< Ezekiel 20 >
1 Ní ọjọ́ kẹwàá, oṣù karùn-ún ọdún keje, ní díẹ̀ nínú àwọn àgbàgbà Israẹli wá wádìí lọ́wọ́ Olúwa, wọn jókòó níwájú mi.
第七年五月初十日,有以色列的幾個長老來求問耶和華,坐在我面前。
2 Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé,
耶和華的話臨到我說:
3 “Ọmọ ènìyàn, sọ fún àwọn àgbàgbà Israẹli, kì ó sì wí fún wọn pé, ‘Báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí, ṣe ki ẹ lè wádìí lọ́dọ̀ mi ni ẹ ṣe wá? Bí mo ti wà láààyè, ní Olúwa Olódùmarè wí, Èmi kì yóò gbà kí ẹ wádìí lọ́dọ̀ mi.’
「人子啊,你要告訴以色列的長老說,主耶和華如此說:你們來是求問我嗎?主耶和華說:我指着我的永生起誓,我必不被你們求問。
4 “Ìwọ fẹ́ dájọ́ wọn bí? Ìwọ fẹ́ dájọ́ wọn bí ọmọ ènìyàn? Nítorí náà fi gbogbo ìwà ìríra baba wọn kò wọ́n lójú,
人子啊,你要審問審問他們嗎?你當使他們知道他們列祖那些可憎的事,
5 kí ó sì sọ fún wọn pé, ‘Báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí, ní ọjọ́ tí mo yàn Israẹli, mo gbé ọwọ́ mi sókè nínú ìbúra sí àwọn ọmọ ilé Jakọbu, mo sì fi ara mi hàn wọn ní Ejibiti, mo gbé ọwọ́ mi sókè nínú ẹ̀jẹ́ wí pé, “Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.”
對他們說,主耶和華如此說:當日我揀選以色列,向雅各家的後裔起誓,在埃及地將自己向他們顯現,說:我是耶和華-你們的上帝。
6 Ní ọjọ́ náà mo lọ búra fún wọn pé, èmi yóò mú wọn jáde kúrò ni ilẹ̀ Ejibiti lọ sí ilẹ̀ ti mo ti wá sílẹ̀ fún wọn, ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti oyin, ilẹ̀ tí ó lẹ́wà jùlọ láàrín àwọn ilẹ̀ yòókù.
那日我向他們起誓,必領他們出埃及地,到我為他們察看的流奶與蜜之地;那地在萬國中是有榮耀的。
7 Mo sì wí fún wọn pé, “Kí olúkúlùkù nínú yín gbé ìríra ojú rẹ̀ kúrò, kí ẹ sì má bá sọ ara yín di àìmọ́ pẹ̀lú àwọn òrìṣà Ejibiti, èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.”
我對他們說,你們各人要拋棄眼所喜愛那可憎之物,不可因埃及的偶像玷污自己。我是耶和華-你們的上帝。
8 “‘Ṣùgbọ́n wọn ṣọ̀tẹ̀ sí mi wọn kò sì gbọ́rọ̀, wọn kò gbé àwòrán ìríra tí wọ́n dojúkọ kúrò níwájú wọn bẹ́ẹ̀ ni wọn kò si kọ̀ àwọn òrìṣà Ejibiti sílẹ̀, torí náà mo sọ pé èmi yóò tú ìbínú gbígbóná mi lé wọn lórí, èmi yóò sì jẹ́ kí ìbínú mi sẹ̀ lórí wọn ní ilẹ̀ Ejibiti.
他們卻悖逆我,不肯聽從我,不拋棄他們眼所喜愛那可憎之物,不離棄埃及的偶像。 「我就說,我要將我的忿怒傾在他們身上,在埃及地向他們成就我怒中所定的。
9 Ṣùgbọ́n nítorí orúkọ mi, mo ṣe ohun tí kò ní jẹ́ kí orúkọ mi bàjẹ́ lójú àwọn orílẹ̀-èdè tí wọn ń gbé láàrín wọn, lójú àwọn ẹni tí mo ti fi ara hàn fún ara Israẹli nípa mímú wọn jáde ní ilẹ̀ Ejibiti.
我卻為我名的緣故沒有這樣行,免得我名在他們所住的列國人眼前被褻瀆;我領他們出埃及地,在這列國人的眼前將自己向他們顯現。
10 Nítorí náà, mo mú wọn jáde ní ilẹ̀ Ejibiti mo sì mú wọn wá sínú aginjù.
這樣,我就使他們出埃及地,領他們到曠野,
11 Mo sì fún wọn ni òfin mi, mo sì fi àwọn òfin mi hàn wọ́n; nítorí pé ẹni tó bá ṣe wọ́n yóò yè nípa wọn.
將我的律例賜給他們,將我的典章指示他們;人若遵行就必因此活着。
12 Bẹ́ẹ̀ ni mo fún wọn ní ọjọ́ ìsinmi gẹ́gẹ́ bí àmì láàrín àwọn àti èmi, kí wọn lè mọ̀ pé èmi ni Olúwa tó sọ wọn di mímọ́.
又將我的安息日賜給他們,好在我與他們中間為證據,使他們知道我-耶和華是叫他們成為聖的。
13 “‘Síbẹ̀; ilé Israẹli ṣọ̀tẹ̀ sí mí nínú aginjù. Wọn kò tẹ̀lé àṣẹ mi, wọn sì kọ àwọn òfin mi sílẹ̀ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹni tó bá pa á mọ́ yóò yè nínú rẹ̀. Wọn sì sọ ọjọ́ ìsinmi mi di aláìmọ́ lọ́pọ̀lọ́pọ̀. Nítorí náà, mo sọ pé èmi yóò tú ìbínú gbígbóná mi sórí wọn, èmi yóò sì pa wọ́n run nínú aginjù.
以色列家卻在曠野悖逆我,不順從我的律例,厭棄我的典章(人若遵行就必因此活着),大大干犯我的安息日。 「我就說,要在曠野將我的忿怒傾在他們身上,滅絕他們。
14 Ṣùgbọ́n nítorí orúkọ mi, mo ṣe ohun tí kò ní mú kí orúkọ mi bàjẹ́ lójú àwọn orílẹ̀-èdè tí mo kó wọn jáde.
我卻為我名的緣故,沒有這樣行,免得我的名在我領他們出埃及的列國人眼前被褻瀆。
15 Nítorí náà, mo tún gbọ́wọ́ mi sókè ní ìbúra fún wọn nínú aginjù pé, èmi kì yóò mú wọn dé ilẹ̀ tí mo fi fún wọn—ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti oyin, ilẹ̀ tí ó lẹ́wà jùlọ láàrín àwọn ilẹ̀ yòókù.
並且我在曠野向他們起誓,必不領他們進入我所賜給他們流奶與蜜之地(那地在萬國中是有榮耀的);
16 Nítorí pé, wọn kọ òfin mi sílẹ̀, wọn kò sì tẹ̀lé àṣẹ mi, wọn sọ ọjọ́ ìsinmi mi dí aláìmọ́. Nítorí pé tọkàntọkàn ni wọn ń tẹ̀lé òrìṣà wọn.
因為他們厭棄我的典章,不順從我的律例,干犯我的安息日,他們的心隨從自己的偶像。
17 Síbẹ̀síbẹ̀ mo wò wọ́n pẹ̀lú àánú, ń kò sì pa wọ́n run tàbí kí òpin dé bá wọn nínú aginjù.
雖然如此,我眼仍顧惜他們,不毀滅他們,不在曠野將他們滅絕淨盡。
18 Ṣùgbọ́n mo sọ fún àwọn ọmọ wọn nínú aginjù pé, “Ẹ má ṣe rìn ní ìlànà àwọn baba yín, ẹ má ṣe pa òfin wọn mọ́, ẹ má ṣe bá ara yín jẹ́ pẹ̀lú òrìṣà wọn.
「我在曠野對他們的兒女說:不要遵行你們父親的律例,不要謹守他們的惡規,也不要因他們的偶像玷污自己。
19 Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín, ẹ tẹ̀lé àṣẹ mi, kí ó sì pa òfin mi mọ́.
我是耶和華-你們的上帝,你們要順從我的律例,謹守遵行我的典章,
20 Ẹ ya ọjọ́ ìsinmi mi sí mímọ́ kí ó lè jẹ́ àmì láàrín wa, ki ẹ lè mọ̀ pé èmi ní Olúwa Ọlọ́run yín.”
且以我的安息日為聖。這日在我與你們中間為證據,使你們知道我是耶和華-你們的上帝。
21 “‘Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ náà ṣọ̀tẹ̀ sí mi. Wọn kò tẹ̀lé àṣẹ mi, wọn kò sì pa òfin mi mọ́ bí o tilẹ̀ jẹ́ pé ẹni tó bá tẹ̀lé àwọn òfin yìí, yóò yè nínú rẹ̀, wọ́n sì tún sọ ọjọ́ ìsinmi mi di aláìmọ́. Nítorí náà, mo sọ pé èmi yóò tú ìbínú mi lórí wọn, Èmi yóò sì mú kí ìbínú gbígbóná mi wá sórí wọn ni aginjù.
只是他們的兒女悖逆我,不順從我的律例,也不謹守遵行我的典章(人若遵行就必因此活着),干犯我的安息日。 「我就說,要將我的忿怒傾在他們身上,在曠野向他們成就我怒中所定的。
22 Síbẹ̀síbẹ̀ mo dáwọ́ dúró, nítorí orúkọ mi, mo sì ṣe ohun tí kò ní ba orúkọ mi jẹ́ lójú àwọn orílẹ̀-èdè ti mo kó wọn jáde lójú wọn.
雖然如此,我卻為我名的緣故縮手沒有這樣行,免得我的名在我領他們出埃及的列國人眼前被褻瀆。
23 Bẹ́ẹ̀ ni pẹ̀lú ọwọ́ ti mo gbé sókè sí wọn, mo búra fún wọn nínú aginjù pé èmi yóò tú wọn ka sì àárín àwọn orílẹ̀-èdè, èmi yóò sì fọ́n wọn káàkiri ilẹ̀ gbogbo,
並且我在曠野向他們起誓,必將他們分散在列國,四散在列邦;
24 nítorí pé wọn kò pa òfin mi mọ́, wọn sì tún kọ àṣẹ mi sílẹ̀, wọn tún sọ ọjọ́ ìsinmi mi di aláìmọ́. Ojú wọn sì wà ní ara òrìṣà baba wọn.
因為他們不遵行我的典章,竟厭棄我的律例,干犯我的安息日,眼目仰望他們父親的偶像。
25 Èmi náà sì fi wọn fún ìlànà tí kò dára àti òfin tí wọn kò le e yè nípa rẹ̀;
我也任他們遵行不美的律例,謹守不能使人活着的惡規。
26 mo jẹ́ kí ó sọ wọn di aláìmọ́ nípa ẹ̀bùn nípa fífi àkọ́bí ọmọ wọn rú ẹbọ sísun, àkọ́bí wọn la iná kọjá, kí èmi sọ wọ́n di ahoro, kí wọn le mọ̀ pé èmi ni Olúwa.’
因他們將一切頭生的經火,我就任憑他們在這供獻的事上玷污自己,好叫他們淒涼,使他們知道我是耶和華。
27 “Nítorí náà, Ọmọ ènìyàn, sọ fún ilé Israẹli kí ó sì wí fún wọn pé, ‘Èyí ní ohun ti Olúwa Olódùmarè wí, nínú èyí tí baba yín ti sọ̀rọ̀-òdì sí mi, nípa kíkọ̀ mí sílẹ̀.
「人子啊,你要告訴以色列家說,主耶和華如此說:你們的列祖在得罪我的事上褻瀆我;
28 Nítorí nígbà tí mo mú wọn dé ilẹ̀ náà, tí mo gbé ọwọ́ mi sókè láti fi í fún wọn, nígbà náà ni wọ́n rí olúkúlùkù òkè gíga, àti gbogbo igi bíbò, wọ́n sì rú ẹbọ wọn níbẹ̀, wọ́n sì gbé ìmúnibínú ọrẹ wọ́n kalẹ̀ níbẹ̀; níbẹ̀ pẹ̀lú ni wọ́n ṣe òórùn dídùn wọn, wọ́n sì ta ohun ọrẹ mímu sílẹ̀ níbẹ̀.
因為我領他們到了我起誓應許賜給他們的地,他們看見各高山、各茂密樹,就在那裏獻祭,奉上惹我發怒的供物,也在那裏焚燒馨香的祭牲,並澆上奠祭。
29 Nígbà náà ni mo wí fún wọn pé, kí ní ibi gíga tí ẹ̀yin lọ yìí?’” (Orúkọ rẹ̀ ni a sì ń pè ní Bama di òní yìí.)
我就對他們說:你們所上的那高處叫甚麼呢?(那高處的名字叫巴麻直到今日。)
30 “Nítorí náà sọ fún ilé Israẹli pé, ‘Èyí ní ohun tí Olúwa Olódùmarè wí, ṣé o fẹ́ ba ara rẹ jẹ́ bi àwọn baba rẹ ṣe ṣe, tiwọn ń ṣe àgbèrè nípa títẹ̀lé àwọn àwòrán ìríra?
所以你要對以色列家說,主耶和華如此說:你們仍照你們列祖所行的玷污自己嗎?仍照他們可憎的事行邪淫嗎?
31 Nígbà tí ẹ̀yin bá san ọrẹ yìí, ìrúbọ ọmọkùnrin ọmọ yín, tí ẹ mú ọmọ yin la iná kọjá, ẹ̀yin ń tẹ̀síwájú láti ba ara yín jẹ́ pẹ̀lú àwọn òrìṣà yín títí di òní yìí, ẹ̀yin yóò ha jẹ wádìí lọ́dọ̀ mi, ìwọ ilé Israẹli? Bí mo ti wà láààyè, ní Olúwa Olódùmarè wí, Èmi ki yóò jẹ́ kí ẹ wádìí lọ́dọ̀ mi.
你們奉上供物使你們兒子經火的時候,仍將一切偶像玷污自己,直到今日嗎?以色列家啊,我豈被你們求問嗎?主耶和華說:我指着我的永生起誓,我必不被你們求問。
32 “‘Ẹ̀yin wí pé, “Àwa fẹ́ dàbí àwọn orílẹ̀-èdè yòókù, bí àwọn ènìyàn ayé, tó ń bọ igi àti òkúta.” Ṣùgbọ́n ohun ti ẹ ni lọ́kàn kò ní ṣẹ rárá.
「你們說:我們要像外邦人和列國的宗族一樣,去事奉木頭與石頭。你們所起的這心意萬不能成就。」
33 Bí mo ti wà láààyè, ní Olúwa Olódùmarè wí, Èmi yóò jẹ ọba lórí yín pẹ̀lú ọwọ́ agbára tí èmi yóò nà jáde pẹ̀lú ìtújáde ìbínú gbígbóná mi.
主耶和華說:「我指着我的永生起誓,我總要作王,用大能的手和伸出來的膀臂,並傾出來的忿怒,治理你們。
34 Èmi yóò si mú yín jáde kúrò láàrín àwọn ènìyàn, èmi yóò sì ṣà yín jọ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè tí a fọ́n yín sí pẹ̀lú ọwọ́ agbára àti apá nínà tí èmi yóò nà jáde àti pẹ̀lú ìtújáde ìbínú gbígbóná ni.
我必用大能的手和伸出來的膀臂,並傾出來的忿怒,將你們從萬民中領出來,從分散的列國內聚集你們。
35 Èmi yóò si mú yín wá sí aginjù àwọn orílẹ̀-èdè, níbẹ̀ ni ojúkójú ni èmi yóò ṣe ìdájọ́ lé e yín lórí.
我必帶你們到外邦人的曠野,在那裏當面刑罰你們。
36 Bí mo ṣe ṣe ìdájọ́ àwọn baba yín nínú aginjù nílẹ̀ Ejibiti, bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò ṣe ìdájọ́ yín ní Olúwa Olódùmarè wí.
我怎樣在埃及地的曠野刑罰你們的列祖,也必照樣刑罰你們。這是主耶和華說的。
37 Èmi yóò kíyèsi i yín bí mo ti mú un yín kọjá lábẹ́ ọ̀pá, èmi yóò sì mú yín wá sí abẹ́ ìdè májẹ̀mú.
我必使你們從杖下經過,使你們被約拘束。
38 Èmi yóò si ṣa àwọn ọlọ̀tẹ̀ kúrò láàrín yín, àti àwọn o lù re òfin kọjá, èmi yóò mu wọn jáde kúrò ni ilẹ̀ tiwọn gbé ṣe àtìpó, wọn ki yóò si wọ ilẹ̀ Israẹli. Nígbà náà ní ẹ̀yin yóò mọ̀ pé, èmi ní Olúwa.
我必從你們中間除淨叛逆和得罪我的人,將他們從所寄居的地方領出來,他們卻不得入以色列地。你們就知道我是耶和華。
39 “‘Ní tí ẹ̀yin, ilé Israẹli, èyí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: Kí olúkúlùkù yín lọ máa sìn òrìṣà rẹ̀, ṣùgbọ́n lẹ́yìn èyí, ẹ̀yin yóò gbọ́ tèmi, ẹ̀yin kò sí ní i bá orúkọ mímọ́ mi jẹ́ pẹ̀lú ọrẹ àti àwọn òrìṣà yín mọ́.
「以色列家啊,至於你們,主耶和華如此說:從此以後若不聽從我,就任憑你們去事奉偶像,只是不可再因你們的供物和偶像褻瀆我的聖名。
40 Nítorí lórí òkè mímọ́ mi, lórí òkè gíga Israẹli, ni Olúwa Olódùmarè wí, níbẹ̀ ni ilẹ̀ náà ní gbogbo ilé Israẹli yóò sìn mí; èmi yóò sì tẹ́wọ́ gba wọ́n níbẹ̀. Níbẹ̀ èmi yóò béèrè ọrẹ àti ẹ̀bùn nínú àkọ́so yín pẹ̀lú gbogbo ẹbọ mímọ́ yín.
「主耶和華說:在我的聖山,就是以色列高處的山,所有以色列的全家都要事奉我。我要在那裏悅納你們,向你們要供物和初熟的土產,並一切的聖物。
41 Èmi yóò tẹ́wọ́ gbà yín gẹ́gẹ́ bí tùràrí olóòórùn dídùn nígbà tí mo ba mú yín jáde láàrín àwọn orílẹ̀-èdè tí a fọ́n yín ká sí, èmi yóò sì fi ìwà mímọ́ mi hàn láàrín yín lójú àwọn orílẹ̀-èdè.
我從萬民中領你們出來,從分散的列國內聚集你們,那時我必悅納你們好像馨香之祭,要在外邦人眼前在你們身上顯為聖。
42 Nígbà náà ni ẹ o mọ̀ pé èmi ní Olúwa, nígbà tí mo bá mú yín wa sí ilẹ̀ Israẹli; sí ilẹ̀ tí mo gbọ́wọ́ mí sókè nínú ẹ̀jẹ́ láti fún àwọn baba yín.
我領你們進入以色列地,就是我起誓應許賜給你們列祖之地,那時你們就知道我是耶和華。
43 Níbẹ̀ ni ẹ ó wa rántí ìwà àti gbogbo ìṣesí yín, èyí tí ẹ̀yin fi sọ ara yín di aláìmọ́, ẹ̀yin yóò sì kórìíra ara yín fún gbogbo ibi tí ẹ̀yin ti ṣe.
你們在那裏要追念玷污自己的行動作為,又要因所做的一切惡事厭惡自己。
44 Nígbà náà ní ẹ̀yin yóò mọ̀ pé, Èmi ni Olúwa, nígbà tí mo bá hùwà sí yín nítorí orúkọ mi ni, tí ń kò hùwà sí yín gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà ibi àti ìwà ìríra yín. Ẹ̀yin ilé Israẹli, ni Olúwa Olódùmarè wí.’”
主耶和華說:以色列家啊,我為我名的緣故,不照着你們的惡行和你們的壞事待你們;你們就知道我是耶和華。」
45 Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá:
耶和華的話臨到我說:
46 “Ọmọ ènìyàn, dojúkọ ìhà gúúsù; wàásù lòdì sí gúúsù kí ìwọ sì sọtẹ́lẹ̀ sí igbó ilẹ̀ gúúsù.
「人子啊,你要面向南方,向南滴下預言攻擊南方田野的樹林。
47 Sọ fún igbó ìhà gúúsù pé: ‘Gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa. Èyí ní ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: Kíyèsi í, èmi yóò dá iná kan nínú rẹ̀, yóò sì jó olúkúlùkù igi tútù nínú rẹ̀, àti olúkúlùkù igi gbígbẹ. Jíjò ọwọ́ iná náà ní kí yóò ṣé é pa, àti gbogbo ojú láti gúúsù dé àríwá ni a ó sun nínú rẹ̀.
對南方的樹林說,要聽耶和華的話。主耶和華如此說:我必使火在你中間着起,燒滅你中間的一切青樹和枯樹,猛烈的火焰必不熄滅。從南到北,人的臉面都被燒焦。
48 Gbogbo ènìyàn yóò sì mọ̀ pé, Èmi Olúwa ni ó dá a, a kì yóò sì le è pa á.’”
凡有血氣的都必知道是我-耶和華使火着起,這火必不熄滅。」
49 Nígbà náà ni mo wí pé, “Háà! Olúwa Olódùmarè! Wọn ń wí fún mi pé, ‘Kì í wa ṣe pé òwe lo ń pa bí?’”
於是我說:「哎!主耶和華啊,人都指着我說:他豈不是說比喻的嗎?」