< Ezra 2 >
1 Lákòókò náà, wọ̀nyí ni àwọn ènìyàn agbègbè Juda tí ó gòkè wá láti ìgbèkùn láàrín àwọn tí a kó lọ, ẹni tí Nebukadnessari ọba Babeli ti fi agbára mú ní ìgbèkùn lọ sí Babeli (wọ́n padà sí Jerusalẹmu àti Juda, olúkúlùkù sí ìlú rẹ̀.
옛적에 바벨론 왕 느부갓네살에게 사로잡혀 바벨론으로 갔던 자의 자손 중에서 놓임을 받고 예루살렘과 유다 도로 돌아와 각기 본성에 이른 자
2 Àwọn wọ̀nyí bá Serubbabeli, Jeṣua, Nehemiah, Seraiah, Reelaiah, Mordekai, Bilṣani, Mispari, Bigfai, Rehumu àti Baanah wá). Iye àwọn ọkùnrin àwọn ènìyàn Israẹli.
곧 스룹바벨과, 예수아와, 느헤미야와, 스라야와, 르엘라야와, 모르드개와, 빌산과, 미스발과, 비그왜와, 르훔과, 바아나 등과 함께 나온 이스라엘 백성의 명수가 이러하니
3 Àwọn ọmọ Paroṣi jẹ́ ẹgbàá ó lé méjìléláàádọ́sàn-án
바로스 자손이 이천 일백 칠십 이명이요
4 Ṣefatia jẹ́ òjìdínnírinwó ó lé méjìlá
스바댜 자손이 삼백 칠십 이명이요
5 Arah jẹ́ ẹgbẹ̀rin ó dín mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n
아라 자손이 칠백 칠십 오명이요
6 Pahati-Moabu (láti ipasẹ̀ àwọn ọmọ Jeṣua àti Joabu) jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjì àti ẹgbẹ̀rin lé méjìlá
바핫모압 자손 곧 예수아와 요압 자손이 이천 팔백 십 이명이요
7 Elamu jẹ́ àádọ́ta lé lẹ́gbẹ̀fà ó lé mẹ́rin
엘람 자손이 일천 이백 오십 사명이요
8 Sattu jẹ́ ọ̀tàdínlẹ́gbẹ̀rún ó lé márùn-ún
삿두 자손이 구백 사십 오명이요
9 Sakkai jẹ́ òjìdínlẹ́gbẹ̀rin
삭개 자손이 칠백 육십명이요
10 Bani jẹ́ òjìlélẹ́gbẹ̀ta ó lé méjì
바니 자손이 육백 사십 이명이요
11 Bebai jẹ́ ẹgbẹ̀ta ó lé mẹ́tàlélógún
브배 자손이 육백 이십 삼명이요
12 Asgadi jẹ́ ẹgbẹ̀fà ó lé méjìlélógún
아스갓 자손이 일천 이백 이십 이명이요
13 Adonikami jẹ́ ọ̀tàlélẹ́gbẹ̀ta ó lé mẹ́fà
아도니감 자손이 육백 육십 육명이요
14 Bigfai jẹ́ ẹgbàá ó lé mẹ́rìndínlọ́gọ́ta
비그왜 자손이 이천 오십 육명이요
15 Adini jẹ́ àádọ́ta lé ní irinwó ó lé mẹ́rin
아딘 자손이 사백 오십 사명이요
16 Ateri (nípasẹ̀ Hesekiah) jẹ́ méjìdínlọ́gọ́run
아델 자손 곧 히스기야 자손이 구십 팔명이요
17 Besai jẹ́ ọrùndínnírinwó ó lé mẹ́ta
베새 자손이 삼백 이십 삼명이요
18 Jora jẹ́ méjìléláàádọ́fà
요라 자손이 일백 십 이명이요
19 Haṣumu jẹ́ igba ó lé mẹ́tàlélógún
하숨 자손이 이백 이십 삼명이요
20 Gibbari jẹ́ márùndínlọ́gọ́rùn.
깁발 자손이 구십 오명이요
21 Àwọn ọmọ Bẹtilẹhẹmu jẹ́ mẹ́tàlélọ́gọ́fà
베들레헴 사람이 일백 이십 삼명이요
22 Netofa jẹ́ mẹ́rìndínlọ́gọ́ta
느도바 사람이 오십 륙명이요
23 Anatoti jẹ́ méjìdínláàádóje
아나돗 사람이 일백 이십 팔명이요
24 Asmafeti jẹ́ méjìlélógójì
아스마웹 자손이 사십 이명이요
25 Kiriati-Jearimu, Kefira àti Beeroti jẹ́ ọ̀tàdínlẹ́gbẹ̀rin ó lé mẹ́ta
기랴다림과 그비라와 브에롯 자손이 칠백 사십 삼명이요
26 Rama àti Geba jẹ́ ẹgbẹ̀ta ó lé mọ́kànlélógún
라마와 게바 자손이 육백 이십 일명이요
27 Mikmasi jẹ́ méjìlélọ́gọ́fà
믹마스 사람이 일백 이십 이명이요
28 Beteli àti Ai jẹ́ igba ó lé mẹ́tàlélógún
벧엘과 아이 사람이 이백 이십 삼명이요
29 Nebo jẹ́ méjìléláàádọ́ta
느보 자손이 오십 이명이요
30 Magbiṣi jẹ́ mẹ́rìndínlọ́gọ́jọ
막비스 자손이 일백 오십 육명이요
31 Elamu mìíràn jẹ́ ẹgbẹ̀fà ó lé mẹ́rìnléláàádọ́ta
다른 엘람 자손이 일천 이백 오십 사명이요
32 Harimu jẹ́ ọ̀rìndínnírinwó.
하림 자손이 삼백 이십명이요
33 Lodi, Hadidi àti Ono jẹ́ ọ̀rìndínlẹ́gbẹ̀rin ó lé márùn-ún
로드와 하딧과 오노 자손이 칠백 이십 오명이요
34 Jeriko jẹ́ ọ̀tàdínnírinwó ó lé márùn-ún
여리고 자손이 삼백 사십 오명이요
35 Senaa jẹ́ egbèji dín lógún ó lé ọgbọ̀n.
스나아 자손이 삼천 육백 삼십명이었더라
36 Àwọn àlùfáà. Àwọn ọmọ Jedaiah (láti ipasẹ̀ ìdílé Jeṣua) jẹ́ ogún dín lẹ́gbẹ̀rin ó dín méje
제사장들은 예수아의 집 여다야 자손이 구백 칠십 삼명이요
37 Immeri jẹ́ àádọ́ta lé lẹ́gbẹ̀rún ó lé méjì
임멜 자손이 일천 오십 이명이요
38 Paṣuri jẹ́ ẹgbẹ̀fà ó lé mẹ́tàdínláàádọ́ta
바스훌 자손이 일천 이백 사십 칠명이요
39 Harimu jẹ́ ẹgbẹ̀rún ó lé mẹ́tàdínlógún.
하림 자손이 일천 십 칠명이었더라
40 Àwọn ọmọ Lefi. Àwọn ọmọ Jeṣua àti Kadmieli (ti ìdílé Hodafiah) jẹ́ mẹ́rìnléláàádọ́rin.
레위 사람은 호다위야 자손 곧 예수아와, 갓미엘 자손이 칠십 사명이요
41 Àwọn akọrin. Àwọn ọmọ Asafu jẹ́ méjìdínláàádóje.
노래하는 자들은 아삽 자손이 일백 이십 팔명이요
42 Àwọn aṣọ́bodè. Àwọn ará Ṣallumu, Ateri, Talmoni, Akkubu, Hatita àti Ṣobai jẹ́ mọ́kàndínlógóje.
문지기의 자손들은 살룸과, 아델과, 달문과, 악굽과, 하디다와, 소배 자손이 모두 일백 삼십 구명이였더라
43 Àwọn ìránṣẹ́ tẹmpili. Àwọn ọmọ. Siha, Hasufa, Tabboati,
느디님 사람들은 시하 자손과, 하수바 자손과, 답바옷 자손과,
44 Kerosi, Siaha, Padoni,
게로스 자손과, 시아하 자손과, 바돈 자손과,
45 Lebana, Hagaba, Akkubu,
르바나 자손과, 하가바 자손과, 악굽 자손과,
46 Hagabu, Ṣalmai, Hanani,
하갑 자손과, 사믈래 자손과, 하난 자손과,
47 Giddeli, Gahari, Reaiah,
깃델 자손과, 가할 자손과, 르아야 자손과,
48 Resini, Nekoda, Gassamu,
르신 자손과, 느고다 자손과, 갓삼 자손과,
50 Asna, Mehuni, Nefisimu,
아스나 자손과, 므우님 자손과, 느부심 자손과,
51 Bakbu, Hakufa, Harhuri.
박북 자손과, 하그바 자손과, 할훌 자손과,
52 Basluti, Mehida, Harṣa,
바슬룻 자손과, 므히다 자손과, 하르사 자손과,
53 Barkosi, Sisera, Tema,
바르고스 자손과, 시스라 자손과, 데마 자손과,
55 Àwọn ọmọ àwọn ìránṣẹ́ Solomoni. Àwọn ọmọ Sotai, Sofereti, Peruda,
솔로몬의 신복의 자손은 소대 자손과, 하소베렛 자손과, 브루다 자손과,
56 Jaala, Darkoni, Giddeli,
야알라 자손과, 다르곤 자손과, 깃델 자손과,
57 Ṣefatia, àwọn ọmọ Hattili, Pokereti ti Haṣebaimu àti àwọn ọmọ Ami.
스바댜 자손과, 하딜 자손과, 보게렛하스바임 자손과, 아미 자손이니
58 Àwọn ìránṣẹ́ tẹmpili àti àwọn ọmọ àwọn ìránṣẹ́ Solomoni jẹ́ irinwó ó dín mẹ́jọ.
모든 느디님 사람과 솔로몬의 신복의 자손이 삼백 구십 이명이었더라
59 Àwọn wọ̀nyí gòkè wá láti àwọn ìlú ti Teli-Mela, Teli-Harṣa, Kerubu, Addoni àti Immeri, ṣùgbọ́n wọn kò lè sọ pẹ̀lú ìdánilójú pé ìdílé àwọn wá láti ara ìran ẹ̀yà Israẹli.
델멜라와, 델하르사와, 그룹과, 앗단과, 임멜에서 올라온 자가 있으나 그 종족과 보계가 이스라엘에 속하였는지는 증거할 수 없으니
60 Àwọn ọmọ Delaiah, Tobiah àti Nekoda jẹ́ àádọ́ta lé lẹ́gbẹ̀ta ó lé méjì.
저희는 들라야 자손과, 도비야 자손과, 느고다 자손이라 도합이 육백 오십 이명이요
61 Àti nínú àwọn ọmọ àwọn àlùfáà. Àwọn ọmọ: Hobaiah, Hakosi àti Barsillai (ọkùnrin tí ó fẹ́ ọmọbìnrin Barsillai ará Gileadi a sì ń fi orúkọ náà pè é).
제사장 중에는 하바야 자손과, 학고스 자손과, 바르실래 자손이니 바르실래는 길르앗 사람 바르실래의 딸 중에 하나로 아내를 삼고 바르실래의 이름으로 이름한 자라
62 Àwọn wọ̀nyí wá ìwé ìrántí ìdílé wọn, ṣùgbọ́n wọn kò rí i, bẹ́ẹ̀ ni a kò kà wọ́n kún ara àlùfáà nítorí, a kà wọ́n sí aláìmọ́.
이 사람들이 보계 중에서 자기 이름을 찾아도 얻지 못한 고로 저희를 부정하게 여겨 제사장의 직분을 행치 못하게 하고
63 Baálẹ̀ pa á láṣẹ fún wọn pé wọn kò gbọdọ̀ jẹ nínú oúnjẹ mímọ́ jùlọ títí tí àlùfáà kan yóò fi ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ pẹ̀lú Urimu àti Tumimu.
방백이 저희에게 명하여 '우림과 둠밈을 가진 제사장이 일어나기 전에는 지성물을 먹지 말라' 하였느니라
64 Gbogbo ìjọ ènìyàn náà jẹ́ ẹgbàá mọ́kànlélógún ó lé òjìdínnírinwó.
온 회중의 합계가 사만 이천 삼백 육십명이요
65 Yàtọ̀ sí ẹgbẹ̀rin dín lẹ́gbàárin ó dín mẹ́tàlélọ́gọ́ta ìránṣẹ́ ọkùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin; wọ́n ní igba akọrin ọkùnrin àti obìnrin.
그 외에 노비가 칠천 삼백 삼십 칠명이요, 노래하는 남녀가 이백명이요
66 Wọ́n ní ọ̀tàdínlẹ́gbẹ̀rin ó dín mẹ́rin ẹṣin; ìbáaka òjìlélúgba ó lé márùn-ún,
말이 칠백 삼십 륙이요, 노새가 이백 사십 오요
67 ràkunmí jẹ́ irinwó ó lé márùndínlógójì àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ẹgbẹ̀rin lé lọ́gbọ̀n ó dín ọgọ́rin.
약대가 사백 삼십 오요, 나귀가 육천 칠백 이십이었더라
68 Ní ìgbà tí wọ́n dé ilé Olúwa ní Jerusalẹmu, díẹ̀ nínú àwọn olórí àwọn ìdílé fi ọrẹ àtinúwá sílẹ̀ fún ṣíṣe àtúnkọ́ ilé Ọlọ́run ní ààyè rẹ̀.
어떤 족장들이 예루살렘 여호와의 전 터에 이르러 하나님의 전을 그곳에 다시 건축하려고 예물을 즐거이 드리되
69 Gẹ́gẹ́ bí agbára wọn, wọ́n fún ilé ìṣúra fún iṣẹ́ yìí ní ọ̀kẹ́ mẹ́ta ó lé lẹ́gbẹ̀rún ìwọ̀n dariki wúrà, ẹgbẹ̀rún márùn-ún fàdákà àti ọgọ́rùn-ún ẹ̀wù àlùfáà.
역량대로 역사하는 곳간에 드리니 금이 육만 일천 다릭이요, 은이 오천 마네요, 제사장의 옷이 일백 벌이었더라
70 Àwọn àlùfáà, àwọn ará Lefi, àwọn akọrin, àwọn aṣọ́bodè àti àwọn ìránṣẹ́ ilé Olúwa ṣe àtìpó sínú àwọn ìlú wọn, pẹ̀lú àwọn ènìyàn mìíràn, àti ìyókù àwọn ọmọ Israẹli ṣe àtìpó sínú ìlú u wọn.
이에 제사장들과 레위 사람들과 백성 몇과 노래하는 자들과 문지기들과 느디님 사람들이 그 본성들에 거하고 이스라엘 무리도 그 본성들에 거하였느니라