1Èyí ni ìran àwọn ọmọ Noa: Ṣemu, Hamu àti Jafeti, tí àwọn náà sì bí ọmọ lẹ́yìn ìkún omi.
This chapter is missing in the source text.
2Àwọn ọmọ Jafeti ni: Gomeri, Magogu, Madai, Jafani, Tubali, Meṣeki àti Tirasi.
3Àwọn ọmọ Gomeri ni: Aṣkenasi, Rifati àti Togarma.
4Àwọn ọmọ Jafani ni: Eliṣa, Tarṣiṣi, Kittimu, àti Dodanimu.
5(Láti ọ̀dọ̀ àwọn wọ̀nyí ni àwọn tí ń gbé agbègbè tí omi wà ti tàn ká agbègbè wọn, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yà wọn, ìdílé wọn ní orílẹ̀-èdè wọn, olúkúlùkù pẹ̀lú èdè tirẹ̀).
6Àwọn ọmọ Hamu ni: Kuṣi, Ejibiti, Puti àti Kenaani.
7Àwọn ọmọ Kuṣi ni: Seba, Hafila, Sabta, Raama, àti Sabteka. Àwọn ọmọ Raama ni: Ṣeba àti Dedani.
8Kuṣi sì bí Nimrodu, ẹni tí ó di alágbára jagunjagun ní ayé.
9Ó sì jẹ́ ògbójú ọdẹ níwájú Olúwa; nítorí náà ni a ṣe ń wí pé, “Bí Nimrodu, ògbójú ọdẹ níwájú Olúwa.”
10Ìjọba rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ni Babeli, Ereki, Akkadi, Kalne, gbogbo wọn wà ní ilẹ̀ Ṣinari.
11Láti ilẹ̀ náà ni ó ti lọ sí Asiria, níbi tí ó ti tẹ ìlú Ninefe, Rehoboti àti Kala,
12àti Resini, tí ó wà ní àárín Ninefe àti Kala, tí ó jẹ́ ìlú olókìkí.
13Ejibiti sì bí Ludimu, Anamimu, Lehabimu, Naftuhimu.
14Patrusimu, Kasluhimu (láti ọ̀dọ̀ ẹni tí àwọn ará Filistini ti wá) àti àwọn ará Kaftorimu.