< Ezekiel 2 >

1 Ó sọ fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, dìde dúró lórí ẹsẹ̀ rẹ. Èmi yóò bá ọ sọ̀rọ̀.”
ויאמר אלי בן אדם עמד על רגליך ואדבר אתך
2 Bí ó ṣe ń sọ̀rọ̀, ẹ̀mí sì wọ inú mi ó mú mi dúró lórí ẹsẹ̀ mi, mo sì ń gbọ́ tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀.
ותבא בי רוח כאשר דבר אלי ותעמדני על רגלי ואשמע את מדבר אלי
3 Ó sọ pé, “Ọmọ ènìyàn, mo ń rán ọ sí àwọn ọmọ Israẹli, sí ọlọ̀tẹ̀ orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti ṣọ̀tẹ̀ sí mi; àwọn àti baba ńlá wọn ti ṣọ̀tẹ̀ sí mi títí di òní olónìí.
ויאמר אלי בן אדם שולח אני אותך אל בני ישראל--אל גוים המורדים אשר מרדו בי המה ואבותם פשעו בי עד עצם היום הזה
4 Àwọn ènìyàn tí mo ń rán ọ sí jẹ́ aláìgbọ́ràn àti ọlọ́kàn líle. Sọ fún wọn pé, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí.’
והבנים קשי פנים וחזקי לב--אני שולח אותך אליהם ואמרת אליהם כה אמר אדני יהוה
5 Bí wọn fetísílẹ̀ tàbí wọn kò fetísílẹ̀ nítorí pé wọ́n ọlọ̀tẹ̀ ilé ni wọ́n—wọn yóò mọ̀ pé wòlíì kan wà láàrín wọn.
והמה אם ישמעו ואם יחדלו כי בית מרי המה--וידעו כי נביא היה בתוכם
6 Àti ìwọ, ọmọ ènìyàn, má ṣe bẹ̀rù wọn tàbí ọ̀rọ̀ ẹnu wọn. Má ṣe bẹ̀rù, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òṣùṣú àti ẹ̀gún yí ọ ká, tí o sì ń gbé àárín àwọn àkéekèe. Má ṣe bẹ̀rù ohun tí wọ́n ń sọ tàbí bẹ̀rù wọn, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọlọ̀tẹ̀ ìdílé ni wọ́n.
ואתה בן אדם אל תירא מהם ומדבריהם אל תירא כי סרבים וסלונים אותך ואל עקרבים אתה יושב מדבריהם אל תירא ומפניהם אל תחת כי בית מרי המה
7 Ìwọ gbọdọ̀ sọ ọ̀rọ̀ mi fún wọn, bí wọ́n gbọ́ bí wọn kọ̀ láti gbọ́ torí pé ọlọ̀tẹ̀ ni wọ́n.
ודברת את דברי אליהם אם ישמעו ואם יחדלו כי מרי המה
8 Ṣùgbọ́n ìwọ, ọmọ ènìyàn, gbọ́ ohun tí mo ń sọ fún ọ. Má ṣe ṣọ̀tẹ̀ bí i ti ìdílé ọlọ́tẹ̀; la ẹnu rẹ kí o sì jẹ ohun tí mo fún ọ.”
ואתה בן אדם שמע את אשר אני מדבר אליך--אל תהי מרי כבית המרי פצה פיך--ואכל את אשר אני נתן אליך
9 Mo sì wò, mo sì rí ọwọ́ kan tí a nà sí mi. Ìwé kíká sì wà níbẹ̀,
ואראה והנה יד שלוחה אלי והנה בו מגלת ספר
10 ó sì tú ìwé náà fún mi. Ní ojú àti ẹ̀yìn ìwé náà ni a kọ ìpohùnréré ẹkún, ọ̀fọ̀ àti ègún sí.
ויפרש אותה לפני והיא כתובה פנים ואחור וכתוב אליה קנים והגה והי

< Ezekiel 2 >