudzināja no zemes visādus kokus, kas jauki bija uzlūkot un labi ēst, un dzīvības koku dārza vidū, arī laba un ļauna atzīšanas koku.
10 Odò kan sì ń ti Edeni sàn wá láti bu omi rin ọgbà náà, láti ibẹ̀ ni odò náà gbé ya sí ipa mẹ́rin.
Un tekošs ūdens iztecēja no Ēdenes, to dārzu slapināt, un no turienes tas dalījās un palika par četrām upēm.
11 Orúkọ èkínní ni Pisoni, òun ni ó sàn yí gbogbo ilẹ̀ Hafila ká, níbi tí wúrà gbé wà.
Pirmai ir vārds Pīšone: tā iet ap visu Havilas zemi, kur zelts ir.
12 (Wúrà ilẹ̀ náà dára, òjìá àti òkúta óníkìsì oníyebíye wà níbẹ̀ pẹ̀lú).
Un tās zemes zelts ir labs; tur ir arī bedellions un sardonika(oniksa) akmens.
13 Orúkọ odò kejì ni Gihoni, òun ni ó sàn yí gbogbo ilẹ̀ Kuṣi ká.
Un otrai upei ir vārds Ģihone; tā tek ap visu Kuša(Moru) zemi.
14 Orúkọ odò kẹta ni Tigirisi, òun ni ó sàn ní apá ìlà-oòrùn ilẹ̀ Asiria. Odò kẹrin ni Eufurate.
Un trešai upei ir vārds Hideķele; tā tek Assura zemei pret rītiem, un ceturtā upe ir Eifrate.
15 Olúwa Ọlọ́run mú ọkùnrin náà sínú ọgbà Edeni láti máa ṣe iṣẹ́ níbẹ̀, kí ó sì máa ṣe ìtọ́jú rẹ̀.
Un Dievs Tas Kungs ņēma cilvēku un to ielika Ēdenes dārzā, lai tas to koptu un sargātu.
16 Olúwa Ọlọ́run sì pàṣẹ fún ọkùnrin náà pé, “Ìwọ lè jẹ lára èyíkéyìí èso àwọn igi inú ọgbà;
Un Dievs Tas Kungs pavēlēja cilvēkam sacīdams: no visiem dārza augļiem tu vari ēst, kā tīk,
17 ṣùgbọ́n ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ nínú èso igi ìmọ̀ rere àti èso igi ìmọ̀ búburú, nítorí ní ọjọ́ tí ìwọ bá jẹ ẹ́ ni ìwọ yóò kùú.”
Bet no tā laba un ļauna atzīšanas koka, no tā tev nebūs ēst, jo kurā dienā tu no tā ēdīsi, tu mirdams mirsi.
18 Olúwa Ọlọ́run wí pé, “Kò dára kí ọkùnrin wà ní òun nìkan. Èmi yóò ṣe olùrànlọ́wọ́ tí ó rí bí i rẹ̀ fún un.”
Un Dievs Tas Kungs sacīja: nav labi, cilvēkam būt vienam; Es tam darīšu palīgu, kas ap to būs.
19 Lẹ́yìn tí Olúwa Ọlọ́run ti dá àwọn ẹranko inú igbó àti gbogbo ẹyẹ ojú ọ̀run láti inú erùpẹ̀ ilẹ̀. Ó sì kó wọn tọ ọkùnrin náà wá láti wo orúkọ tí yóò sọ wọ́n; orúkọ tí ó sì sọ gbogbo ẹ̀dá alààyè náà ni wọ́n ń jẹ́.
Un Dievs Tas Kungs no zemes bija taisījis visus zvērus laukā un visus putnus apakš debess; un Viņš tos veda pie cilvēka, lai redzētu, kā tas tos nosauks, un kā cilvēks nosauktu ikvienu dzīvu dvašu, tā lai būtu viņas vārds.
20 Gbogbo ohun ọ̀sìn, ẹyẹ ojú ọ̀run àti gbogbo ẹranko igbó ni ọkùnrin náà sọ ní orúkọ. Ṣùgbọ́n fún Adamu ni a kò rí olùrànlọ́wọ́ tí ó rí bí i rẹ̀.
Tad cilvēks nosauca vārdus visiem lopiem un putniem apakš debess un visiem zvēriem laukā, bet priekš cilvēka neatradās palīgs, kas ap to būtu.
21 Nígbà náà ni Olúwa Ọlọ́run mú kí ọkùnrin náà sùn fọnfọn; nígbà tí ó sì ń sùn, Ọlọ́run yọ egungun ìhà rẹ̀ kan, ó sì fi ẹran-ara bò ó padà.
Tad Dievs Tas Kungs cilvēkam sūtīja cietu miegu, un tas aizmiga. Un Viņš ņēma vienu no viņa sānkauliem un aizpildīja to vietu ar miesu.
22 Olúwa Ọlọ́run sì dá obìnrin láti inú egungun tí ó yọ ní ìhà ọkùnrin náà, Ó sì mu obìnrin náà tọ̀ ọ́ wá.
Un Dievs Tas Kungs iztaisīja to sānkaulu, ko no cilvēka bija ņēmis, par sievu un pieveda to pie cilvēka.
23 Ọkùnrin náà sì wí pé, “Èyí ni egungun láti inú egungun mi àti ẹran-ara nínú ẹran-ara mi; ‘obìnrin’ ni a ó máa pè é, nítorí a mú un jáde láti ara ọkùnrin.”
Un cilvēks sacīja: šī nu ir kauls no maniem kauliem un miesa no manas miesas, tā taps saukta sieva(vīrene), tāpēc ka tā no vīra ir ņemta.
24 Nítorí ìdí èyí, ọkùnrin yóò fi baba àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀, yóò sì dàpọ̀ mọ́ aya rẹ̀, wọn yóò sì di ara kan.
Tādēļ vīrs atstās savu tēvu un savu māti un pieķersies pie savas sievas, un tie būs viena miesa.
25 Ọkùnrin náà àti aya rẹ̀ sì wà ní ìhòhò, ojú kò sì tì wọ́n.
Un tie abi bija pliki, cilvēks un viņa sieva, un nekaunējās.

< Genesis 2 >