< Ezekiel 31 >
1 Ní ọjọ́ kìn-ín-ní, oṣù kẹta ọdún kọkànlá, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá:
Und es geschah im elften Jahre, im dritten Monat, am Ersten des Monats, da geschah das Wort Jehovas zu mir also:
2 “Ọmọ ènìyàn, sọ fún Farao ọba Ejibiti àti sí ìjọ rẹ̀: “‘Ta ní a le fiwé ọ ní ọláńlá?
Menschensohn, sprich zu dem Pharao, dem König von Ägypten, und zu seiner Menge: Wem gleichst du in deiner Größe?
3 Kíyèsi Asiria, tí ó jẹ́ igi kedari ni Lebanoni ní ìgbà kan rí, pẹ̀lú àwọn ẹ̀ka dáradára tí ó ṣẹ́ ìji bo igbó náà; tí ó ga sókè, òkè rẹ̀ lókè ni ewé tí ó nípọn wà.
Siehe, Assur war eine Zeder auf dem Libanon, mit schönen Zweigen, ein schattendes Dickicht und von hohem Wuchs; und sein Wipfel war zwischen den Wolken.
4 Omi mú un dàgbàsókè: orísun omi tí ó jinlẹ̀ mú kí o dàgbàsókè; àwọn odo rẹ̀ ń sàn yí ìdí rẹ̀ ká, ó sì rán ìṣàn omi rẹ̀ sí gbogbo igi orí pápá.
Die Wasser zogen ihn groß, die Flut machte ihn hoch; ihre Ströme gingen rings um ihre Pflanzung, und sie entsandte ihre Kanäle zu allen Bäumen des Feldes;
5 Nítorí náà ó ga sí òkè fíofío ju gbogbo igi orí pápá lọ; ẹ̀ka rẹ̀ pọ̀ sí i àwọn ẹ̀ka rẹ̀ sì gùn, wọn tẹ́ rẹrẹ nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi.
Darum wurde sein Wuchs höher als alle Bäume des Feldes und seine Zweige wurden groß und seine Äste lang von den vielen Wassern, als er sich ausbreitete.
6 Ẹyẹ ojú ọ̀run kọ ilé sí ẹ̀ka rẹ̀ gbogbo ẹranko igbó ń bímọ ní abẹ́ ẹ̀ka rẹ̀; gbogbo orílẹ̀-èdè ńlá ń gbé abẹ́ ìji rẹ̀.
Alle Vögel des Himmels nisteten in seinen Zweigen, und alle Tiere des Feldes gebaren unter seinen Ästen; und in seinem Schatten wohnten alle großen Nationen.
7 Ọláńlá ní ẹwà rẹ̀ jẹ́, pẹ̀lú títẹ́ rẹrẹ ẹ̀ka rẹ̀, nítorí gbòǹgbò rẹ̀ lọ sí ìsàlẹ̀ sí ibi tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi wà.
Und er war schön in seiner Größe und in der Länge seiner Schößlinge; denn seine Wurzeln waren an vielen Wassern.
8 Àwọn igi kedari nínú ọgbà Ọlọ́run kò lè è bò ó mọ́lẹ̀; tàbí kí àwọn igi junifa ṣe déédé pẹ̀lú ẹ̀ka rẹ̀, tàbí kí a fi igi títẹ́ rẹrẹ wé ẹ̀ka rẹ̀, kò sí igi nínú ọgbà Ọlọ́run tí ó dà bí rẹ̀ ní ẹwà rẹ̀.
Die Zedern im Garten Gottes verdunkelten ihn nicht, Zypressen kamen seinen Zweigen nicht gleich, und Platanen waren nicht wie seine Äste; kein Baum im Garten Gottes kam ihm an Schönheit gleich.
9 Mo mú kí ó ní ẹwà pẹ̀lú ẹ̀ka lọ́pọ̀lọ́pọ̀ tó fi jẹ́ ìlara àwọn igi gbogbo ní Edeni tí í ṣe ọgbà Ọlọ́run.
Ich hatte ihn schön gemacht in der Menge seiner Schößlinge; und es beneideten ihn alle Bäume Edens, die im Garten Gottes waren.
10 “‘Nítorí náà, èyí yìí ní Olúwa Olódùmarè wí: Nítorí pé ó ga lọ sókè fíofío, tí ó sì gbé òkè rẹ̀ ga ju ewé tí ó nípọn lọ, àti nítorí pé gíga rẹ mú kí ó gbéraga,
Darum, so sprach der Herr, Jehova: Weil du hoch geworden bist an Wuchs, und er seinen Wipfel bis zwischen die Wolken streckte, und sein Herz sich erhob wegen seiner Höhe:
11 mo fi lé alákòóso àwọn orílẹ̀-èdè náà lọ́wọ́, fún un láti fi ṣe ẹ̀tọ́ fún un gẹ́gẹ́ bí ìwà búburú rẹ̀. Mo pa á tì sí ẹ̀gbẹ́ kan,
so werde ich ihn in die Hand des Mächtigen der Nationen geben; nach seiner Bosheit soll er mit ihm handeln; ich habe ihn verstoßen.
12 àwọn orílẹ̀-èdè àjèjì aláìláàánú jùlọ ké e lulẹ̀, wọn sì fi kalẹ̀. Àwọn ẹ̀ka rẹ̀ ṣubú sórí òkè àti sí gbogbo àárín àwọn òkè; àwọn ẹ̀ka rẹ̀ tí ó ṣẹ nà sílẹ̀ ní gbogbo àlàfo jíjìn ilẹ̀. Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ilẹ̀ ayé jáde kúrò ní abẹ́ ìji rẹ̀ wọn sì fi sílẹ̀.
Und Fremde, die Gewalttätigsten der Nationen, hieben ihn um und warfen ihn hin; seine Schößlinge fielen auf die Berge und in alle Täler, und seine Äste wurden zerbrochen und geworfen in alle Gründe der Erde; und alle Völker der Erde zogen aus seinem Schatten hinweg und ließen ihn liegen;
13 Gbogbo àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run ṣe àtìpó ni orí igi tí ó ṣubú lulẹ̀ náà, gbogbo àwọn ẹranko igbó wà ní àárín ẹ̀ka rẹ̀.
auf seinen umgefallenen Stamm ließen sich alle Vögel des Himmels nieder, und über seine Äste kamen alle Tiere des Feldes:
14 Nítorí náà kò sí igi mìíràn lẹ́gbẹ̀ẹ́ omi tí ó lè fi ìgbéraga ga sókè fíofío, tí yóò sì gbé sókè rẹ̀ ga ju ewé tí ó nípọn lọ. Kò sí igi mìíràn tí ó ní omi tó bẹ́ẹ̀ tí ó lè ga tó bẹ́ẹ̀; gbogbo wọn ni a kádàrá ikú fún, fún ìsàlẹ̀ ilẹ̀, ní àárín àwọn alààyè ènìyàn, pẹ̀lú àwọn tí o lọ sí ọ̀gbun ní ìsàlẹ̀.
auf daß keine Bäume am Wasser wegen ihres Wuchses sich überheben und ihren Wipfel bis zwischen die Wolken strecken, und keine Wassertrinkenden auf sich selbst sich stützen wegen ihrer Höhe; denn sie alle sind dem Tode hingegeben in die untersten Örter der Erde, mitten unter den Menschenkindern, zu denen hin, welche in die Grube hinabgefahren sind. -
15 “‘Èyí ni Olúwa Olódùmarè wí: Ní ọjọ́ ti a mú u wá sí isà òkú mo fi ọ̀fọ̀ ṣíṣe bo orísun omi jíjìn náà, mo dá àwọn ìṣàn omi rẹ̀ dúró, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi rẹ̀ ní a dí lọ́nà. Nítorí rẹ̀ mo fi ìwúwo ọkàn wọ Lebanoni ní aṣọ, gbogbo igi igbó gbẹ dànù. (Sheol )
So spricht der Herr, Jehova: An dem Tage, da er in den Scheol hinabfuhr, machte ich ein Trauern; ich verhüllte um seinetwillen die Tiefe und hielt ihre Ströme zurück, und die großen Wasser wurden gehemmt; und den Libanon hüllte ich in Schwarz um seinetwillen, und um seinetwillen verschmachteten alle Bäume des Feldes. (Sheol )
16 Mo mú kí orílẹ̀-èdè wárìrì sì ìró ìṣubú rẹ̀ nígbà tí mo mú un wá sí ìsàlẹ̀ isà òkú pẹ̀lú àwọn tí ó lọ sí ọ̀gbun ìsàlẹ̀. Nígbà náà gbogbo igi Edeni, àṣàyàn àti èyí tí ó dára jùlọ nínú Lebanoni, gbogbo igi tí ó ní omi dáradára ni a tù nínú ni ayé ìsàlẹ̀. (Sheol )
Von dem Getöse seines Falles machte ich die Nationen erbeben, als ich ihn in den Scheol hinabfahren ließ zu denen, welche in die Grube hinabgefahren sind. Und alle Bäume Edens, das Auserwählte und Beste des Libanon, alle Wassertrinkenden, trösteten sich in den untersten Örtern der Erde. (Sheol )
17 Àwọn tí ó ń gbé ní abẹ́ òjìji rẹ̀, àwọn àjèjì rẹ ní àárín àwọn orílẹ̀-èdè náà, ti lọ sí ìsàlẹ̀ isà òkú pẹ̀lú rẹ̀, ní dídárapọ̀ mọ́ àwọn tí a fi idà pa. (Sheol )
Auch sie fuhren mit ihm in den Scheol hinab zu den vom Schwerte Erschlagenen, die als seine Helfer in seinem Schatten saßen unter den Nationen. (Sheol )
18 “‘Èwo lára igi Edeni ní a lè fiwé ọ ní dídán àti ọláńlá? Síbẹ̀ ìwọ, gan an wá sílẹ̀ pẹ̀lú àwọn igi Edeni lọ sí ìsàlẹ̀ ilẹ̀; ìwọ yóò sùn ni àárín àwọn aláìkọlà, pẹ̀lú àwọn tí a fi idà pa. “‘Èyí yìí ní Farao àti ìjọ rẹ̀, ní Olúwa Olódùmarè wí.’”
Wem gleichst du so an Herrlichkeit und an Größe unter den Bäumen Edens? Und so sollst du mit den Bäumen Edens hinabgestürzt werden in die untersten Örter der Erde, sollst unter den Unbeschnittenen liegen, bei den vom Schwerte Erschlagenen. Das ist der Pharao und seine ganze Menge, spricht der Herr, Jehova.