< Ezekiel 19 >
1 “Kọ orin ọ̀fọ̀ nítorí àwọn ọmọ-aládé Israẹli
“And you, lift up a lamentation to princes of Israel,
2 wí pé: “‘Èwo nínú abo kìnnìún ni ìyá rẹ̀ ní àárín àwọn kìnnìún yòókù? Ó sùn ní àárín àwọn ọ̀dọ́ kìnnìún ó sì ń tọ́jú àwọn ọmọ rẹ̀.
and you have said: What [is] your mother? A lioness, She has crouched down among lions, She has multiplied her whelps in the midst of young lions.
3 Ó sì tọ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọ rẹ̀ dàgbà, ó sì di kìnnìún tó ní agbára, ó kọ́ ọ láti ṣọdẹ, ó sì ń pa àwọn ènìyàn jẹ.
And she brings up one of her whelps, He has been a young lion, And he learns to tear prey, He has devoured man.
4 Àwọn orílẹ̀-èdè gbọ́ nípa rẹ̀, wọ́n sì fi ẹ̀wọ̀n mú un nínú iho wọn. Wọn fi ẹ̀wọ̀n mu nu lọ sí ilẹ̀ Ejibiti.
And nations hear of him, He has been caught in their pit, And they bring him to the land of Egypt in chains.
5 “‘Nígbà tí abo kìnnìún yìí rí pé ìrètí rẹ̀ sì jásí asán, ó mú ọmọ rẹ̀ mìíràn ó sì tún tọ́ ọ dàgbà di kìnnìún tó ní agbára.
And as she waited she sees that her hope has perished, And she takes one of her whelps, She has made him a young lion.
6 Ó sì ń rìn káàkiri láàrín àwọn kìnnìún nítorí pé ó ti lágbára, o kọ ọdẹ ṣíṣe, ó sì pa àwọn ènìyàn.
And he goes up and down in the midst of lions, He has been a young lion, And he learns to tear prey, He has devoured man.
7 Ó sì wó odi wọn palẹ̀ ó sì sọ àwọn ìlú wọn di ahoro. Ilẹ̀ náà àti àwọn olùgbé ibẹ̀ sì wà ní ìpayà nítorí bíbú ramúramù rẹ̀.
And he knows his forsaken habitations, And he has laid waste [to] their cities, And the land and its fullness is desolate, Because of the voice of his roaring.
8 Nígbà náà ni àwọn orílẹ̀-èdè dìde sí i, àwọn tó yìí ká láti ìgbèríko wá. Wọn dẹ àwọ̀n wọn fún un, wọn sì mú nínú ihò wọn.
And surrounding nations set against him from the provinces. And they spread out their net for him, He has been caught in their pit.
9 Wọn fi ìwọ̀ gbé e sínú àgò, wọn mú un lọ sí ọ̀dọ̀ ọba Babeli, wọn fi sínú ìhámọ́, a kò sì gbọ́ bíbú rẹ̀ mọ́ lórí òkè Israẹli.
And they put him in prison—in chains, And they bring him to the king of Babylon, They bring him into bulwarks, So that his voice is not heard On mountains of Israel anymore.
10 “‘Ìyá rẹ dàbí àjàrà nínú ọgbà àjàrà rẹ̀; tí á gbìn sí etí odò ó, kún fún èso, ó sì kún fún ẹ̀ka nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi.
Your mother, like the vine in your blood, Is being planted by waters, She was bearing fruit and full of boughs, Because of many waters.
11 Àwọn ẹ̀ka rẹ̀ lágbára tó láti fi ṣe ọ̀pá àṣẹ ìjòyè, ó ga sókè láàrín ewé rẹ̀, gíga rẹ̀ hàn jáde láàrín ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ka rẹ̀.
And she has strong rods for scepters of rulers, And she is high in stature above—between thick branches, And it appears in its height In the multitude of its thin shoots.
12 Ṣùgbọ́n ó fà á tu ní ìrunú, á sì wọ́ ọ lulẹ̀, afẹ́fẹ́ láti ìlà-oòrùn sì gbé èso rẹ̀, ọ̀pá líle rẹ̀ ti ṣẹ́, ó sì rọ iná sì jó wọn run.
And she is plucked up in fury, She has been cast to the earth, And the east wind has dried up her fruit, [The] rod of her strength has been broken and withered, Fire has consumed it.
13 Báyìí, a tún ún gbìn sínú aṣálẹ̀ ni ilẹ̀ gbígbẹ àti ilẹ̀ tó ń pòǹgbẹ omi.
And now she is planted in a wilderness, In a dry and thirsty land.
14 Iná sì jáde láti ọ̀kan lára ẹ̀ka rẹ̀ ó sì pa ẹ̀ka àti èso rẹ̀ run, dé bi pé kò sí ẹ̀ka tó lágbára lórí rẹ̀ mọ́; èyí to ṣe fi ṣe ọ̀pá fún olórí mọ́.’ Èyí ni orin ọ̀fọ̀ a o sì máa lo bí orin ọ̀fọ̀.”
And fire goes forth from a rod of her boughs, It has devoured her fruit, And she has no rod of strength—a scepter to rule, A lamentation—and she has become for a lamentation!”