< Genesis 13 >
1 Abramu sì gòkè láti Ejibiti lọ sí ìhà gúúsù, pẹ̀lú aya rẹ̀ àti ohun gbogbo tí ó ní àti Lọti pẹ̀lú.
Abram subió de Egipto — él, su mujer, todo lo que tenía, y Lot con él — al Sur.
2 Abramu sì ti di ọlọ́rọ̀ gidigidi; ní ẹran ọ̀sìn, ó ní fàdákà àti wúrà.
Abram era muy rico en ganado, en plata y en oro.
3 Láti gúúsù, ó ń lọ láti ibìkan sí ibòmíràn títí ó fi dé ilẹ̀ Beteli, ní ibi tí àgọ́ rẹ̀ ti wà ní ìṣáájú rí, lágbedeméjì Beteli àti Ai.
Siguió su camino desde el sur hasta Betel, hasta el lugar donde había estado su tienda al principio, entre Betel y Hai,
4 Ní ibi pẹpẹ tí ó ti tẹ́ síbẹ̀ ní ìṣáájú, níbẹ̀ ni Abramu sì ń ké pe orúkọ Olúwa.
hasta el lugar del altar que había hecho allí al principio. Allí Abram invocó el nombre de Yahvé.
5 Àti Lọti pẹ̀lú, tí ó ń bá Abramu rìn kiri, ní agbo ẹran, ọ̀wọ́ ẹran àti àgọ́.
También Lot, que iba con Abram, tenía rebaños, vacas y tiendas.
6 Ṣùgbọ́n ilẹ̀ náà kò le gbà wọ́n tí wọ́n bá ń gbé pọ̀, nítorí, ohun ìní wọn pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́, dé bi wí pé wọn kò le è gbé pọ̀.
La tierra no podía sostenerlos para que vivieran juntos, pues sus posesiones eran tan grandes que no podían vivir juntos.
7 Èdè-àìyedè sì bẹ̀rẹ̀ láàrín àwọn darandaran Abramu àti ti Lọti. Àwọn ará Kenaani àti àwọn ará Peresi sì ń gbé ní ilẹ̀ náà nígbà náà.
Hubo disputas entre los pastores del ganado de Abram y los pastores del ganado de Lot. Los cananeos y los ferezeos vivían entonces en la tierra.
8 Abramu sì wí fún Lọti pé, “Èmi bẹ̀ ọ́, má ṣe jẹ́ kí èdè-àìyedè kí ó wà láàrín èmi àti ìrẹ, àti láàrín àwọn darandaran wa, nítorí pé ẹbí kan ni àwa ṣe.
Abram le dijo a Lot: “Por favor, que no haya disputas entre tú y yo, y entre tus pastores y los míos, porque somos parientes.
9 Gbogbo ilẹ̀ ha kọ́ nìyí níwájú rẹ? Jẹ́ kí a pínyà. Bí ìwọ bá lọ sí apá ọ̀tún, èmi yóò lọ sí apá òsì, bí ó sì ṣe òsì ni ìwọ lọ, èmi yóò lọ sí apá ọ̀tún.”
¿No está toda la tierra ante ti? Por favor, sepárense de mí. Si te vas a la izquierda, yo me iré a la derecha. O si te vas a la derecha, entonces yo me iré a la izquierda”.
10 Lọti sì gbójú sókè, ó sì ri wí pé gbogbo pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jordani ni omi rin dáradára bí ọgbà Olúwa, bí ilẹ̀ Ejibiti, ní ọ̀nà Soari. (Èyí ní ìṣáájú kí Olúwa tó pa Sodomu àti Gomorra run.)
Lot alzó los ojos y vio toda la llanura del Jordán, que estaba bien regada por todas partes, antes de que Yahvé destruyera a Sodoma y Gomorra, como el jardín de Yahvé, como la tierra de Egipto, al ir a Zoar.
11 Nítorí náà Lọti yan gbogbo pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jordani yìí fún ara rẹ̀, ó sì ń lọ sí ọ̀nà ìlà-oòrùn. Òun àti Abramu sì pínyà.
Así que Lot eligió para sí la llanura del Jordán. Lot viajó hacia el este, y se separaron el uno del otro.
12 Abramu ń gbé ni ilẹ̀ Kenaani, Lọti sì jókòó ní ìlú agbègbè àfonífojì náà, ó sì pàgọ́ rẹ̀ títí dé Sodomu.
Abram vivió en la tierra de Canaán, y Lot vivió en las ciudades de la llanura, y trasladó su tienda hasta Sodoma.
13 Ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin Sodomu jẹ́ ènìyàn búburú, wọn sì ń dẹ́ṣẹ̀ gidigidi ni iwájú Olúwa.
Los hombres de Sodoma eran sumamente malvados y pecadores contra el Señor.
14 Olúwa sì wí fún Abramu lẹ́yìn ìpinyà òun àti Lọti pé, “Gbé ojú rẹ sókè nísinsin yìí, kí o sì wò láti ibi tí o gbé wà a nì lọ sí ìhà àríwá àti sí ìhà gúúsù, sí ìlà-oòrùn àti sí ìwọ̀ rẹ̀.
Yahvé dijo a Abram, después de que Lot se separó de él: “Ahora, levanta tus ojos y mira desde el lugar donde estás, hacia el norte y el sur y hacia el este y el oeste,
15 Gbogbo ilẹ̀ tí ìwọ ń wò o nì ni èmi ó fi fún ọ àti irú-ọmọ rẹ láéláé.
porque daré toda la tierra que ves a ti y a tu descendencia para siempre.
16 Èmi yóò mú kí irú-ọmọ rẹ kí ó pọ̀ bí erùpẹ̀ ilẹ̀, tó bẹ́ẹ̀ tí ó bá ṣe pé ẹnikẹ́ni bá le è ka erùpẹ̀ ilẹ̀, nígbà náà ni yóò tó lè ka irú-ọmọ rẹ.
Haré que tu descendencia sea como el polvo de la tierra, de modo que si un hombre puede contar el polvo de la tierra, también tu descendencia podrá ser contada.
17 Dìde, rìn òró àti ìbú ilẹ̀ náà já, nítorí ìwọ ni Èmi yóò fi fún.”
Levántate, recorre la tierra a lo largo y a lo ancho, porque yo te la daré”.
18 Nígbà náà ni Abramu kó àgọ́ rẹ̀, ó sì wá, ó sì jókòó ní ẹ̀gbẹ́ igi ńlá igbó Mamre, tí ó wà ní Hebroni. Níbẹ̀ ni ó gbé tẹ́ pẹpẹ kan sí fún Olúwa.
Abram trasladó su tienda y vino a vivir junto a las encinas de Mamre, que están en Hebrón, y construyó allí un altar a Yahvé.