< Genesis 11 >

1 Lẹ́yìn náà, gbogbo àgbáyé sì ń sọ èdè kan ṣoṣo.
那时,天下人的口音、言语都是一样。
2 Bí àwọn ènìyàn ṣe ń tẹ̀síwájú lọ sí ìhà ìlà-oòrùn, wọ́n rí pẹ̀tẹ́lẹ̀ kan ní ilẹ̀ Ṣinari, wọ́n sì tẹ̀dó síbẹ̀.
他们往东边迁移的时候,在示拿地遇见一片平原,就住在那里。
3 Wọ́n sì wí fún ara wọn pé, “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a mọ bíríkì kí a sì sún wọ́n jìnà.” Bíríkì ni wọ́n ń lò ní ipò òkúta, àti ọ̀dà ilẹ̀ tí wọn ń lò láti mú wọn papọ̀ dípò ẹfun (òkúta láìmù tí wọ́n fi ń ṣe símẹ́ńtì àti omi).
他们彼此商量说:“来吧!我们要做砖,把砖烧透了。”他们就拿砖当石头,又拿石漆当灰泥。
4 Nígbà náà ni wọ́n wí pé, “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a tẹ ìlú kan dó fún ara wa, kí a sì kọ́ ilé ìṣọ́ kan tí yóò kan ọ̀run, kí a ba à lè ní orúkọ, kí a má sì tú káàkiri sórí gbogbo ilẹ̀ ayé.”
他们说:“来吧!我们要建造一座城和一座塔,塔顶通天,为要传扬我们的名,免得我们分散在全地上。”
5 Ṣùgbọ́n, Olúwa sọ̀kalẹ̀ láti wo ìlú àti ilé ìṣọ́ tí àwọn ènìyàn náà ń kọ́.
耶和华降临,要看看世人所建造的城和塔。
6 Olúwa wí pé, “Bí àwọn ènìyàn bá ń jẹ́ ọ̀kan àti èdè kan tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe iṣẹ́ yìí, kò sí ohun tí wọ́n gbèrò tí wọn kò ní le ṣe yọrí.
耶和华说:“看哪,他们成为一样的人民,都是一样的言语,如今既做起这事来,以后他们所要做的事就没有不成就的了。
7 Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a sọ̀kalẹ̀ lọ, kí a da èdè wọn rú kí èdè wọn má ba à yé ara wọn mọ́.”
我们下去,在那里变乱他们的口音,使他们的言语彼此不通。”
8 Olúwa sì tú wọn ká sórí ilẹ̀ gbogbo, wọ́n sì ṣíwọ́ ìlú náà tí wọn ń tẹ̀dó.
于是耶和华使他们从那里分散在全地上;他们就停工,不造那城了。
9 Ìdí èyí ni a fi pè é ní Babeli nítorí ní ibẹ̀ ni Olúwa ti da èdè gbogbo ayé rú. Olúwa tí sì tú àwọn ènìyàn ká sí gbogbo orí ilẹ̀ ayé.
因为耶和华在那里变乱天下人的言语,使众人分散在全地上,所以那城名叫巴别。
10 Wọ̀nyí ni ìran Ṣemu. Ọdún méjì lẹ́yìn ìkún omi, tí Ṣemu pé ọgọ́rùn-ún ọdún ni ó bí Arfakṣadi.
闪的后代记在下面。洪水以后二年,闪一百岁生了亚法撒。
11 Lẹ́yìn tí ó bí Arfakṣadi, Ṣemu tún wà láààyè fún ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ọdún, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn.
闪生亚法撒之后又活了五百年,并且生儿养女。
12 Nígbà tí Arfakṣadi pé ọdún márùndínlógójì ni ó bí Ṣela.
亚法撒活到三十五岁,生了沙拉。
13 Arfakṣadi sì wà láààyè fún ọdún mẹ́tàlénírinwó lẹ́yìn tí ó bí Ṣela, ó sì bí àwọn ọmọbìnrin àti àwọn ọmọkùnrin mìíràn.
亚法撒生沙拉之后又活了四百零三年,并且生儿养女。
14 Nígbà tí Ṣela pé ọmọ ọgbọ̀n ọdún ni ó bí Eberi.
沙拉活到三十岁,生了希伯。
15 Ṣela sì wà láààyè fún ọdún mẹ́tàlénírinwó lẹ́yìn tí ó bí Eberi tán, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn.
沙拉生希伯之后又活了四百零三年,并且生儿养女。
16 Eberi sì jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n, ó sì bí Pelegi.
希伯活到三十四岁,生了法勒。
17 Eberi sì wà láààyè fún irinwó ọdún ó lé ọgbọ̀n lẹ́yìn tí ó bí Pelegi, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn.
希伯生法勒之后又活了四百三十年,并且生儿养女。
18 Nígbà tí Pelegi pé ọmọ ọgbọ̀n ọdún ni ó bí Reu.
法勒活到三十岁,生了拉吴。
19 Pelegi sì tún wà láààyè fún igba ọdún ó lé mẹ́sàn-án lẹ́yìn tí ó bí Reu, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn.
法勒生拉吴之后又活了二百零九年,并且生儿养女。
20 Nígbà tí Reu pé ọdún méjìlélọ́gbọ̀n ni ó bí Serugu.
拉吴活到三十二岁,生了西鹿。
21 Reu tún wà láààyè lẹ́yìn tí ó bí Serugu fún igba ọdún ó lé méje, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin mìíràn.
拉吴生西鹿之后又活了二百零七年,并且生儿养女。
22 Nígbà tí Serugu pé ọmọ ọgbọ̀n ọdún ni ó bí Nahori.
西鹿活到三十岁,生了拿鹤。
23 Serugu sì wà láààyè fún igba ọdún lẹ́yìn tí ó bí Nahori, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn.
西鹿生拿鹤之后又活了二百年,并且生儿养女。
24 Nígbà tí Nahori pé ọmọ ọdún mọ́kàndínlọ́gbọ̀n, ó bí Tẹra.
拿鹤活到二十九岁,生了他拉。
25 Nahori sì wà láààyè fún ọdún mọ́kàn dín lọ́gọ́fà lẹ́yìn ìbí Tẹra, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn.
拿鹤生他拉之后又活了一百一十九年,并且生儿养女。
26 Lẹ́yìn tí Tẹra pé ọmọ àádọ́rin ọdún ó bí Abramu, Nahori àti Harani.
他拉活到七十岁,生了亚伯兰、拿鹤、哈兰。
27 Wọ̀nyí ni ìran Tẹra. Tẹra ni baba Abramu, Nahori àti Harani. Harani sì bí Lọti.
他拉的后代记在下面。他拉生亚伯兰、拿鹤、哈兰;哈兰生罗得。
28 Harani sì kú ṣáájú Tẹra baba rẹ̀ ní ilẹ̀ ìbí rẹ̀ ní Uri ti ilẹ̀ Kaldea.
哈兰死在他的本地迦勒底的吾珥,在他父亲他拉之先。
29 Abramu àti Nahori sì gbéyàwó. Orúkọ aya Abramu ni Sarai, nígbà tí aya Nahori ń jẹ́ Milka, tí ṣe ọmọ Harani. Harani ni ó bí Milka àti Iska.
亚伯兰、拿鹤各娶了妻:亚伯兰的妻子名叫撒莱;拿鹤的妻子名叫密迦,是哈兰的女儿;哈兰是密迦和亦迦的父亲。
30 Sarai sì yàgàn, kò sì bímọ.
撒莱不生育,没有孩子。
31 Tẹra sì mú ọmọ rẹ̀ Abramu àti Lọti ọmọ Harani, ọmọ ọmọ rẹ̀, ó sì mú Sarai tí i ṣe aya ọmọ rẹ̀. Abramu pẹ̀lú gbogbo wọn sì jáde kúrò ní Uri ti Kaldea láti lọ sí ilẹ̀ Kenaani. Ṣùgbọ́n nígbà tí wọn dé Harani wọ́n tẹ̀dó síbẹ̀.
他拉带着他儿子亚伯兰和他孙子哈兰的儿子罗得,并他儿妇亚伯兰的妻子撒莱,出了迦勒底的吾珥,要往迦南地去;他们走到哈兰,就住在那里。
32 Nígbà tí Tẹra pé ọmọ igba ọdún ó lé márùn-ún ni ó kú ní Harani.
他拉共活了二百零五岁,就死在哈兰。

< Genesis 11 >