< Genesis 10 >

1 Èyí ni ìran àwọn ọmọ Noa: Ṣemu, Hamu àti Jafeti, tí àwọn náà sì bí ọmọ lẹ́yìn ìkún omi.
This is the account of Noah’s sons Shem, Ham, and Japheth, who also had sons after the flood.
2 Àwọn ọmọ Jafeti ni: Gomeri, Magogu, Madai, Jafani, Tubali, Meṣeki àti Tirasi.
The sons of Japheth: Gomer, Magog, Madai, Javan, Tubal, Meshech, and Tiras.
3 Àwọn ọmọ Gomeri ni: Aṣkenasi, Rifati àti Togarma.
The sons of Gomer: Ashkenaz, Riphath, and Togarmah.
4 Àwọn ọmọ Jafani ni: Eliṣa, Tarṣiṣi, Kittimu, àti Dodanimu.
And the sons of Javan: Elishah, Tarshish, the Kittites, and the Rodanites.
5 (Láti ọ̀dọ̀ àwọn wọ̀nyí ni àwọn tí ń gbé agbègbè tí omi wà ti tàn ká agbègbè wọn, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yà wọn, ìdílé wọn ní orílẹ̀-èdè wọn, olúkúlùkù pẹ̀lú èdè tirẹ̀).
From these, the maritime peoples separated into their territories, according to their languages, by clans within their nations.
6 Àwọn ọmọ Hamu ni: Kuṣi, Ejibiti, Puti àti Kenaani.
The sons of Ham: Cush, Mizraim, Put, and Canaan.
7 Àwọn ọmọ Kuṣi ni: Seba, Hafila, Sabta, Raama, àti Sabteka. Àwọn ọmọ Raama ni: Ṣeba àti Dedani.
The sons of Cush: Seba, Havilah, Sabtah, Raamah, and Sabteca. And the sons of Raamah: Sheba and Dedan.
8 Kuṣi sì bí Nimrodu, ẹni tí ó di alágbára jagunjagun ní ayé.
Cush was the father of Nimrod, who began to be a mighty one on the earth.
9 Ó sì jẹ́ ògbójú ọdẹ níwájú Olúwa; nítorí náà ni a ṣe ń wí pé, “Bí Nimrodu, ògbójú ọdẹ níwájú Olúwa.”
He was a mighty hunter before the LORD; so it is said, “Like Nimrod, a mighty hunter before the LORD.”
10 Ìjọba rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ni Babeli, Ereki, Akkadi, Kalne, gbogbo wọn wà ní ilẹ̀ Ṣinari.
His kingdom began in Babylon, Erech, Accad, and Calneh, in the land of Shinar.
11 Láti ilẹ̀ náà ni ó ti lọ sí Asiria, níbi tí ó ti tẹ ìlú Ninefe, Rehoboti àti Kala,
From that land he went forth into Assyria, where he built Nineveh, Rehoboth-Ir, Calah,
12 àti Resini, tí ó wà ní àárín Ninefe àti Kala, tí ó jẹ́ ìlú olókìkí.
and Resen, which is between Nineveh and the great city of Calah.
13 Ejibiti sì bí Ludimu, Anamimu, Lehabimu, Naftuhimu.
Mizraim was the father of the Ludites, the Anamites, the Lehabites, the Naphtuhites,
14 Patrusimu, Kasluhimu (láti ọ̀dọ̀ ẹni tí àwọn ará Filistini ti wá) àti àwọn ará Kaftorimu.
the Pathrusites, the Casluhites (from whom the Philistines came), and the Caphtorites.
15 Kenaani sì bí Sidoni àkọ́bí rẹ̀, àti Heti.
And Canaan was the father of Sidon his firstborn, and of the Hittites,
16 Àti àwọn ará Jebusi, àti àwọn ará Amori, àti àwọn ará Girgaṣi,
the Jebusites, the Amorites, the Girgashites,
17 àti àwọn ará Hifi, àti àwọn ará Arki, àti àwọn ará Sini,
the Hivites, the Arkites, the Sinites,
18 àti àwọn ará Arfadi, àti àwọn ará Semari, àti àwọn ará Hamati. Lẹ́yìn èyí ni àwọn ẹ̀yà Kenaani tànkálẹ̀.
the Arvadites, the Zemarites, and the Hamathites. Later the Canaanite clans were scattered,
19 Ààlà ilẹ̀ àwọn ará Kenaani sì dé Sidoni, lọ sí Gerari títí dé Gasa, lọ sí Sodomu, Gomorra, Adma àti Seboimu, títí dé Laṣa.
and the borders of Canaan extended from Sidon toward Gerar as far as Gaza, and then toward Sodom, Gomorrah, Admah, and Zeboiim, as far as Lasha.
20 Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Hamu, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yà wọn, àti èdè wọn, ní ìpínlẹ̀ wọn àti ní orílẹ̀-èdè wọn.
These are the sons of Ham according to their clans, languages, lands, and nations.
21 A bí àwọn ọmọ fún Ṣemu tí Jafeti jẹ́ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ọkùnrin: Ṣemu sì ni baba gbogbo àwọn ọmọ Eberi.
And sons were also born to Shem, the older brother of Japheth; Shem was the forefather of all the sons of Eber.
22 Àwọn ọmọ Ṣemu ni: Elamu, Aṣuri, Arfakṣadi, Ludi àti Aramu.
The sons of Shem: Elam, Asshur, Arphaxad, Lud, and Aram.
23 Àwọn ọmọ Aramu ni: Usi, Huli, Geteri àti Meṣeki.
The sons of Aram: Uz, Hul, Gether, and Mash.
24 Arfakṣadi sì bí Ṣela, Ṣela sì bí Eberi.
Arphaxad was the father of Shelah, and Shelah was the father of Eber.
25 Eberi sì bí ọmọ méjì: ọ̀kan ń jẹ́ Pelegi, nítorí ní ìgbà ọjọ́ rẹ̀ ni ilẹ̀ ya; orúkọ arákùnrin rẹ̀ ni Joktani.
Two sons were born to Eber: One was named Peleg, because in his days the earth was divided, and his brother was named Joktan.
26 Joktani sì bí Almodadi, Ṣelefi, Hasarmafeti, Jera.
And Joktan was the father of Almodad, Sheleph, Hazarmaveth, Jerah,
27 Hadoramu, Usali, Dikla,
Hadoram, Uzal, Diklah,
28 Obali, Abimaeli, Ṣeba.
Obal, Abimael, Sheba,
29 Ofiri, Hafila àti Jobabu. Gbogbo àwọn wọ̀nyí ni ọmọ Joktani.
Ophir, Havilah, and Jobab. All these were sons of Joktan.
30 Agbègbè ibi tí wọn ń gbé bẹ̀rẹ̀ láti Meṣa títí dé Sefari, ní àwọn ilẹ̀ tó kún fún òkè ní ìlà-oòrùn.
Their territory extended from Mesha to Sephar, in the eastern hill country.
31 Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ẹ̀yà ọmọ Ṣemu gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn, ní èdè wọn, ní ilẹ̀ wọn àti ní orílẹ̀-èdè wọn.
These are the sons of Shem, according to their clans, languages, lands, and nations.
32 Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ẹ̀yà ọmọ Noa gẹ́gẹ́ bí ìran wọn, ní orílẹ̀-èdè wọn. Ní ipasẹ̀ wọn ni àwọn ènìyàn ti tàn ká ilẹ̀ ayé lẹ́yìn ìkún omi.
All these are the clans of Noah’s sons, according to their generations and nations. From these the nations of the earth spread out after the flood.

< Genesis 10 >