< Ezekiel 7 >

1 Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá:
Och HERRENS ord kom till mig; han sade:
2 “Ọmọ ènìyàn, báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí sí ilé Israẹli: “‘Òpin! Òpin ti dé sí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ilẹ̀ náà!
Du människobarn, så säger Herren, HERREN till Israels land: Änden! Ja, änden kommer över landets fyra hörn.
3 Òpin tí dé sí ọ báyìí, èmi yóò sì tú ìbínú mi jáde sí ọ, èmi yóò dájọ́ rẹ gẹ́gẹ́ bí ìwà rẹ, èmi yóò sì san án fún ọ gẹ́gẹ́ bí gbogbo ìwà ìríra rẹ.
Nu kommer änden över dig, ty jag skall sända min vrede mot dig och döma dig efter dina gärningar och låta alla dina styggelser komma över dig.
4 Ojú mi kò ní i dá ọ sì, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò ṣàánú; ṣùgbọ́n èmi yóò san án fún ọ gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà rẹ àti gbogbo ìwà ìríra tó wà láàrín rẹ. Nígbà náà ní ẹ̀yin yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa.’
Jag skall icke visa dig någon skonsamhet och icke hava någon misskund; nej, jag skall låta dina gärningar komma över dig, och dina styggelser skola vila på dig. Och I skolen förnimma att jag är HERREN.
5 “Èyí ni Olúwa Olódùmarè wí: “‘Ibi! Ibi kan ṣoṣo. Kíyèsi, ó bọ̀ ní orí rẹ!
Så säger Herren, HERREN: Se, en olycka kommer, en olycka ensam i sitt slag!
6 Òpin ti dé! Òpin ti dé! Ó ti dìde lòdì sí ọ. Kíyèsi, ó ti dé!
En ände kommer, ja, änden kommer, den vaknar upp och kommer över dig.
7 Ìparun ti dé sórí rẹ, ìwọ tó ń gbé ní ilẹ̀ náà. Àkókò náà dé! Ọjọ́ wàhálà ti súnmọ́ etílé! Kì í ṣe ọjọ́ ariwo ayọ̀ lórí òkè.
Ja se, det kommer! Nu kommer ordningen till dig, du folk som bor här i landet; din stund kommer, förvirringens dag är nära, då intet skördeskri mer skall höras på bergen.
8 Mo ṣetán láti tú ìbínú gbígbóná mi lé ọ lórí àti láti lo ìbínú mi lórí rẹ gẹ́gẹ́ bí gbogbo ọ̀nà rẹ, èmi yóò sì dá ọ lẹ́jọ́ gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà rẹ àti gẹ́gẹ́ bí ìwà ìríra rẹ ni èmi yóò sì san án fún ọ.
Nu skall jag snart utgjuta min förtörnelse över dig och uttömma min vrede på dig, och döma dig efter dina gärningar och låta alla dina styggelser komma över dig.
9 Ojú mi kò ní i dá ọ sí, Èmi kò sì ní wò ọ́ pẹ̀lú àánú; èmi yóò san án fún ọ gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà rẹ àti fún gbogbo ìwà ìríra tí wà láàrín rẹ. “‘Nígbà náà ní ẹ o mọ̀ pé Èmi Olúwa lo kọlù yín.
Jag skall icke visa någon skonsamhet och icke hava någon misskund, jag skall giva dig efter dina gärningar, och dina styggelser skola vila på dig. Och I skolen förnimma att jag, HERREN, är den som slår.
10 “‘Ọjọ́ náà dé! Kíyèsi ó ti dé! Ìparun ti bú jáde, ọ̀pá ti tanná, ìgbéraga ti rúdí!
Se, dagen är inne; se, det kommer! Ordningen går sin gång, riset blomstrar upp, övermodet grönskar;
11 Ìwà ipá ti di ọ̀pá ìwà búburú; ọ̀pá láti jẹ ẹni búburú ní ìyà. Kò sí nínú wọn tí yóò ṣẹ́kù, tàbí nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn, kò sí nínú ọrọ̀ wọn, kò sí ohun tí ó ní iye.
våldet reser sig till ett ris för ogudaktigheten. Då bliver intet kvar av dem, intet av hela deras hop, intet av deras gods, och till intet bliver deras härlighet.
12 Àkókò náà dé! Ọjọ́ náà ti dé! Kí òǹrajà má ṣe yọ̀, bẹ́ẹ̀ ni ki òǹtajà má ṣe ṣọ̀fọ̀; nítorí, ìbínú gbígbóná wà lórí gbogbo ènìyàn.
Stunden kommer, dagen nalkas; köparen må icke glädja sig, och säljaren må icke sörja, ty vredesglöd kommer över hela hopen därinne.
13 Nítorí pé òǹtajà kì yóò rí gbà padà dúkìá èyí tó tà níwọ̀n ìgbà ti àwọn méjèèjì bá wà láààyè. Nítorí ìran tó kan gbogbo ènìyàn yìí kò ní yí padà. Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn, kò sí ọ̀kan nínú wọn tí yóò gba ara rẹ̀ là.
Säljaren skall icke få tillbaka vad han har sålt, om han ens får förbliva vid liv. Ty profetian om hela hopen därinne skall icke ryggas och ingen som lever i missgärning skall kunna hålla stånd.
14 “‘Wọ́n ti fọn ìpè ogun, tí wọ́n sì pèsè ohun gbogbo sílẹ̀, ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí yóò lọ ojú ogun, nítorí ìbínú gbígbóná mi ti wà lórí gbogbo ènìyàn.
Man stöter i basun och rustar allt i ordning, men ingen drager ut till strid; ty min vredesglöd går fram över hela hopen därinne.
15 Idà wà ní ìta, àjàkálẹ̀-ààrùn àti ìyàn wà nílé, idà yóò pa ẹni tó bá wà ní orílẹ̀-èdè, àjàkálẹ̀-ààrùn àti ìyàn yóò pa ẹni tó bá wà ní ìlú.
Ute härjar svärdet och därinne pest och hungersnöd, den som är ute på marken dör genom svärdet, och den som är i staden, honom förtär hungersnöd och pest.
16 Gbogbo àwọn tí ó bọ́ nínú wọn yóò sálà, wọn yóò sì wà lórí òkè. Bí i àdàbà inú àfonífojì, gbogbo wọn yóò máa ṣọ̀fọ̀, olúkúlùkù nítorí àìṣedéédéé rẹ̀.
Och om några av dem bliva räddade, så skola de söka sin tillflykt i bergen och vara lika klyftornas duvor, som allasammans klaga. Så skall det gå var och en genom hans missgärning.
17 Gbogbo ọwọ́ yóò rọ, gbogbo orúnkún yóò di aláìlágbára bí omi.
Alla händer skola sjunka ned, och alla knän skola bliva såsom vatten.
18 Wọn yóò wọ aṣọ ọ̀fọ̀, ẹ̀rù yóò sì bò wọ́n mọ́lẹ̀, ìtìjú yóò mù wọn, wọn yóò sì fá irun wọn.
Människorna skola kläda sig i sorgdräkt, och förfäran skall övertäcka dem, alla ansikten skola höljas av skam, och alla huvuden skola bliva skalliga.
19 “‘Wọn yóò dà fàdákà wọn sí ojú pópó, wúrà wọn yóò sì dàbí èérí fàdákà àti wúrà wọn kò ní le gbà wọ́n ní ọjọ́ ìbínú gbígbóná Olúwa. Wọn kò ní le jẹun tẹ́ ra wọn lọ́rùn tàbí kí wọn kún ikùn wọn pẹ̀lú oúnjẹ nítorí pé ó ti di ohun ìkọ̀sẹ̀ fún wọn.
Man skall kasta sitt silver ut på gatorna och akta sitt guld såsom orenlighet. Deras silver och guld skall icke kunna rädda dem på HERRENS vredes dag, de skola icke kunna mätta sig därmed eller därmed fylla sin buk; ty det har varit för dem en stötesten till missgärning.
20 Wọ́n ń ṣe ìgbéraga pẹ̀lú ohun ọ̀ṣọ́ wọn tí ó lẹ́wà, wọn sì ti fi ṣe òrìṣà, wọn sì tún ya àwòrán ìríra wọn níbẹ̀. Nítorí náà, èmi yóò sọ àwọn nǹkan wọ̀nyí di aláìmọ́ fún wọn.
Dess sköna glans brukade man till högfärd, ja, de gjorde därav sina styggeliga bilder, sina skändliga avgudar. Därför skall jag göra det till orenlighet för dem.
21 Èmi yóò sì fi àwọn nǹkan wọ̀nyí ṣe ìjẹ fún àjèjì àti ìkógun fún àwọn ènìyàn búburú ayé, wọn yóò sì sọ ọ́ di aláìmọ́.
Jag skall giva det såsom byte i främlingars hand och såsom rov åt de ogudaktigaste på jorden, för att de må ohelga det.
22 Èmi yóò gbójú mi kúrò lára wọn, àwọn ọlọ́ṣà yóò sì sọ ibi ìṣúra mi di aláìmọ́; àwọn ọlọ́ṣà yóò wọ inú rẹ̀, wọn yóò sì bà á jẹ́.
Och jag skall vända bort mitt ansikte ifrån dem, så att man får ohelga min klenod; våldsmän skola få draga därin och ohelga den.
23 “‘Rọ ẹ̀wọ̀n irin! Nítorí pé ilẹ̀ náà kún fún ẹ̀ṣẹ̀ ìtàjẹ̀ sílẹ̀, ìlú náà sí kún fún ìwà ipá.
Gör kedjorna redo; ty landet är fullt av blodsdomar, och staden är full av orätt.
24 Èmi yóò mú kí orílẹ̀-èdè ti ó búburú jùlọ láti jogún ilé wọn. Èmi yóò sì fi òpin sí ìgbéraga àwọn alágbára, ibi mímọ́ wọn yóò sì di bíbàjẹ́.
Och jag skall låta de värsta hednafolk komma och taga deras hus i besittning. Så skall jag göra slut på de fräckas övermod, och deras helgedomar skola varda oskärade.
25 Nígbà tí ìpayà bá dé, wọn yóò wá àlàáfíà, lórí asán.
Förskräckelse skall komma, och när de söka räddning, skall ingen vara att finna.
26 Wàhálà lórí wàhálà yóò dé, ìdágìrì lórí ìdágìrì. Nígbà náà ni wọn yóò wá ìran lọ́dọ̀ wòlíì, ṣùgbọ́n ẹ̀kọ́ òfin yóò parun lọ́dọ̀ àlùfáà, bẹ́ẹ̀ ni ìmọ̀ràn yóò ṣègbé lọ́dọ̀ àwọn àgbàgbà.
Den ena olyckan skall komma efter den andra, det ena sorgebudet skall följa det andra. Man skall få tigga profeterna om syner, prästerna skola komma till korta med sin undervisning och de äldste med sina råd.
27 Ọba yóò ṣọ̀fọ̀, ọmọ-aládé yóò wà láìní ìrètí, ọwọ́ àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà yóò wárìrì. Èmi yóò ṣe é fún wọn gẹ́gẹ́ bí ìṣe wọn, èmi yóò ṣe ìdájọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí ìgbékalẹ̀ wọn. Nígbà náà ni wọn yóò mọ̀ pé èmi ní Olúwa.’”
Konungen skall sörja, hövdingarna skola kläda sig i förskräckelse, och folket i landet skall stå där med darrande händer. Jag skall göra med den efter deras gärningar och skipa rätt åt dem såsom rätt är åt dem; och de skola förnimma att jag är HERREN.

< Ezekiel 7 >