< Ezekiel 23 >

1 Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá:
And there is a word of YHWH to me, saying, “Son of man,
2 “Ọmọ ènìyàn, obìnrin méjì wà, ọmọ ìyá kan náà.
Two women were daughters of one mother,
3 Wọn ń ṣe panṣágà ní Ejibiti, wọn ń ṣe panṣágà láti ìgbà èwe wọn. Ní ilẹ̀ yẹn ni wọn ti fi ọwọ́ pa ọyàn wọn, níbẹ̀ ni wọn sì fọwọ́ pa igbá àyà èwe wọn.
And they go whoring in Egypt, They have gone whoring in their youth, There they have bruised their breasts, And there they have dealt with the loves of their virginity.
4 Èyí ẹ̀gbọ́n ń jẹ́ Ohola, àbúrò rẹ̀ sì ń jẹ́ Oholiba. Tèmi ni wọ́n, wọ́n sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin. Ohola ni Samaria, Oholiba sì ni Jerusalẹmu.
And their names [are] Aholah the older, And Aholibah her sister, And they are Mine, and bear sons and daughters. As for their names—Samaria [is] Aholah, And Jerusalem [is] Aholibah.
5 “Ohola ń ṣe panṣágà nígbà tí ó sì jẹ́ tèmi; Ó sì ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ sí àwọn olólùfẹ́ rẹ̀, àwọn jagunjagun ará Asiria.
And Aholah goes whoring under Me, and she lusts on her lovers, on the neighboring Assyrians,
6 Aṣọ aláró ni a fi wọ̀ wọ́n, àwọn gómìnà àti àwọn balógun, gbogbo wọn jẹ́ ọ̀dọ́mọkùnrin arẹwà àwọn tí ń gun ẹṣin.
Clothed with blue—governors and prefects, All of them desirable young men, Horsemen, riding on horses,
7 O fi ara rẹ̀ fún gbajúmọ̀ ọkùnrin Asiria gẹ́gẹ́ bí panṣágà obìnrin, o fi òrìṣà gbogbo àwọn tí ó ní ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ sí i sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́,
And she gives her whoredoms on them, The choice of the sons of Asshur, All of them—even all on whom she lusted, She has been defiled by all their idols.
8 kò fi ìwà panṣágà tí ó ti bẹ̀rẹ̀, ni Ejibiti sílẹ̀, ní ìgbà èwe rẹ̀ àwọn ọkùnrin n bá a sùn, wọn fi ọwọ́ pa àyà èwe rẹ̀ lára wọn sì ń ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ sí i.
And she has not forsaken her whoredoms out of Egypt, For with her they lay in her youth, And they dealt with the loves of her virginity, And they pour out their whoredoms on her.
9 “Nítorí náà mo fi i sílẹ̀ fún àwọn olólùfẹ́ rẹ̀, ará Asiria, tí ó ní ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ sí i.
Therefore I have given her into the hand of her lovers, Into the hand of sons of Asshur on whom she lusted.
10 Wọ́n bọ́ ọ sí ìhòhò, wọ́n sì gba àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin rẹ̀ wọn sì pa wọn pẹ̀lú idà. Ó di ẹni ìfisọ̀rọ̀ sọ láàrín àwọn obìnrin wọ́n sì fi ìyà jẹ ẹ́.
They have uncovered her nakedness, They have taken her sons and her daughters, And they have slain her by sword, And she is a name for women, And they have done judgments with her.
11 “Àbúrò rẹ̀ Oholiba rí èyí, síbẹ̀ nínú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àti panṣágà rẹ̀, Ó ba ara rẹ jẹ́ ju ẹ̀gbọ́n rẹ̀ lọ.
And her sister Aholibah sees, And she makes her unhealthy love more corrupt than she, And her whoredoms than the whoredoms of her sister.
12 Òun náà ní ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ sí ará Asiria àwọn gómìnà àti àwọn balógun, jagunjagun nínú aṣọ ogun, àwọn tí ń gun ẹṣin, gbogbo àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin arẹwà.
She has lusted on sons of Asshur, Governors and prefects, Neighboring ones—clothed in perfection, Horsemen, riding on horses, All of them desirable young men.
13 Mo rí i pé òun náà ba ara rẹ̀ jẹ́; àwọn méjèèjì rìn ojú ọ̀nà kan náà.
And I see that she has been defiled, One way [is] to them both.
14 “Ṣùgbọ́n ó tẹ̀síwájú nínú ṣíṣe panṣágà. O ri àwòrán àwọn ọkùnrin lára ògiri, àwòrán àwọn ara Kaldea àwòrán pupa,
And she adds to her whoredoms, And she sees men carved on the wall, Pictures of Chaldeans, carved with vermillion,
15 pẹ̀lú ìgbànú ni ìdí wọn àti àwọn ìgbàrí ni orí wọn; gbogbo wọn dàbí olórí kẹ̀kẹ́ ogun Babeli ọmọ ìlú Kaldea.
Girded with a girdle on their loins, Dyed attire spread out on their heads, The appearance of rulers—all of them, The likeness of sons of Babylon, Chaldea is the land of their birth.
16 Ní kété tí ó rí wọn, ó ní ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ sí wọn, ó sì rán oníṣẹ́ sí wọn ni Kaldea.
And she lusts on them at the sight of her eyes, And sends messengers to them, to Chaldea.
17 Àwọn ará Babeli wá sọ́dọ̀ rẹ̀, lórí ibùsùn ìfẹ́, nínú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ wọn, wọ́n bà á jẹ́. Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n bà á jẹ́ tán, ó yípadà kúrò lọ́dọ̀ wọn ní ìtìjú.
And sons of Babylon come in to her, To the bed of loves, And they defile her with their whoredoms, And she is defiled with them, And her soul is alienated from them.
18 Nígbà tí ó tẹ̀síwájú nínú iṣẹ́ panṣágà rẹ̀ ní gbangba wọ́n sì tú u sí ìhòhò, mo yí padà kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ ní ìtìjú, gẹ́gẹ́ bí mo ti yípadà kúrò lọ́dọ̀ ẹ̀gbọ́n rẹ̀.
And she reveals her whoredoms, And she reveals her nakedness, And My soul is alienated from off her, As My soul was alienated from off her sister.
19 Síbẹ̀síbẹ̀ ó ń pọ̀ sí i nínú ìdàpọ̀ rẹ̀ bí ó ti ń rántí ìgbà èwe rẹ̀ tí ó jẹ́ panṣágà ní Ejibiti.
And she multiplies her whoredoms, To remember the days of her youth, When she went whoring in the land of Egypt.
20 Nítorí ó fẹ́ olùfẹ́ àwọn olùfẹ́ wọn ní àfẹ́jù, tí àwọn tí nǹkan ọkùnrin wọn dàbí ti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àwọn ẹni tí ìtújáde ara wọn dàbí ti àwọn ẹṣin.
And she lusts on their lovers, Whose flesh [is] the flesh of donkeys, And the emission of horses—their emission.
21 Báyìí ni ìwọ pe ìwà ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ìgbà èwe rẹ wá sí ìrántí, ní ti rírin orí ọmú rẹ láti ọwọ́ àwọn ará Ejibiti, fún ọmú ìgbà èwe rẹ.
You look after the wickedness of your youth, In dealing out of Egypt your loves, For the sake of the breasts of your youth.
22 “Nítorí náà, Oholiba, báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí, Èmi yóò gbé olólùfẹ́ rẹ dìde sí ọ, àwọn tí o kẹ́yìn si ní ìtìjú, èmi yóò sì mú wọn dojúkọ ọ́ ní gbogbo ọ̀nà
Therefore, O Aholibah, thus said Lord YHWH: Behold, I am stirring up your lovers against you, From whom your soul has been alienated, And have brought them in against you from all around.
23 àwọn ará Babeli àti gbogbo ara Kaldea àwọn ọkùnrin Pekodi àti Ṣoa àti Koa àti gbogbo ará Asiria pẹ̀lú wọn, àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin arẹwà, gbogbo àwọn gómìnà àti balógun, olórí oníkẹ̀kẹ́ ogun àti àwọn onípò gíga, gbogbo àwọn tí ń gun ẹṣin.
Sons of Babylon, and of all Chaldea, Pekod, and Shoa, and Koa, All the sons of Asshur with them, Desirable young men, governors and prefects, All of them—rulers and proclaimed ones, All of them riding on horses.
24 Wọn yóò wa dojúkọ ọ pẹ̀lú ohun ìjà, kẹ̀kẹ́ ogun pẹ̀lú kẹ̀kẹ́ ẹrù àti pẹ̀lú ìwọ́jọpọ̀ ènìyàn; wọn yóò mú ìdúró wọn lòdì sí ọ ní gbogbo ọ̀nà pẹ̀lú asà ńlá àti kékeré pẹ̀lú àṣíborí. Èmi yóò yí ọ padà sí wọn fun ìjìyà, wọn yóò sì fi ìyà jẹ ọ gẹ́gẹ́ bí wọn tí tó.
And they have come in against you, With arms, rider, and wheel, And with an assembly of peoples; Buckler, and shield, and helmet, They set against you all around, And I have set judgment before them, They have judged you in their judgments.
25 Èmi yóò sì dojú ìbínú owú mi kọ ọ́, wọn yóò sì fìyà jẹ ọ́ ní ìrunú. Wọ́n yóò gé àwọn imú àti àwọn etí yín kúrò, àwọn tí ó kù nínú yín yóò ti ipá idà ṣubú. Wọn yóò mú àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọkùnrin yín lọ, àwọn tí o kù nínú yín ni iná yóò jórun.
And I have set My jealousy against you, And they have dealt with you in fury, They turn aside your nose and your ears, And your posterity falls by sword, They take away your sons and your daughters, And your posterity is devoured by fire.
26 Wọn yóò sì kó àwọn aṣọ àti àwọn ohun ọ̀ṣọ́ iyebíye yín.
And they have stripped you of your garments, And have taken your beautiful jewels.
27 Èmi yóò sì fi òpin sí ìwà ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àti iṣẹ́ panṣágà tí ẹ bẹ̀rẹ̀ ni Ejibiti. Ẹ̀yin kò ní wo àwọn nǹkan wọ̀nyí pẹ̀lú ìpòùngbẹ, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò ní rántí Ejibiti mọ.
And I have caused your wickedness to cease from you, And your whoredoms out of the land of Egypt, And you do not lift up your eyes to them, And you do not remember Egypt again.
28 “Nítorí báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Èmi yóò fi ọ lé ọwọ́ àwọn tí ó kórìíra, lọ́wọ́ àwọn ẹni tí ọkàn rẹ ti ṣí kúrò.
For thus said Lord YHWH: Behold, I am giving you into a hand that you have hated, Into a hand from which you were alienated.
29 Wọn yóò fìyà jẹ ọ́ pẹ̀lú ìkórìíra, wọn yóò sì kó gbogbo ohun tí o ṣiṣẹ́ fún lọ. Wọn yóò fi ọ́ sílẹ̀ ní ìhòhò goloto, ìtìjú iṣẹ́ panṣágà rẹ ni yóò farahàn. Ìwà ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀ àti panṣágà rẹ.
And they have dealt with you in hatred, And they have taken all your labor, And they have left you naked and bare, And the nakedness of your whoredoms has been revealed, And the wickedness of your whoredoms.
30 Èmi yóò ṣe gbogbo nǹkan wọ̀nyí sí ọ, nítorí ìwọ ti bá àwọn kèfèrí ṣe àgbèrè lọ, o sì fi àwọn òrìṣà wọn ba ara rẹ̀ jẹ́.
To do these things to you, In your going whoring after nations, Because you have been defiled with their idols,
31 Ìwọ ti rin ọ̀nà ti ẹ̀gbọ́n rẹ rìn, Èmi yóò sì fi ago rẹ̀ lé ọ lọ́wọ́.
You have walked in the way of your sister, And I have given her cup into your hand.
32 “Èyí yìí ní ohun ti Olúwa Olódùmarè wí: “Ìwọ yóò mu nínú ago ẹ̀gbọ́n rẹ, ago tí ó tóbi tí ó sì jinnú: yóò mú ìfiṣẹ̀sín àti ìfiṣe ẹlẹ́yà wá, nítorí tí ago náà gba nǹkan púpọ̀.
Thus said Lord YHWH: You drink the cup of your sister, The deep and the wide one (You are for laughter and for scorn), Abundant to contain.
33 Ìwọ yóò mu àmupara àti ìbànújẹ́, ago ìparun àti ìsọdahoro ago ẹ̀gbọ́n rẹ Samaria.
You are filled with drunkenness and sorrow, A cup of astonishment and desolation, The cup of your sister Samaria.
34 Ìwọ yóò mú un ni àmugbẹ; ìwọ yóò sì fọ sí wẹ́wẹ́ ìwọ yóò sì fa ọmú rẹ̀ ya. Èmi ti sọ̀rọ̀ ni Olúwa Olódùmarè wí.
And you have drunk it, and have drained [it], And you gnaw its earthen ware, And you pluck off your own breasts, For I have spoken, A declaration of Lord YHWH,
35 “Nítorí náà báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí: Níwọ́n bí ìwọ ti gbàgbé mi, tí ìwọ sì ti fi mi sí ẹ̀yìn rẹ, ìwọ gbọdọ̀ gba àbájáde ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àti panṣágà rẹ.”
Therefore, thus said Lord YHWH: Because you have forgotten Me, And you cast Me behind your back, Even you also bear your wickedness and your whoredoms.”
36 Olúwa sọ fún mi pé: “Ọmọ ènìyàn, ń jẹ́ ìwọ yóò ṣe ìdájọ́ Ohola àti Oholiba? Nítorí náà dojúkọ wọn nípa ìkórìíra tí wọn ń ṣe,
And YHWH says to me, “Son of man, Do you judge Aholah and Aholibah? Then declare their abominations to them.
37 nítorí wọn ti dá ẹ̀ṣẹ̀ panṣágà ẹ̀jẹ̀ sì wà ní ọwọ́ wọn. Wọn dá ẹ̀ṣẹ̀ panṣágà pẹ̀lú àwọn òrìṣà wọn; kódà wọ́n fi àwọn ọmọ wọn tí wọn bí fún ni ṣe ìrúbọ, gẹ́gẹ́ bí oúnjẹ fún wọn.
For they have committed adultery, And blood [is] in their hands, They committed adultery with their idols, And also their sons whom they bore to Me, They caused to pass over to them for food.
38 Bákan náà ni wọ́n ti ṣe èyí náà sí mi. Ní àkókò kan náà wọn ba ibi mímọ́ mi jẹ́, wọ́n sì lo ọjọ́ ìsinmi mi ní àìmọ́.
Again, they have done this to Me, They defiled My sanctuary in that day, And they have defiled My Sabbaths.
39 Ní ọjọ́ náà gan an wọ́n fi àwọn ọmọ wọn rú ẹbọ sí àwọn òrìṣà, wọn wọ ibi mímọ́ mi lọ wọn sì lò ó ní ìlòkulò. Ìyẹn ní wọn ṣe ní ilé mi.
And in their slaughtering their sons to their idols They also come into My sanctuary in that day to defile it, And behold, thus they have done in the midst of My house,
40 “Wọn tilẹ̀ rán oníṣẹ́ sí àwọn ènìyàn tí wọ́n wá láti ọ̀nà jíjìn, nígbà tí wọ́n dé, ìwọ wẹ ara rẹ fún wọn, ìwọ kún ojú rẹ, ìwọ sì fi ọ̀ṣọ́ iyebíye sára.
And also that they send to men coming from afar, To whom a messenger is sent, And behold, they have come in for whom you have washed, Painted your eyes, and put on adornment.
41 Ìwọ jókòó lórí ibùsùn ti o lẹ́wà, pẹ̀lú tábìlì tí a tẹ́ ní iwájú rẹ lórí, èyí tí o gbé tùràrí àti òróró tí ó jẹ́ tèmi kà.
And you have sat on a couch of honor, And a table arrayed before it, And placed My incense and My oil on it.
42 “Ariwo ìjọ ènìyàn tí kò bìkítà wà ní àyíká rẹ̀; a mú àwọn ara Sabeani láti aginjù pẹ̀lú àwọn ọkùnrin láti ara àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn aláìníláárí, wọ́n sì mú àwọn ẹ̀gbà ọrùn ọwọ́ sí àwọn ọwọ́ obìnrin náà àti ẹ̀gbọ́n rẹ̀, adé dáradára sì wà ní orí wọn.
And the voice of a multitude at ease [is] with her, And Sabeans from the wilderness are brought in to men of the common people, And they put bracelets on their hands, And a beautiful crown on their heads.
43 Lẹ́yìn náà mo sọ̀rọ̀ nípa èyí tí ó lo ara rẹ̀ sá nípa panṣágà ṣíṣe, ‘Nísinsin yìí jẹ kí wọn lo o bí panṣágà, nítorí gbogbo ohun tí ó jẹ́ nìyẹn.’
And I say of the worn-out one in adulteries, Now they commit her whoredoms—she also!
44 Wọn ba sùn bí ọkùnrin ti bá panṣágà sùn, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe sùn pẹ̀lú obìnrin onífẹ̀kúfẹ̀ẹ́, Ohola àti Oholiba.
And they come in to her, As the coming in to a whorish woman, So they have come in to Aholah, And to Aholibah—the wicked women.
45 Ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin olódodo yóò pàṣẹ pé kí wọ́n fi ìyà jẹ àwọn obìnrin tí ó dá ẹ̀ṣẹ̀ àgbèrè tí ó sì ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ nítorí pé panṣágà ni wọ́n ẹ̀jẹ̀ sì wà ní ọwọ́ wọn.
As for righteous men, they judge them with the judgment of adulteresses, And the judgment of women shedding blood, For they [are] adulteresses, And blood [is] in their hands.
46 “Èyí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: Mú àgbájọ àwọn ènìyànkénìyàn wá sọ́dọ̀ wọn ki ó sì fi wọn lé ọwọ́ ìpayà àti ìkógun.
For thus said Lord YHWH: Bring up an assembly against them, And give them to trembling and to spoiling.
47 Àwọn ènìyànkénìyàn náà yóò sọ wọ́n ni òkúta, yóò sì gé wọn lulẹ̀ pẹ̀lú idà wọn; wọn ó sì pa àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin wọn, wọ́n ó sì jó àwọn ilé wọn kanlẹ̀.”
And they have cast the stone of the assembly at them, And cut them with their swords, They slay their sons and their daughters, And they burn their houses with fire.
48 “Èmi yóò sì fi òpin sí ìwà ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ni ilẹ̀ náà, kí gbogbo àwọn obìnrin le gba ìkìlọ̀ kí wọn kí ó ma sì ṣe fi ara wé ọ.
And I have caused wickedness to cease from the land, And all the women have been instructed, And they do not do according to your wickedness.
49 Ìwọ yóò sì jìyà fún ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ, ìwọ yóò sì gba àbájáde àwọn ẹ̀ṣẹ̀ panṣágà tí o dá. Nígbà náà ìwọ yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa Olódùmarè.”
And they have put your wickedness on you, And you bear the sins of your idols, And you have known that I [am] Lord YHWH!”

< Ezekiel 23 >