< Exodus 9 >

1 Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mose pé, “Lọ sọ fún Farao, ‘Èyí ni Olúwa Ọlọ́run àwọn Heberu sọ, “Jẹ́ kí àwọn ènìyàn Mi kí ó lọ, kí wọn bá à lè sìn Mí.”
آنگاه خداوند به موسی فرمود: «نزد فرعون بازگرد و به او بگو که خداوند، خدای عبرانی‌ها می‌فرماید: قوم مرا رها کن تا بروند و مرا عبادت کنند،
2 Bí ìwọ bá kọ̀ láti jẹ́ kí wọn ó lọ, tí ó sì dá wọn dúró.
اگر همچنان آنها را نگه‌داری و نگذاری بروند
3 Ọwọ́ Olúwa yóò mú ààrùn búburú wá sí ara ẹran ọ̀sìn nínú oko, sí ara ẹṣin, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ìbákasẹ, màlúù, àgùntàn àti ewúrẹ́ yín.
بدان که دست خداوند تمام دامهایتان را از گله‌های اسب، الاغ، شتر، گاو و گوسفند، به مرضی جانکاه دچار خواهد کرد.
4 Ṣùgbọ́n Olúwa yóò pààlà sí àárín ẹran ọ̀sìn tí ó jẹ́ ti Israẹli àti ti àwọn ara Ejibiti tí yóò fi jẹ́ pé kò sí ẹran ọ̀sìn ti ó jẹ́ ti ará Israẹli tí yóò kùú.’”
من بین گله‌های مصری‌ها و گله‌های اسرائیلی‌ها فرق خواهم گذاشت، به طوری که به گله‌های اسرائیلی‌ها هیچ آسیبی نخواهد رسید.
5 Olúwa sì dá àkókò kan wí pé, “Ní ọ̀la ni Olúwa yóò ṣe èyí ni ilẹ̀ yìí.”
من این بلا را فردا بر شما نازل خواهم کرد.»
6 Olúwa sí ṣe é ni ọjọ́ kejì. Gbogbo ẹran ọ̀sìn ará Ejibiti kú, ṣùgbọ́n ẹyọ kan kò kú lára ẹran ọ̀sìn àwọn Israẹli.
روز بعد، خداوند همان‌طور که فرموده بود، عمل کرد. تمام گله‌های مصری‌ها مردند، ولی از چارپایان بنی‌اسرائیل حتی یکی هم تلف نشد.
7 Farao rán àwọn ènìyàn rẹ̀ láti lọ ṣe ìwádìí, wọ́n sì rí pé ẹyọ kan kò kú lára àwọn ẹran ọ̀sìn ará Israẹli. Síbẹ̀ náà, Farao kò yí ọkàn rẹ̀ padà àti pé kò jẹ́ kí àwọn ènìyàn ó lọ.
پس فرعون مأموری فرستاد تا تحقیق کند که آیا صحت دارد که از چارپایان بنی‌اسرائیل هیچ‌کدام نمرده‌اند. با این حال وقتی فهمید موضوع حقیقت دارد باز دلش نرم نشد و قوم خدا را رها نساخت.
8 Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mose àti Aaroni, “Ẹ bu ẹ̀kúnwọ́ eérú gbígbóná láti inú ààrò, kí Mose kù ú sí inú afẹ́fẹ́ ni iwájú Farao.
پس خداوند به موسی و هارون فرمود: «مشتهای خود را از خاکستر کوره پر کنید و موسی آن خاکستر را پیش فرعون به هوا بپاشد.
9 Yóò sì di eruku lẹ́búlẹ́bú ni gbogbo ilẹ̀ Ejibiti, yóò sì di oówo ti ń tú pẹ̀lú ìléròrò sí ara àwọn ènìyàn àti ẹran jákèjádò gbogbo ilẹ̀ Ejibiti.”
آنگاه آن خاکستر مثل غبار، سراسر خاک مصر را خواهد پوشانید و بر بدن انسان و حیوان دملهای دردناک ایجاد خواهد کرد.»
10 Nígbà náà ni wọ́n bú eérú gbígbóná láti inú ààrò, wọ́n dúró ní iwájú Farao. Mose sì ku eérú náà sínú afẹ́fẹ́, ó sì di oówo tí ń tú pẹ̀lú ìléròrò ni ara àwọn ènìyàn àti lára ẹran.
پس آنها خاکستر را برداشتند و به حضور فرعون ایستادند. موسی خاکستر را به هوا پاشید و روی بدن مصری‌ها و حیواناتشان دملهای دردناک درآمد،
11 Àwọn onídán kò le è dúró níwájú Mose nítorí oówo ti ó wà lára wọn àti ni ara gbogbo àwọn ara Ejibiti.
چنانکه جادوگران هم نتوانستند در مقابل موسی بایستند، زیرا آنها و تمام مصریان به این دملها مبتلا شده بودند.
12 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run sé ọkàn Farao le, kò sì gbọ́ ti Mose àti Aaroni, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti sọ fún Mose.
اما خداوند همان‌طور که قبلاً به موسی فرموده بود، دل فرعون را سخت کرد و او به سخنان موسی و هارون اعتنا ننمود.
13 Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mose pé, “Dìde ni òwúrọ̀ kùtùkùtù, kí o sì tọ Farao lọ, kí o sì wí fún un pé, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run àwọn Heberu wí, Jẹ́ kí àwọn ènìyàn mi kí ó lọ, kí wọn bá à lè sìn mí,
آنگاه خداوند به موسی فرمود: «صبح زود برخیز و در برابر فرعون بایست و بگو که خداوند، خدای عبرانی‌ها می‌فرماید: قوم مرا رها کن تا بروند و مرا عبادت کنند،
14 nítorí nígbà yìí ni èmi yóò rán àjàkálẹ̀-ààrùn ti ó ní agbára gidigidi sí ọ, sí àwọn ìjòyè rẹ àti sí àwọn ènìyàn rẹ, kí ìwọ kí ó lè mọ̀ pé, kò sí ẹni bí èmi ni gbogbo ayé.
و گرنه این بار بلایای بیشتری بر سر تو و درباریان و قومت خواهم آورد تا بدانید در تمامی جهان خدایی مانند من نیست.
15 Ó ti yẹ kí n ti na ọwọ́ mi jáde láti kọlù ọ́ àti àwọn ènìyàn rẹ pẹ̀lú ààrùn búburú ti kò bá ti run yín kúrò ni orí ilẹ̀.
من تا حالا می‌توانستم دست خود را دراز کنم و چنان بلایی بر سر تو و قومت بیاورم که از روی زمین محو شوید.
16 Ṣùgbọ́n nítorí èyí ni èmi ṣe mú ọ dúró, kí èmi kí ó le fi agbára mi hàn lára rẹ, àti kí a bá à le máa ròyìn orúkọ mi ká gbogbo ayé.
ولی تو را به این منظور زنده نگاه داشتم تا قدرت خود را به تو ظاهر کنم و تا نام من در میان تمامی مردم جهان شناخته شود.
17 Síbẹ̀ ìwọ tún gbógun ti àwọn ènìyàn mi, ìwọ kò sì jẹ́ kí wọn lọ.
آیا هنوز هم مانع قوم من می‌شوی و نمی‌خواهی رهایشان کنی؟
18 Nítorí náà, ni ìwòyí ọ̀la, Èmi yóò rán òjò o yìnyín tí irú rẹ̀ kò tí i rọ̀ rí ni Ejibiti láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ títí di àkókò yìí.
بدان که فردا در همین وقت چنان تگرگی از آسمان می‌بارانم که در تاریخ مصر سابقه نداشته است.
19 Pàṣẹ nísinsin yìí láti kó ẹran ọ̀sìn yín àti ohun gbogbo ti ẹ ni ní pápá wá sí abẹ́ ààbò, nítorí òjò yìnyín yóò rọ̀ sí orí àwọn ènìyàn àti ẹran ti a kò kó wá sí abẹ́ ààbò tí wọ́n sì wà ni orí pápá, wọn yóò sì kú.’”
پس دستور بده تمام حیوانات و آنچه را که در صحرا دارید جمع کنند و به خانه‌ها بیاورند، پیش از آنکه تگرگ تمام حیوانات و اشخاصی را که در صحرا مانده‌اند از بین ببرد.»
20 Àwọn ti ó bẹ̀rù ọ̀rọ̀ Olúwa lára àwọn ìjòyè Farao yára lọ láti kó àwọn ẹrú àti àwọn ẹran ọ̀sìn wọn wá sí abẹ́ ààbò.
بعضی از درباریان فرعون از این اخطار خداوند ترسیدند و چارپایان و نوکران خود را به خانه آوردند.
21 Ṣùgbọ́n àwọn ti kò kà ọ̀rọ̀ Olúwa sí fi àwọn ẹrú wọn àti àwọn ẹran ọ̀sìn wọn sílẹ̀ ni pápá.
ولی دیگران به کلام خداوند اعتنا نکردند و حیوانات و نوکران خود را همچنان در صحرا باقی گذاشتند.
22 Olúwa sọ fún Mose pé, “Gbé ọwọ́ rẹ sókè sí ọ̀run kí yìnyín bá à lè rọ̀ sí orí gbogbo ilẹ̀ Ejibiti, sí orí ènìyàn àti ẹranko, àti sí orí gbogbo ohun ọ̀gbìn tí ó wà ni inú oko.”
آنگاه خداوند به موسی فرمود: «دستت را به سوی آسمان دراز کن تا بر تمامی مصر تگرگ ببارد، بر حیوانات و گیاهان و بر تمامی مردمی که در آن زندگی می‌کنند.»
23 Nígbà tí Mose gbé ọ̀pá rẹ̀ sókè sí ojú ọ̀run, Olúwa rán àrá àti yìnyín, mọ̀nàmọ́ná sì bùsi orí ilẹ̀. Olúwa rọ òjò yìnyín sí orí ilẹ̀ Ejibiti.
پس موسی عصای خود را به سوی آسمان دراز کرد و خداوند رعد و تگرگ فرستاد و صاعقه بر زمین فرود آورد.
24 Yìnyín rọ̀, mọ̀nàmọ́ná sì bẹ̀rẹ̀ sí bùsi orí ilẹ̀ èyí ni ó tí ì burú jù ti ó ṣẹlẹ̀ láti ìgbà ti Ejibiti ti di orílẹ̀-èdè.
در تمام تاریخ مصر کسی چنین تگرگ و صاعقهٔ وحشتناکی ندیده بود.
25 Jákèjádò gbogbo ilẹ̀ Ejibiti ni yìnyín ti pa gbogbo ohun tí ó wà ni orí pápá; ènìyàn àti ẹranko, ó wò gbogbo ohun ọ̀gbìn lulẹ̀ ó sì fa gbogbo igi ya pẹ̀lú.
در سراسر مصر، تگرگ هر چه را که در صحرا بود زد، انسان و حیوان را کشت، نباتات را از بین برد و درختان را در هم شکست.
26 Ilẹ̀ Goṣeni ni ibi ti àwọn Israẹli wà nìkan ni òjò yìnyín náà kò rọ̀ dé.
تنها جایی که از بلای تگرگ در امان ماند، سرزمین جوشن بود که بنی‌اسرائیل در آن زندگی می‌کردند.
27 Nígbà náà ni Farao pe Mose àti Aaroni sì ọ̀dọ́ rẹ̀, ó sì wí fún wọn pé, “Èmi ti ṣẹ̀ ní àkókò yìí; Olúwa jẹ́ olódodo ṣùgbọ́n èmi àti àwọn ènìyàn mi ni aláìṣòdodo.
پس فرعون، موسی و هارون را به حضور خواست و به ایشان گفت: «من به گناه خود معترفم. حق به جانب خداوند است. من و قومم مقصریم.
28 Èyí ti òjò yìnyín àti àrá rọ̀ yìí tó gẹ́ẹ́, gbàdúrà sí Olúwa kí ó dáwọ́ rẹ̀ dúró. Èmi yóò jẹ́ kí ẹ lọ, n kò tún ni dá a yín dúró mọ́.”
حال از خداوند درخواست کنید تا این رعد و تگرگ وحشتناک را بازدارد. دیگر بس است! من هم اجازه خواهم داد بروید؛ لازم نیست بیش از این اینجا بمانید.»
29 Mose dá a lóhùn pé, “Bí mo bá ti jáde kúrò ní àárín ìlú, èmi yóò gbé ọwọ́ mi sókè sí Olúwa, sísán àrá yóò dáwọ́ dúró, yìnyín kò sì ni rọ̀ mọ́, kí ìwọ kí ó lè mọ̀ pé Olúwa ni ó ni ilẹ̀.
موسی گفت: «بسیار خوب، به محض اینکه از شهر خارج شوم دستهای خود را به سوی خداوند دراز خواهم کرد تا رعد و تگرگ تمام شود تا بدانی که جهان از آن خداوند است.
30 Ṣùgbọ́n èmi mọ̀ pé síbẹ̀síbẹ̀ ìwọ àti àwọn ìjòyè rẹ kò bẹ̀rù Olúwa Ọlọ́run.”
ولی می‌دانم که تو و افرادت باز هم از یهوه خدا اطاعت نخواهید کرد.»
31 (A sì lu ọ̀gbọ̀ àti ọkà barle bolẹ̀; nítorí barle wà ní ìpẹ́, ọ̀gbọ̀ sì rudi.
(آن سال تگرگ تمام محصولات کتان و جو را از بین برد، چون ساقهٔ جو خوشه کرده و کتان شکوفه داده بود،
32 Alikama àti ọkà ni a kò lù bolẹ̀, nítorí tí wọ́n kò tí ì dàgbà.)
ولی گندم از بین نرفت، زیرا هنوز جوانه نزده بود.)
33 Nígbà náà ni Mose jáde kúrò ni iwájú Farao, ó kúrò ni àárín ìgboro kọjá lọ sí ẹ̀yìn odi ìlú, ó sì gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè sí Olúwa, sísán àrá àti òjò yìnyín ti ń rọ̀ sì dáwọ́ dúró, òjò kò sì rọ̀ sí orí ilẹ̀ mọ́.
موسی قصر فرعون را ترک کرد و از شهر بیرون رفت و دستهایش را به سوی خداوند بلند کرد و رعد و تگرگ قطع شد و باران بند آمد.
34 Nígbà tí Farao rí i pé òjò àti yìnyín àti àrá ti ń sán ti dáwọ́ dúró, ó tún ṣẹ̀ ní ẹ̀ẹ̀kan sí i. Òun àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ṣì sé àyà wọn le.
ولی وقتی فرعون دید باران و تگرگ و رعد قطع شده، او و درباریانش باز گناه ورزیده، به سرسختی خود ادامه دادند.
35 Àyà Farao sì le, bẹ́ẹ̀ ni kò sì jẹ́ kí àwọn ọmọ Israẹli kí ó lọ, bí Olúwa ti sọ láti ẹnu Mose.
پس همان‌طور که خداوند توسط موسی فرموده بود، دل فرعون سخت شد و این بار هم بنی‌اسرائیل را رها نکرد.

< Exodus 9 >