< Ezekiel 21 >

1 Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ mi wá:
ויהי דבר יהוה אלי לאמר׃
2 “Ọmọ ènìyàn, kọ ojú rẹ sí ìhà Jerusalẹmu, kí o sì wàásù lòdì sí ibi mímọ́. Sọ àsọtẹ́lẹ̀ sí ilẹ̀ Israẹli.
בן אדם שים פניך אל ירושלם והטף אל מקדשים והנבא אל אדמת ישראל׃
3 Kí ó sì sọ fún un pe, ‘Èyí yìí ni Olúwa wí, Èmi lòdì sí ọ. Èmi yóò fa idà mi yọ kúrò nínú àkọ̀ rẹ̀, Èmi yóò sì ké olódodo àti ènìyàn búburú kúrò ni àárín yín.
ואמרת לאדמת ישראל כה אמר יהוה הנני אליך והוצאתי חרבי מתערה והכרתי ממך צדיק ורשע׃
4 Nítorí pé, èmi yóò ké olódodo àti olùṣe búburú kúrò, idà mi yóò jáde láti inú àkọ̀ rẹ̀ lòdì sí gbogbo ènìyàn láti gúúsù títí dé àríwá.
יען אשר הכרתי ממך צדיק ורשע לכן תצא חרבי מתערה אל כל בשר מנגב צפון׃
5 Nígbà náà gbogbo ènìyàn yóò mọ̀ pé, Èmi Olúwa ti yọ idà mi kúrò nínú àkọ̀ rẹ̀; kì yóò sì padà sínú rẹ̀ mọ́.’
וידעו כל בשר כי אני יהוה הוצאתי חרבי מתערה לא תשוב עוד׃
6 “Nítorí náà, mí ìmí ẹ̀dùn ìwọ ọmọ ènìyàn! Mí ìmí ẹ̀dùn pẹ̀lú ọkàn ìbànújẹ́ àti ẹ̀dùn ọkàn kíkorò ní iwájú wọn.
ואתה בן אדם האנח בשברון מתנים ובמרירות תאנח לעיניהם׃
7 Bí wọ́n bá sì bi ọ́, wí pé, ‘Kí ni ó dé tí ìwọ fi ń mí ìmí ẹ̀dùn?’ Ìwọ yóò wí pé, ‘Nítorí ìròyìn tí ó ń bẹ. Gbogbo ọkàn ni yóò yọ́, gbogbo ọwọ́ ni yóò sì di aláìlera; gbogbo ọkàn ní yóò dákú, gbogbo eékún ni yóò sì di aláìlera bí omi?’ Ó ń bọ̀! Yóò sì wa sí ìmúṣẹ dandan, ni Olúwa Olódùmarè wí.”
והיה כי יאמרו אליך על מה אתה נאנח ואמרת אל שמועה כי באה ונמס כל לב ורפו כל ידים וכהתה כל רוח וכל ברכים תלכנה מים הנה באה ונהיתה נאם אדני יהוה׃
8 Ọ̀rọ̀ Olúwa si tún tọ̀ mí wá pé:
ויהי דבר יהוה אלי לאמר׃
9 “Ọmọ ènìyàn, sọtẹ́lẹ̀ wí pé, èyí yìí ní Olúwa wí pé, “‘Idà kan, idà kan, tí a pọ́n, tí a sì dán pẹ̀lú,
בן אדם הנבא ואמרת כה אמר אדני אמר חרב חרב הוחדה וגם מרוטה׃
10 a pọ́n láti pa ènìyàn púpọ̀, a dán an láti máa kọ mọ̀nà! “‘Àwa o ha máa ṣe àríyá ọ̀gọ ọmọ mi? Idà gán gbogbo irú igi bẹ́ẹ̀.
למען טבח טבח הוחדה למען היה לה ברק מרטה או נשיש שבט בני מאסת כל עץ׃
11 “‘Idà ní a yàn láti pọ́n, kí ó lè ṣe é gbámú; a pọ́n ọn, a sì dán an, ó ṣetán fún ọwọ́ àwọn apani.
ויתן אתה למרטה לתפש בכף היא הוחדה חרב והיא מרטה לתת אותה ביד הורג׃
12 Sọkún síta, kí ó sì pohùnréré ẹ̀kún, ọmọ ènìyàn, nítorí yóò wá sórí àwọn ènìyàn mi; yóò wá sórí gbogbo ọmọ-aládé Israẹli ìbẹ̀rù ńlá yóò wá sórí àwọn ènìyàn mi nítorí idà náà; nítorí náà lu oókan àyà rẹ.
זעק והילל בן אדם כי היא היתה בעמי היא בכל נשיאי ישראל מגורי אל חרב היו את עמי לכן ספק אל ירך׃
13 “‘Ìdánwò yóò dé dandan. Tí ọ̀pá aládé Juda èyí tí idà kẹ́gàn, kò bá tẹ̀síwájú mọ́ ń kọ́? Ni Olúwa Olódùmarè wí.’
כי בחן ומה אם גם שבט מאסת לא יהיה נאם אדני יהוה׃
14 “Nítorí náà, ọmọ ènìyàn, sọtẹ́lẹ̀ kí ó sì fi ọwọ́ lu ọwọ́. Jẹ́ kí idà lu ara wọn lẹ́ẹ̀méjì, kódà ní ẹ̀ẹ̀mẹta. Ó jẹ́ idà fún ìpànìyàn idà fún ìpànìyàn lọ́pọ̀lọ́pọ̀, tí yóò sé wọn mọ́ níhìn-ín àti lọ́hùnnún.
ואתה בן אדם הנבא והך כף אל כף ותכפל חרב שלישתה חרב חללים היא חרב חלל הגדול החדרת להם׃
15 Kí ọkàn kí ó lè yọ́ kí àwọn tí ó ṣubú le pọ̀, mo ti gbé idà sí gbogbo bodè fún ìparun. Háà! A mú kí ó kọ bí ìmọ̀nàmọ́ná, a gbá a mú fún ìparun.
למען למוג לב והרבה המכשלים על כל שעריהם נתתי אבחת חרב אח עשויה לברק מעטה לטבח׃
16 Ìwọ idà, jà sí ọ̀tún kí o sì jà sí òsì lọ ibikíbi tí ẹnu rẹ bá dojúkọ.
התאחדי הימיני השימי השמילי אנה פניך מעדות׃
17 Èmi gan an yóò pàtẹ́wọ́ ìbínú mi yóò sì rẹlẹ̀. Èmi Olúwa ti sọ̀rọ̀.”
וגם אני אכה כפי אל כפי והניחתי חמתי אני יהוה דברתי׃
18 Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ mi wá:
ויהי דבר יהוה אלי לאמר׃
19 “Ọmọ ènìyàn la ọ̀nà méjì fún idà ọba Babeli láti gbà, kí méjèèjì bẹ̀rẹ̀ láti ìlú kan náà. Ṣe àmì sí ìkóríta ọ̀nà tí ó lọ sí ìlú náà.
ואתה בן אדם שים לך שנים דרכים לבוא חרב מלך בבל מארץ אחד יצאו שניהם ויד ברא בראש דרך עיר ברא׃
20 La ọ̀nà kan fún idà láti wá kọlu Rabba ti àwọn ará Ammoni kí òmíràn kọlu Juda, kí ó sì kọlu Jerusalẹmu ìlú olódi.
דרך תשים לבוא חרב את רבת בני עמון ואת יהודה בירושלם בצורה׃
21 Nítorí ọba Babeli yóò dúró ni ìyànà ní ojú ọ̀nà, ní ìkóríta, láti máa lo àfọ̀ṣẹ. Yóò fi ọfà di ìbò, yóò béèrè lọ́wọ́ àwọn òrìṣà rẹ̀, òun yóò ṣe àyẹ̀wò ẹ̀dọ̀.
כי עמד מלך בבל אל אם הדרך בראש שני הדרכים לקסם קסם קלקל בחצים שאל בתרפים ראה בכבד׃
22 Nínú ọwọ́ ọ̀tún rẹ ni ìbò Jerusalẹmu yóò ti wá, ní ibi tí yóò ti gbé afárá kalẹ̀, láti pàṣẹ fún àwọn apànìyàn, láti mú ki wọn hó ìhó ogun láti gbé òòlù dí ẹnu-ọ̀nà ibodè, láti mọ odi, àti láti kọ́ ilé ìṣọ́.
בימינו היה הקסם ירושלם לשום כרים לפתח פה ברצח להרים קול בתרועה לשום כרים על שערים לשפך סללה לבנות דיק׃
23 Àfọ̀ṣẹ náà yóò dàbí àmì èké sí àwọn tí ó ti búra ìtẹríba fún un, ṣùgbọ́n òun yóò ran wọn létí ẹbí wọn yóò sì mú wọn lọ sí ìgbèkùn.
והיה להם כקסום שוא בעיניהם שבעי שבעות להם והוא מזכיר עון להתפש׃
24 “Nítorí náà èyí ní ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: ‘Nítorí ti ẹ̀yin ti mú ẹ̀bi yín wá sí ìrántí nípa ìṣọ̀tẹ̀ ní gbangba, ní ṣíṣe àfihàn àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ nínú gbogbo ohun tí ó ṣe, nítorí tí ẹ̀yin ti ṣe èyí, a yóò mú yín ní ìgbèkùn.
לכן כה אמר אדני יהוה יען הזכרכם עונכם בהגלות פשעיכם להראות חטאותיכם בכל עלילותיכם יען הזכרכם בכף תתפשו׃
25 “‘Ìwọ aláìmọ́ àti ẹni búburú ọmọ-aládé Israẹli, ẹni ti ọjọ́ rẹ̀ ti dé, ẹni tí àsìkò ìjìyà rẹ̀ ti dé góńgó,
ואתה חלל רשע נשיא ישראל אשר בא יומו בעת עון קץ׃
26 èyí yìí ní ohun tí Olúwa Olódùmarè wí, tú ìwérí kúrò kí o sì gbé adé kúrò. Kò ní rí bí ti tẹ́lẹ̀, ẹni ìgbéga ni a yóò sì rẹ̀ sílẹ̀.
כה אמר אדני יהוה הסיר המצנפת והרים העטרה זאת לא זאת השפלה הגבה והגבה השפיל׃
27 Ìparun! Ìparun! Èmi yóò ṣé e ni ìparun! Kì yóò padà bọ̀ sípò bí kò ṣe pé tí ó bá wá sí ọ̀dọ̀ ẹni tí ó ní ẹ̀tọ́ láti ni in; òun ni èmi yóò fi fún.’
עוה עוה עוה אשימנה גם זאת לא היה עד בא אשר לו המשפט ונתתיו׃
28 “Àti ìwọ, ọmọ ènìyàn sọtẹ́lẹ̀ kí ó sì wí pé, ‘Èyí yìí ní ohun tí Olúwa Olódùmarè wí nípa àwọn ará Ammoni àti àbùkù wọn: “‘Idà kan idà kan tí á fa yọ fún ìpànìyàn tí a dán láti fi ènìyàn ṣòfò àti láti kọ bí ìmọ̀nàmọ́ná!
ואתה בן אדם הנבא ואמרת כה אמר אדני יהוה אל בני עמון ואל חרפתם ואמרת חרב חרב פתוחה לטבח מרוטה להכיל למען ברק׃
29 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a rí èké nípa yín àti àfọ̀ṣẹ èké nípa yín a yóò gbé e lé àwọn ọrùn ènìyàn búburú ti a ó pa, àwọn tí ọjọ́ wọn ti dé, àwọn tí ọjọ́ ìjìyà wọn ti dé góńgó.
בחזות לך שוא בקסם לך כזב לתת אותך אל צוארי חללי רשעים אשר בא יומם בעת עון קץ׃
30 “‘Dá idà padà sínú àkọ̀ rẹ̀. Níbi tí a gbé ṣẹ̀dá yín, ní ibi tí ẹ̀yin ti ṣẹ̀ wá.
השב אל תערה במקום אשר נבראת בארץ מכרותיך אשפט אתך׃
31 Níbẹ̀ ni èmi yóò ti ṣe ìdájọ́ yín, èmi o sì fi èémí ìbínú gbígbóná mi bá yín jà.
ושפכתי עליך זעמי באש עברתי אפיח עליך ונתתיך ביד אנשים בערים חרשי משחית׃
32 Ẹ̀yin yóò jẹ́ èpò fún iná náà, a yóò ta ẹ̀jẹ̀ yin sórí ilẹ̀ yín, a kì yóò rántí yín mọ́; nítorí Èmi Olúwa ní ó ti wí bẹ́ẹ̀.’”
לאש תהיה לאכלה דמך יהיה בתוך הארץ לא תזכרי כי אני יהוה דברתי׃

< Ezekiel 21 >