< Galatians 6 >
1 Ará, bí a tilẹ̀ mú ènìyàn nínú ẹ̀ṣẹ̀ kan, kí ẹ̀yin tí í ṣe ti Ẹ̀mí mú irú ẹni bẹ́ẹ̀ bọ̀ sípò nínú ẹ̀mí ìwà tútù; kí ìwọ tìkára rẹ̀ máa kíyèsára, kí a má ba à dán ìwọ náà wò pẹ̀lú.
2 Ẹ máa ru ẹrù ọmọnìkejì yín, kí ẹ sì fi bẹ́ẹ̀ mú òfin Kristi ṣẹ.
3 Nítorí bí ènìyàn kan bá ń ro ara rẹ̀ sí ẹnìkan, nígbà tí kò jẹ́ nǹkan, ó ń tan ara rẹ̀ jẹ.
4 Ṣùgbọ́n kí olúkúlùkù yẹ iṣẹ́ ara rẹ̀ wò, nígbà náà, ohun ìmú-ṣogo rẹ̀ yóò jẹ́ nínú ti ara rẹ̀ nìkan, kì yóò sì jẹ nínú ti ọmọnìkejì rẹ̀.
5 Nítorí pé olúkúlùkù ni yóò ru ẹrù ara rẹ̀.
6 Ṣùgbọ́n kí ẹni tí a ń kọ́ nínú ọ̀rọ̀ náà máa pèsè ohun rere gbogbo fún ẹni tí ń kọ́ni.
7 Kí a má ṣe tàn yín jẹ; a kò lè gan Ọlọ́run: nítorí ohunkóhun tí ènìyàn bá fúnrúgbìn, òhun ni yóò sì ká.
8 Nítorí ẹni tí ó bá ń fúnrúgbìn sípa ti ara yóò ká ìdíbàjẹ́ ti ara ṣùgbọ́n ẹni tí ń fúnrúgbìn sípa ti ẹ̀mí yóò ti inú ẹ̀mí ká ìyè àìnípẹ̀kun. (aiōnios )
9 Ẹ má sì jẹ́ kí àárẹ̀ ọkàn mú wa ní ṣíṣe rere, nítorí tí a ó kórè nígbà tí àkókò bá dé, bí a kò bá ṣe àárẹ̀.
10 Ǹjẹ́ bí a ti ń rí àǹfààní gba, ẹ jẹ́ kí a máa ṣoore fún gbogbo ènìyàn, àti pàápàá fún àwọn tí í ṣe ará ilé ìgbàgbọ́.
11 Ẹ wo bí mo ti fi ọwọ́ ara mi kọ̀wé gàdàgbà-gàdàgbà sí yín.
12 Iye àwọn tí ń fẹ́ ṣe àṣehàn ni ara wọn ń rọ yín láti kọlà; kìkì nítorí pé kí a má ba à ṣe inúnibíni sí wọn nítorí àgbélébùú Kristi.
13 Nítorí àwọn tí a kọ ní ilà pàápàá kò pa òfin mọ́, ṣùgbọ́n wọ́n ń fẹ́ mú yin kọlà, kí wọn lè máa ṣògo nínú ara yín.
14 Ṣùgbọ́n kí a má ṣe rí i pé èmi ń ṣògo, bí kò ṣe nínú àgbélébùú Jesu Kristi Olúwa wa, nípasẹ̀ ẹni tí a ti kan ayé mọ́ àgbélébùú fún mi, àti èmi fún ayé.
15 Nítorí pé nínú Kristi Jesu, ìkọlà kò jẹ́ ohun kan, tàbí àìkọlà, bí kò ṣe ẹ̀dá tuntun.
16 Kí àlàáfíà àti àánú wà lórí gbogbo àwọn tí ń rìn ní ìlànà yìí, àti lórí Israẹli Ọlọ́run.
17 Láti ìsinsin yìí lọ, kí ẹnikẹ́ni má ṣe yọ mí lẹ́nu mọ́; nítorí èmi ń ru àpá Jesu Olúwa kiri ní ara mi.
18 Ará, oore-ọ̀fẹ́ Jesu Kristi Olúwa wa, kí ó wà pẹ̀lú ẹ̀mí yín. Àmín.