< Ezekiel 28 >

1 Ọ̀rọ̀ Olúwa tún tọ̀ mí wá wí pé:
Beseda Gospodova je ponovno prišla k meni, rekoč:
2 “Ọmọ ènìyàn, sọ fún ọmọ-aládé Tire pé, ‘Báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí: “‘Nítorí tí ọkàn rẹ gbé sókè sí mi, ìwọ wí pé, “Èmi ni Ọlọ́run; Èmi jókòó sí orí ìtẹ́ òrìṣà, ní àárín gbùngbùn Òkun.” Ṣùgbọ́n ènìyàn ni ọ́, kì i ṣe òrìṣà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé ìwọ rò pé ìwọ gbọ́n bí Ọlọ́run.
»Človeški sin, povej princu Tira: ›Tako govori Gospod Bog: ›Ker je tvoje srce povzdignjeno in si rekel: ›Jaz sem Bog, sedim na Božjem sedežu v sredi morij; ‹ vendar si človek in ne Bog, čeprav si svoje srce postavljal kakor srce Boga.
3 Ìwọ gbọ́n ju Daniẹli lọ bí? Ṣé kò sí àṣírí kan tí ó pamọ́ fún ọ?
Glej, modrejši si kakor Daniel; ni skrivnosti, ki jo lahko skrijejo pred teboj.
4 Pẹ̀lú ọgbọ́n àti ìmọ̀ rẹ, ìwọ tí jèrè ọrọ̀ fún ara rẹ, àti àkójọpọ̀ wúrà àti fàdákà, nínú àwọn ilé ìṣúra rẹ.
S svojo modrostjo in s svojim razumevanjem si si pridobil bogastva in v svojih zakladnicah si si pridobil zlato in srebro.
5 Nípa ọgbọ́n rẹ ńlá àti nípa òwò rẹ, ìwọ ti sọ ọrọ̀ rẹ di púpọ̀, àti nítorí ọrọ̀ rẹ di púpọ̀, ọkàn rẹ gbé sókè, nítorí ọrọ̀ rẹ.
S svojo veliko modrostjo in s svojim preprodajanjem si povečal svoja bogastva in tvoje srce je povzdignjeno zaradi tvojih bogastev.‹
6 “‘Nítorí náà èyí yìí ní Olúwa Olódùmarè wí: “‘Nítorí pé ìwọ rò pé o gbọ́n, pé ìwọ gbọ́n bí Ọlọ́run.
Zato tako govori Gospod Bog: ›Ker si svoje srce postavil kakor srce Boga;
7 Èmi yóò mú kí àwọn àjèjì dìde sí ọ, ẹlẹ́rù nínú àwọn orílẹ̀-èdè; wọn yóò yọ idà wọn sí ọ, ẹwà rẹ àti ọgbọ́n rẹ, wọn yóò sì ba dídán rẹ̀ jẹ́.
glej, zato bom nadte privedel tujce, strašne izmed narodov. Svoje meče bodo izvlekli zoper lepoto tvoje modrosti in omadeževali bodo tvoj sijaj.
8 Wọn yóò mú ọ sọ̀kalẹ̀ wá sínú ihò, ìwọ yóò sì kú ikú gbígbóná, àwọn tí a pa ní àárín Òkun.
Privedli te bodo dol do jame in umrl boš [s] smrtmi tistih, ki so umorjeni v sredi morij.
9 Ṣé ìwọ yóò wá wí pé, “Èmi ni Ọlọ́run,” ní ojú àwọn tí ó pa ọ́? Ìwọ yóò jẹ́ ènìyàn, kì í ṣe Ọlọ́run, ní ọwọ́ àwọn ti yóò pa ọ́.
Ali boš še govoril pred tistim, ki te ubija: ›Jaz sem Bog?‹ Toda ti boš mož in ne Bog, v roki tistega, ki te ubija.
10 Ìwọ yóò kú ikú aláìkọlà, ní ọwọ́ àwọn àjèjì. Èmi ni ó ti sọ ọ́, ní Olúwa Olódùmarè wí.’”
Umrl boš s smrtmi neobrezancev, po roki tujcev, kajti jaz sem to govoril, ‹ govori Gospod Bog.«
11 Ọ̀rọ̀ Olúwa tún tọ̀ mí wá wí pé:
Poleg tega je prišla k meni Gospodova beseda, rekoč:
12 “Ọmọ ènìyàn, pohùnréré ẹkún sórí ọba Tire kí ó sì sọ fún un pé: ‘Èyí yìí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: “‘Ìwọ jẹ́ àpẹẹrẹ ìjẹ́pípé náà, o kún fún ọgbọ́n, o sì pé ní ẹwà.
»Človeški sin, vzdigni žalostinko nad kraljem Tira in mu reci: ›Tako govori Gospod Bog: ›Ti pečatiš vsoto, poln si modrosti in popoln v lepoti.
13 Ìwọ ti wà ní Edeni, ọgbà Ọlọ́run; onírúurú òkúta oníyebíye ni ìbora rẹ; sardiu, topasi àti diamọndi, berili, óníkìsì, àti jasperi, safire, emeradi, turikuose, àti karbunkili, àti wúrà, ìpilẹ̀ṣẹ̀ rẹ àti àwọn òkè rẹ ní a dà, láti ara wúrà, ní ọjọ́ tí á dá ọ ní a pèsè wọn.
Bil si v Raju, Božjem vrtu; vsak dragocen kamen je bil tvoje pokrivalo: sardij, topaz in diamant, beril, oniks in jaspis, safir, smaragd, granat in zlato. Izdelava tvojih bobničev in tvojih piščali je bila pripravljena v tebi na dan, ko si bil ustvarjen.
14 A fi àmì òróró yàn ọ́ gẹ́gẹ́ bí olùtọ́jú kérúbù, torí èyí ni mo fi yàn ọ́. Ìwọ wà lórí òkè mímọ́ Ọlọ́run; ìwọ rìn ni àárín òkúta a mú bí iná.
Ti si maziljen kerub, ki zaslanja; in jaz sem te tako postavil. Bil si na sveti gori Boga; hodil si gor in dol v sredi ognjenih kamnov.
15 Ìwọ pé ní ọ̀nà rẹ, láti ọjọ́ tí a ti dá ọ, títí a fi rí àìṣedéédéé ní inú rẹ.
Bil si popoln na svojih poteh, od dneva, ko si bil ustvarjen, dokler ni bila v tebi najdena krivičnost.
16 Nípa ìtànkálẹ̀ òwò rẹ, ìwọ kún fún ìwà ipá; ìwọ sì dẹ́ṣẹ̀. Nítorí náà ni mo ṣe sọ ọ nù, bí ohun àìlọ́wọ̀ kúrò lórí òkè Ọlọ́run. Èmi sì pa ọ run, ìwọ kérúbù, tí ó bọ́ kúrò ní àárín òkúta a mú bí iná.
Z množico tvojih trgovanj so tvojo sredo napolnili z nasiljem in si grešil, zato te bom pahnil, kot oskrunjenega iz Božje gore in te bom uničil, oh zaslanjajoči kerub, iz srede ognjenih kamnov.
17 Ọkàn rẹ gbéraga, nítorí ẹwà rẹ. Ìwọ sì ba ọgbọ́n rẹ jẹ́, nítorí dídára rẹ. Nítorí náà mo le ọ sórí ayé; mo sọ ọ di awòojú níwájú àwọn ọba.
Tvoje srce se je povzdignilo zaradi tvoje lepote, svojo modrost si izpridil zaradi svojega sijaja. Jaz te bom vrgel na tla, jaz te bom položil pred kralje, da te bodo lahko gledali.
18 Nípa ẹ̀ṣẹ̀ púpọ̀ rẹ àti òwò àìṣòótọ́ rẹ, ìwọ ti ba àwọn ibi mímọ́ rẹ jẹ́. Nítorí náà mo mú kí iná jáde wá, láti inú rẹ, yóò sì jó ọ run, èmi yóò sì sọ ọ́ di eérú lórí ilẹ̀, lójú gbogbo àwọn tí ó ń wò ọ́.
Svoja svetišča si omadeževal z množico svojih krivičnosti, s krivičnostjo svojega preprodajanja; zato bom privedel ogenj iz tvoje srede; ta te bo požrl, jaz pa te bom spremenil v pepel na zemlji, pred očmi vseh tistih, ki te gledajo.
19 Gbogbo orílẹ̀-èdè tí ó mọ̀ ọ́n, ní ẹnu ń yà sí ọ; ìwọ yóò sì jẹ́ ẹ̀rù, ìwọ kì yóò sì ṣí mọ́ láéláé.’”
In tisti, ki te med ljudstvom poznajo, bodo osupli nad teboj. Strahota boš in nikoli te ne bo več.‹«
20 Ọ̀rọ̀ Olúwa tún tọ̀ mí wá wí pé:
Ponovno je prišla k meni Gospodova beseda, rekoč:
21 “Ọmọ ènìyàn, kọ ojú sí Sidoni; kí o sì sọtẹ́lẹ̀ sí i,
»Človeški sin, naravnaj svoj obraz proti Sidónu in prerokuj zoper njega
22 kí ó sì wí pé, ‘Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí: “‘Èmi lòdì sí ọ, ìwọ Sidoni, a ó sì ṣe mí lógo láàrín rẹ. Wọn yóò mọ̀ pé èmi ní Olúwa, nígbà tí mo bá mú ìdájọ́ mi ṣẹ nínú rẹ, tí a sì yá mí sí mímọ́ nínú rẹ.
ter reci: ›Tako govori Gospod Bog: ›Glej, zoper tebe sem, oh Sidón; in proslavljen bom v tvoji sredi in vedeli bodo, da jaz sem Gospod, ko bom izvršil sodbe v njem in bom posvečen v njem.
23 Èmi yóò sì rán àjàkálẹ̀-ààrùn sínú rẹ, èmi yóò sì mú kí ẹ̀jẹ̀ sàn ní ìgboro rẹ, ẹni ti á pa yóò ṣubú ní àárín rẹ, pẹ̀lú idà lára rẹ ní gbogbo ẹ̀gbẹ́, nígbà náà wọn yóò mọ̀ wí pé èmi ni Olúwa.
Kajti vanj bom poslal kužno bolezen in kri na njegove ulice; in ranjeni bodo sojeni v njegovi sredi z mečem na njem, na vsaki strani; in spoznali bodo, da jaz sem Gospod.
24 “‘Kì yóò sì ṣí ẹ̀gún tí ń gun ni ní ilẹ̀ Israẹli mọ́, tàbí ẹ̀gún bíbani nínú jẹ́ ti gbogbo àwọn tí wọn wà ní àyíká wọn, tí wọ́n sì ń fi ojú yẹpẹrẹ wò wọ́n, nígbà náà ni wọn yóò mọ́ wí pé èmi ni Olúwa Olódùmarè.
In ne bo več bodečega osata nad Izraelovo hišo niti kakršnegakoli bolečega trna od vseh, ki so okoli njih, ki so jih prezirali; in spoznali bodo, da jaz sem Gospod Bog.‹
25 “‘Èyí yìí ní Olúwa Olódùmarè wí: Nígbà tí èmi yóò bá sa àwọn ènìyàn Israẹli jọ kúrò ní gbogbo orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti fọ́nká sí, tí a ó sì yà mí sí mímọ́ láàrín wọn lójú àwọn aláìkọlà. Nígbà náà ni wọn yóò gbé ní ilẹ̀ àwọn tìkálára wọn, èyí tí mo fún ìránṣẹ́ mi Jakọbu.
Tako govori Gospod Bog: ›Ko bom Izraelovo hišo zbral izmed ljudstev, med katere so razkropljeni in bom posvečen v njih v očeh poganov, potem bodo prebivali v svoji deželi, ki sem jo dal svojemu služabniku Jakobu.
26 Wọn yóò sì máa gbé ní inú rẹ̀ ní àìléwu, wọn yóò sì kọ́lé, wọn yóò sì gbin ọgbà àjàrà; nítòótọ́ wọn yóò wà ní ìbàlẹ̀ àyà, nígbà tí èmi bá ti mú ìdájọ́ mi ṣẹ̀ sí ara àwọn tí ń ṣátá wọn ní gbogbo àyíká wọn. Nígbà náà ni wọn yóò mọ̀ pé, Èmi ni Olúwa Ọlọ́run wọn.’”
In v njej bodo varno prebivali in gradili bodo hiše in sadili vinograde; da, prebivali bodo z zaupanjem, ko izvršim sodbe nad vsemi tistimi, ki jih prezirajo naokoli njih; in spoznali bodo, da jaz sem Gospod, njihov Bog.‹«

< Ezekiel 28 >