< Ezekiel 10 >
1 Mo sì wò ó, mo rí ohun kan tó dàbí òkúta safire nínú òfúrufú tó wà lókè orí kérúbù, ìrísí ohun yìí sì dàbí ìtẹ́.
我观看,见基路伯头上的穹苍之中,显出蓝宝石的形状,仿佛宝座的形象。
2 Olúwa sì sọ fún ọkùnrin tó wọ aṣọ funfun pé, “Lọ sí àárín àwọn kẹ̀kẹ́ tó wà lábẹ́ kérúbù. Bu ẹyin iná tó kúnwọ́ rẹ láàrín kérúbù, kí o sì fọ́n sórí ìlú náà.” Ó sì lọ lójú mi.
主对那穿细麻衣的人说:“你进去,在旋转的轮内基路伯以下,从基路伯中间将火炭取满两手,撒在城上。” 我就见他进去。
3 Àwọn kérúbù dúró sí apá gúúsù tẹmpili nígbà tí ọkùnrin náà wọlé, ìkùùkuu sì bo inú àgbàlá.
那人进去的时候,基路伯站在殿的右边,云彩充满了内院。
4 Ògo Olúwa sì kúrò lórí àwọn kérúbù, ó bọ́ sí ibi ìloro tẹmpili. Ìkùùkuu sì bo inú tẹmpili, àgbàlá sì kún fún ìmọ́lẹ̀ àti ògo Olúwa.
耶和华的荣耀从基路伯那里上升,停在门槛以上;殿内满了云彩,院宇也被耶和华荣耀的光辉充满。
5 A sì gbọ́ ariwo ìyẹ́ àwọn kérúbù yìí títí dé àgbàlá tó wà ní ìta gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí Ọlọ́run Olódùmarè bá ń sọ̀rọ̀.
基路伯翅膀的响声听到外院,好像全能 神说话的声音。
6 Nígbà tí Olúwa pàṣẹ fún ọkùnrin aláṣọ funfun yìí pé, “Mú iná láàrín àwọn kẹ̀kẹ́, láàrín àwọn kérúbù,” ó sì lọ dúró ṣẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn kẹ̀kẹ́ náà.
他吩咐那穿细麻衣的人说:“要从旋转的轮内基路伯中间取火。”那人就进去站在一个轮子旁边。
7 Ọ̀kan nínú àwọn kérúbù sì nawọ́ sí ibi iná tó wà láàrín kérúbù yòókù. Ó mú lára rẹ, ó fi sínú ọwọ́ ọkùnrin aláṣọ funfun, òun náà gbà á, ó sì jáde lọ.
有一个基路伯从基路伯中伸手到基路伯中间的火那里,取些放在那穿细麻衣的人两手中,那人就拿出去了。
8 (Ohun tó dàbí ọwọ́ ènìyàn wà lábẹ́ ìyẹ́ àwọn kérúbù yìí.)
在基路伯翅膀之下,显出有人手的样式。
9 Nígbà tí mo sì wò, kíyèsí i, àwọn kẹ̀kẹ́ mẹ́rin wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn kérúbù yìí, kẹ̀kẹ́ kọ̀ọ̀kan wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ kérúbù kọ̀ọ̀kan; ìrí àwọn kẹ̀kẹ́ yìí ń tàn yanran bí àwọ̀ òkúta berili.
我又观看,见基路伯旁边有四个轮子。这基路伯旁有一个轮子,那基路伯旁有一个轮子,每基路伯都是如此;轮子的颜色仿佛水苍玉。
10 Ní ti ìrísí wọn, gbogbo wọn jọra wọn; ọ̀kọ̀ọ̀kan rí bí ìgbà tí kẹ̀kẹ́ kan wà nínú kẹ̀kẹ́ mìíràn.
至于四轮的形状,都是一个样式,仿佛轮中套轮。
11 Nígbà tí wọ́n ń lọ, wọ́n tẹ̀lé ọ̀kan nínú ọ̀nà mẹ́rin tí àwọn kérúbù dojúkọ; àwọn kẹ̀kẹ́ náà kò yípadà bí àwọn kérúbù ti ń lọ. Àwọn kérúbù ń lọ sí ibi tí orí dojúkọ láì yà.
轮行走的时候,向四方都能直行,并不掉转。头向何方,他们也随向何方,行走的时候并不掉转。
12 Gbogbo ara wọn àti ẹ̀yìn, ọwọ́ wọn àti ìyẹ́ wọn, àti àwọn kẹ̀kẹ́ kún fún ojú yíkákiri kẹ̀kẹ́, tí àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ní.
他们全身,连背带手和翅膀,并轮周围都满了眼睛。这四个基路伯的轮子都是如此。
13 Mo gbọ́ tí wọ́n pe àwọn kẹ̀kẹ́ yìí ni “kẹ̀kẹ́ àjà.”
至于这些轮子,我耳中听见说是旋转的。
14 Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn kérúbù yìí ni ojú mẹ́rin: ojú èkínní jẹ́ ojú kérúbù, ojú kejì jẹ́ ti ènìyàn, ojú kẹta jẹ́ ti kìnnìún nígbà tí ojú kẹrin jẹ́ ti ẹyẹ idì.
基路伯各有四脸:第一是基路伯的脸,第二是人的脸,第三是狮子的脸,第四是鹰的脸。
15 A gbé àwọn kérúbù sókè. Èyí ni àwọn ẹ̀dá alààyè tí mo rí létí odò Kebari.
基路伯升上去了;这是我在迦巴鲁河边所见的活物。
16 Bí àwọn kérúbù yìí bá ń lọ àwọn kẹ̀kẹ́ ẹgbẹ́ wọn náà yóò lọ; bẹ́ẹ̀ ni bí àwọn kérúbù bá tú ìyẹ́ wọn ká láti dìde nílẹ̀, àwọn kẹ̀kẹ́ yìí kò ní kúrò lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn.
基路伯行走,轮也在旁边行走。基路伯展开翅膀,离地上升,轮也不转离他们旁边。
17 Bí àwọn kérúbù bá dúró díẹ̀ àwọn kẹ̀kẹ́ náà yóò dúró jẹ́ẹ́; bí àwọn kérúbù bá dìde àwọn kẹ̀kẹ́ náà yóò dìde, nítorí pé ẹ̀mí àwọn ẹ̀dá alààyè yìí wà nínú wọn.
那些站住,这些也站住;那些上升,这些也一同上升,因为活物的灵在轮中。
18 Ògo Olúwa kúrò níbi ìloro tẹmpili, ó sì dúró sórí àwọn kérúbù.
耶和华的荣耀从殿的门槛那里出去,停在基路伯以上。
19 Àwọn kérúbù gbé ìyẹ́ wọn sókè, wọ́n sì fò kúrò nílẹ̀ lójú mi, wọ́n sì lọ pẹ̀lú kẹ̀kẹ́ wọn lẹ́ẹ̀kan náà. Wọ́n dúró níbi ìlẹ̀kùn ẹnu-ọ̀nà ìlà-oòrùn ilé Olúwa, ògo Ọlọ́run Israẹli sì wà lórí wọn.
基路伯出去的时候,就展开翅膀,在我眼前离地上升。轮也在他们的旁边,都停在耶和华殿的东门口。在他们以上有以色列 神的荣耀。
20 Àwọn wọ̀nyí ni ẹ̀dá alààyè tí mo rí lábẹ́ Ọlọ́run Israẹli létí odò Kebari, mo sì mọ̀ pé kérúbù ni wọ́n.
这是我在迦巴鲁河边所见、以色列 神荣耀以下的活物,我就知道他们是基路伯。
21 Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní ojú mẹ́rin àti ìyẹ́ mẹ́rin, lábẹ́ ìyẹ́ wọn ni ohun tó jọ ọwọ́ ènìyàn wà.
各有四个脸面,四个翅膀,翅膀以下有人手的样式。
22 Àfiwé ojú àti ìrísí wọn rí bákan náà pẹ̀lú àwọn tí mo rí létí odò Kebari. Olúkúlùkù wọn sì ń lọ sí ọ̀kánkán tààrà.
至于他们脸的模样,并身体的形象,是我从前在迦巴鲁河边所看见的。他们俱各直往前行。