< Ezekiel 26 >
1 Ní ọjọ́ kìn-ín-ní, oṣù kọ́kànlá, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé:
καὶ ἐγενήθη ἐν τῷ ἑνδεκάτῳ ἔτει μιᾷ τοῦ μηνὸς ἐγένετο λόγος κυρίου πρός με λέγων
2 “Ọmọ ènìyàn, nítorí pé Tire sọ nípa Jerusalẹmu pé, ‘Háà! A fọ́ èyí tí í ṣe bodè àwọn orílẹ̀-èdè, a yí i padà sí mi, èmi yóò di kíkún, òun yóò sì di ahoro,’
υἱὲ ἀνθρώπου ἀνθ’ ὧν εἶπεν Σορ ἐπὶ Ιερουσαλημ εὖγε συνετρίβη ἀπόλωλεν τὰ ἔθνη ἐπεστράφη πρός με ἡ πλήρης ἠρήμωται
3 nítorí náà, báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí, kíyèsi i, èmí dojúkọ ọ́ ìwọ tire, Èmi yóò sì jẹ́ kí Orílẹ̀-èdè púpọ̀ dìde sí ọ, gẹ́gẹ́ bí Òkun tí ru sókè.
διὰ τοῦτο τάδε λέγει κύριος ἰδοὺ ἐγὼ ἐπὶ σέ Σορ καὶ ἀνάξω ἐπὶ σὲ ἔθνη πολλά ὡς ἀναβαίνει ἡ θάλασσα τοῖς κύμασιν αὐτῆς
4 Wọn yóò wó odi tire lulẹ̀, wọn yóò sì wo ilé ìṣọ́ rẹ̀ lulẹ̀, Èmi yóò sì ha erùpẹ̀ rẹ̀ kúrò, Èmi yóò sì sọ ọ́ di orí àpáta.
καὶ καταβαλοῦσιν τὰ τείχη Σορ καὶ καταβαλοῦσι τοὺς πύργους σου καὶ λικμήσω τὸν χοῦν αὐτῆς ἀπ’ αὐτῆς καὶ δώσω αὐτὴν εἰς λεωπετρίαν
5 Yóò sì jẹ́ ibi nína àwọ̀n tí wọn fi ń pẹja sí láàrín Òkun, ní Olúwa Olódùmarè wí. Yóò di ìkógun fún àwọn orílẹ̀-èdè.
ψυγμὸς σαγηνῶν ἔσται ἐν μέσῳ θαλάσσης ὅτι ἐγὼ λελάληκα λέγει κύριος καὶ ἔσται εἰς προνομὴν τοῖς ἔθνεσιν
6 Ìlú tí ó tẹ̀dó sí, ní àárín gbùngbùn ilẹ̀ rẹ̀ ni a ó fi idà sọ ọ́ di ahoro. Nígbà náà ní wọn yóò mọ̀ pé, Èmi ni Olúwa.
καὶ αἱ θυγατέρες αὐτῆς αἱ ἐν τῷ πεδίῳ μαχαίρᾳ ἀναιρεθήσονται καὶ γνώσονται ὅτι ἐγὼ κύριος
7 “Nítorí báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí: Kíyèsi i, láti ìhà àríwá ni èmi yóò ti mú Nebukadnessari ọba Babeli, ọba àwọn ọba, dìde sí Tire pẹ̀lú ẹṣin àti kẹ̀kẹ́ ogun pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́ṣin àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ológun.
ὅτι τάδε λέγει κύριος ἰδοὺ ἐγὼ ἐπάγω ἐπὶ σέ Σορ τὸν Ναβουχοδονοσορ βασιλέα Βαβυλῶνος ἀπὸ τοῦ βορρᾶ βασιλεὺς βασιλέων ἐστίν μεθ’ ἵππων καὶ ἁρμάτων καὶ ἱππέων καὶ συναγωγῆς ἐθνῶν πολλῶν σφόδρα
8 Yóò sì fi idà sá àwọn ọmọbìnrin rẹ ní oko, yóò sì kọ́ odi tì ọ́, yóò sì mọ òkìtì tì ọ́, yóò sì gbé àpáta sókè sí ọ.
οὗτος τὰς θυγατέρας σου τὰς ἐν τῷ πεδίῳ μαχαίρᾳ ἀνελεῖ καὶ δώσει ἐπὶ σὲ προφυλακὴν καὶ περιοικοδομήσει καὶ ποιήσει ἐπὶ σὲ κύκλῳ χάρακα καὶ περίστασιν ὅπλων καὶ τὰς λόγχας αὐτοῦ ἀπέναντί σου δώσει
9 Yóò sì gbé ẹ̀rọ ogun tí odi rẹ, yóò sì fi ohun èlò ogun wó ilé ìṣọ́ rẹ palẹ̀.
τὰ τείχη σου καὶ τοὺς πύργους σου καταβαλεῖ ἐν ταῖς μαχαίραις αὐτοῦ
10 Àwọn ẹṣin rẹ̀ yóò pọ̀ dé bí pé wọn yóò fi eruku bò ọ́ mọ́lẹ̀. Àwọn ògiri rẹ yóò mì tìtì fún igbe àwọn ẹṣin ogun kẹ̀kẹ́ ẹrù àti kẹ̀kẹ́ ogun nígbà tí ó bá wọ ẹnu-ọ̀nà odi gẹ́gẹ́ bí ènìyàn tí ń wọ ìlú láti inú àwọn ògiri rẹ̀ ti ó di fífọ́ pátápátá.
ἀπὸ τοῦ πλήθους τῶν ἵππων αὐτοῦ κατακαλύψει σε ὁ κονιορτὸς αὐτῶν καὶ ἀπὸ τῆς φωνῆς τῶν ἱππέων αὐτοῦ καὶ τῶν τροχῶν τῶν ἁρμάτων αὐτοῦ σεισθήσεται τὰ τείχη σου εἰσπορευομένου αὐτοῦ τὰς πύλας σου ὡς εἰσπορευόμενος εἰς πόλιν ἐκ πεδίου
11 Pátákò ẹsẹ̀ ẹṣin rẹ̀ ni yóò fi tẹ gbogbo òpópónà rẹ mọ́lẹ̀; yóò fi idà pa àwọn ènìyàn rẹ, àwọn ọ̀wọ́n rẹ ti o lágbára yóò wó palẹ̀.
ἐν ταῖς ὁπλαῖς τῶν ἵππων αὐτοῦ καταπατήσουσίν σου πάσας τὰς πλατείας τὸν λαόν σου μαχαίρᾳ ἀνελεῖ καὶ τὴν ὑπόστασίν σου τῆς ἰσχύος ἐπὶ τὴν γῆν κατάξει
12 Wọn yóò kó ọrọ̀ rẹ, wọn yóò sì fi òwò rẹ ṣe ìjẹ ogun; wọn yóò sì wó odi rẹ lulẹ̀, wọn yóò sì ba àwọn ilé rẹ dídára jẹ́, wọn yóò sì kó àwọn òkúta rẹ̀, àti igi ìtì ìkọ́lé rẹ̀, àti erùpẹ̀ rẹ̀, dà sí inú Òkun.
καὶ προνομεύσει τὴν δύναμίν σου καὶ σκυλεύσει τὰ ὑπάρχοντά σου καὶ καταβαλεῖ σου τὰ τείχη καὶ τοὺς οἴκους σου τοὺς ἐπιθυμητοὺς καθελεῖ καὶ τοὺς λίθους σου καὶ τὰ ξύλα σου καὶ τὸν χοῦν σου εἰς μέσον τῆς θαλάσσης ἐμβαλεῖ
13 Èmi yóò sì mú ariwo orin rẹ̀ dákẹ́ àti ìró dùùrù orin rẹ̀ ni a kì yóò gbọ́ mọ́.
καὶ καταλύσει τὸ πλῆθος τῶν μουσικῶν σου καὶ ἡ φωνὴ τῶν ψαλτηρίων σου οὐ μὴ ἀκουσθῇ ἔτι
14 Èmi yóò sọ ọ di àpáta lásán, ìwọ yóò sì di ibi tí a ń sá àwọ̀n ẹja sí. A kì yóò sì tún ọ mọ nítorí Èmi Olúwa ti sọ ọ̀rọ̀ ní Olúwa Olódùmarè wí.
καὶ δώσω σε εἰς λεωπετρίαν ψυγμὸς σαγηνῶν ἔσῃ οὐ μὴ οἰκοδομηθῇς ἔτι ὅτι ἐγὼ ἐλάλησα λέγει κύριος
15 “Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí sí Tire: Ǹjẹ́ àwọn erékùṣù kì yóò ha wárìrì nípa ìṣubú rẹ, nígbà tí ìkórìíra ìpalára àti rírẹ́ni lọ́run bá ń ṣẹlẹ̀ ní inú rẹ?
διότι τάδε λέγει κύριος κύριος τῇ Σορ οὐκ ἀπὸ φωνῆς τῆς πτώσεώς σου ἐν τῷ στενάξαι τραυματίας ἐν τῷ σπάσαι μάχαιραν ἐν μέσῳ σου σεισθήσονται αἱ νῆσοι
16 Nígbà náà ni gbogbo àwọn ọmọ-aládé etí Òkun yóò sọ̀kalẹ̀ láti orí ìtẹ́ wọn, wọn yóò sì pa àwọn aṣọ ìgúnwà wọn da, tì wọn yóò sì bọ́ àwọn aṣọ iṣẹ́ ọnà abẹ́rẹ́ kúrò. Ẹ̀rù yóò bò wọ́n, wọn yóò sì jókòó lórí ilẹ̀ pẹ̀pẹ̀, wọn yóò sì máa wárìrì ní gbogbo ìgbà, ẹnu yóò sì yà wọ́n sí ọ́.
καὶ καταβήσονται ἀπὸ τῶν θρόνων αὐτῶν πάντες οἱ ἄρχοντες ἐκ τῶν ἐθνῶν τῆς θαλάσσης καὶ ἀφελοῦνται τὰς μίτρας ἀπὸ τῶν κεφαλῶν αὐτῶν καὶ τὸν ἱματισμὸν τὸν ποικίλον αὐτῶν ἐκδύσονται ἐκστάσει ἐκστήσονται ἐπὶ γῆν καθεδοῦνται καὶ φοβηθήσονται τὴν ἀπώλειαν αὐτῶν καὶ στενάξουσιν ἐπὶ σέ
17 Nígbà náà wọn yóò gbóhùn ẹkún sókè nítorí rẹ, wọn yóò sì wí fún ọ pé: “‘Báwo ni a ṣe pa ọ́ run, ìwọ ìlú olókìkí ìwọ tí àwọn èrò okun ti gbé inú rẹ̀! Ìwọ jẹ alágbára lórí okun gbogbo òun àti àwọn olùgbé inú rẹ̀; ìwọ gbé ẹ̀rù rẹ lórí gbogbo olùgbé ibẹ̀.
καὶ λήμψονται ἐπὶ σὲ θρῆνον καὶ ἐροῦσίν σοι πῶς κατελύθης ἐκ θαλάσσης ἡ πόλις ἡ ἐπαινεστὴ ἡ δοῦσα τὸν φόβον αὐτῆς πᾶσι τοῖς κατοικοῦσιν αὐτήν
18 Nísinsin yìí erékùṣù wárìrì ní ọjọ́ ìṣubú rẹ; erékùṣù tí ó wà nínú Òkun ni ẹ̀rù bà torí ìṣubú rẹ.’
καὶ φοβηθήσονται αἱ νῆσοι ἀφ’ ἡμέρας πτώσεώς σου
19 “Èyí yìí ní Olúwa Olódùmarè wí: Nígbà tí mo bá sọ ọ́ di ìlú ahoro, gẹ́gẹ́ bi àwọn ìlú tí a kò gbé inú wọn mọ́, àti nígbà tí èmi yóò mú ibú agbami Òkun wá sí orí rẹ, omi ńlá yóò sì bò ọ́,
ὅτι τάδε λέγει κύριος κύριος ὅταν δῶ σε πόλιν ἠρημωμένην ὡς τὰς πόλεις τὰς μὴ κατοικηθησομένας ἐν τῷ ἀναγαγεῖν με ἐπὶ σὲ τὴν ἄβυσσον καὶ κατακαλύψῃ σε ὕδωρ πολύ
20 nígbà tí èmi yóò mú ọ wálẹ̀ pẹ̀lú àwọn tí ó sọ̀kalẹ̀ lọ sínú ihò, pẹ̀lú àwọn ènìyàn àtijọ́. Èmi yóò sì gbé ọ lọ si bi ìsàlẹ̀, ní ibi ahoro àtijọ́, pẹ̀lú àwọn tí ó sọ̀kalẹ̀ lọ sínú ihò, ìwọ kì yóò sì padà gbé inú rẹ̀ mọ́, èmi yóò sì gbé ògo kalẹ̀ ní ilẹ̀ àwọn alààyè.
καὶ καταβιβάσω σε πρὸς τοὺς καταβαίνοντας εἰς βόθρον πρὸς λαὸν αἰῶνος καὶ κατοικιῶ σε εἰς βάθη τῆς γῆς ὡς ἔρημον αἰώνιον μετὰ καταβαινόντων εἰς βόθρον ὅπως μὴ κατοικηθῇς μηδὲ ἀνασταθῇς ἐπὶ γῆς ζωῆς
21 Èmi yóò ṣe ọ ní ẹ̀rù, ìwọ kì yóò sì ṣí mọ́. Bí a tilẹ̀ wá ọ, síbẹ̀ a kì yóò tún rí ọ mọ́, ní Olúwa Olódùmarè wí.”
ἀπώλειάν σε δώσω καὶ οὐχ ὑπάρξεις ἔτι εἰς τὸν αἰῶνα λέγει κύριος κύριος