< Galatians 1 >
1 Paulu, aposteli tí a rán kì í ṣe láti ọ̀dọ̀ ènìyàn wá, tàbí nípa ènìyàn, ṣùgbọ́n nípa Jesu Kristi àti Ọlọ́run Baba, ẹni tí ó jí i dìde kúrò nínú òkú.
Παῦλος, ἀπόστολος οὐκ ἀπ᾽ ἀνθρώπων, οὐδὲ δι᾽ ἀνθρώπου, ἀλλὰ διὰ Ἰησοῦ Χριστοῦ καὶ Θεοῦ πατρὸς τοῦ ἐγείραντος αὐτὸν ἐκ νεκρῶν,
2 Àti gbogbo àwọn arákùnrin tí ó wà pẹ̀lú mi, Sí àwọn ìjọ ní Galatia:
καὶ οἱ σὺν ἐμοὶ πάντες ἀδελφοί, ταῖς ἐκκλησίαις τῆς Γαλατίας·
3 Oore-ọ̀fẹ́ sí yín àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wá àti Jesu Kristi Olúwa,
χάρις ὑμῖν καὶ εἰρήνη ἀπὸ Θεοῦ πατρὸς καὶ Κυρίου ἡμῶν Ἰησοῦ Χριστοῦ,
4 ẹni tí ó fi òun tìkára rẹ̀ dípò ẹ̀ṣẹ̀ wa, kí ó lè gbà wá kúrò nínú ayé búburú ìsinsin yìí, gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ Ọlọ́run àti Baba wa, (aiōn )
τοῦ δόντος ἑαυτὸν ὑπὲρ τῶν ἁμαρτιῶν ἡμῶν, ὅπως ἐξέληται ἡμᾶς ἐκ τοῦ ἐνεστῶτος αἰῶνος πονηροῦ κατὰ τὸ θέλημα τοῦ Θεοῦ καὶ πατρὸς ἡμῶν, (aiōn )
5 ẹni tí ògo wà fún láé àti láéláé. Àmín. (aiōn )
ᾧ ἡ δόξα εἰς τοὺς αἰῶνας τῶν αἰώνων· ἀμήν. (aiōn )
6 Ó yà mi lẹ́nu pé ẹ tètè yapa kúrò lọ́dọ̀ ẹni tí ó pè yín sínú oore-ọ̀fẹ́ Kristi, sí ìyìnrere mìíràn.
Θαυμάζω ὅτι οὕτω ταχέως μετατίθεσθε ἀπὸ τοῦ καλέσαντος ὑμᾶς ἐν χάριτι Χριστοῦ εἰς ἕτερον εὐαγγέλιον,
7 Nítòótọ́, kò sí ìyìnrere mìíràn bí ó tilẹ̀ ṣe pé àwọn kan wà, tí ń yọ yín lẹ́nu, tí wọ́n sì ń fẹ́ yí ìyìnrere Kristi padà.
ὃ οὐκ ἔστιν ἄλλο, εἰ μή τινές εἰσιν οἱ ταράσσοντες ὑμᾶς καὶ θέλοντες μεταστρέψαι τὸ εὐαγγέλιον τοῦ Χριστοῦ.
8 Ṣùgbọ́n bí ó ṣe àwa ni tàbí angẹli kan láti ọ̀run wá, ni ó bá wàásù ìyìnrere mìíràn fún yín ju èyí tí a tí wàásù rẹ̀ fún yín lọ, jẹ́ kí ó di ẹni ìfibú títí láéláé!
ἀλλὰ καὶ ἐὰν ἡμεῖς ἢ ἄγγελος ἐξ οὐρανοῦ εὐαγγελίζηται ὑμῖν παρ᾽ ὃ εὐηγγελισάμεθα ὑμῖν, ἀνάθεμα ἔστω.
9 Bí àwa ti wí ṣáájú, bẹ́ẹ̀ ni mo sì tún wí nísinsin yìí pé, bí ẹnìkan bá wàásù ìyìnrere mìíràn fún yín ju èyí tí ẹ̀yin tí gbà lọ, jẹ́ kí ó di ẹni ìfibú títí láéláé!
ὡς προειρήκαμεν, καὶ ἄρτι πάλιν λέγω· εἴ τις ὑμᾶς εὐαγγελίζεται παρ᾽ ὃ παρελάβετε, ἀνάθεμα ἔστω.
10 Ǹjẹ́ nísinsin yìí, ènìyàn ni èmi ń wá ojúrere rẹ̀ ní tàbí Ọlọ́run? Tàbí ènìyàn ni èmi ń fẹ́ láti wù bí? Bí èmi bá ń fẹ́ láti wu ènìyàn, èmi kò lè jẹ́ ìránṣẹ́ Kristi.
ἄρτι γὰρ ἀνθρώπους πείθω ἢ τὸν Θεόν; ἢ ζητῶ ἀνθρώποις ἀρέσκειν; εἰ γὰρ ἔτι ἀνθρώποις ἤρεσκον, Χριστοῦ δοῦλος οὐκ ἂν ἤμην.
11 Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀, ará, pé ìyìnrere tí mo tí wàásù kì í ṣe láti ipa ènìyàn.
Γνωρίζω δὲ ὑμῖν, ἀδελφοί, τὸ εὐαγγέλιον τὸ εὐαγγελισθὲν ὑπ᾽ ἐμοῦ ὅτι οὐκ ἔστι κατὰ ἄνθρωπον·
12 N kò gbà á lọ́wọ́ ènìyàn kankan, bẹ́ẹ̀ ni a kò fi kọ́ mi, ṣùgbọ́n mo gbà á nípa ìfihàn láti ọ̀dọ̀ Jesu Kristi.
οὐδὲ γὰρ ἐγὼ παρὰ ἀνθρώπου παρέλαβον αὐτὸ οὔτε ἐδιδάχθην, ἀλλὰ δι᾽ ἀποκαλύψεως Ἰησοῦ Χριστοῦ.
13 Nítorí ẹ̀yin ti gbúròó ìgbé ayé mi nígbà àtijọ́ nínú ìsìn àwọn Júù, bí mo tí ṣe inúnibíni sí ìjọ ènìyàn Ọlọ́run rékọjá ààlà, tí mo sì lépa láti bà á jẹ́.
Ἠκούσατε γὰρ τὴν ἐμὴν ἀναστροφήν ποτε ἐν τῷ Ἰουδαϊσμῷ, ὅτι καθ᾽ ὑπερβολὴν ἐδίωκον τὴν ἐκκλησίαν τοῦ Θεοῦ καὶ ἐπόρθουν αὐτήν,
14 Mo sì ta ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹlẹgbẹ́ mi yọ nínú ìsìn àwọn Júù láàrín àwọn ìran mi, mo sì ni ìtara lọ́pọ̀lọ́pọ̀ sì òfin àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn baba mi.
καὶ προέκοπτον ἐν τῷ Ἰουδαϊσμῷ ὑπὲρ πολλοὺς συνηλικιώτας ἐν τῷ γένει μου, περισσοτέρως ζηλωτὴς ὑπάρχων τῶν πατρικῶν μου παραδόσεων.
15 Ṣùgbọ́n nígbà tí ó wú Ọlọ́run ẹni tí ó yà mí sọ́tọ̀ láti inú ìyá mi wá, tí ó sì pé mi nípa oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀.
Ὅτε δὲ εὐδόκησεν ὁ Θεὸς ὁ ἀφορίσας με ἐκ κοιλίας μητρός μου καὶ καλέσας διὰ τῆς χάριτος αὐτοῦ
16 Láti fi ọmọ rẹ̀ hàn nínú mi, kì èmi lè máa wàásù ìyìnrere rẹ̀ láàrín àwọn aláìkọlà; èmi kò wá ìmọ̀ lọ sọ́dọ̀ ẹnikẹ́ni,
ἀποκαλύψαι τὸν υἱὸν αὐτοῦ ἐν ἐμοί, ἵνα εὐαγγελίζωμαι αὐτὸν ἐν τοῖς ἔθνεσιν, εὐθέως οὐ προσανεθέμην σαρκὶ καὶ αἵματι,
17 bẹ́ẹ̀ ni èmi kò gòkè lọ sì Jerusalẹmu tọ àwọn tí í ṣe aposteli ṣáájú mi, ṣùgbọ́n mo lọ sí Arabia, mo sì tún padà wá sí Damasku.
οὐδὲ ἀνῆλθον εἰς Ἱεροσόλυμα πρὸς τοὺς πρὸ ἐμοῦ ἀποστόλους, ἀλλὰ ἀπῆλθον εἰς Ἀραβίαν, καὶ πάλιν ὑπέστρεψα εἰς Δαμασκόν.
18 Lẹ́yìn ọdún mẹ́ta, nígbà náà ni mo gòkè lọ sì Jerusalẹmu láti lọ kì Peteru, mo sì gbé ọ̀dọ̀ rẹ̀ ní ìjọ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún,
Ἔπειτα μετὰ ἔτη τρία ἀνῆλθον εἰς Ἱεροσόλυμα ἱστορῆσαι Πέτρον, καὶ ἐπέμεινα πρὸς αὐτὸν ἡμέρας δεκαπέντε·
19 èmi kò ri ẹlòmíràn nínú àwọn tí ó jẹ́ aposteli, bí kò ṣe Jakọbu arákùnrin Olúwa.
ἕτερον δὲ τῶν ἀποστόλων οὐκ εἶδον εἰ μὴ Ἰάκωβον τὸν ἀδελφὸν τοῦ Κυρίου.
20 Nǹkan tí èmi ń kọ̀wé sí yín yìí, kíyèsi i, níwájú Ọlọ́run èmi kò ṣèké.
ἃ δὲ γράφω ὑμῖν, ἰδοὺ ἐνώπιον τοῦ Θεοῦ ὅτι οὐ ψεύδομαι.
21 Lẹ́yìn náà mo sì wá sí agbègbè Siria àti ti Kilikia.
ἔπειτα ἦλθον εἰς τὰ κλίματα τῆς Συρίας καὶ τῆς Κιλικίας.
22 Mo sì jẹ́ ẹni tí a kò mọ̀ lójú fún àwọn ìjọ tí ó wà nínú Kristi ni Judea.
ἤμην δὲ ἀγνοούμενος τῷ προσώπῳ ταῖς ἐκκλησίαις τῆς Ἰουδαίας ταῖς ἐν Χριστῷ·
23 Wọ́n kàn gbọ́ ìròyìn wí pé, “Ẹni tí ó tí ń ṣe inúnibíni sí wa rí, ní ìsinsin yìí ti ń wàásù ìgbàgbọ́ náà tí ó ti gbìyànjú láti bàjẹ́ nígbà kan rí.”
μόνον δὲ ἀκούοντες ἦσαν ὅτι ὁ διώκων ἡμᾶς ποτε νῦν εὐαγγελίζεται τὴν πίστιν ἥν ποτε ἐπόρθει,
24 Wọ́n sì yin Ọlọ́run lógo nítorí mi.
καὶ ἐδόξαζον ἐν ἐμοὶ τὸν Θεόν.