< Genesis 15 >

1 Lẹ́yìn èyí, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Abramu wá lójú ìran pé, “Abramu má ṣe bẹ̀rù. Èmi ni ààbò rẹ, Èmi sì ni èrè ńlá rẹ.”
After these things the LORD’s word came to Abram in a vision, saying, “Don’t be afraid, Abram. I am your shield, your exceedingly great reward.”
2 Ṣùgbọ́n Abramu wí pé, “Olúwa Olódùmarè, kí ni ìwọ yóò fi fún mi níwọ̀n ìgbà tí èmi kò bímọ, Elieseri ará Damasku ni yóò sì jogún mi,”
Abram said, “Lord GOD, what will you give me, since I go childless, and he who will inherit my estate is Eliezer of Damascus?”
3 Abramu sì tún tẹ̀síwájú pé, “Ìwọ kò fún mi ní ọmọ, nítorí náà ẹrú nínú ilé mi sì ni yóò jẹ́ àrólé mi.”
Abram said, “Behold, you have given no children to me: and, behold, one born in my house is my heir.”
4 Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tún tọ̀ ọ́ wá pé, “Ọkùnrin yìí kọ́ ni yóò jẹ́ àrólé rẹ bí kò ṣe ọmọ tí ìwọ bí fúnra rẹ̀ ni yóò jẹ́ àrólé rẹ.”
Behold, the LORD’s word came to him, saying, “This man will not be your heir, but he who will come out of your own body will be your heir.”
5 Olúwa sì mú Abramu jáde sí ìta ó sì wí fún un pé, “Gbé ojú sókè sí ọ̀run kí o sì ka àwọn ìràwọ̀ bí ó bá ṣe pé ìwọ le è kà wọ́n.” Ó sì wí fun un pé, “Nítorí náà, báyìí ni irú-ọmọ rẹ yóò rí.”
The LORD brought him outside, and said, “Look now toward the sky, and count the stars, if you are able to count them.” He said to Abram, “So your offspring will be.”
6 Abramu gba Olúwa gbọ́, a sì kà á sí òdodo fún un.
He believed in the LORD, who credited it to him for righteousness.
7 Ó sì tún wí fún un pé, “Èmi ni Olúwa tí ó mú ọ jáde láti Uri ti Kaldea láti fún ọ ní ilẹ̀ yìí láti jogún.”
He said to Abram, “I am the LORD who brought you out of Ur-Kasdim, to give you this land to inherit it.”
8 Ṣùgbọ́n Abramu wí pé, “Olúwa Olódùmarè, báwo ni mo ṣe lè mọ̀ pé ilẹ̀ náà yóò jẹ́ ohun ìní mi?”
He said, “Lord GOD, how will I know that I will inherit it?”
9 Nítorí náà, Olúwa wí fún un pé, “Mú abo màlúù, ewúrẹ́ àti àgbò ọlọ́dún mẹ́ta mẹ́ta wá, àti àdàbà kan àti ọmọ ẹyẹlé kan.”
He said to him, “Bring me a heifer three years old, a female goat three years old, a ram three years old, a turtledove, and a young pigeon.”
10 Abramu sì mú gbogbo nǹkan wọ̀nyí wá, ó sì là wọ́n sí méjì méjì, ó sì fi ẹ̀là èkínní kọjú sí èkejì, ṣùgbọ́n kò la àwọn ẹyẹ ní tiwọn.
He brought him all these, and divided them in the middle, and laid each half opposite the other; but he didn’t divide the birds.
11 Àwọn ẹyẹ igún sì ń wá sórí òkú ẹran náà, Abramu sì ń lé wọn.
The birds of prey came down on the carcasses, and Abram drove them away.
12 Bí oòrùn ti ń wọ̀, Abramu sùn lọ fọnfọn, òkùnkùn biribiri tí ó kún fún ẹ̀rù sì bò ó.
When the sun was going down, a deep sleep fell on Abram. Now terror and great darkness fell on him.
13 Nígbà náà ni Olúwa wí fún Abramu pé, “Mọ èyí dájú pé, irú-ọmọ rẹ yóò ṣe àtìpó ní ilẹ̀ àjèjì, wọn ó sì sọ wọn di ẹrú, wọn ó sì pọ́n wọn lójú fún irinwó ọdún.
He said to Abram, “Know for sure that your offspring will live as foreigners in a land that is not theirs, and will serve them. They will afflict them four hundred years.
14 Ṣùgbọ́n orílẹ̀-èdè náà tí wọn yóò máa sìn, ni èmi ó dá lẹ́jọ́, lẹ́yìn náà ni wọn ó sì jáde pẹ̀lú ọrọ̀ púpọ̀.
I will also judge that nation, whom they will serve. Afterward they will come out with great wealth;
15 Ṣùgbọ́n ìwọ yóò tọ àwọn baba rẹ lọ ni àlàáfíà, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ yóò sì di arúgbó kí a tó gbé ọ sin.
but you will go to your fathers in peace. You will be buried at a good old age.
16 Ní ìran kẹrin àwọn ìran rẹ yóò padà wá sí ibi. Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ará Amori kò ì tí ì kún òsùwọ̀n.”
In the fourth generation they will come here again, for the iniquity of the Amorite is not yet full.”
17 Nígbà tí oòrùn wọ̀ tí ilẹ̀ sì ṣú, ìkòkò iná tí ń ṣèéfín àti ọwọ́ iná sì ń kọjá láàrín ẹ̀là ẹran náà.
It came to pass that, when the sun went down, and it was dark, behold, a smoking furnace and a flaming torch passed between these pieces.
18 Ní ọjọ́ náà gan an ni Olúwa dá májẹ̀mú pẹ̀lú Abramu, ó sì wí pé, “Àwọn ìran rẹ ni èmi yóò fi ilẹ̀ yìí fún, láti odò Ejibiti dé odò ńlá Eufurate:
In that day the LORD made a covenant with Abram, saying, “I have given this land to your offspring, from the river of Egypt to the great river, the river Euphrates:
19 ilẹ̀ àwọn ará Keni, àti ti ará Kenissiti, àti ará Kadmoni,
the land of the Kenites, the Kenizzites, the Kadmonites,
20 àti ti ará Hiti, àti ti ará Peresi, àti ti ará Refaimu.
the Hittites, the Perizzites, the Rephaim,
21 Àti ti ará Amori, àti ti ará Kenaani, àti ti ará Girgaṣi àti ti ará Jebusi.”
the Amorites, the Canaanites, the Girgashites, and the Jebusites.”

< Genesis 15 >